cultura-x-deduped-yoruba / deduplicated_output.json
mxronga's picture
Upload deduplicated_output.json
ad80a09 verified
raw
history blame contribute delete
No virus
106 kB
{"text": "Iye owó ọjà Bitcoin lọwọlọwọ máa ń wà ni imudojuiwọn ní gbogbo ìṣẹjú 3 àti pé USD ni ó jẹ́ orísun tí ó wà ní sẹpẹ́ fún ìsirò rẹ̀. Àwọn ìdíyelé Bitcoin ní àwọn kọ́rẹ́ńsì mííràn dà lórí àwọn ìwọ́n pàsípààrọ̀ USD tí ó báamu. Ní ìsàlẹ, ìwọ yóò tún rí àwọn iye ṣíṣẹ́ owó tí ó gbajúmọ ní àwọn AFN", "timestamp": "2022-11-30T06:54:11Z", "url": "https://paxful.com/yo/calculator/btc-to-AFN", "source": "OSCAR-2301"}
{"text":"Nísàlẹ̀ ni àtòjọ àwọn àjápọ̀ mọ́ àwọn ibiìtakùn míràn tí wọ́n únta ìwé tuntun àti ìwé àtijọ́, wọ́n sì le ní ọ̀rọ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa àwọn ìwé tí ẹ únwá:","timestamp":"2022-11-28T08:20:42Z","url":"https:\/\/yo.m.wikipedia.org\/wiki\/P%C3%A0t%C3%A0k%C3%AC:BookSources\/1576078000","source":"OSCAR-2301"}
{"text": "Iye owó ọjà Bitcoin lọwọlọwọ máa ń wà ni imudojuiwọn ní gbogbo ìṣẹjú 3 àti pé USD ni ó jẹ́ orísun tí ó wà ní sẹpẹ́ fún ìsirò rẹ̀. Àwọn ìdíyelé Bitcoin ní àwọn kọ́rẹ́ńsì mííràn dà lórí àwọn ìwọ́n pàsípààrọ̀ USD tí ó báamu. Ní ìsàlẹ, ìwọ yóò tún rí àwọn iye ṣíṣẹ́ owó tí ó gbajúmọ ní àwọn MUR", "timestamp": "2022-11-28T20:50:39Z", "url": "https://paxful.com/yo/calculator/btc-to-mur", "source": "OSCAR-2301"}
{"text": "Àwọn oníṣe ìmúdájú fùnrawọn jẹ́ àwọn oníṣẹ́ tí ó ti tó ọjọ́ mẹrin tí wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ tí wọ́n s̀ì ti ṣe àtúnṣe bíi mẹ́wá sí àwọn àyọ́kà. A lè gbẹ̀rí àwọn oníṣẹ́ yí jẹ́ díẹ̀ wípé wọn kò lè dojú àwọn àyọkà rú.", "timestamp": "2021-03-01T17:46:56Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Wikipedia:%C3%80w%E1%BB%8Dn_on%C3%AD%E1%B9%A3e_%C3%ACm%C3%BAd%C3%A1j%C3%BA_f%C3%B9nraw%E1%BB%8Dn", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ni àkójọpọ̀ àwọn ìfihàn àtọ̀runwá àti àwọn ìkéde tí ó ní ìmísí ti a fúnni fún ìdásílẹ̀ àti ìlànà ti ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn ìpín náà jẹ́ àwọn tí a darí wọn sí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn, àwọn ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́, àwọn ìkìlọ̀, àti àwọn ìyànjú tí ó wà fún ire gbogbo aráyé ó sì jẹ́ ìpè sí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti gbọ́ ohùn Olúwa Jésù Krístì, tí ó nsọ̀rọ̀ sí wọn fún wíwà ní àlãfíà ti ara àti ìgbàlà ayérayé wọn.", "timestamp": "2021-12-08T19:37:17Z", "url": "https://www.churchofjesuschrist.org/study/scriptures/dc-testament?lang=yor", "source": "OSCAR-2201"}
{"text": "A dá sílè fún àwọn ènìyàn tí wọn fẹ́ràn láti mò nípa èdè Yorùbá, àṣà àti ìṣe ilẹ̀ kóòtù ojire. Kíkó àwọn ọmọ wa ni Èdè Yorùbá", "timestamp": "2021-03-07T12:45:52Z", "url": "https://edeyorubarewa.com/itelorun/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn onímọ̀ nípa èdè ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ sọ wí pé kí ìlọsíwájú ó tó dé bá Ilẹ̀ Adúláwọ̀, ó pọn dandan kí ó ní ìlànà ìṣọwọ́ kọ èdè tàbí ìlànà kíkọ tí ó jẹ́ tirẹ̀. Èdè tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí Niger-Congo tí ó jẹ́ èdè ìran tí ó ti wà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ tí ó sì lajú bí èdè Yorùbá ò gbọdọ̀ gbọ́kàn tẹ ìlànà àyálò fún kíkọ èrò àti ìmọ̀ ìrírí ayé rẹ̀.\nÀwọn alágbàwí èdè gbà wí pé lílo ìlànà Látíìnì, tí ó jẹ́ ìṣọwọ́kọ láti ilẹ̀ òkèèrè, fún kíkọ àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ sílẹ̀, fi ilẹ̀ náà sínú ipò ẹrú.", "timestamp": "2021-03-02T00:50:43Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2020/03/10/608/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìpínlẹ̀ Imo ni wọ́n dá sílẹ̀ ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún 1976, àwọn Àtòjọ àwọn Gómìnà Gómìnà tí wọ́n ti ja ní Ìpínlẹ̀ naa:", "timestamp": "2021-02-28T00:49:44Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Ipinle_Imo", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn igbimọ yìí là gbọ pé wọn yóò ṣe ìwádìí láti mọ iye àwọn nǹkan táwọn tọọgi bajẹ fún ìjọba láti pèsè owó iranwọ fún wọn, kí ọjà wọn lé túbọ̀ padà bọ̀ sípò tó wà tẹ́lẹ̀.", "timestamp": "2021-03-07T23:56:55Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/11/leyin-rogbodiyan-iwode-ifehonuhan.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Nínú àwọn èèyàn náà sọ pé àwọn eleto ìlera tí gba ayẹwo lára wọn, tí wọn sì ti fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé àwọn kò ní àrùn aṣekupani Covid-19 tí wọn ń pariwo.", "timestamp": "2021-03-05T04:55:34Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/e-gba-wa-lowo-awon-soja-o-awon-omo.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "4Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, 51.5,18: If 4.6.àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, 6ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin. 7Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán. 8Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, 9ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.\n19Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè. 20Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn. 21Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́.", "timestamp": "2021-02-27T10:29:34Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/tncv/%E0%B9%80%E0%B8%AD%E0%B9%80%E0%B8%AA%E0%B9%80%E0%B8%84%E0%B8%B5%E0%B8%A2%E0%B8%A5/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "17Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìṣirò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.", "timestamp": "2021-02-24T23:40:16Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/cro/hebrejima/13/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìpínlẹ̀ Rivers tí a tún mọ̀ bíi Rivers, ni ìkan nínú àwọn ìpínlẹ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà 36. Gẹ́gẹ́ bí dátà ìkanìyàn tó jáde ní ọdún 2006 ṣe fihàn, ìpínlẹ̀ náà ní iye ènìyàn 5,198,716, èyí sọ ọ́ di ìpínlẹ̀ tó ní iye èniyàn púpọ̀jùlọ kẹfà ní Nàìjíríà.[5] Olúìlú àti ìlú tótóbijùlọ rẹ̀ ni Port Harcourt. Ìlú Port Harcourt ní Nàìjíríà gẹ́gẹ́bí gbọ̀ngàn àwọn ilé-iṣẹ́ epo. Ìpínlẹ̀ Rivers jámọ́ Òkun Atlantiki ní gúúsù, ó ní bodè mọ́ àwọn ìpínlẹ̀ Imo and Abia ní àríwá, ìpílẹ̀ Akwa Ibom ní ìlàòrùn, àti àwọn ìpínlẹ̀ Bayelsa àti Delta ní ìwọ̀òrùn. Ìpínlẹ̀ Rivers ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà tí nínú wọn ni: àwọn Ikwerre, àwọn Ijaw, àwọn Ògóni àti àwọn ẹ̀yà púpọ̀ míràn. Orúkọ fún àwọn ará ìpínlẹ̀ yìí ni \"Riverians\" tàbi \"àwọn ará Rivers\".[6][7]", "timestamp": "2021-02-25T01:59:07Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Rivers_State", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "\"Gbenga Adeboye tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ wí pé àwọn kan nínú àwọn sọrọsọrọ ẹgbẹ́ wá yóò dìde lòdì sí mi lori àwọn nǹkan tòun ń sọ nípa mi, ó sì dárúkọ àwọn méjì. Ẹni kínní nínú àwọn méjèèjì yìí ló rán àwọn agbanipa sì mi lọ́dún 2011, ṣùgbọ́n tí orí kò mi yọ.", "timestamp": "2021-03-03T10:53:10Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/asotele-gbenga-adeboye-ni-ko-je-kawon.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lónìí, Gómìnà Oyetọla ni àwọn tó wà a kọlu òun kì í ṣe àwọn ọdọ tó ń fẹhonu hàn rárá, nítorí pé àwọn ọdọ tó ń jà fún ẹtọ wọn jẹ ẹni tó ń tẹle òfin orílẹ̀ èdè yìí.", "timestamp": "2021-02-24T17:08:13Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/10/gomina-oyetola-tu-asiri-awon-toogi-to.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ọ̀pọ ẹ̀mí ló sọnù sí ìkọlù láàrín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ẹlẹ́sìn Shia tí wọ́n ń pè fún ìtúsílẹ̀ adarí wọn, EL-Zakzaky.", "timestamp": "2021-03-05T21:18:47Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/media-49134255", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Babajide ṣe àwọn ìlérí yìí lásìkò to sàbẹ̀wò sí olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìlú Ikeja láti báwọn sọ̀rọ̀ ìwúrí.\n\"Pàtàkì jùlọ nínú àwọn ìwé ẹ̀bẹ̀ ọlọ́pàá ní fífún àwọn ọmọ ọlọ́pàá tó d'olóògbé ni ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́, mo si ti dári àjọ tó n mójú tó ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ nípìnlẹ̀ Eko láti fún gbogbo àwọn ọmọ wọ́n ni ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́.", "timestamp": "2021-03-05T01:46:15Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/10/endsars-gomina-sanwo-olu-kede-eko-ofe.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn Aládùgbóò tó báwọn akọròyìn ṣọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé géètì tó wà lẹ́yìn làwọn olè bá wọlé, wọ́n ní láago mẹ́rin ìdájí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà táwọn ẹṣọ tó wà nínú ilé náà ti sùn lọ.", "timestamp": "2021-02-28T07:10:22Z", "url": "http://asa.ooduarere.com/a%E1%B9%A3a-yoruba/w-lpaa-t-awn-to-fle-e-mko/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Kò sài tún kan sárá sí Gómìnà lórí bó se gbọ́rọ̀ àwọn òsìsẹ́ tíjọba tọ́kọjá gbasẹ́ lọ́wọ́ wọn yẹ̀wò, tó sì fún wọn nísẹ́ padà.", "timestamp": "2021-02-28T19:37:14Z", "url": "https://radionigeriaibadan.gov.ng/2019/08/07/egbe-osise-ipinle-oyo-so-isepataki-owo-osu-tuntun/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ní àarin odún (1960) sí Ọdún (1996) àwọn tí ó n sọ èdè yìí dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù mọ́kànlá. Àkọtọ́ èdè wọn muná dóko; ṣùgbọ́n wọn kìí lo àmì ohùn lórí gbogbo ọ̀rọ̀ wọn. Àkọtọ wọn tó wuyì yìí lo mú kí ohun èdè wọn dín kù ní lílò.\nKongo tàbí Kikongo – ó jẹ́ èdè Bantu, àwọn ènìyàn Bakongo ni wọn ń sọ ọ́. Ààrin ilẹ̀ Afíríkà ni ó wà. Àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù méje ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n kó ní ẹrú ní ilẹ̀ Afíríkà tí wọ́n sì tà wọ́n fún America ni wọ́n ń sọ èdè yìí. Àwọn bí i mílíọ̀nù ni wọ́n ń lo èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè méjì.", "timestamp": "2021-02-27T09:42:48Z", "url": "https://yo.m.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8_K%C3%B3ng%C3%B2", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, àwọn ọmọ ojú ogún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn àwọn ṣọja ni wọn ti wá ní imurasilẹ láti kọjú ìjà sí àwọn afurasi ọ̀daràn wọn ní wón fẹẹ dá wàhálà ńlá nipinlẹ Kwara.", "timestamp": "2021-03-01T22:52:57Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/07/ogun-fun-ogun-awon-soja-ree-loju-ogun.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Eléyìí jẹ́ àṣà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá fi máa nkọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré, bí àwọn ọmọ bá ti lè mọ̀ àṣà yìí, kò sí ẹni tí ó lè gbà a ́ lọ́wọ́ wọn mọ́, àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá máa nṣe ògo púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ilé tí wọ́n tètè máa ńfi kọ́ àwọn ọmọ wọn, ṣé Yorùbá bọ̀: wọ́n ní àti kékeré ni a ti npẹ̀ka ìrókò, nítorí tí ó bá ti dàgbà tán kí ó má bàá gbẹ̀bọ lọ́wọ́ ẹni.