url
stringlengths
37
41
id
stringlengths
1
5
text
stringlengths
2
134k
title
stringlengths
1
120
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74313
74313
Ahmed Ahmed Ahmed Ahmed (Lárúbáwá: ‎), (tí wọ́n bí ní June 27, 1970) jẹ́ ọmọ Orílẹ̀ èdè America, tó tan mọ́ ilẹ̀ Egypt, tó jẹ́ òṣèrékùnrin àti apanilẹ́rìn-ín.
Ahmed Ahmed
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74314
74314
Sohail Ahmed Sohail Ahmed (Pùnjábì: ) (tí wọ́n bí ní 1 May 1963), tó tún ń jẹ́ Azizi (Urdu: ), jẹ́ òṣèrékùnrin, apanilẹ́rìn-ín àti olùdarí fíìmù ti ilẹ̀ Pakístàn.
Sohail Ahmed
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74315
74315
Franklyn Ajaye Franklyn Ajaye (tí wọ́n bí ní May 13, 1949) jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, òṣèrékùnrin àti òǹkọ̀wé ti Orílẹ̀ èdè America.
Franklyn Ajaye
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74316
74316
Anna Akana Anna Kay Napualani Akana (tí wọ́n bí ní August 18, 1989) jẹ́ òṣèrébìnrin, apanilẹ́rìn-ín, olórin, òṣìṣẹ́ lórí àtiYoutube. Ó ti ṣàfihàn lórí fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, fíìmù àti orin.
Anna Akana
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74318
74318
Nasser Al Qasabi Nasser bin Qassim Al Qasabi (Lárúbáwá: ‎, tí wọ́n bí ní 28 November 1961 ní Riyadh, Saudi Arabia) jẹ́ òṣèrékùnrin ti ilẹ̀ Saudi Arabia. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré ní ọdún 1984, ó sì gbajúgbajà fún ẹ̀dá-ìtàn tó máa ń kó nínú eré "Tash Ma Tash" (Arabic: طاش ما طاش). Ní ọdún 2012, Nasser wà lára àwọn adájọ́ fún ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ti "Arabs Got Talent".
Nasser Al Qasabi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74319
74319
Rory Albanese Rory Scot Albanese (tí wọ́n bí ní May 29, 1977) jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, òǹkọ̀wé ìtàn apanilẹ́rìn-ín, àti olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ti Orílẹ̀ èdè America.
Rory Albanese
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74320
74320
Eddie Albert Edward Albert Heimberger (tí wọ́n bí ní 22, 1906, tó sì ṣaláìsí ní May 26, 2005) jẹ́ òṣèrékùnrin àti onínúure ti Orílẹ̀ èdè America.
Eddie Albert
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74321
74321
Alan Alda Alan Alda (; tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Alphonso Joseph D'Abruzzo; tí wọ́n bí ní January 28, 1936) jẹ́ òṣèrékùnrin, apanilẹ́rìn-ín, òǹkọ̀wé àti olùdarí eré, ti Orílẹ̀ èdè America.
Alan Alda
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74322
74322
Dave Allen David Tynan O'Mahony (6 July 1936 – 10 March 2005), tí ọ̀pọ̀ ènìyàn Dave Allen, jẹ́ apanilẹ́rìn-ín ti ilẹ̀ Ireland, àti òṣèrékùnrin.
Dave Allen
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74323
74323
Gracie Allen Grace Ethel Cecile Rosalie Allen (July 26, 1895 – August 27, 1964) fìgbà kan jẹ́ akọrin, òṣèrébìnrin, àti apanilẹ́rìn-ín tó di gbajumọ̀ lágbààyé, látàrí iṣẹ́ rè pẹ̀lú George Burns.
Gracie Allen
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74324
74324
Marty Allen Morton David Alpern (March 23, 1922 – February 12, 2018), tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọl sí Marty Allen, jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, òṣèrékùnrin à ti onínúure ti Orílẹ̀ èdè America. Ó ṣeré gẹ́gẹ́ bí i apanilẹ́rìn-ín ní ilé-ijó, tí wọ́n sì máa ń pè é ní "The Darling of Daytime TV".
Marty Allen
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74325
74325
Cristela Alonzo Cristela Alonzo jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, òṣèrébìnrin, òǹkọ̀wé àti aṣàgbéjáde eré, tó ṣàfihàn nínú ABC sitcom "Cristela." Èyí mu kó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ láti Mexico tó máa kọ́kọ́ ṣẹ̀dá, ṣàgbéjáde, àti kọ eré apanilẹ́rìn-ín kan.
Cristela Alonzo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74326
74326
Ọjà Tejuosho Tejuosho Market jẹ́ ọjà gbajúgbajà kan ní Ojuelegba-ọjú ọnà Itire Yaba, Ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọjà náà pín sí ọ̀nà méjì (Phase I and Phase II), ó sì ní ọ̀pọ̀lọpò ohun àmúyẹ bí i iná, omi, ilé-oúnjẹ, ilé-ìfowópamọ́, àyè láti gbọ́kọ̀ sí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ijàm̀bá iná ba ọjà náà jẹ́, tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, Stormberg Engineering Limited, àti First Bank of Nigeria pawọ́ pọ̀ láti tún ọjà náà ṣe.
Ọjà Tejuosho
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74327
74327
Ìjígbé àwọ̀n ọmọ ilé ìwé Chibok Ní oru ọjọ́ kẹrìnlá sí kẹ̀ẹ́dọ́gún ọdún 2014, àwọn ìkọ̀ ogun Boko Haram jí àwọn ọmọ obìnrin ẹ̀rin dín ní ọ́rin-lé-nígba(279) gbé ní Government Girls School ní ìlú Chibok, Ìpínlẹ̀ Bornu, Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé jẹ́ Krìstẹ́nì. Kí ikọ̀ náà tó ya wo ilé ìwé náà, wọ́n ti ti ilé ìwé náà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin nítorí ìbẹ̀rù nípa ètò àbò, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ilé ìwé náà wá ilé ìwé láti wá kọ ìdánwò wọn nínú ìmọ̀ physics. Mẹ́tàdínlógójì nínú àwọn ọmọ náà yọ bó lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ náà nípa fífò jábọ́ nínú ọkọ̀ tí wọ́n fi kó wọn, àwọn Ọmọ ogun Nàìjíríà rí àwọn kan gbà padà. Àwọn míràn gbàgbọ́ pé wọ́n sì ma tú àwọn ọmọ náà sílẹ̀, àwọn míràn sì gbàgbọ́ pé díè nínú àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé ti sọ ẹ̀mí wọn nù. Wọ́n rí Amina Ali, ọkàn lára àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé ní oṣù Kàrún ọdún 2016. Ó ní àwọn ọmọ tó kù wà nínú ìhámọ́ ikọ̀ náà, ṣùgbọ́n mẹ́fà ti kú nínú wọn. Ní oṣù kẹrin ọdún 2021, ọdún méje lẹ́yìn ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sè, àwọn ọmọ tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ni ó sì sọnù.
Ìjígbé àwọ̀n ọmọ ilé ìwé Chibok
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74330
74330
Yoruba People in the Atlantic slave trade History of the Yoruba tribes involvement in the Atlantic Slave Trade Àwọn ènìyàn Yorùbá ṣe kó ipa púpọ̀ nínú àṣà àti ètò ọrọ̀-ajé nínú òwò ẹrú ti òwo ẹrú Atilantiki láti ìgbà tí a lè sọ pé ó ti wà ní ọdún 1400 títí di 1900 CE. Ẹḿpáyà Ọ̀yọ́. Láti ọdún 1400 lọ, ni aláyélúà ti Ẹḿpáyà Ọ̀yọ́ ti kógo sí sọ èdè Yorùbá di "lingua franca" sí gbogbo àwọn agbègbè Volta. Ní bí ìparí 18th century, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Ọ̀yọ́ tì nítorí kò sí ìdí kan púpọ̀ láti ṣẹ́gun. Bíi bẹ́ẹ̀, Ọ̀yọ́ kọjú gbogbo akitiyan wọn sórí òwò àti jíjẹ́ alárenà fún àwọn olówò ẹrú trans-Saharan àti trans-Atlantic. Àwọn European gbé iyọ̀ wọ òde Ọ̀yọ́ lásìkò ìjọba Ọba Obalokun. Ká dúpẹ́ fún jíjẹ gàba rẹ̀ ní ìdó náà, jẹ́ kí àwọn olókoòwò Ọ̀yọ́ lè ṣòwò pọ̀ pẹ̀lú àwọn European ní Porto Novo àti Whydah. Níbí yìí ni wọ́n ti ta àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀daràn Ọ̀yọ́ Ẹḿpáyà fún àwọn òǹrà Dutch àti Portuguese. Ipa Àṣà. Ní àfikún sí ipa tí òwò ẹrú kó, àti lẹ́yìn(ò-rẹyìn oúnjẹ àti èdè àwọn Afro-Amẹríkà, àmúwọlé àṣà Yoruba jẹ́ ẹ̀rí tó nípọn nínú irú àkọọ́lẹ̀ ẹ̀sìn Yoruba bíi Santería, Candomblé Ketu, àti àwọn ẹ̀mí àbáláyé mìíràn.
Yoruba People in the Atlantic slave trade
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74331
74331
Ìsìnrú gbèsè Ìsìnrú gbèsè ni jíjẹ́ ẹ̀jẹ́ láti ṣiṣẹs fún èlò míràn án láti dógò fún gbèsè tí ènìyàn jẹ ẹlòmíràn. Èyí mú kí ẹni tí ó ya ìkejì lọ́wọ́ wà ní àkóso ẹnikejì títí di ìgbà tí ó ma rí owó náà ṣan. The services required to repay the debt may be undefined, and the services' duration may be undefined, thus allowing the person supposedly owed the debt to demand services indefinitely. Wọ́n le sìrún gbèsè láti iran kan sí òmíràn. Lọ́wọ́ lọ́wọ́, ìsìnrú gbèsè jẹ́ gbọ́gì lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi kó àwọn ènìyàn lẹ́rú pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó lé ní mílíọ̀nù mẹjọ lábé ìsìnrú yìí ní ọ̀nà tí kò tó gẹ́gẹ́ bí International Labour Organization ṣe sọ ní ọdún 2005. Àṣà ìsìnrú yìí sì wọ́pọ̀ ní ìwọ̀ gúúsù Asia àti apá díè nínú ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù Áfríkà. Ìdásí mẹjọ nínú mẹ́wàá àwọn tí ó wà nínú ìsìnrú ní South Asia wà lábé ìsìnrú gbèsè. Àìbá àwọn tí ó ń kó ènìyàn lẹ́rú lọ́nà yìí wí jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí ìsìnrú gbèsè ṣì wọ́pọ̀ lónìí.
