text
stringlengths
1
44.6M
Tako ìfé-inú Àlàmú, ó rí i pé òun ti ń fi àwòrán nǹkan hàn Làbákẹ́ lọ́nà tààrà àti ẹ̀bùrú.
Àlàmú ń ṣe gbogbo ohun tó ṣeéṣe láti bíi nínú, láti dà á láàmú.
Chutni sọ bí àìsí àtìlẹ́yìn tó késejárí ṣe mú u nira láti jà tako ìwà pálapàla yìí.
Ní Taiwan, àgbékalẹ̀ẹ ọnà alágbára kan tí a gbé sí àárín gbùngbùn Taipei ń ṣe ìrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún-un 1989.
Ẹ dúró dìgbà tí màá sọ ìda rẹ̀ fún yín -- ìdá mọ́kàn-lé-láàdọ́ta (61%).
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nínú rògbòdìyàn àjàkálẹ̀-àrùn ibà Ebola ọdún-un 2018 ní DR Congo, àwọn àyẹ̀wòkan àyẹ̀wòkàn tí a ṣe ní ara àwọn ẹni tí ó ti lu gúdẹ àrùn Ebola "tí ó tẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìwà-ọmọlúwàbí kan" — lábẹ́ ìtọ́nàa Oníṣègùn Muyembe àti ìjọba orílẹ̀-èdèe DR Congo — dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn níkẹyìn.
Wọ́n pa ohùn mọ́ mi lẹ́nu!
Famalay kì í bẹ̀rù láyé láti tì ọ́ lẹ́yìn ní ìgbà gbogbo...
O ní láti tẹ̀lé àwọn ọmọ orílẹ̀-ède South Africa, Zimbabawe, Ghana, Nigeria.
Tí wọn ò bá ní àjọṣepọ̀ tààrà tàbí ànfàní látara àwọn ẹranko náà, wọn ò ní ìdí kankan láti dáábò bò wọ́n.
Síbẹ̀síbẹ̀, mo ti jìyà nítorí ìwà pálapàla yìí.
Ó ti rí ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn Sènábù láti ọ̀kánkán bí wọ́n ṣe ń bọ̀ láti ọjà.
Ayàwòrán náà gba ìpè àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn-in ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí ó túwíìtì àwòrán náà pẹ̀lú wípé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó mú un wálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni CHRD ṣe ti sọ.
Àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe ò ju kí wọ́n ba ti ènìyàn jẹ́.
Ìṣọdẹ-àjẹ́ ṣì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko India
Síbẹ̀, tí a bá ti ọ̀nà ìṣe-àti-àsà wò ó, ó ṣe kókó láti sọ wí pé ìtúmọ̀ ayaba and ọbabìnrin yàtọ̀ síra wọn: Ọbabìnrin túmọ̀ sí "queen" lédè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí ayaba jẹ́ "wife of the king".
Làbákẹ́ padà bẹ̀rẹ̀ si í tún ara rẹ̀ bi.
VPN mìíràn tí ó ní ìlànà ààbò tó yàrá ọ̀tọ̀ lè jẹ́ ti ọ̀daràn.
Làbákẹ́ tú èrò ọkàn rẹ̀, pẹ̀lú ìbínú sín ǹ kan tí ó pè ní àìṣòtítọ́ nínú àníyàn àti fọ ara rẹ̀ mọ́. Inú Àdìó sì dùn.
Pakistan is not only about terrorism and a conservative society there is more to us.
Adẹ́tẹ̀ẹ́ ní òun ò lè fún wàrà, ṣùgbọ́n òún lè yí i dànù.
Á rẹ́rìn-ín músẹ́ jẹ́jẹ́, á máa wojú yín bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀.
Fúnmi lọ́jọ́ méjì sí mẹ́ta.
[Ìsàlẹ̀] Kò tó [lá ti yọ ọ́] nìkan, Ààrẹ tí kò ka nǹkan sí náà gbọdọ̀ jẹ́ yíyọ kúrò nínú ìṣàkósọ gbogbo kí ojú rẹ̀ le wálẹ̀.
Èyí ni ìdí kan pàtàkì tó fi jẹ́ pé ìyá ní ó lọmọ lóòótọ́.