\nBí ọmọdékùnrin bá ti jí ní òwúrọ̀, ó di dandan kí ó dọ̀bálẹ̀ gbọọrọ láti kí àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ọmọdébìnrin náà gbọ́dọ̀ kúnlẹ̀ pẹ̀lú orúnkún rẹ̀ méjèèjì ní ilẹ̀, àwọn òbí ẹni nìkan kọ́ ni a máa nkí ní ilẹ̀ Yorùbá; gbogbo àwọn àgbàlagbà àti àwọn tí ó junilọ ni a gbọ́dọ̀ kí bákan náà pẹ̀lú, irú ọmọ tí ó bá ní irú ìwà yìí ni a npè ní ọmọ tí ó ní Ẹ̀kọ́ ilé.\nKò sí àkókò tí ó wà tí àwọn ọmọ káárọ̀ oòjíire kò ní ìkíni fún, wọ́n tún ní àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ngbà kí ọba àti àwọn ìjòyè ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí ó yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn yòókù. Fún àpẹẹrẹ, a máa ńkí ọba ilú báyìí pé:", "timestamp": "2021-03-05T07:55:48Z", "url": "https://englishtoyoruba.com/a%E1%B9%A3a-ikini-tabi-eko-ile/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ní Ǹjẹ́ mo kéré? àwọn òǹkàwé àtèwe-àtàgbà bákan náà tẹ̀ lé ọmọbìnrin náà Tamia rin ìrìn àjò tó kún fún àwọn ohun ìyanu. Wọ́n jọ ṣàwárí pé ìwọ̀n ní ààlà àti pé Tamia tọ̀nà gan-an lọ́nà tó wá. “Alárinrin” ni ìdájọ́ ìwé ìròyìn ìṣòwò Eselsohr, “àgbàyanu gidigidi fún àwọn ìdílé elédè méjì, àti àwọn ọmọ ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi,” ni Börsenblatt sọ àti ìwé ìròyìn alàtúnyẹ̀wò náà Kirkus Reviews fohùn jẹ́jẹ́ ṣe àpọ́nlé “fún àwọn ọmọdé tí wọ́n gbádùn láti máa dúró lórí ojú ìwé tó kún fún àwọn ẹ̀dá onídán àti àwọn àlàyé aibọgbọnmu [...]tí wọ́n sọ ni àwọn ọ̀rọ̀ ṣókí àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbà ni lọ́kàn àti àwọn àwòrán ìdánúṣe.” Kà á síwájú síi…", "timestamp": "2021-03-02T01:47:16Z", "url": "https://www.philippwinterberg.com/yo/books.php", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Bi wọn ṣe fáwọn aráàlú, pàápàá àwọn tó kú díẹ̀ kaato fún n'ipinlẹ Ogun, bẹ́ẹ̀ ni wọn fáwọn èèyàn ni Èkó, Ọ̀yọ́ àti bẹẹ bẹẹ lọ.", "timestamp": "2021-03-05T04:21:43Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/soosi-mfm-gbarada-won-f-araalu-lounje.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Wọn le fún ọ ní àlàyé tí kò tọ́ ní ilé ìta òògùn, àwọn oníṣègùn náà sì le fún ọ. Ìhámọ́ oyún sísẹ́ láwùjọ ní àwọn ibìkan ńfa àròsọ àti àlàyé tí kò tọ́ ní agbègbè kọ̀ọ̀kan, láàrín àwọn òṣìṣẹ́ pàápàá.\nÀwọn olùdámọ̀ràn wa kẹ́kọ̀ọ́ gboyè, wọn kò sì fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ fún wọn nípa lílo òògùn ìsẹ́yún àti bí wọ́n ṣe ń lòó. A máń tèlé ìlànà ètò àjọ ìlera àgbáyé. Bí ó bá ṣe pàtàkì, a lè tọ́ka rẹ sí àjọ tí ó ṣeé fokàń tán tí ó le ràn ó lọ́wọ́ láti rí oògùn ìsẹ́yún, tàbí wá àlàyé ní agbègbè rẹ nípa rẹ̀. [3]", "timestamp": "2021-02-28T19:12:47Z", "url": "https://safe2choose.org/yo/wa-ogun-iseyun/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "5Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò. 6Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run. 7Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. 8Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.\n9Èmi kọ̀wé sí ìjọ: ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá. 10Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa: èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnrarẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí ó sì ń fẹ́ gbà wọ́n, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ.", "timestamp": "2021-03-06T08:56:02Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/kjv/3-john/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìṣàìtó àwọn enzymes àti àwọn ọlọ́kọ̀ tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìyípo urea lè fa àwọn àìsàn tí ó rọ̀ mọ́ ìyípo urea bíi:", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Previous article Ààrẹ orílẹ̀ èdè America, Trump, ti ní àwọn ICE ma bẹ̀rẹ̀ si ní dá àwọn ènìyàn tí kò yẹ kí wọ́n wà ní ìlú àwọn padà sí ìlú wọ́n ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.", "timestamp": "2021-03-09T00:41:24Z", "url": "https://iroyinowuro.com.ng/2019/06/19/aworan-igbakeji-komisona-olopaa-ipinle-eko-ti-n-fa-ejo-lori-afefe/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Èdè Khoisan yìí gẹ́gẹ́ bí a ti sọ síwájú ń dín kù síi lójoojúmọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń di ohun ìgbàgbé. Ohun tí ó fa èyí ni pé àwọn tí wọ́n ń sọ àmúlùmálà èdè Khoisan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè mìíràn tí ó gbilẹ̀ ní agbègbè wọn; wọ́n sì dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdè abínibí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ní àkọ́silẹ̀ kankan tí ó sì fíhàn pé sísọnù tí àwọn èdè wọ̀nyí sọnù, kò lè ní àtúnṣe. Ó jẹ́ ohun tí ó nira díẹ̀ láti sọ pé iye àwọn ènìyàn kan pàtó ni wọ́n ń sọ èdè Khoisan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó gòkè bọ̀, a kò sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn Òyìnbó ń ṣètò ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì tún ni pé ìwọ̀nba la lè sọ mọ nípa ohun ti ó ń ṣẹlẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ fi hàn pé, ní bíì ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, iye nọ́nbà tí wọ́n kọ sílẹ̀ kò ṣeé tẹ̀lé mọ́; àkọsílẹ̀ sọ wí pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà Igba (120,000 – 200,000) ni wọn, ṣùgbọ́n èyí ti di ohun àfìsẹ́yìn bí eégún fí aṣọ. Wọn kò tó bẹ́ẹ̀ mọ́. Díẹ̀ lára àwọn èdè khoisan àti iye àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́.\nÀfihàn ìgbésí ayé àwọn olùṣọ èdè Khoisan ni ọ̀rọ̀-èdè (Vocabulary) wọn jẹ́. Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn olùṣọ èdè wọ̀nyí ń gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìírà, èyí mú kí wọ́n ní àwọn ọ̀rọ̀-èdè tí ó súnmọ́ ọdẹ ṣíṣe, ẹranko, Kóríko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.", "timestamp": "2021-02-25T11:58:23Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Koisaanu", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "5Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. 6Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. 77: Gẹ 19.Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.", "timestamp": "2021-02-25T08:16:10Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/ntlr/iuda/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Wikipedia jẹ́ ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́ tó wà nítorí akitiyan awọn oníse rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa nínú iṣẹ́-ọwọ́ yìí lè dá àyọkà tuntun tàbí ṣàtúnṣe àwọn àyọkà tó wà. Àfikún kọ̀ọ̀kan únjẹ́ kíkọ sílẹ̀ sínú ìtàn àwọn ojúewé bẹ́ẹ̀sìni wọ́n únhàn nínú àwọn àtúnṣe tuntun. Àwọn ohun tí wọn kò bá ní ìbámu pọ̀ mọ́ ìwé ìmọ̀ Wikipedia yíò jẹ́ píparẹ́.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ọpọ àwùjọ àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú apá Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti wà ṣáájú kí wọ́n ó to ní ìmọ̀ àti òye a ń kọ̀tàn nípa àwọn ènìyàn. Àwọn mìíràn lára wọn jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ̀dó sí àwọn ìletò káàkiri látàrí òwò àti kárà-kátà tí wọ́n ma ń ṣe, tàbí lẹ́yìn tí àwọn Lárúbáwá kò wọn lẹ́rú ní ńkan bí ọ̀rùndún méje sèyìn (7th centuries). [5][6]", "timestamp": "2021-03-04T22:34:33Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Black_people", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì buyì káàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ní àgbáyé Kwa ní èdè Yorùbá bátan; kwa jẹ́ ẹ̀yà kan ní Niger-Congo. A lè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lé ní Ọgbọ̀n mílíọ̀nùn tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ.", "timestamp": "2021-03-07T12:09:29Z", "url": "https://yo.m.wikipedia.org/wiki/%C3%88d%C3%A8_Yor%C3%B9b%C3%A1", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Previous article Àwọn imigiráṣọ̀n yóò tó bẹ̀rẹ̀ sí ní dá àwọn àlejò tí kò yẹ kí wọ́n wà ní Nàìjíríà padà sí ìlú wọn.", "timestamp": "2021-03-04T11:47:59Z", "url": "https://iroyinowuro.com.ng/2019/06/17/mercy-aigbe-n-ki-ara-re-fun-ayeye-ojo-baba/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "16Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.\n17Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí 18wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.", "timestamp": "2021-03-01T06:04:17Z", "url": "https://www.biblica.com/bible/niv/numbers/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Yàtọ̀ sí àwọn aráàlú tó jẹ́ nínú àǹfààní nla yìí, àwọn ẹlẹwọn tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tún gbà oúnjẹ àtàwọn èròjà oúnjẹ fún asiko yii.", "timestamp": "2021-03-08T03:24:01Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/gomina-abdulrazaq-gbe-osuba-kare-fun.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ṣùgbọ́n, ìyá àwọn ọmọ náà ní ''òun fí ẹjọ́ ọkọ òun sun àwọn ẹbí rẹ̀ nígbà tí òun ṣe àkíyésí àrà tó n fi àwọn ọmọbìnrin náà dà, àmọ́ tí wọn kò gbé ìgbésẹ̀ kankan. Àti pé, níṣe ni ọkùnrin nàá n dún kookò mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá takòó.", "timestamp": "2021-03-01T19:48:20Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/afrika-44250628", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Láti ní ojú ewé fún ara wọn àti àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn. Ẹ wo inú Wikipedia:Ojú ewé oníṣe fún kíni àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ ẹ́tọ́ àti àwọn ohun tí kò jẹ́ èwọ̀ níbẹ̀ (àwọn ojúewé yìí náà le jẹ́ títúnṣe lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn).", "timestamp": "2021-03-03T14:55:47Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Wikipedia:Wikipedians", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Èròngbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣe ìwádìí sí ohun tí àwọn ará Àkúrẹ́ máa ń lo orin fún ní àwùjọ wọn. Ó jẹ́ ọ̀nà láti ṣẹ̀dámọ̀ àwọn orin àwùjọ Àkúrẹ́, láti ṣàlàyé ìṣẹ̀ṣe àwọn orin wọn àti láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó tí orin máa ń dá lé.\nÀ ṣe àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò láti ọdọ̀ àwọn ọ̀kọrin. Apohùn ìṣẹ̀nbáyé àti àwọn abínà-ìmọ̀. A ṣe àdàkọ àwọn orin tí a gbà jọ, a sì ṣe àgbéyẹwò àwọn iṣẹ́ tí wọn ti wà nílẹ̀ lórí orin ní àwọn agbègbè mìíràn. A ka àwọn ìwá tí ọwọ́ wa tẹ̀ ní agbègbè náà, a sì rí ọ̀kọ́ tó wúlò fún wa lórí orí ọ̀rọ̀ tí iṣẹ́ wa yìí dá lé.\nIṣẹ́ yìí tún fi hàn pé ẹ̀sìn ní o máa ń bí àwọn orin ẹ̀sìn ní àwùjọ Àkúrẹ́ àti pé àṣà àti ìṣe àwùjọ ni ó máa ń ṣe okùnfà fún àwọn orin aláìjọmẹ́sìn.", "timestamp": "2021-03-06T04:45:07Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80k%C3%BAr%E1%BA%B9%CC%81", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Gómìnà t’ẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ayodele Fayose náà wà lára àwọn tó kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí àti ẹbí olóògbé.O ròyìn rẹ̀ pé ojúlówó olóṣèlú tó fẹ́ràn àwọn èèyàn ẹkùn rẹ̀ ni.", "timestamp": "2021-02-28T06:14:10Z", "url": "http://asa.ooduarere.com/a%E1%B9%A3a-yoruba/gbo-n-tawon-eekan/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "3Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá. 4Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli. 5Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.