Ìsìnrú gbèsè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74332
74332
Nínà Àtẹ̀lẹsẹ̀ Nínà Àtẹ̀lẹsẹ̀ tàbí bastinado jẹ́ ọ̀nà láti fa ìrora tàbí yẹ̀yẹ́ nípa nína àtẹ̀lẹ̀sẹ̀ ẹlòmíràn, pàápàá jù lọ, ẹrú. Yàtò sí àwọn ọ̀nà míràn láti na ènìyàn, nínà àtẹ̀lẹ̀sẹ̀ ma ń sábà fa ìrora ṣùgbọ́n kìí sábà ṣe ẹni tí wọ́n ń nà léṣe, wọ́n ma ń sábà lo ẹgba tínrín bi pankẹ́rẹ́. Àkọsílẹ̀ nípa nína àtẹ̀lẹ̀sẹ̀ tàbí bastinado ní Europe ní ọdún 1537, àti ní China ní ọdún 960. Àwọn míràn gbàgbọ́ gbé Bíbélì tọ́kaṣí bastinado nínú Bíbélì Mímọ́ (Prov. 22:15; Lev. 19:20; Deut. 22:18), èyí sì fi hàn pé wọ́n ti ń lo ọ̀nà ìbáwí yìí láti ìṣẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n lo ọ̀nà ìbáwí ní àwọn ilé ìwé Jẹ́mánì àti Austria ní àwọn ọdún 1950s.
Nínà Àtẹ̀lẹsẹ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74333
74333
Karayuki-san Àwọn Obìnrin tí wón jì gbé laarin ṣẹ́ńtúrì Kọkàndínlógún Karayuki-san (唐行きさん)jẹ́ orúkọ tí àwọn ará ilè Japan tí wọn fún obìnrin tí wọn fí ipá jí gbé lọsí àwọn àgbègbè bí apá ìlà oòrùn Asia, Siberia, Russian , Australia, India láti lọ lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí òsìsẹ̀ ìbálòpó láti yọ wọ́n kúrò nínú ìṣẹ́ láàrín ṣẹ́ńtúrì kọkàndíńlógún sí ogún ṣẹ́ńtúrì.
Karayuki-san
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74334
74334
Ìjọba Dahomey Ìjọba Dahomey () jẹ́ ìjọba kan ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà tí orílẹ̀ èdè Benin wà lọ́jọ́ òní. Ìjọba náà wà láti ọdún 1600 títí di 1904. Wọ́n kó Dahomey sí orí òkè Abomey, ìjọba náà di alágbára lágbègbè rẹ̀ ní àwọn ọdún 1700s, wọ́n sì ségun àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní gúúsù wọn láti tan ilẹ̀ wọn, àwọn ilẹ̀ bi Whydah ti ìjọba Whydah tí etí odò Atlantic èyí tí ó mú wọn ní àṣẹ sí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣe triangular trade. Láàrin àwọn ọdún 1800s, ìjọba Dahomey di alágbára àgbègbè náà kí ó tó di pé Ìpínlẹ̀ Oyo. Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè ní orílẹ̀ Europe tí ó wá sí ilẹ̀ náà kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa rẹ̀. Ìjọba Dahomey jẹ́ alágbára ní agbègbè náà tí ọ̀rọ̀ ajé wọn dá lórí Okoẹrú. Ìjà ilẹ̀ padà bẹ̀rẹ̀ sí ń ní bọ́yọ̀ láàrin orílẹ̀ èdè France àti ìjọba náà, èyí fa Ìjà Franco-Dahomean àkọ́kọ́ ní ọdún 1890, orílẹ̀ èdè Faransé sì ségun ogun náà. Ìjọba náà padà lólẹ̀ ní ọdún 1894 nígbà tí àwọn ọmọ ogun Faranse pa ọba Dahomey ní ogun Franco-Dahomean kejì.
Ìjọba Dahomey
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74336
74336
Bilal Ibn Rabah Companion of Muhammad and first Islamic mu'azzin (c.580–640) Ojúewé yìí jẹ mọ́ nípa the companion of Muhammad. Fún the Mosque named in his honour, ẹ wo: Rachel's tomb. Bilāl ibn Rabāḥ (Lárúbáwá: ‎), c. 580–640, jẹ́ ọ̀kan lára sàhabé tí Ànọ́bì Muhammad (S.W.T) gbẹ́kẹ̀le tí ó sí fọkàntàn tí Ànọ́bi náà sì jẹ́ ọ̀kan lára òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run ran sí àwọn mùsùlùmí. Wọ́n bi sí Ìlu Mecca, tí wọ́n ṣì gbà ọ òun nì Mu'azzin àkọ́kọ́ nínú ìtàn, tíó jẹ́ pé ànọ́bí gan-an fúnrarẹ̀ ni ó yàn. Ó jẹ́ ẹrú kan tẹ́lẹ̀rí tí ó wá láti Orílé èdè Ethiopia, tí ó sì jẹ́ olókìkí látàrí òhun dídùn tí ó ní tí ó sì fí ń pè àwọn ẹrùsìn ọlọ́run láti wà kí Ìrun. Ó jáde láyé ní Odún 640, tí ó sì wà ní ọmọ ọgọ́ta ọdún.
Bilal Ibn Rabah
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74337
74337
Àwọn ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn  <templatestyles src="Hlist/styles.css"></templatestyles>  <templatestyles src="Hlist/styles.css"></templatestyles> . Àwọn ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn jẹ àwọn ìlànà àwọn ìwà tí ó tó sí ọmọ ènìyàn láti máa wù tí wọ́n sì ń dáàbòbò nígbàgbogbo ní àárín ara wa tàbí láàárín àgbègbè kan àti ní gbogbo ìlú kárí ayé. [2] Wọ́n jẹ́ ohun tí ó rọrùn tí a kò sì le è gbà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ó ètò ìpìlè tí ó tọ́ sí ènìyàn nítorí tí ọ́ jẹ́ ẹlẹ́ran ara 4] àti fún gbogbo ènìyàn pátápátá ” láìka ọjọ́ orí wọn, ìran abínibí, ipò , èdè, ẹ̀sìn, ẹ̀yà tàbí ipò tí ènìyàn lè wà . Wọ́n wúlò níbi gbogbo àti ní gbogbo ìgbà fún gbogbo ẹ̀dá láyé e àti pé wón dọ́gba tàbí bákànáà ni àwọn ẹ̀tọ́ yìí fún gbogbo ènìyàn. Wọ́n a máa nilo ìtara àti ìlànà ofin àti fífi ipá mú àwọn ènìyàn láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ènìyàn àti ti ẹlòmíràn, àti wí pé a kò gbọ́dọ̀ mú àwọn ẹ̀tọ́ yìí kúrò àyàfi tí ìjọba bá sọ ohun tí irú ẹ̀dá náà bá ṣe àti irú ìyá tí ó tọ́ sì ẹ̀dá tí ó rú òfin Ẹkọ ti awọn ẹtọ eniyan ti ni ipa pupọ laarin ofin kariaye ati awọn ile-iṣẹ agbaye ati agbegbe. Awọn iṣe nipasẹ awọn ipinlẹ ati awọn ajọ ti kii ṣe ijọba ṣe ipilẹ ti eto imulo gbogbo eniyan ni kariaye. Èrò àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn dámọ̀ràn pé “tí a bá lè sọ pé ọ̀rọ̀ àsọyé ti gbogbo ènìyàn lágbàáyé lágbàáyé ní èdè ìwà rere kan, ti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni.” [7] Awọn iṣeduro ti o lagbara ti ẹkọ ti awọn ẹtọ eniyan ṣe tẹsiwaju lati fa aibalẹ pupọ ati awọn ijiyan nipa akoonu, iseda ati awọn idalare ti awọn ẹtọ eniyan titi di oni. Itumọ gangan ti ọrọ "ti o tọ" jẹ ariyanjiyan ati pe o jẹ koko-ọrọ ti ariyanjiyan imọ-ọrọ ti o tẹsiwaju ; [8] nigba ti o wa ni isokan pe eto eda eniyan ni orisirisi awọn ẹtọ ti o yatọ gẹgẹbi ẹtọ si idajọ ododo, idaabobo lodi si isọdọmọ, idinamọ ipaeyarun, ominira ọrọ sisọ tabi ẹtọ si ẹkọ, ariyanjiyan wa nipa ewo ninu awọn ẹtọ pato wọnyi yẹ ki o wa ninu ilana gbogbogbo ti awọn ẹtọ eniyan; diẹ ninu awọn onimọran daba pe awọn ẹtọ eniyan yẹ ki o jẹ ibeere ti o kere ju lati yago fun awọn ilokulo ti o buruju, lakoko ti awọn miiran rii bi idiwọn giga. O tun ti jiyan pe -funni”, botilẹjẹpe a ti ṣofintoto ero yii. Aṣáájú òtítọ́ ti ọ̀rọ̀ àsọyé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jẹ́ àbá èrò orí àwọn ẹ̀tọ́ àdánidá èyí tí ó farahàn gẹ́gẹ́ bí ara àṣà òfin àdánidá ti igba atijọ. Aṣa atọwọdọwọ yii ni ipa pupọ nipasẹ awọn kikọ ti awọn onimọran Kristiani akọkọ ti St Paul gẹgẹbi St Hilary ti Poitiers, St Ambrose, ati St Augustine . Augustine wà lára àwọn tó kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bí àwọn òfin èèyàn ṣe tọ́ sí, tí wọ́n sì gbìyànjú láti ṣàlàyé àwọn ààlà ohun tí àwọn òfin àti ẹ̀tọ́ tó wáyé látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó dá lórí ọgbọ́n àti ẹ̀rí ọkàn, dípò kí wọ́n fi àwọn èèyàn lélẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́, àti pé bí wọ́n bá jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn èèyàn láti ṣègbọràn sí àwọn òfin. ti o jẹ alaiṣõtọ .
Àwọn ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74338
74338
Ìkónilẹ́rú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Traditional slave trade in southeastern Nigeria Ìkónilẹ́rú ti fi ara hàn ní gbogbo ọ̀nà káàkiri gbogbo ìtàn Nàìjiríà. ó fara hàn jùlọ ni àsìkò òwò-ẹrú Atlantic àti òwò-ẹrú-Saharan. Òwò-ẹrú tí di ohun tí ó lòdì sí òfin báyìí kárí-ayé àti ní orílè-èdè Nìgéríà pàápàá. Ní orílè-èdè Nàìjíríà, àwọn ìṣe, àti ẹ̀ṣìn tí ṣokùfa àìlèdẹkun ìtànká láàárín ìṣe, ìṣẹ̀ṣe àti àwọn ìṣe ẹ̀sìn pẹ̀lú àwọn aṣòfin orílẹ̀-èdè ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Áfríkà èyí sì fún wọn ní agbára láti fi ipá ní àkóso tí kò sí òfin tó dè wọ́n lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn èyí tí ó di ìkónilẹ́rú ní ayé-òde òní. Ìkónilẹ́rú tó wọ́pọ̀ jùlọ ni orílẹ-ẹ̀dè Nàìjíríà ni kíkó àwọn ènìyàn ní ọ̀nà tí kò ní ẹ̀tọ́ àti fífí ọmọdé-ṣerú Nítorí pé ó ṣòro láti dá òwò-ẹrú tí ìgbàlódé mọ̀, ó ṣòro láti gbógun ti ìṣe yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́pé àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé ń sapá láti fi òpin si. Ìtàn òwò-ẹrú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òwò-ẹrú ní apá Gúsù Nàìjíríà ni ó ṣáájú ipa tí àwọn òyìnbó ó sì tẹ̀síwáju lábẹ́lẹ̀ lẹ́yìn tí òpin tí débá òwò-ẹrú ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn. Nígbà tí òwò-ẹrú gígbé kọjá omi Atlantic dé, àwọn tó ṣe òwò-ẹrú ní apá gúsù mọ́ ìlà-oòrùn Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ẹrú fún àwọn òyìnbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé àwọn alákòóso àwọn ilè Britain ti fi òpin sí òwò-ẹrú lábéélẹ̀ ní àárín 1880, wọ́n fí ààyè gbà á dáadáa títí wọ1930s, òpìn sí dé bàá pátápátá ní ọdún 1940s.