Akọ̀ròyìn Esdras Ndikumana túwíìtì:
Òǹkọ̀wé tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà Adaobi Tricia Nwaubani làdíi rẹ̀ fún àgbáyé lórí ètò ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tí ó jẹ́ àbáṣepọ̀ pẹ̀lú BBC, wípé ìrísíi Trump gẹ́gẹ́ bí "ọkùnrin alágídí" mú kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ènìyàn jù lọ ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ó fẹ́ràn-an rẹ̀ dé góńgó:
Bótilẹ̀jẹ́pé 2FA ń fún ni ní ààbò tó péye fún ìfẹ̀rílàdí, ewu àtìmóde ìṣàmúlòo rẹ le è wáyé, fún àpẹẹrẹ, o kò mọ ibi tí o ṣ'ọwọ́ọ̀ ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ sí tàbí o ti pàdánùu rẹ, tàbí pààrọ̀ ike pélébé SIM rẹ, tàbí rìnrìn àjò sí ìlú mìíràn láì tan ìrìn-káàkiri orí ẹ̀rọọ̀ rẹ.
Ojúlé ìṣàsopọ̀ ẹ̀rọ-ayélujára
Láti wá mọ̀ wí pé a ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni pé tí ẹ bá ṣàfiwée gbogbo ǹkan níbí sí orílẹ̀-ède South Africa, ó kọ̀ funfun ni, nítorí ní orílẹ̀-ède South Africa, ní ọdọọdún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀rìn-dín-nírinwó (300,000) àwọn ìyá tí wọ́n ní kòkòro apa sójà ara ni wọ́n bímọ.
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, kò ní ọkàn láti kojú ìgbáyàsókè ayé àti ìṣòro.
Ní orílẹ̀-èdèe Côte d'Ivoire ní ọjọ́ 6, Oṣù kẹrin, àwọn afẹ̀hónúhàn ti iná bọ ibi àyẹ̀wò àrùn COVID-19 kan, ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni wí pé agbègbè tí èró pọ̀ sí ni wọ́n sọrí ibi àyẹ̀wò náà sí tí kò sì bójúmu.
Bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣì ń dàgbà sókè nínú ìmọ̀ rẹ̀, ó wà káàkiri.
Làbákẹ́ nìkan kọ́ ló dájọ́ rẹ̀ báyìí.
Àwọn alákòóso láǹfààní láti lò o.
Á dáwọ́ dúró díẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ń dáwọ́ dúró pátápátá nígbà tí oorun ti ń kún ojú rẹ̀.
Idà ń wó ilé ara ẹ̀ ó ní òún ń ba àkọ̀ jẹ́.
“Hùn...hùn...” “Àwọn ìdáhùnsi ìmúnibínú ńkọ́?
Tàbí ẹni tí ó mọ̀ nípa ọkọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ – ọkùnrin ni, kó má jẹ̀ ẹ́ obìnrin.
Nígbàkugbà tí Àlàmú bá wọ ilé ìtọ̀, Làbáké náà ádúró nítòsí, á máa yọjú láti ibi ihò kọ́kọ́rọ́ ilèkùn ilé ìtọ̀.
“Bẹ́ẹ̀ ni…….bẹ́ẹ̀ ni. Mo mọ̀ pé ìwọ ni Àlàmú ……..ṣùgbọ́n…….ṣùgbọ́n.”
Fún ìdí èyí, ó tó kí ó kúkú bẹ̀rẹ̀ sí i rẹ́rìn- ín músẹ́ láti ìsìnyí nínú ìrètí áti ìgbàgbọ́ pé gbogbo nǹkan a sìse fún rere.
Aaka ò gbé ọ̀dàn; igbó ní ń gbé.
Màá jókòó báyìí, á bá mi lórí ìjókòó báyìí...mo ń dúró...mò ń dúró...
Apá ibẹ̀ nínú ìlú ni Làbákẹ́ ṣe àbẹ̀wò sí nígbà tó kọ́kọ́ dé láti ìlú òyìnbó.
Àárín gbùngbùn Àríwá, Àríwá Ìlà-oòrùn, Àríwá Ìwọ̀-oòrùn, Àjìǹdò-gúúsù, Ìwọ̀-oòrùn gúúsù, àti Ìlà-oòrùnun gúúsù.
Kò sí nǹkan tí wọn ó le ṣe tí òfin àti àsẹ bá dàrú.
Nítorí orílẹ̀ èdèe tí ó gbajúmọ̀ jù lọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ yóò yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ sí ìjọba ìfipámúnisìn ní kété tí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bá di títẹ̀ bọlẹ̀.
Àpò Àlàmú ń jò gidigidi, ìparí oṣù sì ń jẹ́ àsìkò fún un láti làágùn tútù, ó jẹ́ àsìkò fún un láti lejú kí ó sì ranjú bí ó ṣe ń wo ètò ìṣúná owó rẹ̀ lésẹẹsẹ̀.