\n17Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.", "timestamp": "2021-03-03T23:50:49Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/htb/dani%C3%ABl/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ó ti pẹ́ tí BBC tí ní àwọn ìlànà tó ń gba kọ ìròyìn tí yóò sí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àlàklẹ tí ó yẹ nínú ètò ìròyìn kíkọ. Láti mú kí ó rọ̀rùn fún yín láti rí bí a ṣe ń lo àwọn ìlànà ìlànà ní yàrá ìkóròyìn jọ wa, a ti kọ gbogbo àwọn ǹkan ti yóò wúlò fún yín sí ipele yìí.\nIlé iṣẹ́ ìròyìn BBC máá ń fi ìyàtọ̀ sí àwọn ìròyin tí a le fí àwọn ìdí rẹ múlẹ̀ àtí àwọn èyí ti àwọn ènìyàn kan sọ èrò ọkàn wọ́n lásán. a máa n lo ẹ̀rọ ìkàwé se àkọle rẹ̀ si ipele mẹ́fà:", "timestamp": "2021-03-08T11:23:00Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/institutional-48528718", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ajakaye làwọn tí kò ìyàwó àti ọmọ olóògbé náà lọ sí ibùdó ayẹwo, táwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ láti wá àwọn tí olóògbé náà ni ibaṣepọ pẹ̀lú kò tó o kú.", "timestamp": "2021-03-03T23:35:49Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/koronafairoosi-pa-eeyan-meje-l-ati-kano.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "I ni ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ àwọn àtúnṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà díẹ̀-díẹ̀, kí wọn sì fi àwọn irinṣẹ íkẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.\nAbdulRazaq jẹ́ kó di mimọ pé kí í ṣe atunkọ àwọn kíláàsì ni wọn ń pè ní ilé ẹ̀kọ́ gidi, bí kò ṣe àwọn irinṣẹ àti eto ìlànà ẹ̀kọ́ àgbáyé ni wọn fi ń dá ògidì ilé ẹ̀kọ́ tó pé ojú owó, tó sì lòun ṣetan láti ṣe é.", "timestamp": "2021-03-05T00:46:13Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/09/eyi-tun-ga-o-kwara-fee-se-atunse-ile.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "A fẹ́ mí àwùjọ wa ó dára, kí ó láàbò kí ó sì wà ní àláfía fún ẹnikẹ́ni ti ó bá fẹ dara lọ̀ mọ. Bákan náà, a tún fẹ́ dáàbò bo iṣẹ́ àkànṣe.wa gbogbo lọ́wọ́ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kí wọn ó má lè daaru.", "timestamp": "2021-02-27T01:32:15Z", "url": "https://meta.m.wikimedia.org/wiki/Universal_Code_of_Conduct/Draft_review/yo", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Next article Ilé ìjọsìn Celestial ń béèrè fún ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọdé mẹ́ta tí bàbá wọn àti ìyàwó rè ń fi ìyà jẹ nítorí ìyá wọn ti kú.", "timestamp": "2021-03-06T11:41:20Z", "url": "https://iroyinowuro.com.ng/2019/06/27/olopaa-ti-gbe-a%E1%B9%A3ofin-ti-o-ni-oun-ma-a-na-awon-oni%E1%B9%A3owo-ajeji-ti-won-ko-ba-kuro-ni-ilu/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian.\nNí ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.", "timestamp": "2021-03-01T05:30:07Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%80w%E1%BB%8Dn_%C3%A8d%C3%A8_Niger-K%C3%B3ng%C3%B2", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Fún àwọn obìnrin tí oyún wọn wà ní oṣù mẹ́wàá sí mọ́kànlá, o máa rí àwọn atọ́ka àìlera bíi ẹ̀jẹ̀ dídà àti inú rírun. Ó sì ṣeé ṣe kí o rí ọlẹ̀ inú nígbàtí ó bá já bọ́ sílẹ̀ [1]. Lọ́pọ̀ ìgbà ọlẹ̀ náà le dàpò mọ́ ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ dídì, a kìí sí ì mọ̀ pé ó wà níbè, àmọ́ ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ wípé kò jẹ́ tuntun tí o bá dáa mọ̀. Má bẹ̀rù ó ṣeé yí mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ nǹkan oṣù láti jùú dànù tàbí kí o sàn-án dànù sí ilé ìyàgbẹ́.", "timestamp": "2021-02-28T18:42:15Z", "url": "https://safe2choose.org/yo/iseyun-pelu-ogun/iseyun-pelu-misoprostol-nikan/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Igbesẹ yìí kọ ṣẹyin bí wọn ṣe ni àwọn aláṣẹ lẹka ètò ìdájọ́ orílẹ̀-èdè yìí ni wón bù ọwọ lu àwọn adajọ tuntun náà, kò tó di pé ìjọba Èkó bu ontẹ luu, tí wọn sì búra fún wọn.", "timestamp": "2021-03-07T23:21:40Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/sanwo-olu-bura-fawon-adajo-mejo-l-bee.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ní àwùjọ Yorùbá, á ní àwọn ọ̀nà ìsèlú tiwa tí ó dá wa yàtọ̀ sí ẹ̀yà tàbí ìran mìíràn. Kí àwọn Òyìnbó tó dé ní àwa Yorùbá ti ni ètò ìsèlú tiwa tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀. Tí ó sì wà láàárin ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Yàtọ̀ sí tí àwọn ẹ̀yà bí i ti ìgbò tí ó jẹ́ wí pé àjọrò ni wọn n fi ìjọba tiwọn ṣe (acephalous) tàbí ti Hausa níbi tí àsẹ pípa wà lọ́wọ́ ẹnìkan (centralization).\nA tún ń àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó ń dáàbò bo ọba àti ìlú. Àwọn ni wọn ń kojú ogun. Àwọn ni o n lọ gba isakọlẹ fọ́ba. A tún ní àwọn onífá, Babaláwo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.\nÈtò òsèlú wa tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí ni ó mú kí ó sòro fún àwọn òyìnbọ́ láti gàba tààrà lórí wa (Indirect rule). Àwọn ọba àti ìjòyè wa náà ni wọn ń lò láti ṣèjọba lórí wa. Ó pẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó rí wa wọ.", "timestamp": "2021-03-02T16:53:29Z", "url": "https://yo.m.wikipedia.org/wiki/Politics", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "“Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́. 6Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ. 7Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ mọ́.", "timestamp": "2021-02-26T21:17:30Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/tncv/%E0%B9%80%E0%B8%99%E0%B8%AB%E0%B8%B0%E0%B8%A1%E0%B8%B5%E0%B8%A2%E0%B9%8C/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Aṣọ Àdìrẹ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn aṣọ ìbílẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá. Tọmọdé tàgbà ni ó ń wọ aṣọ àdìrẹ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ọnà oríṣríṣi sí lára nílànà ìbílẹ̀, tí ó sì wà ní àwọ̀ oríṣríṣi sí.[1] [2]", "timestamp": "2021-03-03T09:18:33Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/A%E1%B9%A3%E1%BB%8D_%C3%80d%C3%ACr%E1%BA%B9", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ké síta lórí bí àwọn jàǹdùkú tó fi ìwọ́de End SARS bojú, ṣe ń kọlu àwọn ọ́fíìsì àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn ní ìpínlẹ̀ Èkó.\nÓ ní àwọn jàǹdùkú náà pa ọlọ́pàá méjì ní àgọ́ wọn tó wà ní Orile, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ṣe ogun lọ́gọ̀ ọlọ́pàá lése, kí wọ́n tó dáná sun àwọn agbègbè mẹ́wàá míì, tí àwọn ọlọ́pàá máa ń kórajọ sí.", "timestamp": "2021-02-28T05:56:56Z", "url": "http://asa.ooduarere.com/breaking-news/jaduku-pa-lpaa-meji-jo/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "4Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. 5Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. 6Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”", "timestamp": "2021-03-01T10:53:37Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/hhh/%D7%94%D7%91%D7%A9%D7%95%D7%A8%D7%94-%D7%A2%D7%9C-%D7%A4%D7%99-%D7%9E%D7%AA%D7%99/11/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Bí àwọn tí ó ti kó àrùn COVID-19 ṣe ń pọ̀ọ́ sí i ní Balkans, àwọn ilé ìjọsìn kan kò yí ọwọ́ àwọn ìlànà ìsìn tí ó lè mú kí àrùn Coronavirus ó ràn bí i pápá inú ọyẹ́ padà.\nÌlànà ìsìn tí a mọ̀ sí Jíjẹara àti mímu ẹ̀jẹ̀ Olúwa tàbí Oúnjẹ Ìkẹyìn ní èyí tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Krístì tí ó ń tẹ̀lé ìlànà ìsìn àtijọ́ yóò máa pín wáìnì tí a ti sọ di mímọ́ mu pẹ̀lú ṣíbí kan náà, àwọn Ìjọ Àgùdàá máa ń jẹ ẹ̀bẹ àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi ẹnu gbà lọ́wọ́ àlùfáà.\nÀmọ́ àwọn aṣojú ìjọba tìkarawọn ń tàpá sí òfin ìdènà ààrùn yìí. Lọ́jọ́ ìsinmi ajẹmẹ́sìn kan lọ́jọ́ Ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ààrẹ àti àwọn onípò nínú ìṣèjọba rẹ̀ lọ sí ìsìn kan.\nNí tirẹ̀, Àjọ Ìlànà-ìsìn Àtijọ́ ti Korea ṣe ìfilọ̀ nípa àwọn àyípadà tó dé bá ìsìn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àfilélẹ̀ Iléeṣẹ́ Ètò Ìlera:\nÀwọn onígbàgbọ́ tíbẹ̀rùbojo àrùn apànìyàn náà ti sojo s'ọ́kan wọn yóò pa ìfènuko àwọn ère inú ilé ìjọsìn lára. Bí ó bá wù wọ́n, wọ́n leè sọ fún àlùfáà wí pé ṣíbí ti wọn ni àwọn fẹ́ lò fi gba Ẹ̀jẹ̀ Olúwa mu.", "timestamp": "2021-03-02T01:16:40Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2020/03/13/629/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Fún ìdí èyí ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà ní àgbáyé, wọn kò fọwọ́ yẹpẹre mú ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí àti gbogbo ohun tó so mọ́ ọ ̣̣", "timestamp": "2021-03-03T14:36:11Z", "url": "https://yo.m.wikipedia.org/wiki/P%C3%A0t%C3%A0k%C3%AC:MobileDiff/540114", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ibùdó yìí jẹ́ ilé ìṣúra àwọn “èdè ìperí”, ó sì ní àlàálẹ̀ fún àwọn tí ó bá fẹ́ fi ara tọrẹ fún iṣẹ́ ọ̀fẹ́ láti ṣe àfikún tàbí dámọ̀ràn èdè ìperí.", "timestamp": "2021-02-28T19:08:31Z", "url": "https://www.yobamoodua.org/ayipada-oju-ojo/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "ìtùnú wa, inúrere wa, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ojúlùmọ̀, tàbí àwọn àlejò. Olùgbọ̀wọ́ ti Olúwa ni a jẹ́ níbí lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú àṣẹ láti sìn àti láti gbé àwọn ọmọ Rẹ̀ sókè. Ó nígbẹ́kẹ̀lé lórí ìkọ̀ọ̀kan lára wa. . . .", "timestamp": "2021-03-05T04:35:24Z", "url": "https://jds.clubschermaancona.it/e-ba-wa-yin-oluwa-halleluyah.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "26Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. 27Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.", "timestamp": "2021-02-25T16:46:50Z", "url": "https://www.biblica.com/bible/niv/romans/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìlú Muṣin ní àwọn ohun amáyéderùn bíi ilé ìwòsàn àti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ tí tí dé ilé ẹẹ̀kọ́ girama pẹ̀lú ohun èlò tìgbà lo de fún àwon akẹ́ẹ̀kọ́. Ìlú Muṣin tún ní àwọn ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a lè gbà wọ inú ìlú yìí, àwọn ọ̀nà náà ni, ọ̀nà Èkó, Ṣómólú àti Ìkẹjà. Àwọn ẹ̀yà Yorùbá ni ó pọ̀jù nínú àwọn olùgbé agbègbè yí, tí ó sì jẹ́ èdè abínibí Yorùbá ni wọ́n ń sọ jù níbẹ̀ [2]", "timestamp": "2021-03-01T10:51:21Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Agb%C3%A8gb%C3%A8_%C3%8Cj%E1%BB%8Dba_%C3%8Cb%C3%ADl%E1%BA%B9%CC%80_Mushin", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ ẹ sì ẹni tó tako ọ̀rọ̀ tí Kẹmi Olunlọyọ sọ yìí, ṣùgbọ́n pupọ nínú àwọn tí wọn kò gbà ti obìnrin náà ní wọn ń sọ pé àrùn ọpọlọ lo ń dá a láàmú, àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí ó ṣojú lásán.", "timestamp": "2021-03-04T00:36:37Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/gbajumo-oniroyin-tu-asiri-nla-nipa-oku.