Ìkónilẹ́rú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74339
74339
Jihad ti Usman dan Fodio Military conflict in Nigeria and Cameroon (1804–1808) Jihad ti Usman dan Fodio jẹ ija ẹlẹsin-ologun to waye in Orilẹ ede Naijiria ati ilu Cameroon. Ogun naa bẹrẹ nigba ti a lè Usman Dan Fodiyo, ogbon tarigi onimọ ẹsin islam ati olukọ kuro ni Gobir, eleyi ṣẹlẹ lati ọwọ ọkan ninu akẹẹkọ rẹ Ọba Yunfa. Usman Dan Fodiyo ṣè agbatẹru awọn ologun ẹsin islam lati ṣè jihad lori afin ilẹ hausa to wa ni ariwa órilẹ ede Naijiria. Awọn ologun Usman Dan Fodiyo Kapa ọpọlọpọ ilẹ hausa nibi tan ti gba koso lori Gobir ni ọdun 1808 ti wọn si pa Yunfa. Ija yi lo yi sisi dida Sokoto Caliphate silẹ, eleyi lo pada di ọkan lara awọn ipinlẹ to tobi julọ ni ilẹ Afirica. Aṣèyọri yi ló ṣipaya jihad óriṣiriṣi miran to pada waye ni apa Iwọọrun ilẹ Afrika. Itan ati Agbẹkalẹ. Ilu Kanem-Bornu lagbara lati century ti ẹlẹkeji din logun sẹyin. Eyi ló jasi didinku ninu awọn afin to daduro ni ilẹ hausa eleyi ti Sheikh Al'amkn El-kanemi ti kapa. Afin Kanem-Bornu ni a kọju ija ogun si nibi ti wọn ti kapa Usman Dan Fidio ti wọn si sọ sinu tubu. Lẹyin óriṣirísi ọgun to waye lẹyin ọdun diẹ ni Sheikh Al'amin Elkanemi tu Usman Dan Fodio silẹ. Ogun. Usman dan Fodio ti a bini ọdun 1754 dara pọ mọ awọn aririn ajo oni mimọ ẹskn islam ni ọdun 1770 to si di gbajumọ ni ọdun 1790. Tẹlẹ ri, Iwasu Usman fisi akoso idari Gobir ṣugbọn bi oṣè n gbajumọ si bẹni o dinku lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu oludari igbana. Eyi ló mu ki Sarkin Gobir Nafata, Ọba ti Gobir fi ifilọ lẹ lori Iwasu Usman.Ni ọdun 1801, akẹẹkọ Usman Dan Fodio tẹlẹ̀ri di Ọba Gobir to si ṣè alèèkun fifi ara ni Usman lẹyin naa lo le kuro ni Gobir lọsi abule ti Defel. Ni ọdun 1803, Yunfa kogun ba awọn olutẹle ilana Usman Fan fodio eyi lo mu ki awọn yiju pada lati kogun ba awọn ologun yunfa ti wọn si tu Usman silẹ. Ni ọdun 1804, awọn olutẹle ilana Usman Dan fodio bẹrẹ sini korajọ lati kuró lẹ̀yin Gobir ti wọn si sọ Usman Dan Fodio ni Amir al-Mu'minin, eyi tu mọ si oludari olododo.
Jihad ti Usman dan Fodio
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74340
74340
Àwọn Yorùbá tó ń ṣòwò ẹrú gba ojú omi Atlantic History of the Yoruba tribes involvement in the Atlantic Slave Trade Àwọn Ẹ̀yà Yorùbá kópa tó pọ̀ nínú okoòwò ẹrú ṣíṣe gba ojú omi Atlantic, pàápàá jù lọ nípa àṣà àti ètò-ọ̀rọ̀-ajé ní ọdún 1400 sí 1900 CE. Àwọn ìlú tí Ọ̀yọ́ ń pàṣẹ lé. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1400 síwájú, àwọn ìlú tí ìṣèjọba Ìlú Ọ̀yọ́ ń pàṣẹ fún jẹ́ kí Èdè Yorùbá di èdè ìṣèjọba káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ìwọ̀-oòrùn Africa. Ní gẹ̀gẹ̀rẹ́ òpin sẹ́ńtúrì méjìdínlógún (18th century), wọn ò mójú tó àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ mọ́ nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ìlú tí wọ́n fẹ́ gbà mọ́ sábẹ́ àṣẹ Ìlú Ọ̀yọ́ . Dípò èyí, Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹra mọ́ Okoòwò Ẹrú káàkiri àgbègbè ilẹ̀-adúláwò, pàápàá jùlọ lápá Ìwọ̀-oòrùn Afrika. Europeans bringing salt arrived in Oyo during the reign of King Obalokun. Nítorí gbajúmọ̀ wọn nínú Okoòwò Ẹrú, àwọn olókoòwò ẹrú Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní bá àwọn Òyìnbó Ìlẹ̀ Europe ṣòwò ẹrú ní Porto Novo ati Whydah. Ní àkókò yìí ni àwọn Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní tá àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá mú fún àwọn olókoòwò ẹrú láti orílẹ̀-èdè Nederland àti Portugal. Ipa àṣà. Ipa tí àṣà, pàápàá jù lọ kò kéré rárá, ní àfikún sí ipa tí àṣà kó nínú okoòwò ẹrú, àti nígbà tí ó ń tẹ̀síwájú, lórí oúnjẹ àti èdè ìbílẹ̀ Afrika àti àwọn òyìnbó, kíkó àṣà àwọn Yorùbá wọ̀lú fara hàn lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú Ẹ̀sìn Yorùbá bí ó ṣe jẹyọ nínú àwọn ẹ̀sìn bíi Santería, Candomblé Ketu, àti àwọn ìbọ mìíràn.
Àwọn Yorùbá tó ń ṣòwò ẹrú gba ojú omi Atlantic
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74341
74341
Ìsìnrú ní Afíríkà Nínú ìtàn, ìsìnrú jẹ́ nǹkan tí ó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀Áfríkà, bí ó ṣe gbajúmọ̀ ní àwọn apá míràn ní àgbáyé láyé àtijọ́. nígbà tí Oko ẹrú trans-Saharan, Oko ẹrú Indian Ocean àti Oko ẹrú Atlantic (tí ó bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1500s) bẹ̀rẹ̀, àwọn tí ó ń kọ́ni lẹ́rú tẹ́lẹ̀ ní Áfíríkà bẹ̀rẹ̀ sí ń ta àwọn ẹrú fún àwọn orílẹ̀ èdè tí kò sí ní Áfíríkà. Àwọn ènìyàn sì ń sìnrú ní Afíríkà ní òní bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n ti fi òfin dẹ̀ẹ́. Nínú àwọn ìwé ìtàn nípa Áfríkà, oko ẹrú pín sọ́nà méjì, àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú láti sìnrú ní Afíríkà àti àwọn tí wọ́n ń tà síta ilẹ̀ Áfíríkà. Oríṣi ọ̀nà ni wọ́n fi ń sìrún ní Áfríkà: Ìsìnrú gbèsè, ìsìnrú àwọn tí wọ́n kó lójú ogun, ìsìnrú fún ìbálòpò tí kò tọ́, àti ìsìnrú àwọn ọ̀daràn.
Ìsìnrú ní Afíríkà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74342
74342
Osu caste Àṣà Osu caste jẹ́ àṣà ní |Ilẹ̀ Ìgbò tí ó lòdì sí ìbádọ́rẹ́ àti fífẹ́ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń pè ní "Osu". Nínú ìtàn, àwọn Osu jẹ́ ẹrú òrìṣà ("Alusi") ti àwọn Igbo; wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn Osu kìí ṣe ènìyàn pàtàkì bi "Nwadiala" tàbí "diala". Bí ó ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ti mọ àwọn kan bi osu láti ìgbà tí àwọn ilẹ̀ íbọ̀ ti wà lábé òfin ilẹ̀ tí a ń pè ní Odinani. Òrìṣà tí wọ́n ń pè ní Ala ni ó ṣe òfin tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀lẹ́ kí wọ́n bà le ṣe rere, kí elédùmarè tí wọ́n sì ma ń pè ní Chukwu, ba le súre fún wọn. Àwọn tí ó pa tàpá sí òfin yìí ni wọ́n ma lé jáde kí òrìṣà má bà bínú sí wọn, àti pé, kí ìwà yí má bá ma tàn káàkiri, àwọn ènìyàn tí wọ́n lé jáde yìí ni wọ́n ń pè ní Osu. Wọ́n ma ń tà wọ́n fún ẹrú tàbí kí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí àwọn òrìṣà tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó ń bẹ̀rẹ̀ fún ìrúbọ láti "wẹ ilẹ̀ náà mọ́". Àwọn míràn di oṣú nítorí pé wọn kò tẹ̀lẹ́ ìlànà ọba tàbí ìlànà ìlú.
Osu caste
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74343
74343
Bight ti Biafra Bight ti Biafra (Atun ma n pe ni Bight ti Bonny ni órilẹ ede Naijiria) jẹ bight to wa ni ìwọ oòrùn aringbungbun etikun ilẹ́ afrika ni ila-oorun gulf ti orilẹ ede Guinea. Àgbègbè. Bight ti Biafra, tabi Mafra (orukọ ilu Mafra ni southern Portugal), larin Capes Formosa ati Lopez, jẹ ila-oorun ti Gulf ti ilẹ Guinea; o kun fun erekusu Bioko [Equatorial Guinea], São Tomé ati Príncipe. Orukọ Biafra ta fi pilẹ ilu naa ni ko ni itumọ mọ ni igba diẹ lẹyin 19th century. Map ti ọdun 1710 map jẹ koyewa pẹ ibi ti a mọ si "Biafra" wa ni órilẹ ede Cameroon. Bight ti Biafra yasi ila-oorun lati River Delta ti Niger ni apa ariwa tofi de Cape Lopez ni Gabon.Ni ẹgbẹ Odo ti Niger, awọn odo yoku to de bay ni odo ti Cross, odo ti Calabar, Ndian, Wouri, Sanaga, Odo ti Nyong, Ntem, Mbia, Mbini, Muni ati Odo ti Komo. Awọn etikun to wa ni Bay ni Bioko ati Príncipe; awọn etikun to tun pataki ni Ilhéu Bom Bom, Ilhéu Caroço, Elobey Grande ati Elobey Chico. Awọn orilẹ ede to tun wa ni Bight ti Biafra ni Cameroon, the eastern ti ilẹ Nigeria, Equatorial Guinea (Bioko Island ati Rio Muni) pẹlu Gabon. Itan. Bight ti ilẹ afrika ṣè agbatẹru 10.7% ti awọn ti wọn ko lẹru ti wọn si kolọ si ilẹ America lati ọdun 1519-1700. Larin ọdun 1701-1800 awọn ẹru naa lẹkun si pẹlu 14.97%. Lara awọn nkan ti wọn ji lati Bight ti Biafra ni Bamileke, Igbo, Tikar, Bakossi, Fang, Massa, Bubi ati bẹẹbẹ lọ. Awọn ti ọmọ ilẹ afrika ti wọn kọ lẹru di ọmọ ilẹ oke okun ti wọn si ta wọ ni ilẹ Virginia. Ilẹ Virginia ati agbegbe rẹ ko ẹru to le ni ọgbọn ni ọna ẹgbẹrun. Awọn ẹru ilẹ cameroon ni a ma nta lọpọ tori pẹ wọn gba ki wọn ku ju ki wọn kowọn lẹru lọ. Ni arin century ti meji dinlogun, Bonny di agbatẹrun ibi ti a tin ṣẹ owo ẹru tita to si tayọ ala si awọn oko ẹru tẹlẹri ni Elem Kalabari Larin ọdun 1525 ati 1859, Britain ṣè akoso two-thirds awọn ẹru to wa lati Bight of Biafra. Ni óṣu August, Ọdun 1861, Bight ti Biafra ati agbegbe Bight ti ilẹ́ Benin (lori akoso ilẹ British consuls) di united British consulate, labẹ́ akoso British consuls: Ni ọdun 1967, the Eastern Region of Nigeria yọ ara wọn kuro ni ilẹ naijiria ti wọn si yọ orukọ lati etikun Bight ti Biafra,lati ọminira tuntun ti Republic of Biafra. Ominira naa jẹ oniti kukuru nigba ti ipinlẹ tuntun naa tuka si ija ogun abẹle ti ilẹ naijiria. Ni ọdun 1975, Ijọba Orilẹ ede Naijiria so órukọ Bight ti Biafra di Bight ti Bonny.
