text
stringlengths
1
44.6M
Atọ́ka 7: Àwòrán Túwíìtì kan láti ọwọ́ iléeṣẹ́ Ballard and Partners tí í sẹ́ ayédèrú ìwádìí tí wọ́n purọ́ mọ́ wọn pé wọ́n ṣe.
Irun yẹn ... bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀kan lára àwọn nǹkan ti ìyá wá wá rè é.
COVID-19 ṣe àgbéǹde ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀
Ó ṣépè fún mi, ó pè mí ní orúkọ oríṣìíríṣìí.
Ṣùgbọ́n ṣá, mo túbọ̀ ń ní ìrètí síi nípa orílẹ̀-ède Nàìjíríà lónìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Ilé-ìfowópamọ́ ń lò wọ́n láti ṣe ìpinnu ẹ̀yáwó.
Gbogbo wọn ni ó ní ìtàn kan tàbí òmíràn tí ó jẹ mọ́ ìjìyà láti ọwọ́ ẹ̀dá ọmọ ènìyàn adáríhununrun.
Wàá jíṣẹ́ mi Tinú? Ọmọ tó gbọ́n. Ọmọ tó gbọ́n dáadáa. Ó dáa bẹ́ẹ̀”.
Ọ̀rọ̀-ìfiwọlé fún ìyí-dátà-padà-sí-odù-ààbò (bíi ìyí-dátà-padà-sí-odù-ààbò díìskì kíkún)
Kíyèsára wí pé àwọn ìwífún àjẹmọtaraẹni rẹ lè di rírí fún àwọn ẹlòmíràn, èyí gbáralé ọ̀nà tí a gbà ṣàtòpọ̀ iṣẹ́-àìrídìmú àti bí o ti rí àyè bá wọlé sí iṣẹ́-àìrídìmú náà.
Trump ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ olólùfẹ́ ní gúúsù orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà
Ẹni tí a fẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tó ní kò sí irú òun.
“Kílódé? Kí ni Àlàmú?”, ìpòruru dé bá Làbákẹ́. Ó dẹ ọwọ́ rẹ̀ lọ́rùn ọkọ rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ó sìkó o lé èjìká ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìtúúbá.
Àwọn ilé ìyáwèékàwé, ilé àwọn ọmọ aláìlóbìí, ilé ìyínipadàsírere, ibi ìpéjọ àwọn ọ̀dọ́, yàrá ẹ̀kọ́ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, àti àwọn ohun ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá ìlànà iléèwé mu mìíràn
Eré gbogboó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìdíje àròkọ ọlọ́rọ̀ 1,200 tí ó dá lóríi "ìdí tí mo fi nífẹ̀ẹ́ sí láti máa gbọ́ rédíò" fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé gíga.
Oníṣẹ́ ìlú ni àwọn amọ̀nà, olùkọ́, oníṣègùn àti àwọn onímọ̀ mìíràn.
Ṣùgbọ́n ó ní láti fèsì sí díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ náà tí Àdìó ń sọ, bi bẹ́ẹ̀ kọ́, Àdìó á kó gbogbo ẹ̀bi lé e, á sì dá a lẹ́bi gbogbo rẹ̀.
Ó rẹ wà láti wò - àwòrán àlàáfíà tí ó ṣe ojú jẹ́jẹ́ ni, bí ènìyàn bá ń wò ó láti ọ̀nà jíjìn.
Òun náà máa jáde bá yìí. Jáde! Jáde! Jáde kúrò nínú ìsopọ̀ ègún! Jáde kúrò nínú ilé tí gbogbo èèyàn ti ya wèrè.
Gbogbo ìkàni ayélukára rẹ̀ ló kún fún àwòran fọ́rán náà, pẹ̀lu àwòran ìfipábánilòpọ̀ àti ìdúkokò ikú pẹ̀lu èébú nípa ìgbàgbọ mùsùlùmi rẹ̀.
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń rí ìyàtọ̀ náà.
Wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ lábẹ́ òru nígbà tí àwọn olódodo lọ́kùnrin lóbìnrin ti sun oorun àsùnwọra.