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹbí èdè yìí tó àádọ́sàn-án. Àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin. Gúsù ìlà-oòrùn Asia ní pàtàkì ní China àti Indonesia ni wọ́n ti ń sọ wọ́n jù. Àwọn kan sì tún ń sọ wọ́n ní apá ìwọ̀-oòrùn àríwá India àti ní Erékùsù Nicobar (Nicobar Island). Àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ẹbí èdè yìí tí ó ṣe pàtàkì ni Mon-Khmer (tí ó jẹ́ pé nínú rẹ̀ ni àwọn èdè pọ̀ sí jù), Munda àti nicobarese. Àwọn méjèèjì tó gbẹ̀yìn yìí ni wọ́n ń sọ ní ìwọ̀-oòrùn àdúgbò Mon-khmer. Láti fi ìmọ̀ ẹ̀dá èdè pín àwọn èdè yìí sòro díẹ̀ nítorí pé díẹ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó ní àkọsílẹ̀ àti pé ìbáṣepọ̀ tí ó wà ní àárín àwọn ẹbí èdè yìí àti àwọn ẹbí èdè mìíràn kò yé èèyàn tó.", "timestamp": "2021-03-01T10:49:56Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Ositiro-Esiatiiki", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "O wa a jẹ kò di mimọ pé kani kii ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ tí gba idanilẹkọọ dáadáa ní, ó ṣeé ṣe kí àṣírí àwọn afurasi ajinigbe náà má tú sí wọn lọ́wọ́, kí wọn sì ti lọọ pá ọmọ náà dànù.\nÓ wà fi dá àwọn ọmọ ipinlẹ Ogun àti agbegbe rẹ lójú wí pé kí wọn fọkanbalẹ, kí wọn sì má ṣe bẹ̀rù mọ nítorí pé asiko táwọn wá yìí, àsìkò táwọn tí wọ ìyá ìjà pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn ni, ati pe ko saaye fún ìwà ọ̀daràn kankan mọ.", "timestamp": "2021-03-05T18:53:56Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/konilegbele-e-wo-omo-kekere-t-vgn-gba.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Lọ́wọ́lọ́wọ́ kò sí ìkọ̀ nínú ojúewé yìí. Ẹ le wá àkọlé ojúewé yìí nínú àwọn ojúewé mìíràn, tàbí wá àwọn àkọọ́lẹ̀ tó bámu, sùgbọ́n ẹ kò ní àṣẹ láti ṣ'ẹ̀dá ojúewé yìí.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Johnson gbà pé Ọ̀yọ́ ni àwọn Ẹ̀gbá ti wá. O ní àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbá tòótọ́ lé ti orírun wọn de Ọ̀yọ́. ó tún tẹ̀ síwájú síi pé ọmọ àlè tàbí ẹrú ni Ẹ̀gbá tí kò bá ní orírun láti Ọ̀yọ́. Àwọn olóyè wọn wà lára àwọn Ẹ̀sọ́ Aláàfin láyé àtijọ́, àtipé àwọn olóyè yìí ló sá wá sí Abẹ́òkúta lábẹ́ olórí wọn tó jẹ́ àbúrò ọba Ọ̀yọ́ nígbà náà.\nDélànà ní tirẹ̀ ní etí ilé-ifẹ̀ ni àwọn Ẹ̀gbá tó kọ́kọ́ dé tẹ̀ dó sí. Àwọn ni ó pè ní Ẹ̀gbá Gbàgùrà. Wọ́n dúró súú sùù súú káàkiri. Olú ìlú wọn sì ni “ÌDDÓ” tí ó wà níbi tí Ọ̀yọ́ wà báyìí. Àwọn ìsí kejì sun mọ ìsàlẹ̀ díẹ̀. Wọ́n kọjá odò ọnà. Àwọn ni Ẹ̀gbá òkè-ọnà. Òsilẹ̀ ni ọba wọn. Òkó ni olú ìlú wọn .Ẹ̀gbá Aké ló dé gbẹ̀yìn.\nAjísafẹ́ ní ọ̀tẹ̀ ló lé àwọn Ẹ̀gbá kúrò ni ilé- ifẹ̀ wá Kétu. Láti Kétu ni wọn ti wá sí Igbó- Ẹ̀gbá kí wọn to de Abẹ́òkúta ní 1830. Sàbúrí Bíòbákú náà faramọ́ èyí. Lọ́rọ̀ kan sá, àwọn Ẹ̀gbá ti ilé- ifẹ̀ wá, wọ́n ni ohun i se pẹ̀lú oko Àdágbá, Kétu, àti igbó-Ẹ̀gbá. Ìtàn tún fi yé ni síwájú sii pé ìlú Ẹ̀gbá pọ̀ ní orílẹ̀ olúkúlùkù ló sì ń ní ọba tirẹ̀, fífọ́ tí orílẹ́ Ẹ̀gbá fọ́ lò gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ìtàn ti sọ, 1821 ni Ìjà tó fọ́ gbogbo Ìlú Ẹ̀gbá ti sẹlẹ̀. Ohun kékeré ló dá Ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn òwu àti àwọn Ìjẹ̀bú ni ọjà Apòmù, Ogun Ọ̀yọ́ àti tí ifẹ̀ dà pọ̀ mọ́ ogun Ìjẹ̀bú láti bá Òwu jà. Àgbáríjọ ogun yìí dé ìlú àwọn Òwu ní tọ̀ọ̀ọ́tọ́ sùgbọ́n àwọn Òwu lé wọn padà títí wọ́n fi dé àárín àwọn Gbágùrá to wa ni Ìbàdàn. Inú àwọn Gbágùrá kò dùn sí è́yí wọ́n ti lérò pé ogun yóò kó àwọn Òwu. Èyí náà ló sì mú àwọn Gbágùrá tún gbárajọ láti pẹ̀lú ogun Ọ̀yọ́, Ìjẹ̀bú àti ifẹ̀ kí wọn le borí ogun Òwu. Wọ́n sẹ́gun lóòótọ́ sùgbọ́n lánlẹ́yìn, àkàrà Ríyìíkẹ́ ni ọ̀rọ̀ náà dà nígbẹ̀yìn. Òjò ń podídẹrẹ́ ni, àwòko ń yọ̀. Kò pẹ́ ẹ̀ ni ogun Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀sà, Ọ̀yọ́ àti ifẹ̀ rí i mọ́ pé àsé àwọn Ẹ̀gbá kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ tẹ̀ǹbẹ̀ lẹ̀kun sí àwọn Ẹ̀gbá. Wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo Ìlú wọn tán lọ́kọ̀ọ̀kan.\nÈyí tí ó wá burú jù níbẹ̀ ni ti IKÚ Ẹ́GẸ́ tó jẹ olóyè ifẹ̀ kan. Lámọ́di asíwájú Ẹ̀gbá kan ló páa nígbà tí ǹ dìtẹ̀ mọ ọn. Sùgbọ́n àwọn ọ̀tá kò sàì pa òun náà sán. Ọ̀tẹ̀ àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun tí wọn ń dí mọ́ àwọn Ẹ̀gbá yìí ló mú wọn pinnu láti kúrò ní ibùjókòó wọ́n. Àwọn babaláwo wọn gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ sánlẹ̀, wọn rí odù òfúnsàá. Wọ́n kifá lọ wọ́n kifá bọ̀, wọ́n ní wọn yóò dé Abẹ́òkúta, àwọn aláwọ̀ funfun yóò sì wá láti bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn babaláwo wọn náà ni Tẹ́jú osó láti Ìkìjà Òjo (a ń-là-lejì- ogbè) ara Ìlúgùn àti Awóbíyìí ará irò. 1830 Sódẹkẹ́ lo sáájú pẹ̀lú àwọn Ẹ̀gbá Aké. Balógun Ìlúgùn kó Ẹ̀gbá òkè-ọnà kẹ́yìn. Wọn kò rántí osù tí wọ́n dé Abẹ́òkúta mọ́ sùgbọ́n àsìkò òjò ni. Nígbà tí wọn kọ́kọ́ dé, wọ́n do sí itòsí Olúmọ, olúkúlùkù ìlú sa ara wọn jọ, wọn do kiri Ẹ̀gbá Aké, Ẹ̀gbá òkè-ọnà àti Ẹ̀gbá Gbágùrá ló kọ́kọ́ dé sí Abẹ́òkúta. Ni 1831 ni àwọn Òwu sẹ̀sẹ̀ wá bá wọn tí àwọn Ẹ̀gbá sì gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Àwọn Ẹ̀gbádò tí wọ́n bá ní Ìbarà ló sọ wọ́n ni Ẹ̀gbá, nínú ọ̀rọ̀ “Ẹ̀GBÁLUGBÓ” ni wọ́n sì tí fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Àwọn òpìtàn ní àwọn Ẹ̀gbádò ni ń gbé ìpadò nígbà tí àwọn Ẹ̀gbá ní gbé ni òkè ilẹ̀. Òpìtàn míìràn tún ní ìtumọ̀ Ẹ̀gbá ni “Ẹ GBÀ Á “ lálejò nítorí pé wọ́n gba àwọn Òwu àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń wá abẹ́ ààbò sá sí mọ́ra.\nA ti sọ pé kálukú ẹ̀yà Ẹ̀gbá ló ń da ọmú ìyá rẹ̀ gbé, sị́bẹ̀, kò sàìsí ìbásepọ̀ díẹ̀ láàárín wọn. Lọ́nà kìnní, gbogbo Ẹ̀gbá ló gbà Abẹ́òkúta sí ìlú wọn.Wọn ni ilẹ̀ níbẹ̀, sùgbọ́n wọn a máa lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti lọ múlẹ̀ oko. Ní ìparí ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń wálé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oko ẹ̀yìn odi ìlú báyìí lo ti di ìlú fún wọn. Abúlé ni wọn n pe àwọn ìletò wọ̀nyí. Kò sí ọmọ Ẹ̀gbá kan tí kò ní abúlé . Ètò abúlé wọ́ pọ̀, ó sì gún régé, Baálẹ̀ tàbí olóróko (olórí oko) ni o wà ní ipò ọ̀wọ̀ jùlọ. Bákan náà ló jẹ́ pé gbogbo wọn lo jọ ń bú ọlá fún àwọn ẹni ńlá wọn. Kò sí pé apá kan kò ka àwọn ẹni àná yìí wọ̀nyìí́ kún. Orò tún jẹ́ ẹ̀sìn kan tó so wọ́n pọ̀. Nílélóko ni wọn ti ń sọdún orò lọ́dọọdún. Àwọn olórò ìlú kan lè mú orò wọn dé ìlú mìíràn láìsí ìjà láìsí ìta. Lóòótọ́, ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní òrìsà tirẹ̀ tó se pàtàkì, fún àpẹẹrẹ, àwọn Òwu ló ni Òtòǹpòrò àti Ẹlúkú. Àwọn Odò ọnà ló ni Agẹmọ, àwọn ìbarà lo ni Gẹ̀lẹ̀dẹ́. Òrìsà Àdáátán, ọ̀tọ̀ ni. O máa ń sẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìgbà pé tí ìlú kan bá parí ọdún tiwọn lónìí, tí àdúgbò míìràn le bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ keje ẹ̀. Èyí kò sí yi padà láti ọjọ́ pípẹ́ wá.", "timestamp": "2021-03-02T14:01:15Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Abeokuta", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Orílẹ̀-èdè ni agbègbè tàbí ilẹ̀ kàn tí ó ní ààlà, tí ó sì ní àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe àkóso lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọba.", "timestamp": "2021-03-03T01:31:55Z", "url": "https://yo.m.wikipedia.org/wiki/Orile-ede", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "4Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. 5Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. 6Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. 7Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. 8Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.", "timestamp": "2021-02-27T16:24:27Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/cro/matej/24/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "1Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 2“Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, 3Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. 4Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an.", "timestamp": "2021-03-04T21:40:44Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/cro/matej/23/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Orílẹ̀-èdè Mauritania ti Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ jẹ́ ìdàpọ̀ àwọn Lárúbáwá àti àwọn aláwọ̀ dúdú, àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sọ pé àwọn aláwọ̀ dúdú ti ń dojúkọ ìyàsọ́tọ̀ àti ìlòkulò fún ìgbà pípẹ́.\nLọ́dọọdún, bí àwọn tí wọ́n dipò mú ṣe ń ṣe ìrántí ìgùnkè wọn sí ipò gíga pẹ̀lú ìdùnnú, ẹbí àwọn olùfarapa máa ń sunkún, tí wọ́n sì máa ń fi ẹhónú hàn pẹ̀lú ìbànújẹ́ fún àtúnṣe àti ìdájọ́ òdodo. Àwọn tí ó wà nípò àṣẹ kàn ń gbìyànjú láti ri apá òmìnira tí kò farahàn yìí mọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe dìbò yan òfin ìdáríjì ìjọba ní ìkọ̀kọ̀ lọ́dún 1993 tí wọ́n sì fìdí ìgbàgbé ìjọba múlẹ̀ nípa ìpakúpa àwọn ológun náà lọ́gbọ̀n ọdún sẹ́yìn.\nLáìsí àní-àní, èpè ja àwọn ológun 28 yẹn lóru ọjọ́ náà. Bí i ti àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Diallo Oumar Demba àti àbúròo rẹ̀ Diallo Ibrahima tí a yẹgi fún pẹ̀lú àkọsílẹ̀ nọ́ḿbà tí ó tẹ̀lé ara wọn tí a fi gègé kọ sí wọn lára. Ohun tí ó mú èyí bani nínú jẹ́ jù ni fún ẹni láti rí ikú tí ó pa ẹ̀gbọ́n ẹni. Àwọn apani ṣe iṣẹ́ wọn pé, wọn kò sì dáwọ́ dúró lẹ́yìn tí wọ́n yẹgi fún wọn, wọ́n tún wọ́ òkúu wọn nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń jókòó lé wọn lórí.\nOṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ni a fi wá ọkọ mi, ṣùgbọ́n pàbó ni ó já sí… Àwọn ẹ̀ṣọ́-ibodè sọ fún wa pé àìsàn ọkàn ló pa á, tí èyí kò sì jẹ́ òtítọ́. Wọ́n mú àwọn tó jẹ́rìí pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n so wọ́n, wọ́n sì fi ìyà oró jẹ wọ́n pẹ̀lú rẹ̀. Ní iwájú wọn ni wọ́n ti pa á.\nKardiata Malick Diallo, tí ó jẹ́ igbákejì, sọ ọrọ àròjinlẹ̀ ní ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Mauritania láti máà jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbàgbé, tí ó sì fi ẹ̀sùn kàn ààrẹ tí ó wà lórí oyè pé ó ń dáàbò bo àwọn oníṣẹ́-ibi náà, tí wọ́n ṣì ń dipò gíga mú nínú ìjọba nígbà tí wọn kò tí ì wá nǹkan ṣe sí ẹ̀tọ́ àwọn olùfarapa:\nNí oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2018, nínú àwọn adarí ipò ìjọba 24, márùn-ún péré ni àwọn tí ó jẹ́ aláwọ̀ dúdú àti elẹ́yà-méjì, tí wọ́n ń ṣojú ìdá 70 àwọn mẹ̀kúnù. Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnù ni wọ́n kò ní aṣojú láàárín àwọn aṣojú tí wọ́n dìbò yàn, láàárín àwọn ẹgbẹ́ àbò àti àwọn adarí ipò ìjọba ìbílẹ̀.\nNítorí ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà yìí ṣì ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Mauritania, ìdájọ́ òdodo kò sí ní àrọ́wọ́tó fún àwọn ẹni orí-kó-yọ àti àwọn ìdílé wọn.", "timestamp": "2021-03-02T02:15:30Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2019/01/02/123/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àarẹ Buhari ti wá pàsẹ kí isẹ́ ìwádi tó yá ní kọ́nmọ́kánmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ lórí isẹ́ àwọn ìgbìmọ̀ alásẹ àjọ náà.