Bight ti Biafra
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74347
74347
Ènìyàn gbígbé káàkiri Gbígbé ènìyàn kiri jẹ́ ìṣòwò ti ènìyàn fún ìdí ti iṣẹ́-ipá líle, iṣẹ́ ìfipábánilòpọ̀, ẹrú ìbálòpò, tàbi ìlòkulò ìbálòpọ̀ fún ìṣòwò . Gbígbé ènìyàn kiri le wáyé láàárin orílẹ̀-èdè kan tàbí orílẹ̀-èdè méjì. Ó yàtọ̀ sí ti gbígbé ènìyàn wọ ìlú lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí, èyí tí ó jẹ́ àjọmọ̀ ẹni tí a gbé pẹ̀lú. Gbígbé ènìyàn kiri jẹ́ ìdálẹ́bi fún ìlòdil sí àwọn ẹ̀tọ́ ènìyàn nípasẹ̀ àwọn àpéjọ káríayé, ṣùgbọ́n aàbò òfin yàtọ̀ káàkiri àgbáyé. Ọ̀kẹ́ aìmọye ni àwọn tí ó faragbá káṣá iṣẹ́ yìí káàkiri àgbáyé. Oríkì. Ìlànà UN láti dèènà, tẹ̀mọ́lẹ̀ àti fi ìyà jẹ àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn gbígbé ènìyàn káàkiri, pàápàá àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, èyítí ó ní àwọn ìbuwọ́lù 117 àti àwọn ẹgbẹ́ 173, ṣàlàyé gbígbé ènìyàn káàkiri bí: a) ... ìgbanisíṣẹ́, gbígbé tàbí gbígba àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ ìrókeke tàbí lílo ipá tàbi àwọn ọ̀nà mìíràn, ti ìjínigbé, jìbìtì, ti ẹ̀tàn, ìlòkulò agbára tàbi ti ipò aìlágbára tàbi ti fífún tàbi gbígba àwọn sísanwó tàbi àwọn aǹfàní láti rí ìfọwọ́sí ènìyàn tí ó ní ìṣàkóso lórí ènìyàn mìíràn, fún ìdí ìlòkulò. Ìwà ìlòkulò yóò pẹ̀lú, ó kéré jù, lílo ẹlòmíràn fún panṣágà tàbí àwọn ọ̀nà ìlòkulol ìbálòpọ̀ mìíràn, iṣẹ́ tí a fi agbára mú tàbí àwọn iṣẹ́ tipátipá, ẹrú tàbí àwọn iṣé tí ó jọra sí ẹrú, ìyọkúò, ìyípadà tàbi gbíngbin àwọn ẹ̀ya ara. (b) Ifiweranṣẹ ti olufaragba gbigbe kakiri ni awọn eniyan si ilokulo ti a pinnu ti a gbekalẹ ni ipin-ipin (a) ti nkan yii ko ni ṣe pataki nibiti eyikeyi awọn ọna ti a gbekalẹ ni isọ-apakan (a) ti lo; (c) Rikurumenti, gbigbe, gbigbe, gbigbe tabi gbigba ọmọ fun idi ti ilokulo ni ao gba si “kakiri ni awọn eniyan” paapaa ti eyi ko ba kan eyikeyi awọn ọna ti a ṣeto siwaju ninu ipin-ipin (a) ti eyi nkan; (d) "Ọmọ" yoo tumọ si eyikeyi eniyan labẹ ọdun mejidilogun.
Ènìyàn gbígbé káàkiri
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74348
74348
Bight ti Benin Bight ti Benin tabi Bay ti Benin ni Bight to wa ni Gulf ti Guinea ni etikun iwọ oorun ti ilẹ Afrika to gba órukọ rẹ̀ lati iṣẹdalẹ afin ti Benin. Àgbègbè. Bight ti Benin tọ kasi ila oorun fun kilometres ti oji le ni ẹ̀gbẹta (400 mi) lati Cape St. Paul lọsi Nun outlet ti Niger River. Lati ila oorun o tẹsi waju lọsi Bight of Bonny (Bight ti Biafra tẹlẹ̀ri). Bight naa ni a sọ lorukọ lati órukọ afin ti ilẹ Benin. Bight ti Benin gbẹkele owo oko ẹ̀ru ṣiṣe to gbajumọ lẹyin ti ijọba amunisin wọle. Ounka sọpe Benin ma n ko ẹrun ẹgbẹrun kan pẹlu ẹ̀gbẹ̀fa wọle lọdun. Itan. Ni ọjọ akọkọ óṣu february,ọdun 1862 ni ijọba ti British da Bight ti Benin ti British protectorate lori akoso consul ti Bight ti Benin silẹ. Bight ti Benin fun igba pipẹ ti ni aṣèpọ pẹlu oko ẹru, ibudo wọn ni a pe ni Etikun awọn Ẹru. Lati Ọdun 1807 wasilẹ lẹyin ti oko ẹru ti di ewọ fun Britons, Awọn Royal Navy da squadron ti iwọ oorun Ilẹ Afrika lati palẹ oko ẹru mọ. Akitiyan yi lọsiwaju si to si gboro ni ọdun 1833 nigba ti oko ẹru di ewo kakiri Igboriko ti ilẹ British. Ni ọjọ kẹfa, Óṣu August, Ọdun 1861 ni Bight ti Biafra protectorate ati Bight ti Benin protectorate darapọ lati di united British protectorate to pada dapọ lati ilẹ Naijiria.
Bight ti Benin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74349
74349
Àwọn àkókò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fòpin sí owo-eru àti Iwofa Fífòpin sí Ẹrú kíkó wáyé lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oríṣiríṣi orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹlẹ̀ léraléra ní tẹ́lẹ̀ntẹ́lẹ̀ ní ìpele tí ó ju ọkàn lọ - fún àpẹẹrẹ, fífòpin sí ẹrú kíkó wáyé ní àwọn àgbègbè kan gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ibòmíràn gẹ́gẹ́ àṣẹ ìṣèjọba àgbègbè wọn. Ìgbésẹ̀ òpin yìí máa ń dá lé òfin tàbí ilana tí ìjọba kọ̀ọ̀kan là kalẹ̀ láti fi dè é. Àwọn àkókò wọ̀nyí yóò ṣàfihàn àwọn òfin àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n fòpin sí ẹrú kíkó àti ìwọ̀fà níní ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú kíkó jẹ́ ìwà ọ̀daràn lóòótọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé lónìí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ibi ni okoòwò ẹrú ṣì tún wà káàkiri ní àgbáyé, pàápàá jùlọ nílẹ̀ adúláwọ̀ Áfríkà, Asia, àti Eastern Europe, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ìjọba. Láyé àtijọ́. Láyé àtijọ́ tí ojú ṣì dúdú, ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè àti ìlú Europe àti àwọn ìlú ni òkè-òkun ní wọ́n fàyè gba ẹrú ṣíṣe pàápàá jùlọ láti san gbèsè tàbí àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn, èyí yàtọ̀ gedegbe sí ní mímú onígbèsè nípa láti wá ṣiṣẹ́ dípò gbèsè tí ó bá jẹ́, ṣùgbọ́n èyí kò sọ onígbèsè di ẹrú pọ̀ǹbélé fún ẹni tí ó jẹ lowo kò sí sí anfaani láti ṣe bí ó ṣe wuni fún onígbèsè bí ó ṣe máa ń rí, tí ó sọ ẹrú di dúkìá olówó ẹni tí ó lẹ́rú, tàbí kí ẹrú tí ó wá láti ìdílé ọba sọ anfaani rẹ̀ nù gẹ́gẹ́ bí ọba lóla nítorí pé ó ń sìngbà ẹrú bí ó ṣe máa ń rí nínú ọjà okoòwò ẹrú. Àwọn àtúnṣe tí a kọ sí ìsàlẹ̀ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí òfin Salon ní ìlú Athens, ti Lex Poetelia Papiria ní Republican Rome, tàbí àwọn ìlànà tí wọ́n là kalẹ nínú Bíbélì lédè Hébérù nínú ìwé Deuteronomy fi ìlànà sí ẹrú níní àti ìgbà sísìn lápapọ̀ nípa fífi òfin àti ìlànà de àwọn àṣàkáṣà nínú ẹrù níní àti ìgbà sínsìn tí àwọn olówò máa ń fi ẹrú wọn ṣe (bẹ́ẹ̀, àwọn àtúnṣe Roman dá ààbò bo àwọn ọmọ Rome, àtúnṣe àwọn Athenian dá ààbò bo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wọn bákan náà, bẹ́ẹ̀ náà àwọn òfin tí ó wà nínú ìwé Deuteronomy fàyè gba òmìnira fún àwọn ọmọ Hebrew fún ìwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń singba), ṣùgbọ́n kò sí àwọn anfaani wọ̀nyí fún àwọn ààrè àti àwọn tí kìí ṣe ojúlówó ọmọ ìlú.
Àwọn àkókò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fòpin sí owo-eru àti Iwofa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74350
74350
Ìsìnrú ní Rómù àtijọ́ Ìsìnrú ní Róòmù àtijó kó ipa pàtàkì ní àwùjọ àti ètò ọrọ ajé Róòmù. Yàtò sí lílò wọ́n láti ṣe iṣẹ́ agbára, wọ́n lọ àwọn ẹrú fún ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ilé àti fún àwọn iṣẹ́ ọpọlọ míràn. Àwọn tí ó ń ka owó àti àwọn oníṣègùn nígbà náà jẹ́ ẹrú. Àwọn ẹrú tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Gríkì ma ń sábà jẹ́ alákọ̀wẹ́. Àwọn tí kò jẹ́ ọ̀mọ́wẹ́ ma ń ṣisẹ́ nínú ọkọ, ilẹ̀ kùsà. Òfin Róòmù àtijọ́ ka àwọn ẹrú gẹ́gẹ́ bi ohun ìní, wọn kò sì ní àṣẹ sí ayé ara wọn. Wọn kìí tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú sílẹ̀, àwọn olówó wọn sì láṣẹ láti fìyà jẹ wọ́n, lò wọ́n fún ìbálòpọ̀ tí kò tó, sọ wọ́n di aṣẹ́wó, náà wọ́n tàbí pa wọ́n. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ̀wẹ̀, àwọn ẹrú bẹ̀rẹ̀ sí ń ní àwọn òmìnira kọ̀kan lábé òfin, pẹ̀lú pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìwà àwọn olówó wọn tí kò tó lé òfin létí. Ọ̀nà gbòógì tí Róòmù fi ń rí ẹrú ni nípa kíkó ẹrú lójú ogun.