Kò gba àyà rẹ̀ ní ìṣéju mẹ́ta láti bẹ̀rẹ̀ si í mí.
Ó yára fi òpin sí ìpè náà.
Dídúró sílé yìí kì í se ohun tó bá àwọn onísẹ́ ọwọ́ àti oníṣẹ́ ìgbẹ́mìíró tí ó ń gbé ní Mozambique àti Cape Verde lára mú rárá. Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ-ènìyàn Tomás Queface túwíìtì:
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn tí ò sí ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba Novaya Gazeta ti ṣe sọ, ó yẹ kí ètò náà tí yóò ṣe àfihàn àwọn ajìjàǹgbara LGBT ní Yaroslavl wáyé ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú 23, ní oṣù Ṣẹẹrẹ.
Mo ní, "Ǹjẹ́ o dárúkọ kùkúyè?
Ǹkan tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ mọ̀ nípa àwọn ọmọọ̀ yín.
Ní ìparí ọdún 2015, ọlọ́pàá pa òǹyàwòrán Christophe Nkezabahizi pẹ̀lú àwọn ọmọ-lẹ́bí mẹ́ta, ní àsìkò ìbò tí ìfẹ̀hónú wá sáyé.
Làbákẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ gbé kẹ́tùlù nílẹ̀... Oníkálukú sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ!
Ilẹ̀kùn náà ṣí yàrá náà sì kún fún àwọn ìyá, àwọn ìyá tí wọ́n lọ́mọ lọ́wọ́, tí wọ́n jókòó, tí wọ́n ń sọ́rọ̀, tí wọ́n ń tẹ́tí.
Ẹ̀gbẹ́ alájòótà yìí ti tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin abala 505(a) tí ó ní wípé ọ̀daràn ni ẹni tí ó bá polongo ọ̀rọ̀, àyesọ, tàbí jábọ̀ irúu rẹ̀ pẹ̀lú èrò láti mú kí ikọ̀ ajagun ó máà ka ojúṣe rẹ̀ kún tàbí kùnà láti ṣe ojúṣee rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀, kò sí àní-àní, kò sí àní-àní, ó ní láti ṣe é.
Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn – Yẹmí Ọṣìńbàjò (APC), ọmọ Yoruba, àti Peter Obi (PDP), ọmọ Igbo, jẹ́ Ọmọ-lẹ́yìn-in-krístì — àmọ́ láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ikọ̀ ẹ kú oríire!
Àwọn aláboyún tí wọ́n ní kòkòro apa sójà ara gbọ́dọ̀ gba iṣẹ́ PMTCT láti lè ní àwọn ìkókó tí ò ní kòkòro apa sójà ara.
Àwọn alátìlẹ́yìn-in rẹ̀ ń pè fún ìtúsílẹ̀ẹ rẹ̀ lóríi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, látàrí wípé a ti yọ àbọ̀ ẹ̀dọ rẹ̀ nítorí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn àti ìṣòro kíndìnrín.
Ó lèbínú tàpa sáṣẹ. Ó mọ bí wọ́n ṣe ń fi ojú pípọ́n hàn kí ó sì fi ẹ̀rín ṣẹ̀sín ènìyàn.
Ó yẹ kí a tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé tàbí kọ ọ́ sílẹ̀ kí a máa gbé e kiri.
Ìjìyà yóò wá sópin
Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó dára, ilé àdágbé tiwọn ní ìgbèríko ìlú, lọ́nà to yára kíá kíá.
Màdáámù ti ń kanra ganan lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Ìràwọ̀ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Ivory Coast Didier Drogba túwíìtì:
1. Ó gbọdọ̀ ṣe é jó sí, síbẹ̀ ó ní láti dùn ún ní etí àwọn ènìyàn tí yóò “mú wọn gbàgbé ara” ní orí ìtàgé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin tí yóò mú ayọ̀ jáde, èyí tí a mọ Ijó ìta-gbangba mọ́.
"I Have a Red in My Wipe" clip tẹ́lẹ̀.
Boniface Igbeneghu, ọ̀jọ̀gbọ́n Ifásitìi Èkó, Nàìjíríà ti bá ẹni tí ó wọ ìbòjú yìí ṣe erée gélé ní àìmọye ìgbà (Àwòrán láti BBC #SexForGrades)
" Ó kàn sí mi lẹ́yìn òsẹ̀ méjì pẹ̀lú ìwé yìí: ìdókówò mi àkọ́kọ́ nínú ìpín ìdókówò ilẹ̀-òkèrè jẹ́ ti British America Tobacco.