À ń retíi rẹ̀ kí ó dé kíákíá ní àlàáfíà ara àti ẹ̀mí, a ó máa gbé àwọn ìròyìn síta nípa ìròyìn yìí bí ó ba ṣe ń tẹ̀ wá lọ́wọ́.
Gbìyànjú kí o lo àṣàkalẹ̀ ọ̀rọ̀ EFF láti ṣe gbólóhùn ìfiwọlé ọlọ́rọ̀ kan.
Síbẹ̀, ṣọ́ra - àwọn to ni aṣojú wọ̀nyí lè rí dátà tí o fi ránṣẹ́ sí àti bọ̀ wá láti ibùdó-ìtàkùn-àgbáyé ààbò mìíràn.
À ń bẹ̀rù alájá, ajá ṣebí òun là ń bẹ̀rù.
A mọ̀ wí pé láti ṣe àkọsílẹ̀ nípa àwọn ọmọ ènìyàn, àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ wọ̀nyí máa ṣègbè ní gbogbo ìgbà wọn ò sì ní péye tó bẹ́ẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ni……kiní dúdú yẹn tún ní. Ó rí i dáadáa - tí wọ́n wọ́nọn sórí ọbẹ̀ ègúsí náà...
Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ nínú ọgbà ìtọ́jú….. màmá tún fi ojú inú ọkàn rẹ̀ rí Èṣùníyì níbi tí ó ti ń fá irun tó kún bí igbó tó wà lórí aláìsàn rẹ̀.
Kò gbọdọ̀ pe àkíyèsí àwọn aládúgbò rárá.
Bí a bá ti mọ là ń dé; a-láì-lẹ́ṣin kì í dé wọ̀nwọ̀n.
Ilé-iṣẹ́ ti sọ ayẹyẹ àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó di èèwọ̀. Ṣùgbọ́n akọ̀wé láti ẹ̀ka ètò-òṣìṣẹ́ ti fi òró Kérésìmesì (ẹ̀bùn Kérésìmesì tí ó wọ́pọ̀) fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀.
Àjùsẹ́wọ̀n fún yẹ̀yẹ́
Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún 2018, ààrẹ orílẹ̀-èdè South Korea gba ìdájọ́ ẹ̀wọn odún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n fún àwọn ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú ìwà-ìbàjẹ́.
Mo tẹ̀lé àwọn ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọ́n gbónu tí wọ́n ń rín ìrìnàjò káàkiri ẹkùn náà, tí wọ́n ń ya àwòrán ara wọn tí wọ́n sì ń fi ránṣẹ ́lábẹ́ ìkàni #ilẹ̀Adúláwọ̀mi.
Tí ẹ̀ka owó lágbàyé bá tẹ̀síwájú láti máa yá àwọn ilé-iṣẹ́ kùkúyè lówó, láti dókówò nínu kùkúyè, tó sì ń gbìyànjú láti jèrè lára ilé-iṣẹ́ kùkúyè, à ń ṣiṣẹ́ tako arawa ni.
Báwo ni Àlàmú yóò ṣé dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún nǹkan tí ó ti ṣé láti ràn án lọ́wọ́ láti oṣù mẹ́sàn-án sẹ́yìn tí ó ti wà nínú ìṣòro, ọ̀run àpáàdì tó ń jó, ọ̀run àpáàdì lórílẹ̀ ayé.
Màmá ní ìrírí tí ó tó láti lè dá ọwọ́ agbára àwọn ọ̀tá mọ̀, ó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá lè ṣiṣẹ́ láti ìta àti lábẹ́lé.
Ǹkan tí èmi àti ikò mi ṣàwárí láìpẹ́ yìí ni wí pé àwọn hóró àìsan jẹjẹrẹ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ wọ́n sì máa ń dari ètò ìgbésẹ̀ wọn, lóri bí wọ́n ṣe súnmọ́ra wọn nínu agbègbè-àìfojúrí kókó.
Fi ìbéèrè ohun tí o fẹ́ ṣàwárí ṣọwọ́.