Ìsìnrú ní Rómù àtijọ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74351
74351
Ẹrú Kíkó Ẹrú kíkó níṣe pẹ̀lú kí àwọn ológun kó àwọn ènìyàn kúrò ní agbègbè tí wọ́n ń gbé lọ sọ wọ́n di ẹrú ní ilẹ̀ ibòmíràn. Tẹ́lẹ̀, èyí jẹ́ ohun tó tọ́ tàbí tí ó jẹ mọ́ ogun jíjá, ṣùgbọ́n lóde-òní ẹ̀ṣẹ̀ ni ó jẹ́. Láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ni ẹrú kíkó ti wà. Ní ilẹ̀ Sumer (tí a mọ̀ sí Iraq lóde-òní) ni àkọsílẹ̀ ẹrú kíkó ti wáyé jù lọ. Ìjénìyàngbé àti àwọn ẹrú láti ara ogun jíjà ni ó ṣokùnfà àwọn ẹrú ilẹ̀ Áfíríkà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣọ̀fà àti Ìjẹniníyà náà wà lára àwọn ohun tí ó bí ẹrú. Ìmọ̀-ẹ̀rọ àti àwọn àyípadà tó ti ń dé bá àṣà àti ìṣe ti ń mu kí kíkó ẹrú àti ìfènìyàn ṣọfà máa parẹ́. Àwọn Ìdí. Ẹrú kíkó jẹ́ ìlànà ipá láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀-ajé, nígbà tí ọ̀wọ́n àwọn ohun-èlò bá wáyé, èyí máa ń fa kí wọ́n fi ipá pèsè iye àwọn ohun-èlò tó pọ̀, ìdí nìyí tí àwọn lílọ àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé kíkó ènìyàn lẹ́rú bẹ̀rẹ̀ sí ní wáyé, ìlànà ipá láti ṣẹ̀dá àwọn ohun-èlò wọ̀nyí náà ni wọn ń ṣàmúlò láti pèsè oúnjẹ àti àwọn ohun-èlò mìíràn. Ẹrú kíkó gbòòrò bẹ́ẹ̀ ó sì tún ń yá ní àwọn etí-òkun ilẹ̀ Áfíríkà, ilẹ̀ Europe ìgbàanì, Mesoamerica, àti ní sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ilẹ̀ Asia. Kíkó àwọn ènìyàn lẹ́rú àwọn ará Crimean–Nogai ní agbègbè ìlà-oòrùn Europe pèsè àwọn ẹrú mílíọ̀nù méjì tàbí mẹ́ta fún Ẹkùn Ottoman láàárín sẹ́ńtúrì mẹ́rin. Bákan náà, àwọn ajalèlókun Barbary láti sẹ́ńtúrì kẹrìndínlógún títí kan 1830 kópa nínú kíkó àwọn ènìyàn lẹ́rú ní ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn etí-òkun agbègbè Europe títí kan Iceland, tí wọ́n sì tún kó àwọn ènìyàn lẹ́rú lọ sí ọjà ẹrú àwọn Mùsùlùmí ní agbègbè Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà àti Àárín Ìlà-oòrùn. Kíkó àwọn ènìyàn lẹ́rú káàkiri agbami Atlantic jẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe kó èrè rẹ̀ gan-an, tí wọ́n sì ń fọwọ́ si kí ìtẹ̀síwájú láti máa kó àwọn ènìyàn ẹ̀yà Áfíríkà lẹ́rú kí wọ́n le máa ṣiṣẹ́ ní àwọn oko ọ̀gẹ̀dẹ̀ ilẹ̀ America.
Ẹrú Kíkó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74352
74352
Ìbálòpò fún ẹ̀mí Ìbálòpọ̀ fún ẹ̀mí túnmọ̀ sí kí ènìyàn ma ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó láti pèsè fún àwọn nǹkan àwọn àìní tí ó ṣe pàtàkì fún wọ́n. Ó túnmọ̀ sí kí àwọn tí kò nílé lórí tàbí àwọn tí ó kò ní ànfàní púpò láwùjọ ma lọ Ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti pèsè fún oúnjẹ, ibi tí wọ́n ma gbórílé àti àwọn míràn. Ìwọ́pọ̀ rẹ̀. Ìbálòpọ̀ fún wọ́pọ̀ káàkiri àgbáyé, wọ́n sì ti ṣe òpò ìwádìí nípa rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè Afghanistan, United States, Canada, Mexico, Philippines, Thailand, New Zealand, Colombia, Kenya, Uganda, àti South Africa. Àwọn òòlù wádìí ti fihàn pé nínú àwọn aláì nílé ní North America, ìkan nínú mẹ́ta wọn ti ní ìbálòpò láti pèsè fún àwọn àìní tí ó ṣe pàtàkì.
Ìbálòpò fún ẹ̀mí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74353
74353
Black Lives Matter Black Lives Matter (BLM) jẹ́ Ìwọ́de, ìjà àti ìṣọ̀rọ̀ lòdì sí Ìṣẹlẹ́yàmẹ̀yà, ìfìyàjẹ, àti àwọn nǹkan míràn tí Àwọn aláwọ̀ dúdú ń dójú kọ. Àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú ìjà fún ètọ́ náà ni ìjà lòdì sí Ìyà àìtó láti owó àwọn agbófinró bi Ọlọ́pá àti ìfìyàjẹ àwọn aláwò dúdú. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú pípa Trayvon Martin, Michael Brown, Eric Garner, Rekia Boyd, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn lọ́nà àìtọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìwọ́de lórí ọ̀rọ̀ yìí ni ó jẹ́ Ìwọ́de àlàáfíà, wọn kò mú wàhálà dání.
Black Lives Matter
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74354
74354
Triangular trade Trade among three ports or regions Triangular trade or triangle trade jẹ owo to waye lati igberiko mẹta tabi agbegbe. Triangular trade ma n ṣẹlẹ nigbati igberiko kan ba gbe ọja lọsi ibi ti wọn ti nilo rẹ ti eyi ṣi jẹ agbegbe ti wọn ti ma n gba ọja wọle. Eyi ni a ma fin ṣè ale kun ba awọn owo ti o ku ju ṣuwọn ni oriṣiriṣi agbeegbee. Oko Ẹru Atlantic Olọna Mẹta. Owo ti ọlọna mẹta to gbajumọ julọ ni owo ẹru ṣiṣe ọlọna mẹta larin ile Europe, Afrika ati America lati Century mẹrin dinlogun ati ọkan dinlogun. Ọkọ óju omi awọn ẹru ma n kuro lati ibudo awon Europe (Gẹgẹbi Bristol and Nantes lọsi Ibudo Afrika pẹlu oja ti wọn ṣe ni ilẹ Europe. Nibẹ, awọn olowo oko ẹru ṣiṣe ma nta awọn ẹru ilẹ Afrika pẹlu gbigba ọja lẹyin naa ni wọn lọsi ilẹ America lati ta awọn ẹru naa ni ilẹ Europe. Awọn ẹru ilẹ́ Afrika ni wọn ma nlo lati fi ṣiṣẹ ni inu oko lati ṣiṣẹ lori oun agbẹ gẹgẹbi Sugar,Cotton ati Tobacco. Awọn oloko ẹru tita nigba miran lati ilẹ Europe maa n wasi ilẹ Afrika fun rawọn. Iṣiro. Gẹgẹbi iwadi ti ile iwe giga ti Emory muwa ati Henry Louis Gates Jr.Owo Oko Ẹru ti Trans-Atlantic ṣiro si 12.5 milionu ẹru ti wọn gbe lati ilẹ Afrika lọsi colonies ni North and South America. Website Voyages: The Trans-Atlantic Slave Trade Database ko data lori awọn ti wọn ti ko sẹyin lati ilẹ Africa past trafficking in slaves from Africa. Eyi firan wa pe awọn orilẹ to ko ni lẹru julọ ni Portugal, Great Britain, France ati Spain.
Triangular trade
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74355
74355
Oko Ẹru ti Adayeba Oko Ẹru ti Adayeba (Tabi Oko Ẹru ti Aristotelian) jẹ ariyanjiyan lori Óṣèlu Aristotle to da loripe eniyan jẹ ẹru ni adayeba ṣugbọn awọn toku jẹ ẹru latari ofin tabi convention. Ọrọ ti Aristotle sọ lóri oko ẹru. Aristotle Ṣalaye pe ẹru adayeba jẹ ẹni ti o jẹ ọmọ gẹgẹbi adayeba ṣugbọn ẹlo mira lo ni. O ṣe alaye ṣiwaju pe ẹni naa ni oun alumọni ti olowo rẹ le lo nigba kigba to ba ti wu. Aristotle ṣe alaye pe kiko ni lẹru pẹlu agidi o kinṣe nkan to lere ninu nigba owo ẹru naa o ba tijẹ ti adayeba. Iṣẹ Aristotle ni aimoye eniyan ti tako. Darrell Donns sọpẹ ọrọ Aristotle lori owo ẹru ko dọmọran to. Awọn olumoye yoku sọpẹ ipo ẹru adayeba ṣè yipada niwọn igba ti itumọ ti Aristotle fun adayeba ṣe yipada. Ipà. Stoic lodi ironu ti Aristotle lori owo ẹru ṣiṣe ti adayeba ni letter ti Seneca ati ibomiran. Ni Century ti mẹrin dinlogun ti ilẹ amẹrica koni lẹru, ariyanjiyan lori kiko ni lẹru bẹrẹ. Ọpọlọpọ awọn akonilẹru lofi ọwọ si owo ẹru ṣiṣe ti wọn si lo aimoye ọna lati fi idi rẹ mulọ. Bartolomé de las Casas fi ọwọ si ṣiṣe awọn eniyan ni pẹlẹ pẹlẹ lori yiyi wọn pada lai ma kowọn lẹru. Las Casas lodi si ibaṣè awọn alawọ dudu lọwọ awọn Spaniards. Ni ọdun 1520, Las Casas ri Ọba Holy Roman Emperor Charles V (Charles I ti Spain) lori ṣise awọn eniyan ni jẹjẹ. Ni óṣu April, ọdun 1550, Las Casas ati Juan Ginés de Sepúlveda pade ni ilu Spain lori ariyanjiyan nipa kiko awọn ilẹ America lẹru ati lori ọrọ Aristotle nipa ẹru ti adayẹba. Sepúlveda sọpa ipo aye tuntun awọn akonilẹru, awọn Amerindinas jẹ ẹru adayeba. Las Casas tako ọrọ Aristotle lori Barbarians ati lori lilo ọrọ naa fun awọn ilẹ Indian.