“Ṣé o mọ̀ bóyá ó ní ìṣoro kankan?”
Níbi ìpàdé kan láàárín àwọn méjèèjì, Igbeneghu ṣẹ́ iná pa, ó sì ní kí ọmọdébìnrin náà ó fẹ́nu ko òhun lẹ́nu, tí ó sì tún dì mọ́ ọn gbádígbádí nínúu iyàraa iṣẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wà ní títì pa.
Nígbà tí wọn kọ́kọ́kó wọ inú ilé náà ní kété tí wọn ṣègbeyàwó, ó wà pẹ̀lú ìrètí gíga láti sọ ilé náà di párádísè.
Àwọn méjì gbòógì òǹdíjedupò sí ipò ààrẹ, Ààrẹ tí ó wà lórí àléfà kó ìbò ẹgbẹẹgbẹ̀rún 15 tí ó mú u borí olórogún-un rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, Atiku Abubakar, pẹ̀lú "àlàfo idà 56 sí ìdá 41".
Kò kàn án bín-in-tín báyìí.
Wọ́n ń tọpa wọn pẹ̀lú àwọn ìkànì ètò-ẹ̀kọ́ àti àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ ètò-ẹ̀kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ wọn.
Fi àyè gba àwọn ẹ̀rọ-ayárabíàṣá mìíràn lórí ìṣàsopọ̀ yìí láti ṣàgbéwọlé àwọn ìkànnì mi tí kò sí lákàálẹ̀.
Èyí kò gbé mi lọ́kàn bíi ti ìlàkàkà àwọn ọmọ-adúláwọ̀ tí ó ń ṣe ìrìnàjò nínúu ilẹ̀-adúláwọ̀.
Síbẹ̀, òtítọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò ní ohun-èlò, tí kò sí àyèwò àti ìtọ́jú, ìda ogójì -- ìda ogójì àwọn ọmọ ni wọ́n ní i -- ìda ogójì kojúu ìdá méjì – ìyàtọ̀ tó pọ̀ gidi gan.
Nígbà tí àwọn ara ìlu Burundi sá fún wàhálà òṣèlú, wọ́n wá báwa, sí àwọn orílẹ̀-èdè tókù nílẹ̀ Adúláwọ̀.
Sènábù ṣàlàyé fún màmá pẹ̀lú ọkàn mímó àìlẹ́bí àti omijé lójú rẹ̀.
Óyá gbìyànjú ẹ̀.
Ọjọ́ ìbànújẹ́ àti wàhálà rẹ̀ ti níye.
Obama ni wá, Garvey ni wa, Marley ni wa, Angelou ni wa, Walcott ni wa.
Ìfòfinde ìsoyìgì pẹ̀lú ọmọdé máa ń fi ààbò fún àwọn ọmọdébìnrin, láì ro bí wọ́n ṣe wọ ilé ìwé.
Ọ̀kanòjọ̀kan ọnà ni ó wà ní ara ilé náà — àwọn àràbarà ọnà abẹ́ àjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Òfin ni yó sọ ara ẹ̀; ìyàwó tí ń na ọmọ ìyáálé.
Àwa, tí a wà nínú ìlú, ni a ó fi ààbò bò tí a ó sì ké pe àwọn aráa wa ní òkè òkun, kí àwọn náà ó ké gbàjarè, nítorí ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà ṣe kókó fún wọn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, ìjọba Burundi ti ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn lábẹ́ United Nations tí wọ́n sì sọ pé àwọn kò nílòo wọn mọ́.
Ní báyìí, kò sí ọ̀nà tí èyí fi jẹ́ àwíjàre fún ìwà-ìbàjẹ́.
Àwọn oníkọkúkọ ní ìṣọ̀kan
Transgender Pride march takes place in Pakistan
Ọmọ rẹ̀ tí ó mọ̀, lọ́kàn ara rẹ̀ ti lọ sí ìrìnàjò àrèmabọ̀.
Mo dẹ̀ ní ìdánilójú pé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ tó tọ́, a máa ṣègun ààrùn burúkú yìí.
Àwọn méjèèjì kàn ṣáà ń níì gbàmọ́ra àti ìfaradà fún ara wọn ni.
Ní kò pẹ́ kò pẹ́ yìí ni ìwádìí àyẹ̀wò tí Pew Research Centre ṣagbátẹrùu rẹ̀ fi hàn wípé ọ̀gọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà "fi Ògún-un rẹ̀ gbárí" wípé Trump "yóò gbé ìgbésẹ̀ tí ó lààmìlaka nípa ti ọ̀ràn àgbáyé".