Èsì tí a gbà dára tó bẹ́ẹ̀ ni ó mú wa tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò alẹ́ nínú oṣù tí yìnyín bá ń bọ́ tí ojú ọjọ́ bá tútù.
Ajá kì í gbó níbojì ẹkùn.
Ó lè di ẹrù rẹ̀ kí ó kó kúrò nínú ilé rẹ̀ kí ó lọ ṣe àlejò ní ilé olólùfẹ́ rẹ̀ kan.
Ọkọ náà kọsẹ̀ nínú yàrá ìgbàlejò, ó sì kú, ebí sì ṣe wẹ́rẹ́ pa ìyàwó sí orí ibùsùn.
Bí a bá ń gúnyán, kòmẹsẹ̀ á yọ.
Lẹ́yìn tí ó bá ti wọn òògùn náà tán, Màmá yípo yípo lẹ́ẹ̀marùn-ún gẹ́gẹ́bí babaláwo rẹ̀ ṣe la kalẹ̀.
Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, màmá ti dijú, ó sì rí ara rẹ̀ nínú ọgbà ìtọ́jú wèrè Èṣùníyì lábúlé.
Ọ̀rọ̀ nípa "ìbéèrè ààbò"
Èyí ni ìtọ́jú ajẹmọ́ ìṣègùn tó kọjá òògùn lásán.
PR: Adarí iléeṣẹ́ wa ni, Irina Reyder
Gbogbo obìnrin Azerbaijan ni ó fẹ́ fi ìwà jọ ìyá àgbà Saray.
Àwọn àdàlù àmì aṣorí tí ó yanrantí àti/tàbí àmì aṣorí alàìyanrantí wà ní ìlà ìbú àkọkọ́
Ọ̀wọ́ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láwùjọ náà tún rí wí sí ìpinnu àti ṣètò irú ìbéèrè báyìí:
Ìwò ìdààmú wà lójú màmá.
Ṣàkówọlé àwọn ohun àmúlò Kolibri tí ó wà lórí ẹ̀rọ mìíràn, ó lè jẹ́ nínú ìṣàsọpọ̀ agbègbè kan náà tàbí ní orí ẹ̀rọ-ayélujára
Wọ́n rí ipa rere látàrí ìyíde tí àwọn aṣòfin "sì rí ìdí tí ó fi yẹ kí àwọn gbọ́ sí àwọn ọ̀dọ̀ ìbílẹ̀ " lẹ́nu torí wọ́n ń “lé iwájú nínú ìjà fún VAPP,” Hashim ṣàlàyé ọ̀rọ̀.
Èyí ti dá wàhálà ìsásàálà sílẹ̀, a ti rí àwọn ará Burundi tí wọ́n sá lọ sí Tanzania, Rwanda, Congo àti Uganda.
Ní báyìí, oríti bá Làbákẹ́ ṣe é, Á gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọlọ́rọ̀.
Pa àwárí dé
DCMA mọ rírì orin gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó leè ró àwọn ènìyàn lágbára àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó lè mú ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ bá àwọn ènìyàn láì wo ti àṣà — ó sì tún ń pèsè àǹfààní iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ẹ̀bùn àmọ́ tí ó ń tiraka láti jẹ.
Bí ọ̀kan-àn rẹ kò bá balẹ̀ nípa ìpàdánù ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ọ rẹ tàbí ẹ̀rọ ìfẹ̀rílàdí mìíràn, tẹ odù wọ̀nyí jáde kí o sì máa gbé e kiri.
Ṣùgbọ́n kò sí àyè mọ́.
“Màmá tú gèlè rẹ̀, ó bọ́ bùbá rẹ̀, ó bọ́ bàtà, ó sì ju ìró rẹ̀ sílẹ̀! Ó dúró díẹ̀ –ó ń mí lókè lókè...'
Ilà fàdákà tírín tí ẹ rí níbí yìí, ilẹ̀ Adúláwọ̀ nìyẹn.
Ìgbàgbọ́ọ wa ni wípé bí ikú bá kanlẹ̀kùn, ẹ̀míi wọn yóò máa ráre kiri ní àárín-in àdúgbò àti ní òpópónà, láti máa rán àwọn ènìyàn létí nípa ìtúmọ̀ ìwà láyé.