Oko Ẹru ti Adayeba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74356
74356
Etikun ti Swahili Coastal area of the Indian Ocean in southeast Africa Etikun ti Swahili jẹ etikun ti ocean ti indian ni East Africa ti awọn ẹya Swahili ngbe. Eyi lekun pẹlu Dar es Salaam; Sofala (ni Mozambique); Mombasa, Gede, Pate Island, Lamu, and Malindi (ni Kenya); and Kilwa (ni Tanzania).Óriṣiri coastal islands to wa ni Swahili coast ni Zanzibar ati Comoros. Agbègbè ti a mọsi etikun ti Swahili ni a mọ ni adayeba gẹgẹbi Azania tabi Zingion ni igba Greco-Roman ati Zanj tabi Zinj ni Middle Eastern, Indian, and Chinese literature lati the 7th to the 14th century.Ọrọ "Swahili" tumọsi awọn ara etikun ni ede larubawa ti wọn si yọ ọrọ naa lati Sawahil("coasts"). Awọn ara Swahili people ati àṣa wọn dara pọ lati ẹya ilẹ Afrika ati larubawa.Awọn Swahili jẹ olutaja ti wọn tayọ latara awọn àṣà. Etikun Swahili ni àṣa, agbègbè, ẹsin to da yatọ. Itan. Nigba aye tẹ̀lẹri, ki igba Swahili to ṣẹlẹ, agbegbe naa kun fun ayika to da lori oniru iṣẹ gẹgẹbi agbẹ ati owo ẹja ṣiṣe. Awọn ti wọn gbe ni etikun swahili gbẹ kẹle agbẹ ṣiṣe lori jijẹ ati mimu wọn. Nigba ti owo ṣiṣe bẹrẹ ni etikun naa, awọn oluṣowo larubawa ma nbẹnu atẹlu awọn ti kinṣe musulumi ati awọn àṣa ilẹ Afrika. Eyi lojẹ ifasẹyin fun awọn eyan jakan ti ilẹ Afrika lati ma dasi agbegbe.Eleyi lo jasi ikorajọ àṣa Swahili ati agbegbe rẹ papa eyi to da lori owo ṣiṣè Etikun erekusu. Óriṣiriṣi erekusu lo wa ni etiku ti swahili bi Zanzibar, Kilwa, Mafi ati Lamu. Pupọ ninu awọn erekusu yi lagbara latara awọn owo ṣiṣe. Awọn oluamọni ti wọn ni Mangroves ati Owo ẹja ṣiṣe. Owo Ẹru. Ni arin ọdun 1450 ati 1900 CE awọn eniyan million ni wọn ta ni owo ẹru si Europe, Afrika ati Asia ti wọn si gbe wọn lọ si awọn oluṣowo ẹru lati okun Mediterranean, Ọna Silk, Indian Ocean, Okun pupa ati Desert ti Sahara. Kotodi 18th century, owo oko ẹru ni east Afrika etikun kere. Awọn obinrin ati ọmọde ni wọn ma n ko lẹru ni aye Asia to ri pe wọn ma lowọn lati ṣiṣẹ ọmọ ọdọ ati Ibalopọ. Awọn ọmọ ti a bi lati awọn ẹru ti wọn ko bi Ale jẹ ọmọ ti wọn tọju gẹgẹ́bi awọn ara iyoku to yatọ si ẹru. Óriṣiriṣi ija larin awọn ẹru lo ti ṣẹlẹ ni arin ọdun 1869 ati 1883 CE ni ilu Basra, agbegbe kan to wa ni órilẹ ede Iraq. Ija awọn ẹru ni a npe ni Zanj Renellion. Ijagbara yi jasi itusilẹ awọn ẹruọ̀kẹ́ màrún-dín-ní-ọgbọ̀n, Ija naa ṣẹlẹ fun ọdun mẹerin leelogun. Awọn ẹru ti wọn to maarun leelogun lọna ẹgbẹrun doju ija kọ awọn ilu ti wọn si tu awọn ẹru ẹgbẹ silẹ lẹyin naa ni wọn ji ounjẹ ati oun ilo ogun. Ija yi lo dinku agbara ti Abbasids ni lori awọn ẹru. Nigba ija naa, awọn ẹru labẹ oludari Ali Ibn Muhammad jagun si Basra. Ọpọlọpọ awọn ẹru to kopa ninu ija naa jẹ Awọn alawọ dudu ilu Afrika.
Etikun ti Swahili
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74357
74357
Proslavery Proslavery túmọ̀ sí fífi ọwọ́ sí ìsìnrú. Ìsìnrú jẹ́ ohùn tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àtijọ́ míràn fi owó sí, ó sì jẹ́ ohun tí ó farahàn nínú ìwé mímọ́. Àwọn ìwé àkọọ́lẹ̀ Amẹ́ríkà àti Britain àtijọ́ náà tún fọwọ́ sí ìsìnrú, pàápàá jù lọ, àwọn ìwé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kí Ìjà abẹ́lé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ṣẹlẹ̀. Àwọn kọ̀kan tí ó fọwọ́ sí ìsìnrú ma ń tọ́ka sí Bíbélì mímọ́, wọ́n gbàgbọ́ pé a bí àwọn kọ̀kan láti jẹ́ ẹrú, àwọn míràn sì gbàgbọ́ pé ìsìnrú jẹ́ ohun tí a ti ń ṣe láti ìṣẹ̀báyé.
Proslavery
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74358
74358
Ìsìnrú ní Gríkì àtijọ́ Ìsìnrú jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ Gríkì láyé àtijó, bí ó ti wọ́pọ̀ ní àwọn àwùjọ míràn nígbà náà. Àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń lọ àwọn ẹrú fún ni iṣẹ́ àgbẹ̀, iṣẹ́ kùsà àti gẹ́gẹ́ bi ọmọ ọ̀dọ̀ fún iṣẹ́ nínú ilé. Ní Gríkì àtijọ́, wọn kò ka ẹrú mọ́ ara àwùjọ ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn gẹ́gẹ́ bi ohun ìní. Ọ̀pọ̀ ẹrú kò lẹ́tọ́ lọ́wọ́ ara wọn, wọ́n sì wà lábé olówó wọn tí ó le rà wọ́n, tà wọ́n, tàbí yá wọn fún ẹlòmíràn. Ìgbìyànjú láti ṣe ìwádìí nípa Ìsìnrú ní Gríkì àtijọ́ ti bá àwọn ìṣòro pàdé. Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìsìnrú nígbà náà tako ara wọn, ọ̀pọ̀ wọn sì dá lórí ilẹ̀ Athens nìkan.
Ìsìnrú ní Gríkì àtijọ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74359
74359
Taiwo Olowo Olóyè Daniel Conrad Taiwo (tí a bí ní ọdún 1781 tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ ogún oṣù kejì ọdún 1901), àwọn ènìyàn tún mọ̀ọ́ sí Taiwo Olówó. Ó jẹ́ olùtà ohun ìjà ogun, olówó àwọn ẹrú, afifúni àti olórí àdúgbò kan nígbà tí Èkó wà lábé ìjọba Britain. Ìpìlẹ̀ rẹ̀. A bí Taiwo Olowo ní ọdún 1781 ní Isheri, àdúgbò kan ní ìpínlẹ̀ Eko. Baba rẹ̀, Oluwole, jẹ́ Olofin ìlú rẹ̀, ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1809. Olowo kó lọ sí ìlú Èkó ní ọdún 1848 ó sì jẹ́ ẹrú Ogunmade fún ìgbà díẹ̀.
Taiwo Olowo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74360
74360
Okoro Idozuka Okoro Idozuka jẹ oludari ti 19th Century ati jagun jagun ni agbegbe Arondizuogu, ilẹ Naijiria. Arakunrin naa jẹ olujiroro agba si oludasilẹ abule Ndiakunwanta Uno Arondizuogu. Okoro jẹ gbajumọ oniṣowo ẹru ṣiṣe to lowo lọwọ. Igbeèsi Àye Okoro. Idozuka ni a bisi agbegbe Awka ṣugbọn ti o ko lọsi Arondizuogu ni Century. Arakunrin naa pada yi órukọ Abisọ rẹ Bọda Okoli si ti Aro. Okoro jẹ baba fun Nwankwo Okoro. Okoro Idozuka jẹ̀ ọkan lara awọn oludari to pataki ni Arondizuogu to si jẹ eniyan jakan ni Aro titi di eni. Ìnira ti Okoro dojukọ. Ni ọdun 1819, awọn ẹniyan fi aimoye ẹsun kan Okoro lori jiji awọn eniyan gbe, eyi jẹ ọna lati ba owo arakunrin naa jẹ. Lati ra iyi rẹ̀ pada, Okoro mu lẹ, eyi jẹ ọkan lara imulẹ meje to tobi julọ ni aye igbana. Imulẹ yi ni eyi ti ẹni kẹni to ba fẹ mulẹ maa nṣe ti yo fi ori rẹ̀ bura fun awọn óriṣa ṣugbọn ti yoo lo ayọmọ awọn ẹni mẹfa to sumọ julọ. Imulẹ yii lagbara to bẹ gẹ to jẹ pe ti ẹni naa ba jẹbi ẹsun taa fikan, awọn óriṣa yii ko ni pa oun nikan afi ki wọn mu awọn mẹfa ti wọn fikun imulẹ naa. Fun ti imulẹ ti Mazi Okoli Idozuka fẹ ṣe, wọn ni ki o fi awọn molẹbi sinu imulẹ naa ati gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti a bisi ilẹ Akunwanta. Nigbati Mazi Okoro Idozuka ṣetan lati ṣè imulẹ naa, O wa awọn ọkunrin mẹfa ṣugbon o kuna a tiri ẹni keje ninu awọn ara ilẹ rẹ. Mmelonye yanda ọmọ rẹ Agosi, eyi lomu ki awọn to fi ẹsun kan Okoro jawọ kuro ninu ọrọ naa.
Okoro Idozuka
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74361
74361
Ologun Kutere Ologun Kutere jẹ gẹ́gẹ́ bi Oba Èkó láti 1780s títí di ọdún 1803. Òun ló jẹ́ lẹ́yìn Oba Eletu Kekere, ẹni tí ó wà lórí oyè láti ọdún sí 1775 and 1780. Ologun Kutere jẹ́ ọmọ Erelu Kuti, ẹni tí ó jé ọmọ Oba Ado, àti Alaagba ('Alagbigba'), ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Ìjẹ̀sà àti olùbádámọ̀ràn Oba Akinsemoyin. Ìtàn rẹ̀. Bàbá Kutere jẹ́ Babaláwo ní Ìpínlẹ̀ Èkó nígbà àwọn ọdún 1700s. Nígbà tí Kutere wà lórí oyè, ìbárà láàrin Èkó àti and Ijebu wọ́pọ̀ si, àwọn Ìjẹ̀bú gbé oúnjẹ wá láti gba iyọ̀, tobacco, spirits, àti àwọn ìkan míràn tí àwọn Èkó gbà lọ́wọ́ àwọn ara ẹrú tí orílẹ̀ èdè Portugal. Ologun Kutere lówó, ó sì jẹ́ ẹni tí ọ̀pọ̀ bẹ̀rù. Kutere ní ọmọ tópọ̀, àwọn bi;Eshinlokun, Adele Ajosun, Akitoye, Akiolu, Olukoya, àti Olusi.