\nÓ ní ó yẹkí ìgbésẹ̀ tó gúnmọ́ wà láàrin àwọn agbófinró, àwọn àjọ tó ńse ìwádi àti ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ láti léè tètè mọ àwọn ìsòro tó ńdí ìsowó síse ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn oun tí ó ńdí ìlọsíwájú agbègbè Niger Delta lọ́wọ́.", "timestamp": "2021-03-05T04:14:40Z", "url": "https://radionigeriaibadan.gov.ng/2020/07/17/aare-buhari-pase-iwadi-kiakia-lori-oro-ajo-nddc/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "1Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 2Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́.", "timestamp": "2021-03-07T05:46:23Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/hhh/%D7%90%D7%92%D7%A8%D7%AA-%D7%A4%D7%95%D7%9C%D7%95%D7%A1-%D7%94%D7%A8%D7%90%D7%A9%D7%95%D7%A0%D7%94-%D7%90%D7%9C-%D7%98%D7%99%D7%9E%D7%95%D7%AA%D7%99%D7%95%D7%A1/6/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn àdàkọ jẹ́ ohun ìlò pàtàkì MediaWiki, sùgbọ́n wọ́n dojúrú fún ọ̀pọ̀ àwọn oníṣe tí wọn kò mọ iṣẹ́ wọn. Nítoríẹ̀ àwọn àdàkọ gbọdọ̀ ní ìwé-àlàyé tó ún ṣàlàyé iṣẹ́ wọn.", "timestamp": "2021-02-24T21:03:25Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Wikipedia:%C3%8Cw%C3%A9-%C3%A0l%C3%A0y%C3%A9_%C3%A0d%C3%A0k%E1%BB%8D", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ni ó ní òfin tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàláàyè oyún ṣíṣẹ́ àti lílo òògùn oyún ṣíṣẹ́. Ní àwọn orílẹ̀ èdè kan tí wọn ti fààyè gba oyún ṣíṣẹ́, púpọ̀ nínú àwọn oníṣègùn òyìnbó fi ara mọ́ lílo àwọn òògùn tí à ń pè ní mifepristone àti misoprostol láàrín ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá àkọ́kọ́ oyún náà. Misoprostol nìkan náà sì lè ṣiṣẹ́ ní àkókò yìí. Àwọn àmì oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn kò yàtọ̀ sí ti ìgbà tí oyún bá wálẹ̀ fúnraarẹ̀. Èèyàn sì lè sẹ́yún fúnraarẹ̀ pẹ̀lú òògùn láìsí ewu.", "timestamp": "2021-03-07T08:09:48Z", "url": "https://www.howtouseabortionpill.org/yo/about/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Next article Ààrẹ orílẹ̀ èdè America, Trump, ti ní àwọn ICE ma bẹ̀rẹ̀ si ní dá àwọn ènìyàn tí kò yẹ kí wọ́n wà ní ìlú àwọn padà sí ìlú wọ́n ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.", "timestamp": "2021-03-06T08:08:02Z", "url": "https://iroyinowuro.com.ng/2019/06/19/owo-vigilante-ti-te-awon-ole-ti-n-da-awujo-laamu-ni-ipinle-imo/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ó lè rẹ èèyàn tàbí kí ó ní inú rírú, òtútù àti arábìnrin gbígbóná ní àkókò yìí. Ọpọlọpọ obìnrin ni ó sì sọ pé bí àwọn ṣe mọ̀ pé oyún náà ti wálẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dá, ara wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní balẹ̀.", "timestamp": "2021-03-07T08:41:43Z", "url": "https://www.howtouseabortionpill.org/yo/faq/side-effects-complications-of-abortion-pills/nausea-after-misoprostol/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Èyí ni ayẹyẹ tó kẹ́yìn láṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ó máa ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọkọ-ojúọnà bá ti san gbogbo ẹrù ìdána. Àwọn ìdílé ìyàwó-ojú ọnà yóò wa sètò láti sìn ìyàwó lọ ilé ọkọ rẹ. Ọ̀kan-ọ̀-jọ̀kan àwọn ẹbí ìyàwó àti ọkọ á máa wúre fún ìyàwó àti ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó. Jíjẹ àti mímu máa ń pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu.\nÌbálé ni bíbá ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀ gbé nílé láì tí bá ọkùnrin kankan sùn rí kí ó tó lọ ilé ọkọ. Ó jẹ́ àṣà tí ó gbajúmọ̀ tí ó sìn máa ń buyì kún ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé. Ìwúrí ni ó máa ń jẹ́ fún ọkọ ìyàwó tí ó bá bá ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé nílé. Lálẹ́ ìgbeyàwó, àwọn òbí ọkọ yóò tité aṣọ funfun sí orí ibùsùn nínú yàrá ọkọ ìyàwó-àṣẹ̀ṣẹ̀gbé láti fi gba ìbálé rẹ̀. Iyì ńlá ni fún àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ rẹ bá bá nílé, ó túmọ̀ sí wípé ọmọbìnrin náà kò tíì mọ ọkùnrin rí. Odidi agbè ẹmu tàbí odidi páalí ìsáná, ìyàn àti ọbẹ̀ tí ó dára ní àwọn ẹbí ọkọ ìyàwó yóò gbé lọ fún àwọn òbí ìyàwó laarọ kùtùkùtù ọjọ́ kejì láti fi dúpẹ́ lọwọ wọn wípé odidi ni wọ́n bá ọmọ wọn, èyí ni oúnjẹ ìbálé, ìyàwó yóò tún gba owó ìbálé tíì ṣe ọ̀kẹ́ méjì lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀. Ohun ìtìjú àti ìbànújẹ́ ni ó máa ń jẹ́ fún ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé tí ọkọ rẹ̀ kò bá bá nílé àti ìdílé rẹ̀. Kódà, ònínàbì àti òníranù ni Yòóbá máa ń ka irú ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé bẹ́ẹ̀ sì.", "timestamp": "2021-02-24T17:08:36Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cgb%C3%A9y%C3%A0w%C3%B3", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ẹwẹ, ilé buwọlu ìyànsípò àwọn alákoso náà, tí wọ́n sọ̀rọ̀ wọn láti sisẹ́ wọn bíì sẹ, kíwọn sì ma jáà àwọn tónígbàgbọ́ nínú wọn, ní tọmọ̀n.", "timestamp": "2021-02-25T12:58:56Z", "url": "https://radionigeriaibadan.gov.ng/2020/08/26/ile-igbimo-asofin-ipinle-ekiti-buwolu-oruko-awon-meje-toje-fifi-sowo-geege-bi-alakoso/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Kọmísọ́nà fún ọ̀rọ̀ ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Eko, Kehinde Bamigbetan nínú àtẹ̀jáde fún àwọn oníròyìn sọwípé àbẹ̀wò Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ní Ọ́jọ́bọ̀ àti Ẹtì ọ̀sẹ̀ yii sí ìpínlẹ̀ náà, ló jẹ́ kí wọ́n fún àwọn ènìyàn ní ìsinmi ọjọ́ kan náà.\nÀwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé wà nínú àwọn tó farapa nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú. Ẹka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní bíí", "timestamp": "2021-03-09T08:28:31Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/afrika-43562730", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "ṣùgbọ́n èdè Gẹẹsì ni gbogbo wọn. Ṣùgbọ́n, mo ti jẹ́ kí wọ́n túmọ̀ wọn sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èdè, àtòkọ gbogbo àwọn ìwé mi ní èdè Yoruba yóò sì wà ní ojú ewé yìí.\nẸ̀wẹ̀, àwọn tí ó ti wà ní àrọ́wọ́tó láti ọ̀dọ̀ àwọn olùtajà wa tàbí tí wọ́n ntúmọ̀ lọ́wọ́ ni wọ́n wà nínú àtòkọ tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí. Nígbà tí àkọlé àwọn ìwé náà bá yí padà sí ojú òpó ẹ̀rọ ayélujára, a ó mú yín lọ sí àwọn ojú ewé tí ó ní àwọn àfikún àlàyé nípa àwọn ìwé ní èdè Yoruba nípa títẹ̀ sórí wọn.", "timestamp": "2021-02-25T12:45:57Z", "url": "https://meganthemisconception.com/foreign-translations/books-in-yoruba-awon-iwe-ni-ede-yoruba/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "8Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára. 9Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, 10fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro. 11Gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.\n18Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípasẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere; 19Máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere. Èyí ti àwọn mìíràn ti mú kúrò lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn; 20Nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Aleksanderu wà; àwọn tí mo ti fi lé Satani lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọ́n má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.", "timestamp": "2021-02-26T19:16:32Z", "url": "https://www.biblica.com/bible/niv/1-timothy/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "59Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un. 60Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.\n73Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa ààmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”", "timestamp": "2021-02-28T19:01:52Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/pev/matteo/26/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Dọkita Edu ni ìjọba àpapọ̀ kò pèsè fún ipinlẹ tí kò ní àrùn náà, àwọn nǹkan tí wọn lé fi dènà itankalẹ rẹ, ìdí re e tó fi ní kí wọn fi wọn silẹ.", "timestamp": "2021-03-05T03:23:09Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/osise-ncdc-to-wa-wo-cross-river-yoo-ru.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn oníròyín méjì ni ìròyìn ti fihàn pé wọ́n wà nínú nǹkan bíi ọ̀ọ́dúnrún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí wọ́n gbé lọ káàkiri àwọn iléèwé nípínlẹ̀ náà báyìí.", "timestamp": "2021-03-08T04:24:14Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/43776776", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní ẹsẹ̀ òsì ní ọta ìbọn náà ti bàá tí wọ́n sì ti gbé e lọ sí iléèwòsàn ńlá Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà lágbègbè Owode ní ìlú Ọ̀yọ́.", "timestamp": "2021-03-07T01:54:18Z", "url": "http://iroyinowuro.com.ng/2021/01/04/o%E1%B9%A3i%E1%B9%A3e-amotekun-kan-yinbon-fun-olopaa-niluu-oyo/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Kò yẹ ki ìjọba àpàpọ lágbára lóri ìjọbá ìpínlẹ̀ nígbà ti wọn dé, èyí si ni ó gba àgbà lọ́wọ́ àwọn gómìnà ìpínlẹ̀, àti pé ìjọba kò ti ṣe òun ti ó tọ, ti wọ̀n ò bá pàdà sí ìgbà ti àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ ba ní akoso ohun to tọ si wọn, láti fí mú ìdàgbàsóke bá ìpínlẹ̀ wọ́n láì kọ́kọ́ lọ si Abuja.", "timestamp": "2021-03-06T02:38:34Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2019/06/nadeco-ni-dandan-ni-ki-ajo-inec-kede.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Seyi Makinde, gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti lu gbẹ́dẹ àrùn kòkòrò apanirun Coronavirus ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Gómìnà náà fi ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun náà lédè lórí ẹ̀rọ alátagbà rẹ̀, ìyẹn Twitter ní ọjọ́ ajé. Gómìnà náà wá rọ àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wípé kí wọ́n tẹ́lẹ̀ gbogbo ìlànà tí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera […]", "timestamp": "2021-03-05T04:04:25Z", "url": "https://ybtcnewsyoruba.com.ng/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn àgbà ọjẹ òṣèré tíátà kan nílẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n fi iṣẹ oojọ tí wọn yan láàyò lé ọmọ bibi wọn lọ́wọ́ láti jogún rẹ.\nBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ àwọn àgbà òṣèré tíátà náà tí jáde láyé, tí àwọn míràn nínú wọn sì wà lókè eepẹ, síbẹ̀ àwọn ọmọ tí wọn fi iṣẹ lé lọ́wọ́, sì ń ṣe ilédè lọ lẹ́yìn wọn lagbo tíátà.", "timestamp": "2021-03-05T19:23:13Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/eyi-l-gbajugbaja-osere-tiata-ti-won.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ọkùnrin náà là gbọ pé ó tún kọ àwọn èèyàn làwọn nnkan ti wọn lé ṣe lórí ààbò ara wọn, àti pàápàá bo tún ṣe sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí wá káàkiri láti dáàbò bo èmi àti dúkìá tó jẹ́ wọn lógún.", "timestamp": "2021-03-05T20:30:31Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/ikolu-awon-adigunjale-oga-vgn-n-ogun-f.