ṣe o ò rí i tẹ́lẹ̀ ni? Dídún ẹ̀ náà kò dáa tó...
Olórí Orílẹ̀-èdè China àgbà Xi Jinping dákẹ́ rọrọ lórí àjàkálẹ̀ àrùn yìí àyàfi ìgbà tí ó di ọjọ́ 20, Oṣù Kìn-ín-ní Ọdún, tí ó kéde fún ará ìlú lẹ́yìn oṣù kan tí àrùn náà ti ń ṣọṣẹ́, pé ọ̀ràn náà ti kọjá àfẹnusọ.
Gbogbo ohun àmúlò tí ó bá ti ara tìrẹ jáde gbọdọ̀ wà lábẹ́ àṣẹ kan náà.
Èyí ni oríkèé pàtàkì tí ó sọnù nínu àyo ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú àdínkù bá ìwà-ìbàjẹ́ nígbẹ́yìn.
O lè lò ó bí o bá rí àyè sí Ibi Ìpamọ́ Ìwífún-alálàyé Kolibri.
Irọ́ tí wọ́n pa pé àwọn Yorùbá ń tiná bọ ìsọ̀ àwọn ọmọ Igbo nílùú Èkó
Àwọn obìnrin wònyí wá síbí fún ìtọ́jú, ṣùgbọ́n a mọ̀ wí pé ṣíṣe àyẹ̀wò kan, fífún ènìyàn lógùn nìkan, kò tó.
Ó sọ̀rọ̀ síwájú sí i :
Lọ́jọ́ 1, oṣù kẹrin, àwọn oníṣẹ́ ìwádìí ọmọ ilẹ̀ Faransé méjì, Oníṣègùn Jean-Paul Mira, àti Camille Locht, dá a lábàá lórí ètò kan ní orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán wí pé Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ni ó yẹ kí wọn ó ti kókó dán egbògi àjẹsára tí yóò ká apá àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà sàn wò, gẹ́gẹ́ bí Al-Jazeera ti ṣe jíyìn ìròyìn náà.
Ìjọba Mozambique ti ń ṣe àfihàn ìṣáájú burúkú nípa ṣíṣe ìdíwọ́ ẹ̀tọ́ ẹni láti sọ̀rọ̀ àti rírí ọ̀nà gbọ́ ìròyìn ní agbègbè náà.
Fún ìdáhùn kíákíá, níbo ni Àlàmú lọ?
Ìbànújẹ́ gba ọkàn mi poo látàríi àlàálẹ̀ Ilé-Ìfowópamọ́ Àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò mú ìfowó ránṣẹ́ sí òkè òkun rọrùn; n kò le è dá owó ìrìnàjò ọ̀fẹ́ tí ó pọn dandan láti dá padà padà fún àwọn tí ó ni owó.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé ṣe ìpolongo àti ìpanupọ̀ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àgbáyé gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ láti ọjọ́ tí wọ́n dé akoto ọba.
PR: Bẹ́ẹ̀ ni, a ti ní Alexey Lazorenko gẹ́gẹ́ bí Adarí, Irina Reyder ni nísẹ̀yín.
Àwọn ajìjàǹgbara ní Madrid fi ẹ̀hónú hàn lórí ìrúfin ẹ̀tọ́ LGBT ní Russia
Channel One ò sọ bí ìyàtọ̀ ṣe wà láàárín bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń ronú sí ìfowópamọ́.
Nísinsìnyí, Àlàmú ti jáde láì dágbére, kò jẹ́ kí ó mọ èrò ọkàn rẹ̀. Láìsí àní-àní ọ̀dọ̀ olólùfẹ́ ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ ni ó lọ ní àsìkò yẹn. Afẹ́fẹ́ òwúrọ̀ náà tutù, ìmí-ẹ̀dùn owú sì mú Làbákẹ́ lójijì tí ó sì wá ń ṣàfẹ́rí ọkọ rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ara rẹ̀ ń wà lọ́nà lemọ́lemọ́, láìlè mú u mọ́ra.