Ologun Kutere
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74362
74362
Niara Bely Niara Bely (c.1790-1879) ti a mọ ni gbajumọ gẹgẹbi Elizabeth Bailey Gomez jẹ olori ti Luso-Ilẹ Afrika jẹ óniṣowo pataki ni Century ti okan dinlogum. Arabinrin na jafafa lori owo oko ẹru ṣiṣe ni Farenya, Ilẹ Guinea. Itan Igbesi Àye Niara. Niara Bely jẹ ọmọbinrin Emmanuel Gomez, Oludari ti Bakia ti Luso-Ilẹ Afrika ni ilẹ Guinea. Niara kawe ni Liverpool. Ni ọdun 1809, Niara fẹ oniṣowo ẹru Stiles Edward Lightbourn nibi ti wọn kọkọ gbe ni Bangalan. Bely ṣiṣe owo ni Farenya, Guinea. O bẹrẹ́ sini gbe ni ile alaja meji eyi to maa n pe nk Afin. Agbegbe yi di Abule nigbati Bely bẹrẹ iṣẹ owo oko ẹru, eleyi pada di ọna owo ṣiṣe lati oke ti Fouta Djallon. Ni Ọjọ mẹta dinlogun, Óṣu January, ọdun 1852, ijọba ilẹ British ati Sierra Leone pẹlu apapọ oludari abule fagile owo oko ẹru ṣiṣe ni agbegbe naa. Mary Faber (Óniṣowo Ẹru) ri ayipada yi gẹẹbi ipalara fun owo rẹ parapọ pẹlu Niara Bely ati Charles lati lodi si ifagile naa ni odo to wa ni isalẹ ti Susu. Ija yi ni kogbe Faber, Bely ati Wilkinson ni ọdun 1855. Akoko yi ni owo oko ẹru ṣiṣe di afisẹyin eleyi lo mu ki awọn olowo oko ẹru bẹrẹ owo miran. Iku Niara. Ni ọjọ mẹfa dinlogun, óṣu April, ọdun 1879, Niara Bẹly ku eyi to jẹ ti ojiji lẹyin ti wọn si mimọ ni ijọ Anglican gẹgẹbi ọrọ ọkan lara awọn olubagbe rẹ. Ni akọkọ, A sin Niara si abẹ igi cheese ni arin abule ṣugbọn ni ọdun 1966, wọn gbẹ sare si agbegbe naa ti wọn sin oku rẹ si
Niara Bely
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74363
74363
N'Gangue M'voumbe Niambi N'Gangue M'voumbe Niambi jẹ́ ọba ìjọba Loango ní àwọn ọdún tó gbẹ̀yìn ọdún 1600s. Ó rí ọ̀pọ̀ èrè nínú títa àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bi ẹrú fún orílẹ̀ èdè [[Kingdom of Portugal|Portugal]. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ [[Olfert Dapper]], Niambi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà ogun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kò mọ bí a ṣe ń lò wọ́n.
N'Gangue M'voumbe Niambi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74364
74364
Caty Louette Caty Louette tabi Cathy Louet (1713-d. lẹyin 1776) jẹ oniṣowo pataki ti ilẹ Afrika. Caty jẹ ọkan lara awọn eniyan jakan ni agbegbe ti Gorèe. Caty Louette jẹ̀ ọmọbinrin arakunrin to wa lati ilẹ French Nicolas Louët, to jẹ oṣiṣẹ ilẹ̀ french ti east india ati mistress rẹ Caty de Rufisque ti Gorèe. Louette di signare-consort ti Pierre Aussenac de Carcassone ti ilẹ french, óṣiṣẹ ti East India ti ilẹ French. Caty Louette jẹ gbajumọ oniṣowo ẹru ti Gorèe. Caty le kọ ati ka, eyi lo mu ko jẹ obinrin to lowo gidi gan to si ni oko ẹru to tobijulọ ni 1767. Caty ni ẹru 68 nibi awọn oniṣowo ẹru ti ma nta awọn ẹru kaki wọn fiwọn pamọ.
Caty Louette
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74365
74365
Fenda Lawrence Fenda Lawrence (1742 – lẹ́yìn 1780), jẹ́ olóko òwò ẹrú Áfíríkà tí ó ṣiṣẹ́ yìí ní Saloum, ìlú Kaur. Ìtàn ayé rẹ̀. Fenda Lawrence gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Gambia ní àwọn ọdún 1700s. Ní àdúgbò náà, ó jé òlùbádúna dúrà láàrin àwọn oníṣòwò Britain, France àti àwọn oníṣòwò Áfíríkà. Ó di ipò yìí mú lẹ́yìn ìgbà tí ó fẹ́ Òyìnbó kan. Lawrence ṣiṣẹ́ láti Saloum ìlú tí Kaur. Ní ọdún 1772, Lawrence lọ sí Thirteen Colonies ti America láti ṣòwò. Nígbà yìí, ó ti yapa láti ọ̀dọ̀ Oko òyìnbó tí ó fẹ́. Nígbà tí ó wọ ọkọ ojú "New Britannia", Lawrence mú ẹrú márùn-ún pẹ̀lú ara rẹ̀. Ọkọ̀ náà déCharleston, South Carolina, lẹ́yìn ọjọ́ méjìdínlógójì tí ọ́ gbéra. Adarí ọkọ̀ náà, Stephen Deane, sì tẹ̀lé Lawrence lọ sí Georgia.
Fenda Lawrence
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74366
74366
Ìpalára Ìpalára jẹ́ ìṣeni-láída búburú ní ara, tí ó le ba ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ tàbí wíwà láyé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀. A tún le ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbanilára jẹ́ tí ó le dín iyì ohun kù, bùrẹ́wà ohun bẹ́ẹ̀, àìlèṣe rẹ̀, tàbí kí ó sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ di aláìpé. Ní ayé òde-òní, èrò yìí túmọ̀ sí ohun tí ó burú jáì. Àká-ọ̀rọ̀. Ní 2019, Michael H. Stone, Gary Brucato, àti Ann Burgess dábàá ìlànà àìgbẹ̀fẹ̀ láti le ṣèyàtọ̀ "ìpalára" àti "ìyakúrò", nítorí gbígbé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí síra máa ń sábà wáyé. Wọ́n sì dábàá pé ìyakúrò níṣe pẹ̀lú "ìyọkúrò pátápátá, lọ́nàkọ́nà tó bá gbà, apá ńlá kan lára alàyè tàbí òkú, ní pàtó, orí irú ẹni tàbí òkú bẹ́ẹ̀, apá, ọwọ́, ìbàdí, ẹsẹ̀, tàbí àtẹ́lẹ́ẹsẹ̀". Nígbà tí ìpalára lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀ níṣe pẹ̀lú "ìyọkúrò tàbí ìbàjẹ́ àìní-àtúnṣe lọ́nàkọnà àwọn ìpín ara ńláńlá ènìyàn tó wà láàyè tàbí tó ti kú. Ó le jẹ́ yíyọ kóró-ẹpọ̀n, àwọn ẹ̀yà ara inú, tàbí yíya àwọn". Nípasẹ̀ àwọn ìlànà wọ̀nyí, yíyọ ọwọ́ ènìyàn pátápátá máa túmọ̀ sí "ìyọkúrò", nígbà tí ṣíṣe ìjàmbá fún ìka-ọwọ́ yóò jẹ́ ìpalára, tí yíyọ gbogbo òkè ara títí dé ẹsẹ̀ yóò jẹ́ ìyakúrò, nígbà tí yíyọ tàbí ṣíṣe ìjàmbá fún ọyàn tàbí àwọn ẹ̀ya-ara mìíràn yóò jẹ́ ìpalára. Ìpalára Gẹ́gẹ́ bí i Ìfiyajẹ Ènìyàn. James Gavin ti Douglas, Lanarkshire jẹ́ èyí tí etí rẹ̀ di gígé sọnù nítorí ó kọ̀ láti ṣe ìkọsílẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn rẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè Japan, Gonsalo Garcia àti àwọn ará rẹ̀ jìyà irú ìfìyàjẹ yìí. Bákan náà, ní agbègbè-agbára àwọn Kólónì Mẹ́tàlá, fún ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké bí i tí ènìyàn kan bá jí ẹlẹ́dẹ̀ gbé le fà kí wọ́n la etí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n ge bọ́, ìgbà mìíràn sì wà tí ìfìyàjẹ fún ẹni tó bá ń ṣe àtúnrọ àwọn ohun ni láti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú epo tó bá wà lórí iná, àpẹẹrẹ ìpalára ìwọ̀-oòrùn nìyí. Síwájú sí i, òmìnira kò díwọ́ ìṣèdájọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kù. Bí àpẹẹrẹ, ní agbègbè Gúúsù-mọ́-ìlà-oòrun (ilẹ̀ Tennessee), àpẹẹrẹ ìdájọ́ àìfilélẹ̀ kíkan lábẹ́ Cumberland Compact wáyé ní 1793 nígbàtí Adájọ́ John McNairy ṣe ìdájọ fún olè ẹṣin àkọ́kọ́, John mcKain Jr., pé kí wọ́n só orí àti ọwọ́ rẹ̀ mọ́ igi ẹlẹ́wọ̀n kan fún wákàtí kan fún ẹgba mọ́kàdínlógójì, wọ́n sì tún gé etí rẹ̀ méjèèjì kúrò, lẹ́yìn náà ni wọ́n kọ lẹ́tà "H" àti "T" sí ẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjèèjì. Gégé ahọ́n burú jáì, ṣùgbọ́n kò wọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí i oríṣi ìpalára àti ìfìyàjẹ. Nítorí ahọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun-èlò ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ dídà yóò pọ̀ olùjìyà bẹ́ẹ̀ sì le tipa rẹ̀ kú. Nebahne Yohannes, tí ó jẹ́ olùgbẹjọ́ aláìyege fún olùjọba ìtẹ́ Ethiopia jẹ́ èyí tí etí rẹ̀ méjèèjì àti imú rẹ̀ di gígé sọnù, lẹ́yìn náà ni wọ́n tu sílẹ̀.Àmúlò irúfẹ́ ìpalára fún àwọn olùgbẹjọ́ aláìyege ìtẹ́ ọba yìí ti wà láti àìmọye ọdún sẹ́yìn ní agbègbè àárín-ìlà-oòrùn. Nítorí láti tayọ gẹ́gẹ́ bí Ọba láyé ìgbà náà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ wà ní pípé. Irú ìpalára àwọn ẹlẹ́ṣẹ́ yìí máań wáyé kí ó le jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn.