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Odùduwà ó kúrò láyé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbrẹ̀ ni wọ́n tinfún ká orílẹ̀ kúrò ní Ifẹ̀, tí wọ́n sìbti lààmì -laaka kákiri ìletò tiiwọn nàà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni wọ́n ti dá ìjọba tiwón náà kalẹ̀ nílú tí àwọn náàbtẹ̀dó sí gẹ́gẹ bí Ọba, tí wọ́n sì ń fi yé àwọn ọmọ tiwọn náà wípé Ile-Ife ni àwọn ti wá", "timestamp": "2021-02-26T10:38:12Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Oduduwa", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "O ni àwọn ọdọ tí kò din ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n láàárín ọdún sì àsìkò yìí, tó sì ni ẹgbẹ̀rún méjì ni wọn yóò kọ́kọ́ jẹ́ àǹfààní náà, tí wọn yóò sì gba iwe ẹ̀rí.", "timestamp": "2021-03-05T03:25:07Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/igbadun-repete-f-odo-egberun-l-ogbon-ni.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "- Àǹfààní: Ó lè tètè ṣe àwárí oyún ju àyèwò ìtọ̀ lọ àti wípé ìgbàmíràn ó le sọ ọ̀sẹ̀ tí oyún náà jẹ́ (tí ó bá jẹ́ ti iye)", "timestamp": "2021-02-28T18:20:02Z", "url": "https://safe2choose.org/yo/isirooyun/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àjọ tó n mójútó ètò ìlera ní àgbáyé, WHO, ní wọ́n fi ilé ìwòsàn ti wọn ti n gba itọju sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ní àwọn gbọdọ̀ gbé wọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì.\nWHO ní àwọn ẹbí àwọn aláìsàn nà wá sí ibùdó ìtọ́jú ọ̀hún, tó jẹ́ ti àjọ aláànú, Medecins Sans Frontieres, tí wọ́n sì ní kí wọ́n yọ̀ǹda àwọn ènìyàn wọn fún wọn, kí àwọn le gbé wọn lọ fún ètò àdúrà, tí wọ́n sì gbé wọn lọ lórí ọkàdà.\nNí báyìí, wọ́n tí n ṣọ́ àwọn ẹbí àwọn aláìsàn mẹ́tẹ̀ẹ́ta, tí díẹ̀ lára wọn sì ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí Ebola.\nỌjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kárùn, ni àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn ará ìlú ní abẹ́rẹ́ àjẹsára, láti dá ìtànkálẹ̀ àìsàn náà dúró.", "timestamp": "2021-02-28T01:07:55Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/afrika-44235906", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àjọ UNICEF ní pé bó tilẹ̀ jẹ pé àwọn ò sinmi, sùgbọ́n àwọn ọmọde ní Nàìjíríà kò sì tii ní ẹ̀tọ́ sí ètò ìlera, oúnjẹ, ètò ẹ̀kọ́ àtí àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn.\nỌmọ ọdún mejì yìí kò dé iléèwé rí, àmọ́ ó mọ olú ìlú orílẹ̀-èdè ogójì àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mii tó wà láyé.", "timestamp": "2021-02-27T20:11:08Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/afrika-48419775", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn tí ẹ ń wo yìí lọ́wọ́ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tún ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ. Lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọn dá wàhálà silẹ, tí wọn sì tún ń lo àǹfààní ẹ láti ja àwọn èèyàn lólè ni wọ̀nyí.", "timestamp": "2021-03-08T15:42:23Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/awon-omo-egbe-okunkun-mi-in-tun-wo-gau-n.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Káyọ̀dé Alabi tó tún jẹ́ alága igbimọ COVID-19 nibi tó ti ń báwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ àwọn Haúsá náà sọ̀rọ̀ tún sọ pé àwọn tó ní aarun náà tí wọn ń rí lásìkò yìí ni wón kíi ṣe ọmọ-onilu, bí kò ṣe àwọn àlejò tí wọn ń wọlé wá.\nNibẹ lo tí rọ àwọn igbimọ náà wí pé kí wọn sọ fún gbogbo àwọn èèyàn wọn níbikíbi tí wọn ba wa, tí wọn ń gbèrò láti wa jókòó síbi tí wọn ba wa nítorí pé kò saaye rárá.", "timestamp": "2021-03-08T00:40:43Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/nnkan-de-alejo-to-ba-wo-kwara-yoo-ru.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Kété tí wọn sọ fún ohun àti ọkọ rẹ pé ọmọ mẹta lo bí ní ẹkan náà, inu wọn bàjé, wọn sì bu sekun, iporuru gba ọkàn wọn nítorí pé wọn etaoko sí nkan abàmì ni ìlú wọn, ẹni èyí tó jẹ́ wípé wọn a ìkan nínú àwọn ọmọ náà fún ẹbọ.\nṢùgbọ́n ìtàn fi yẹ wá pé gbogbo àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú pípa ọkàn lára àwọn ọmọ náà o kije tí wọn fi ta téru ni pa.\nLẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti parí ẹ̀kọ́, ẹ̀gbọ́n baba rẹ lọ fi sì ẹnu ẹ̀kọ́ ìṣe aṣọ ríran, ó sì kó ìṣe náà fún ọdún mẹsan kí ó tó gbà òmìnira.\nkí ó sì tó kúrò ní orílè èdè Kamẹrúùnù ó ṣe ẹ dá ìwé tí yíò ma ko orúkọ àwọn ènìyàn sì tí ó pe orúkọ rẹ ni alàjọ sómólú ojojumo.\nṢùgbọ́n kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ó lọ fi lọ ẹ̀gbọ́n bàbá tí ó sí sọ pé kí ó má ṣe látàrí àwọn tí ó ti ṣe sẹ́yìn tó jẹ́ wípé gbèsè ni wọn jẹ bo, kò gbo ohun tí ẹni yí sọ, ó tún lọ sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin, ẹ̀gbọ́n rẹ yí ni ó mú lọ sí odò olùṣọ́àgùntàn tí wọn sì gba àdúrà tí wọn sì ni ọ̀nà rẹ ni kí má ṣe ṣùgbọ́n wọn kii ni lọọ pé kí ó má fi òtítọ́ inú ṣe.\nNígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ó lọ sí odò àwọn ìyá l’oja gbogbo àwọn ó sì dá lóhùn wọn wípé tí yíò kowó àwọn sá lọ tí ó bá yá, ṣùgbọ́n baba alàjọ sómólú kò ko irewasì ọkàn, nígbà tí ó yá àwọn ìyá l’oja bá fi owó àwọn ọmọ wọn dán wò lèyí tí òsì yege láti ìgbà náà ni wọn ti dá àjọ fún.\nBàbá gba àjọ fún bíi ogun ọdún, àgbà dee bàbá ó sile jáde lọ gba àjọ mọ ṣùgbọ́n àwọn oní baara tí ó nífẹ̀ẹ́ bàbá má ń mú owó àjọ wọn wá sí ilé, bàbá kọ ìyàwó ọmọ rẹ bí wọn ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà, tí ó sì jẹ pé òhun náà lọ má ń gba àjọ lọ́wọ́ àwọn ni baara wọn.", "timestamp": "2021-03-07T11:34:15Z", "url": "https://edeyorubarewa.com/itan-baba-alajo-somolu/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "16Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.\n22Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn. 23Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). 24Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” 25Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. 26Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.", "timestamp": "2021-02-26T01:18:54Z", "url": "https://www.biblica.com/bible/niv/judges/1/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Odù Ifá pín sí ojú odù igba ó lé Mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (256) nígbà tì àwọn ojú odù wọ̀nyí náà pín sí ọ̀nà mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ oríṣiríṣi bíi: ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìmọ̀ ní bí ayé ṣe wà, ìmọ̀ ìṣègùn, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Odù ifá àti àwọn ẹ̀sẹ̀ ifá tí wọ́n pín sí tún dá lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ayé, òdodo, tí ó kún fọ́fọ́ fún àlàyé níoa àyànmọ́ ẹ̀dá òun ọ̀nà ibùlà fún ọmọ adáríhurun. Bákan náà ló tún jẹ́ ìmọ̀ ọ̀nà ìwádìí tí Elédùà yọ̀nda fú Ọ̀rúnmìlà baba Àgbọnìrègún láti fi ṣọmọ aráyé lóore. Àwọn odù Idá wọ̀nyí dà bí ojúpọ̀nà tí ọmọ ènìyàn lè gbà láti rí àyànmọ́ wọn lò ní kíkún, nípa bì àwọn Babaláwo tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ ifá bá ṣe ṣàlàyé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú Odù tì ó bá yọ fún ẹni abdífá fún gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rúnmìlà tí ó jẹ́ Babaláwo àkọọ́kọ́ ṣe làá kalẹ̀.", "timestamp": "2021-03-03T08:39:08Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/Od%C3%B9_If%C3%A1", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Pẹ̀lú àwọn àìṣedéédéé wọ̀nyí, ìmọ̀-ẹ̀rọ ti ṣe ìrànwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lórí àwọn gbàgede orí ayélujára, tí ó ti mú ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun wáyé. Èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti gòkè àgbà látàrí àwọn lílo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tuntun bí i ẹ̀rọ-ìléwọ́ àti ẹ̀rọ ọpọ́n ayárabíàṣá, tí ó sì ń bí àwọn gbólóhùn tuntun tí a fi ń pe àwọn irinṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tuntun wọ̀nyí. Èyí sì ti fẹ bí a ti ṣe ń lo àwọn èdè wọ̀nyí lójú.\nÀwọn ìpèníjà t'ó tara ìmọ̀-ẹ̀rọ wá yìí ni yóò mú ìdàgbàsókè bá èdè — ó máa ń fa àròjìnlẹ̀ fún ìgbéga èdè àti ìmọ̀-ẹ̀rọ.", "timestamp": "2021-03-02T01:17:30Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2020/03/11/621/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ní orí Twitter, Ezekwesili mú ìbànújẹ́ rẹ̀ wá sí ìrántí: “Ẹ̀dùn ọkàn ni fún mi pé àwọn ọmọdé tí a rán nílé ìwé di pípa bí ẹran dé ibi wí pé àwọn òbí wọn kò lè dá àwọn ọmọ wọn mọ̀.”\nÀìfiyèsí àwọn tí ó farapa yóò túbọ̀ jẹ́ kí àṣà ìfipábánilòpọ̀ àti ìyọlẹ́nu ó gbilẹ̀ sí i, tí ó sì di “kò tán ń dìí ‘ẹ” fún àwọn tí ń jìyà ìpalára tí ó gbóyá láti sọ ìrírí tí ó ń pààrà ọkàn wọn síta. Gbogbo wa ni a mọ bí àwọn tí ó farapa ní Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí ṣe máa ń gba ẹ̀bi.", "timestamp": "2021-03-02T02:17:39Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2020/06/09/740/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ilẹ̀ Nàijírìa lóti wá lára àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n ti jàjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àrùn polio pẹ̀lú àwọn àkọlé èyí tí wọ́n tíì tò sí tije ìtẹ́wọ́gbà lájọ agbègbè ilẹ̀ adúláwọ̀ tón sisẹ́ láti fòpin sí àrùn polio.", "timestamp": "2021-02-25T12:57:24Z", "url": "https://radionigeriaibadan.gov.ng/2020/06/19/orile-ede-naijiria-ti-kuro-lawujo-awon-ti-won-ni-arun-romolapa-romo-lese-w-h-o/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó, Arákùnrin Akeredolu, ní ọjọ́ àìkú, ni ó hún yọ àwọn Gómìnà akegbẹ́ rẹ̀ púrò nínú ẹ̀sùn tí àwọn ará ìlú wón fi kàn wón wípé wọ́n gbé àwọn oúnjẹ tí ó yẹ kí wọn pín lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn kòrona pamọ ní ìpínlè wọn.\nAkeredolu, ẹni tí ó jẹ́ alága àjọ àwọn gómìnà ni gúúsù-iwoorùn, ni ó sọ pé ohun tí ó fa ìdádúro pínpín àwọn oúnjẹ náà ni pé àwọn Ìpínlẹ̀ kò tètè ríi gbà.", "timestamp": "2021-02-25T07:28:26Z", "url": "https://affairstv.com/2020/11/01/awon-gomina-ko-ko-awon-ounje-ti-o-ye-ki-won-pin-lasiko-ajakale-aarun-korona-pamo-akeredolu/?shared=email&msg=fail", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "1Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. 2Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, 3Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.\n7Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti. 8Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. 9Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ.", "timestamp": "2021-02-26T01:32:35Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/bds/gen%C3%A8se/50/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn ní ṣe làwọn ọlọ́pàá ipinlẹ Èkó dá àwọn dọkita láàmú, pàápàá àwọn tó ń ṣe ìtọ́jú àwọn tó ń ní àrùn Covid-19, ìyẹn Koronafairọọsi.\nÓ làwọn kò lè là ojú silẹ káwọn ọlọ́pàá máa fìyà jẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn lọ́nà aitọ, àti pé àwọn kò lè gbà kí wọn máa ṣíṣẹ lai si eto ààbò tó péye fún wọn.", "timestamp": "2021-03-03T12:07:30Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/idaamu-nla-tun-de-ba-sanwo-olu-nitori.