Àwọn àwùjọ ìgbèríko ń kópa pàtàkì láti kojú pípa àti òwo ẹranko igbo lọ́nà àìbófinmu, tí wọ́n jẹ́ olórí ewu tó ń dàmú àwọn kìnìhún àti àwọn ẹranko igbó mìíràn.
A fi ọwọ́ọ ṣìgún òfin mú Alaa a sì mú u kúrò ní ilé ẹbíi rẹ̀ nínú oṣù Belu ọdún 2013.
Àwọn ojú ìwé ìfiwọlé wọ̀nyí sábà máa ń rí bí òótọ́ ti yóò tàn ọ́ láti fi orúkọ-ìdánimọ̀ àti ọ̀rọ̀-ìfiwọléè rẹ sílẹ̀.
Bí kò bá jọ ibùdó tí o mọ̀ tẹ́lẹ̀, máà tẹ̀síwájú!
Sùgbọ́n ẹ ṣì ní láti mú u wá sibí
Ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ yìí lè nípa lórí ẹ̀tọ wa ní àwọn ọ̀nà tó ṣe pàtàkì.
Ohùn Àgbáyé ṣe ẹ̀dàa ìròyìn náà ní abẹ́ ìtọwọ́bọ̀wé àjọṣe pọ̀ ìkóròyìnjọ.
Wọ́n ti sọ fún un pé nígbà tí ọtí bá wọ àgọ́ ara rẹ̀, gbogbo àgọ́ ara rẹ̀ á dáhùn sí i.
Ní ọdún-un 1997, Joenia Wapichana di obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil.
Àjọ ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ Croatia náà en ti ṣ'òfin tó dá lé àrùn náà, ní France, ibi ìrìnàjò mímọ kan ní ìlú Lourdes ti di títì pa.
Ó padà wá á tọrọ àforíjì, lẹ́yìn tí a ti bu ẹnu àtẹ́ lù ú, fún túwíìtì "tí ó lè dá wàhálà sílẹ̀ " bí a ti rí i nínú Àwòrán.
Ní ọdún-un 2014 àwọn alátìlẹ́yìn Ààrẹ àná ààrẹ Jonathan àti ẹgbẹ́ olóṣèlú Peoples’ Democratic Party (PDP) fi "àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan irọ́ " léde ní orí ẹ̀rọ-ayélujára láti tako Ezekwesili. Dókítà náà sọ nínú àtẹ̀jáde àwòrán-olóhùn Twitter kan ti ọjọ́ 14, oṣù Igbe ní ìsààmì ọdún mẹ́fà tí àwọn ọmọdébìnrin náà ti di àwátì wí pé: “kí á má purọ́ wọ́n tàbùkù mi, wọ́n sì ṣe kèéta.
Màdáámú...màdáámú..., Ọlọ́run nìkan ló lè gba èèyàn lọ́wọ́ ìṣòro ayé yìí o.
Bí èyí bá kàn ọ́ gbọ̀ngbọ̀n, máà mú ọ̀rọ̀-ìfiwọléè rẹ ṣiṣẹ́ pọ̀ s'ínúu kùkukùru, kàkà bẹ́ẹ̀ fi wọ́n pamọ́ sórí ẹ̀rọọ̀ rẹ.
Àmọ́ pẹ̀lú ìdásílẹ̀ tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, ipò yẹpẹrẹ ni òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìlú náà nítorí wípé ìtìmọ́lé àti ìfìyàjẹ àwọn akọrin, akọ̀ròyìn, àti ajìjàǹgbara ṣì wà síbẹ̀ sẹpẹ́.
Màdáámú, àwọn èèyàn náà sọ ìdí rẹ̀ fún mi. Ṣé wà á dẹ́kun!
Kò sí bí ènìyàn ṣe lè dá ọkùnrin tí ò bá náá ní dúró.
Àlàmú á bẹ̀rẹ̀ gbólóhùn kan dáadáa, á sì dánudúró lójijì, pẹ̀lú òṣé, kíkùn tàbí ẹ̀rín.