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìwé náà tí akọwe àgbà ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹwọ lo sọ pé kí àjọ WHO lọ máa palẹmọ ẹrú wọn kò too tó ọjọ́ kẹfà oṣù kejila ọdún 2021 tí wọn yóò fi ilẹ̀ náà silẹ pátápátá.", "timestamp": "2021-03-01T22:21:07Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/07/trump-le-ajo-who-kuro-l.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ọ̀gá àgbà Àjọ náà nípìnlẹ̀ náà, Ajagunfẹ̀yìntì Olayanju sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Kínní, ọdún 2021 ni àwọn ọ̀dọ́ yìí kọlu àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà ní Agọ-Arẹ lásìkò tí wọ́n ń rin ìrìnàjò lọ sí ìlú Tede.\nÓ ní wọn kò bá wàhálà kankan pàdé nílùú Agọ-Arẹ, wọ́n jẹ́ kí wọ́n ó kọjá lẹ́yìn tí wọ́n sọ pé ìjọba ìbílẹ̀ Ìtẹ̀síwájú ni àwọn ti wá fún iṣẹ́ àkànṣe.", "timestamp": "2021-03-04T16:35:22Z", "url": "http://iroyinowuro.com.ng/2021/01/26/awon-odo-kolu-awon-o%E1%B9%A3i%E1%B9%A3e-amotekun-ni-tede/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Nagogo ni bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò rí ẹnì kankan mú nínú wọn, ṣùgbọ́n tó ní oríṣiríṣi ohun ìbẹ̀rù lo kún inú ilé wọn náà, èyí tó làwọn rí nnkan bí ìgbà tó kún fún ẹ̀jẹ̀, orí òkú gbígbẹ, aṣọ àti ìwé tí wọn kọ orúkọ àwọn àgbà olóṣèlú sì.", "timestamp": "2021-03-08T00:51:30Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/aye-gbege-o-won-ba-oruko-awon-agba.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Bẹẹ lo sọ pé ó ṣe pàtàkì fáwọn òṣìṣẹ́ láti lè lo àwọn irinṣẹ ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí láti máa fi ṣíṣẹ láti ilé wọn lai jẹ pe wọn lọ sibiṣẹ.", "timestamp": "2021-03-08T15:30:44Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/05/iyalenu-nla-gomina-abdulrazaq-kopa-ninu.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Gẹ́gẹ́ bí àlejò orí Twitter, àwọn akópa ìpolongo náà á sọ̀rọ̀ nípa àfojúsùn wọn àti ihà tí wọ́n kọ sí èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀, pẹ̀lú ìtàn wọn, ìlò wọn lórí ayélujára àti ojú ayé, ìdojúkọ wọn àti àwọn ìlànà àmúlò tuntun tí wọ́n ní fún ìgbéǹde èdè náà. Bí ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣe ń kó ipa pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ń ṣe ìdènà fún pàtàkì àwọn èdè abínibí.\nJọ̀wọ́ ṣe àyẹ̀wò ètò ìsàlẹ̀ yìí fún àwọn tí ó ti darapọ̀ mọ́ wa láti sọ̀rọ̀ nípa ìtàn-an wọn. À ń gbèrò láti ní àkọsílẹ̀ búlọ́ọ̀gù kúkúrú nípa àwọn “àlejò” náà lọ́kọ̀ọ̀kan.", "timestamp": "2021-03-02T01:30:04Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2019/03/19/310/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ó sì lè ṣẹ́ oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mọ́kànlá pẹ̀lú òògùn ìṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó láìsí ewu, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wà tí a gbọ́dọ̀ ro.\nOyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ yọ lára àwọn obìnrin. Ẹ̀jẹ̀ yìí lè pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ, ẹ̀jẹ̀ dídì sì lè wà níbẹ̀. Ó ṣeéṣe kí àwọn tí oyún wọn bá wà láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mọ́kànlá rí ohun tí wọn ò dá mọ̀, tàbí tí ó jọ awọ kékeré. Eléyìí ò kí ń ṣe nǹkan èèmọ̀, má ṣe jáyà. Ara àwọn àmì pé oyún náà ti ń wálẹ̀ bí ó ṣe yẹ ní. O lè da ẹ̀jẹ̀ dídì tàbí awọ náà sí inú ilé ìgbọ̀nsẹ̀, bíi nǹkan oṣù. Tí òfin bá lòdì sí oyún ṣíṣẹ́ ní agbègbè rẹ, sọra tí o bá fẹ́ sọ àwọn ohun tí àwọn ènìyàn lè dámọ̀ nù. Má sì ṣe sọ ọ́ sí ibi tí àwọn ènìyàn yóò ti ríi.", "timestamp": "2021-03-07T08:45:28Z", "url": "https://www.howtouseabortionpill.org/yo/abortion-pill-between-10-and-11-weeks/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìlú ń ké pe àwọn ọmọ rẹ̀ (àwọn ọmọ ìlú) láti dojú ìjà kọ ìwà elẹ́yàmẹyà àti ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní Russia òde-òní. Jẹ́ kí ìpèe rẹ̀ ta ọ́ jí!", "timestamp": "2021-03-02T02:16:57Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2019/02/08/206/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ó ní lóòótọ́ Ìjọba ń fi àwọn lọ́kàn balẹ̀ pé Sunday Igboho kò ní leè ṣe ohun tó wí síbẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn tó bá mọ̀ ọ́n làwọn ń bẹ̀ báyìí ki wọ́n bá àwọn pẹ̀tù síi nínú kí wọ́n sì le jókòó ṣọ̀rọ̀ náà ní ìtùbí ìnùbí.\nÓ ní àwọn kò palẹ̀mọ́ ẹrù kankan mọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn kò tilẹ̀ mọ ibi tí àwọn leè doríkọ nítorí pé agbègbè náà ni gbogbo àwọn mọ̀ ní ilé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ wọn ti gbé níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.", "timestamp": "2021-03-07T02:31:19Z", "url": "http://iroyinowuro.com.ng/2021/01/21/seriki-fulani-ke-gbajare-e-dakun-e-bawa-be-sunday-igboho/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara ní awá ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyé, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àtí àwọn ẹmí búburú ní ojú ọrun.", "timestamp": "2021-02-28T04:16:41Z", "url": "https://www.beblia.com/pages/search.aspx?Language=Yoruba2014&SearchType=Contains&Context=No&SearchBooks=%2C67%2C&SearchTerm=%E1%BB%8Crun&DLang=Yoruba2014&Book=40&Chapter=1", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Nínú ilé rẹ̀ níbi tí òun àti àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti jọ wo ìkéde náà lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì, n'íṣe ni àyọ̀ wọn kún.\nNínú ọrọ tirẹ, gómìnà Ibikunle Amosun ti ìpínlẹ̀ Ògùn ní ìdìbò yìí ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ tí àwọn ará ìlú ní nínú ẹgbẹ́ APC. Ó ní pẹ̀lú ìjáwé olúborí yìí, ẹgbẹ́ náà ti wá fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní àwon ìpínlẹ̀ tó wà ní Gúúsù ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.", "timestamp": "2021-03-07T19:16:08Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/afrika-44837784", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn irinṣẹ́ tí a n lò ní ilé-ìwòsàn pẹ̀lú lè fa àìsàn hepatitis C, àwọn bí i: abẹ́rẹ́ àti ọ̀pá-abẹ́rẹ́ tí-a-tún-lò, ìgò òògùn alájùmọ̀lò, àwọn garawa fún pípo òògùn, àti àwọn irin iṣẹ́ fún iṣẹ́–abẹ tí a kò bọ̀ ní omi gbígbóná.[11] Àwọn ohun-èlò iṣẹ́ ìlera àti ìtọ́jú-eyín ni n fa ọ̀pọ̀ títàn ka àìsàn HCV ní orílẹ̀-èdè Egypt, orílẹ̀-èdè náà tí àìsàn náà ti wọ́ pọ̀ jùlọ ní àgbáyé.[22]", "timestamp": "2021-03-02T14:06:22Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/J%E1%BA%B9%CC%80d%E1%BB%8D%CC%80j%E1%BA%B9%CC%80d%E1%BB%8D%CC%80_C", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Wọn ní Logun tí ń rí àwọn àpẹẹrẹ àrùn yìí lára rẹ, èyí tó mú kó kan sáwọn eleto ìlera fún àyẹ̀wò lọsẹ tó kọjá, tí wọn sì ṣeé fún un.", "timestamp": "2021-03-01T22:55:47Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/07/o-ma-se-o-arun-koronafairoosi-tun-pa.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìjọba àpapọ̀ sọ pé gbogbo àwọn irẹsi náà lo wá nibamu láti jẹ, tí kò sì ní ìpalára tí yoo ṣe fún agọ ara àwọn aráàlú tó bá jẹ́ ẹ.", "timestamp": "2021-03-08T16:59:54Z", "url": "https://www.awikonko.com.ng/2020/04/e-tun-gbo-nnkan-t-apapo-so-l-iresi-ti.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Ìfẹ́ Orílẹ́-èdè Ẹni jẹ́ aáyan ìfọkànsìn láti fìfẹ́hàn fún orílẹ̀-èdè ẹni ní ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìlú tí ìṣẹ̀dá wọn jọra. Èyí lè jẹ́ àpapọ̀ orísìírísìí àdámọ́ tó jẹ mọ́ ìlú ẹni; lára wọn ni ẹ̀yà, àṣà, ètò-òṣèlú tàbí ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀. Ó jẹ́ àkójọpò ìmọ̀ tó sunmo ìgbórílẹ̀-èdè ẹni ga (nationalism).[1][2][3]", "timestamp": "2021-02-26T19:15:57Z", "url": "https://yo.wikipedia.org/wiki/%C3%8Cf%E1%BA%B9%CC%81_Or%C3%ADl%E1%BA%B9%CC%81-%C3%A8d%C3%A8_%E1%BA%B8ni", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Díaz jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn àti a-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọ ènìyàn tí ó jẹ́ ògbólógbòó ajàfúnẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n sì mọ ìṣe rẹ̀ fún un l'órílẹ̀ èdè Venezuela àti òkè òkun fún ìdásọ́rọ̀ àti ìtakò ìjọba Nicholas Maduro. Ó ti tó ìgbà díẹ̀ kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti olùdásọ́rọ̀ òṣèlú tí ó gbajúmọ̀ n nì, Naky Soto, tí wọn sì ń ṣe ìgbéjáde àwọn fídíò àti ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ayélujára èyí tí ó dá lórí ìṣèlú àti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní Venezuela. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ́ni àti olùgbé-lárúgẹ ìdásílẹ̀ àyè ọ̀tọ̀ fún àwọn ará ìlú àti àwọn àkànṣe eto ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ tí kò lọ́wọ́ ìjọ̀ba nínú. Díaz tún jẹ́ olùkópa nínú ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé fún ọdún mẹ́wàá.", "timestamp": "2021-03-02T01:57:34Z", "url": "https://yo.globalvoices.org/2019/03/13/303/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "5Abrahamu sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Isaaki. 6Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn.", "timestamp": "2021-03-08T01:02:09Z", "url": "https://www.biblica.com/america-latina/biblia/biblia-online/tncv/%E0%B8%9B%E0%B8%90%E0%B8%A1%E0%B8%81%E0%B8%B2%E0%B8%A5/25/ycb/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lámì ẹ̀yẹ torí àtúnṣe ńlá tí wọ́n ṣe síbi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà, tí wọ́n sì pàtẹ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àṣà ìbílẹ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Bòlífíà.", "timestamp": "2021-02-26T15:12:37Z", "url": "https://ebv.vanitymania.it/iwe-ogun-ibile.html", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Previous article Ilé ìjọsìn Celestial ń béèrè fún ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọdé mẹ́ta tí bàbá wọn àti ìyàwó rè ń fi ìyà jẹ nítorí ìyá wọn ti kú.", "timestamp": "2021-02-26T16:13:47Z", "url": "https://iroyinowuro.com.ng/2019/06/27/igbakeji-aare-yemi-osinbajo-lo-ki-igbakeji-aare-orile-ede-america-mike-pence/", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Mínísítà ní ìwádìí sì n lọ lọ́wọ́ láti mọ ẹni tó wa ọkọ̀ òfurufú náà àti àwọn òṣìṣẹ́ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ nílùú Eko àti ilú Abuja nígbà ti ọkọ̀ náà gbéra nílùú Eko àti ìgbà tó balẹ̀ ní Abuja", "timestamp": "2021-02-25T15:16:38Z", "url": "https://www.bbc.com/yoruba/48350841", "source": "OSCAR-2109"}
{"text": "Àwọn Yorùbá ní ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe ìsirọ̀, bẹ́ẹ̀ ní àti ọmọkékeré ní àwọn Yorùbá ti ń kọ́ ọmọ wọn ni ìṣirò ní ṣíṣe. Wọn yóò ni kí ó máa fi ení, èjì kọrin, ṣere bíi", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ààrẹ fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ Òndó ní fásitì nàá, Popoọla Morayọ Samson sọ fún BBC pe ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó ṣèlérí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá láti fi tùwọ́n l'ójú. Ṣùgbọ́n, ó ní àwọn kò fẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nàá, ẹ̀dínwó owó ilé-ìwé l'àwọ́n fẹ́.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Níwọ̀ngbà ọjọ́ diẹ tókù kétò ìdìbò sípò Gómìnà wáyé nípínlẹ̀ Èkìtì, ó ti lé lọ́gọ̀rún àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tíwọ́n ti mú lọ́kanòjọ̀kan ibùdó tó ń bẹ yíká àwọn ìlú àtabúlé nípínlẹ̀ náà.\nọ̀gbẹ́ni Hammed sàlàyé pé, gbogbo àwọn ami dúdú kọ̀ọ̀kan tó wà láwọn ìlú àtàwọn abúlé yíká ìpínlẹ̀ náà láwọn tí sèpalẹ̀mọ́ wọn nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo àwọn àjọ aláábo pátá, káláfìa lè lè ba jọba.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ara àwọn nǹkan tí ó sokùn fa ogun àgbáyé àkọ́kọ́ nìyí Ogun àgbáyé àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ láàárin orílẹ̀-èdè méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Austria-Humgary ati Serbia. Ìlú kékeré kan ní awọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí. Orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ló kọ́kọ́ gba ìlú yìí lọ́wọ́ ẹ̀kẹjì nínú ogun kan tó wáyé ní ọdún 1908. Orílẹ̀-èdè kejì wá ń dún kòkò lajà láti gba ìtú yìí padà. Sáájú àsìkò yìí, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀lẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ṣe gbún-ùn gbùn-ùn gbún-ùn sí ara wọn. Sáájú ogun àgbéyé kìíní, àwọn orílẹ̀-èdè ló máa ń jẹ gàba lórí àwọ́n orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà máà, kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní mú sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ń jà fún òmìnira.\nOrílẹ̀-èdè [Belgium] gba òmìnìra ní ọdún 1830, nígbà tí ilẹ̀ [Germany] gba tiwọn ní 1871. Ìjà òmìnìra wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lólogbó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kọ́kọ́ tako èyí, síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò rí nǹkan ṣe si èyí. Gbogbo àwọn tí wọ́n tí wọ́n ti jẹ́ gàba lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Gbogbo wọn kóra pọ̀. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ sí sẹlẹ̀, àti àwọ́n ìsòro tí ó rọ̀ mọ́ ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtọ̀ sí èyí, wíwá àwọn òyìnbó sí ilẹ̀ aláwò dúdú [Africa] wà lára àwọn nǹkan to sokùnfà ogun àgbáyé kìíní. Owó ló gbé àwọn òyìnbó dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, wọ́n wá ri pé yíò rọrùn fún àwọn láti rí nǹkan àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n ń fẹ́ tí àwọn bá mú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú sìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ìjọ̀ bèrè sí wáyé láàárin wọn lórí orílẹ̀-èdè tí oníkálukú wọn yíò mú sìn. Nígbà tí wọ́n ń pín ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn, bí wọn ṣe pin kò tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kan lọ́rùn lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn nígbà náà Àyọrísí gbogbo wàhálà yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí funra sí ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó nǹkan ijà olóró jọ. Àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn sọ̀rẹ́ láti gbógun ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Nígbà tí ogun yìí yóò fi bẹ̀rẹ̀, awọn orílẹ̀-èdè alágbára pín ara wọn sí ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ẹ̀wẹ̀, ìJọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti fi àìdunú hàn sí bí wọ́n se ńpa àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí ní ìlú òyìnbó láì jìnà síra.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Àwọn adigunjalè náà pa ọlọ́pàá mẹ́fà àti àwọn ará ìlú mẹ́fà níbi ìkọlù sí àwọn ilé ìfowópamọ́ márùń ní ìlú Ọ̀ffà.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó, tó fìdí ìsẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní, wọn kò tíì mọ ẹnití ọkùnrin naa jẹ́ àti ibití ó ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rí ojú ọgbẹ́ ní ara òkú náà.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ìlù Àgẹ̀rẹ̀ jẹ́ ìlù àtijọ́, ìlù àtayébáyé. Nítorí ìró aminlẹ̀ tí ó ní, ìlù àgẹ̀rẹ̀ ni ìlù àwọn ògbójú ọdẹ àtijọ́. Bákannáà, wọ́n máa ńlù ìlù àgẹ̀rẹ̀ nígbàtí ọlóde tàbí onífa tàbí ọba ìlú bá pa ipò dà. Ní àfikún, wọ́n tún máa ńlu ìlù àgẹ̀rẹ̀ fún àwọn ọba àti ìjòyè láti yẹ́ wọn sí.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Owóorí sísan ni ilẹ̀ Nigeria wà ni ìbámu pẹ̀lú ìlànà bi wọn se ń se káàkiri àgbáyé. Étò yìí ni ó fi àǹfààní sílẹ̀ fun ìdàgbàsòkè, nibi ti àwọn tó ń gba owó osù gọbọi yóò san owóorí wọn gẹ́gẹ́ bí owo tí wọn ń gbà ni gbogbo àkókò supgbọ́n tó jẹ́ wí pé ọ̀pọ̀ àwọn onísẹ́ àdáni, àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ ati àwọn ilé isẹ́ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan kìí san owóorí wọn déédé látàrí bí àwọn tó wà ní ẹ̀ka owóorí gbígbà kò se mọ iye tó ń wọlé sí àpò irú àwọn ènìyàn wọ̀nyìí.\nỌ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ ni kò ni òsìsẹ́ to lati mọ àkọsílẹ̀ nipa iye àwọn ènìyàn to ń san owóorí ni ìpínlẹ̀ wọn.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ogun Ẹkú dédé àsìkò yìí ẹ̀yin ọmọ ogun. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́kí á tún bọ̀ sọwọ́pọ̀ láti gbé ògo ilẹ̀ Yorùbá ga.Inù mi dùn púpọ̀ sí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀ẹ̀tí kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá yálà nílẹ̀ Yorùbá tàbí ní òkè òkun bá lè bẹ̀rẹ̀ láti máa kọ́ ọ̀pọlọ̀pọ̀ nínú àwọn àròkọ wọn ní èdè abínibí wà nítorí òní kọ́ àmọ́ nítorí ọjọ́ ọ̀la kí àwọn ọmọ tí wọn kò ì tíì bí lè rí nnkan kà nípa gbogbo ohun mère mère tí ó n sẹlẹ̀ jákè jádò àgbáyé.\nTí a bá wo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sì ní máa gbérí níwọ̀n ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn a ri wí pé púpọ̀ nínú wọn ni wọn fi èdè abínibí kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ́n, kòsí iṣẹ́ìwádìí kan tí wọ́n se tí wọ́n kò kọ ní èdè wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé èdè gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n gbà fi se ìwádìí náà. Ó seni láànu láti máa pàdé àwọn ara ilé nílu òyìnbó kí wọ́n máa fara pamọ́ ki a máà ba pè wọ́n ní ọmọ Yorùbá.Ogún lọ́gọ̀ àwọn olùkọ́ni nílu òyìnbó ni wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá sùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo akitiyan wọn kò sí ọ̀kan soso nínú isẹ́ ìwádìí wọ́n pẹ̀lú aroko tí ó wà ní èdè Yorùbá- Kí ló dé?", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ìyá àgbà ó gbẹ́yìn nínú àjọọṣepọ̀ láti kọ́ áwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀. Èròǹgbà wọn ni láti ríi wípé Àjàyi àti àwọn ọmọdé ìyókùn ńhu ìwà ọmọlúàbí.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ìwé Àjàyí gbọ́ ìtumọ̀ ìlù jẹ́ ìwé tí a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní fún àkàgbádùn àwọn ọmọdé pẹ̀lú àwọn òbí. Ìwé yǐ fi ìlò èdè àti ẹwà èdè Yorùbá bíi òwe, àṣàyàn ọ̀rọ̀, oríkì àti ìjìlẹ̀ ọ̀rọ̀ hàn. Bákannáà, ìwé yǐ tún fi àṣà àti ìṣe Yorùbá hàn ní ọ̀nà tí ó le rọrùn fún àwọn ọmọdé wa láti tẹ̀lé.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Àjàyí fẹ́ràn àwọn ẹbí rẹ̀, pàá-pàá jùlọ Ìyá àgbà fún ààlọ́ tí wọn máa ńpa nípa ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́.\nÀjàyi bá àwọn òbi rẹ̀ lọ sí ibi ìwúyè ní ìlú Ayépé, ní ibi tí ó ti pàdé àwọn ọmọ ẹ́gbọ́n ìyá rẹ̀, Àdùkẹ́ àti Àdùní. Àyándìran onílù àrà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aríjóyọ̀ sọ ìlù sí wọn ní’bàdí, oyin mọmo, oyin àdò ni!", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ìkìlọ̀: Ibùdó dátà ti jẹ́ títìpàdé fún ìtọ́jú, nípa bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní le fi àwọn àtúnṣe yín pamọ́ lásìkò yìí. Tí ẹ bá fẹ́ ẹ le fi ìkọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú fáìlì ìkọ̀rọ̀ fún ìgbà míràn.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Àwọn fáìlì ìsàlẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ lílò sùgbọ́n wọn kò sí. Àwọn fáìlì láti ibi-àkósí òkèrè le jẹ́ títò síbẹ̀ bótilẹ̀jẹ́pé wọ́n wà. Ìrú àwọn àdájú irọ́ báhun yíò jẹ́ fífagi lé lórí. Láfikún, àwọn ojúewé tí wọ́n ní fáìlì tí kò sí nínú jẹ́ títòjọ sínú Ẹ̀ka:Àwọn ojúewé pẹ̀lú àwọn ìjápọ̀ fáìlì gígé.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Ilé isẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà sọwípé lóòtọ́ ni ìsẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀ sùgbọn ènìyàn mẹ́ta làwọn rí òkú rẹ́ nígbà tí àwọn dé ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà.\nTí a kò bá gbàgbé, ìsẹ̀lẹ̀ yíí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Àarẹ Muhamadu Buhari se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà, tó sì se ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọba àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àsẹ wípé kí wọ́n palẹ̀ àwọn ọlọ́sà mọ́ lágbèègbè náà.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ pé àwọn kò tíì leè sọ bóyá àdó olóró ló bú nílééṣẹ́ ìtoògùn kan ní ìlú Ilé ifẹ̀.\nỌ̀gá ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun sọ pé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò wáyé rí, àwọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun àtúnṣẹ̀ rẹ̀.\nNígbà tí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, Ọláfimíhàn Adéoyè bẹ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù náà ti ṣẹ̀lẹ̀ wò lọ́jọ́ ajé, ó ní àwọn agbófìnró yóò máa ṣètò àbò tó gbópọn fún àwọn aráàlú.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Àwọn agbébọn náà tó máàrún níye nígbà tí wọ́n kọ̀lú àgọ́ ọlọ́pàá náà ní agogo méjì òru ọjọ́ ìṣẹ́gun tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.\nKòsí ẹni tó lè sọ ní pàtó ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣùgbọ́n ìròyìn sọ pé àwọn agbébọn náà gbe ìbọn kan lọ pẹ̀lú àwọn ọta ìbọn.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọpaa Hisbah ṣe sọ, oní nààbì ní àwọn ọmọbinrin yìí, tí wọn sì ń wa àwọn oníbara nínú iṣẹ́ wọn, sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbinrin yìí ló sọ pe, ìdíkan tàbí òmíràn ló gbé àwọn jáde kúrò nílé ní àsìkò ti wọn mú àwọn.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Anguidae jẹ́ orúkọ àwọn ẹbí tí ó tóbi tí ó jẹ́ ti aláǹgbá ti Northern Hemisphere. Àwọn tí ó wà ní ẹgbẹ́ yìí ni àwọn slowworm, alángbá gílásì àti alángbá inú omi, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n pín ẹbí yìí sí àwọn ẹbí mẹ́ta tí ó sì ní àwọn ẹ̀yà mẹ́rìnlé làádọ́rún ní àwọn ìdílé mẹjọ. Wọ́n ní àwọn osteodem tó le ní abẹ́ awọ ara wọn àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwpọn èyà yí ní àwọn ọwọ́ kúkurú tàbí tí kò sí rárá, léyí tí ó jẹ́ kí wọ́n dàbí ejò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òmíràn ní ọwọ́ tó pé.[2]", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}
{"text": "Àwọn olórí ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ti sọfún ìjọba àpapọ̀ pe ko fíì ọ̀rọ̀ owó osù tuntun tí wọ́n fẹ́ ma san fún àwọn òsìsẹ́ falẹ̀, bí kòbá fẹ́ kí àwọn òsìsẹ́ fárígá.", "timestamp": "", "url": "", "source": "OSCAR-2019"}