Ìpalára
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74367
74367
Akitoye Akítóyè (kú lọ́jọ́ kejì oṣù kẹsàn-án ọdún 1853), tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń ṣìpè nígbà mìíràn ní Akíntóyè, jẹ Ọba Eko ní ẹ̀mẹjì; ó kọ́kọ́ jọba láti ọdún 1841 sí 1845, lẹ́yìn náà, ó tún jọba láti ọdún 1851 sí 1853. Bàbá rẹ̀ ni Ọba Ologun Kutere, àwọn àbúrò rẹ̀ sì ni àwọn Ọba aládé Ọṣìnlokùn àti Àdèlé Àjọsùn. Bí ó ṣe jọba. Wọ́n pa Ọba Olúwọlé ọdún 1841 nígbà tí àrá kan sán tí nǹkan bí àgbá ìbọn kan sì bẹ́ ní ààfin Ọba. Àwọn Afọbajẹ ìbá ìránṣẹ́ pe Ọmọba Kosoko láti wá gorí ìtẹ́ bàbá rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó mọ ibi tó wà. Yàtọ̀ sí èyí, ìjà láàárín Eletu Odibo ati Kòsọ́kọ́ fàá tí Eletu fi dènà Kòsọ́kọ́ láti jọba. Nítorí ìdí èyí, wọ́n fi Akítóyè, ẹni tí ó jẹ́ àbúrò bàbá Kòsọ́kọ́ àti àbúrò sí Ọṣinlokùn jỌba Èkó. Akíkanjú oníṣòwò àti olówó ẹrú, Madam Tinubu, tí ó ti kọ́kọ́ fẹ́ Adele lọ́kọ gbárùkù ti àbúrò ọkọ rẹ̀, Akítóyè láti jọba dípò Kòsọ́kọ́. Bí Kòsọ́kọ́ ṣé lé Akítóyè kúrò lórí oyè. Àwọn olóyè, pàápàá jù lọ Eletu Odibo gbìyànjú láti tako Ìlà kàkà Akítóyè láti parí ìjà pẹ̀lú àbúrò bàbá ẹ́, ṣùgbọ́n kò gbà, ó fi àìmọ̀kan rẹ̀ parí ìjà náà pẹ̀lú Kòsọ́kọ́, ó sì pàṣẹ pé kí Kòsọ́kọ́ padà sí ìlú Èkó. Kòsọ́kọ́ wọ ọkọ̀ ojú omi tí gbajúmọ̀ olówò ẹrú, José Domingo Martinez padà sí ìlú Èkó. Akítóyè gbìyànjú láti tu Kòsọ́kọ́ lójú pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹ̀bùn, kódà, ó dá a lọ́lá oyè nípa fífi i jẹ òye Ọlọ́jà tí Eréko. Kòsọ́kọ́ yára lo anfaani yìí láti láti wá ojú rere àwọn olóyè ajagun, àti àwọn ará ìlú tí wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí. Nígbà tí ó yá, gbajúmọ̀ tí Kòsọ́kọ́ gbajúmọ̀ láàárín àwọn olóyè sí ní kọ Eletu Odibo nínú, loofahri ìdí èyí, ó gba ìlú Badagry; lọ. Èyí kò tẹ́ Ọba Akítóyè lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ló pàṣẹ fún Eletu Odibo láti padà sí Èkó, èyí bí Kòsọ́kọ́ nínú, ó sì pinnu pé bí Eletu Odibo bá padà sí Èkó, òun yóò dé ara òun ládé, tí òun yóò sì jọba. Wàhálà yìí bẹ́ sílẹ̀ láàárín Ọba Akítóyè àti Ọmọba Kòsọ́kọ́. Lásìkò náà, Kòsọ́kọ́ rán aláago rẹ̀ láti kéde káàkiri igboro Èkó pé "kí wọ́n kìlọ̀ fún màjèsín tí wọ́n fi jọba láàfin pé kó ṣọ́ra rẹ̀, pé bí kò bá ṣọ́ra, yóò jìyà, yóò jẹwé e yá". Akítóyè náà kò gbẹ́nu rọ̀, òun náà rán aláago rẹ̀ pé kó lọ kéde ikilọ pé, "a ti ti òjé bọ olóòṣà lọ́wọ́, kò sí baba ẹni tí ó lè bọ́ ọ". Inú bí Kòsọ́kọ́, ó sì fèsì pé, ó sì fèsì pé bí òjẹ́ ò bá ṣe é bọ́, òun yóò gé e". Rògbòdìyàn yìí mú Kòsọ́kọ́ àti àwọn sọ̀ǹgbè rẹ̀ dá wàhálà ogún Olómirò silẹ n'ilu Èkó lọ́dún. Àwọn sọ̀ǹgbè Kòsọ́kọ́ kógun ja Ọba Akítóyè láàfin rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Ogun yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí Akítóyè fi salo gba orí omi ọ̀sà, lápá àríwá gba etí omi Agboyi pẹ̀lú iranlowo Òṣòdì Tápà, tí ó jẹ́ Balógun Kòsọ́kọ́. Oshodi Tapa parọ́ fún Kosoko pé lo ìṣújú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti sá lọ. Akítóyè kọjá sí Abẹ́òkúta, níbi tí wọ́n ti gbà á láàyè láti ṣe àtìpó. ìbẹ̀rù Akítóyè mú Kosoko, ó sì pàṣẹ fún àwọn Ẹ̀gbá láti gé orí Akítóyè wá fún òun, ṣùgbọ́n àwọn Ẹ̀gbá kọ̀. Nígbà tí ó di ọdún 1845,àwọn Ẹ̀gbá ran Akítóyè lọ́wọ́ láti sá lọ sí Badagry, ìlú àwọn ogunléndé àwọn ọmọ Èkó. Ní Badagry, Akítóyè wá àwọn ọmọ ogún mọ́ra pẹ̀lú iranlowo àwọn ajiyinrere òyìnbó àti ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí John Beecroft ṣojú fún. Madam Tinubu àti àwọn alatileyin Akítóyè náà sá lọ fara pamó sí Badagry nígbà tí Kosoko jọba Èkó. Àtìpó ní Badagry, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òyìnbó Bìrìtìkó, àti ète okoòwò ẹrú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú láti gbapò ọba rẹ̀ ní Èkó padà láti Badagry kò ṣe é ṣe, Akítóyè lọ béèrè fún iranlọwọ láti ọ̀dọ̀ àwọn Aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pàápàá jùlọ Gómìnà tí Cape Coast, ó sì ṣe àdéhùn láti tẹ̀lé ìlànà okoòwò ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pàápàá jùlọ, àdéhùn láti fòpin sí okoòwò ẹrú. Nígbà tí ó di ọdún oṣù Kejìlá 1850, Akítóyè tún sìpẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì : Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ kí ẹ fi ṣe ìrànlọ́wọ́ fúnmi nì wọ̀nyí..., wípé ẹ yóò gbàjọba ìlú Èkó, ẹ yóò sì ri àsíyá ilẹ̀ bọlẹ̀ níbẹ̀, àti pé, ẹ yóò dámi padà gẹ́gẹ́ bí ọba aládé ìlú Èkó pẹ̀lú ààbò tó péye, bí ẹ bá ṣe èyí, màá fọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti fòpin sí okoòwò ẹrú, tí màá sì máa bá yín ṣòwò tí ó bá òfin mu. Ìrànlọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti bí wọ́n ṣe dá Akítóyè padà sí ipò Ọba ìlú Èkó lẹ́ẹ̀kejì lóṣù Kejìlá ọdún 1851. Oríṣiríṣi ìgbésẹ̀ ló wáyé láti ọwọ àwọn ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Akítóyè, tí ó ti ṣe àdéhùn láti fòpin sí okoòwò ẹrú, láti lè padà sórí ìtẹ́ Ọba ìlú Èkó lẹ́ẹ̀kejì. Àwọn òyìnbó ajíyìnrere ìjọ Anglican ni Badagry àti àwọn oníṣòwò ìlú Ẹ̀gbá àti Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ò fẹ́ ìdíwọ́ fún òwò wọn di pàǹpá pọ̀, wọ́n sì ran Akítóyè lọ́wọ́ nílùú Èkó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbiyanju Akítóyè láti takò fífi òpin sí okoòwò ẹrú jẹ́ ìwà ìmọtaraeninìkan, èyí tí ó tako òyìnbó ọ̀rẹ́ rẹ̀ ara ìlú Gẹ̀ẹ́sì, Domingo Martinez, tí ó ti fìgbà kan ràn án lọ́wọ́ láti gba ipò ọba rẹ̀ padà ṣùgbọ́n tí kò ṣeé ṣe lọ́dún 1846. Lọ́jọ́ kerindinlogbon oṣù Kejìlá ọdún 1851, ọjọ́ tí wọ́n ti wá sọ di ọjọ́ ìkógun ja Èkó tàbí ọjọ́. Ọjọ́ burúkú ni ọjọ́ náà, Ọba Kòsọ́kọ́ sa gbogbo agbára rẹ̀, ṣùgbọ́n pàbó ló jásí, nígbà tí ó di ọjọ́ kejidinlogbon oṣù Kejìlá ọdún 1851,ogun yìí, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ogun Ahóyaya tàbí Ogun Agidingbì borí Kòsọ́kọ́, tí Kòsọ́kọ́ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sálọ sí Ìjẹ̀bú. Lẹ́yìn èyí, wọ́n dá Akítóyè padà gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú Èkó lẹ́ẹ̀kejì. Nígbà tí ó di ọjọ́ kìíní oṣù kìíní odun 1852,Akítóyè fọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn Láàárín Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Èkó láti fòpin sí okoòwò ẹrú. Ikú àti ipa rẹ̀. Akítóyè kú lọ́jọ́ kejì oṣù kẹsàn-án ọdún lẹ́yìn ikú rẹ̀, ọmọ rẹ̀ Dòsùmú jọba. Ọba Dòsùmú gbàgbọ́ pé ewọ ni àwọn olóyè alátìlẹ́yìn Ọba àná, Kòsọ́kọ́: Òṣòdì Tápà, Ajéníà, àti Ipossu fún bàbá òun, Akítóyè jẹ. Ṣùgbọ́n Jean Herskovits ní tirẹ̀ lérò pé Akítóyè pa ara rẹ̀ ni nígbà tí ó rí i pé gbajúmò òun ń dínkù nílùú Èkó, àti pé nígbà tí ó rí i pé òun kò lé mú àdéhùn tí ó bá àwọn Òyìnbó ṣe ṣẹ dojú àmì . Láti ṣe ayẹyẹ ìrántí ikú rẹ̀, wọ́n gbé Ẹ̀yọ̀ àkọ́kọ́ jáde ní Èkó. Ọmọọmọ Akítóyè, Ìbíkúnlè Akítóyè jọba Èkó láti ọdún 1925 sí 1928.
Akitoye
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74368
74368
Ìpakúpa
Ìpakúpa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74369
74369
Atlantic slave trade Slave trade – 16th to 19th centuries Ìsòwò Ẹrú níAtlantic tàbí transatlantic slave trade jẹ́ tàbí ìgbà tí àwọn oníṣòwò Ẹrú bá gbé àwọn èèyàn aláwọ̀ dúdú Kúrò gẹ́gẹ́ bí eru láti orílé Áfíríkà lọsí Amẹ́ríkà. Àwọn ará Yúróòpù wọn á máa lo ọkọ̀ ojú omi ẹrú tí wọ́n fi ń ṣe òwò ẹrú máa ń lo ọ̀nà ìṣòwò onígun mẹ́ta àti Arin Àárín inú Atlantic déédéé, ó sì wà láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún sí Ṣẹ́ńtúrì kọkàndíńlógúnPúpọ́ júlọ nínú àwọn tí wọ́n gbé lọ fún ìṣòwò ẹrù nipasẹ̀ transatlantic jẹ́ àwọn ènìyàn láti àárín Africa àti Ìwọ̀-oòrùn Africa tí Àwọn onísòwò ẹrú tí Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà tí tà sí àwọn oníṣòwò ẹrú bíi àwọn Portuguese, British, Spanish, Dutch, ati Faranse tí àwọn náà ń tá ẹrù. nígbà tí àwọn míìràn tí wọn mú tààrà nípasẹ àwọn oníṣòwò ẹrú ní àwọn ibi ogun létí òkun
Atlantic slave trade
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74370
74370
Jumbes ti Nkhotakota Jumbes ti Nkhotakota jẹ akojọpọ awọn oniṣowo ilẹ Larubawa-Swahili ti wọn gbe ni Nkhotakota, iwọ oorun ti ibudo ti Malawi. Iṣẹ wọn ni ki wọn ma fi àṣọ gba Ivory ati ẹru ni etikun ti Swahili. Awọn óniṣowo yi lo gbe ẹsin musulumi ati àṣa rẹ̀ wa si agbegbe Nikhotakota ti wọn si tun jẹ ẹni akọkọ lati gbin irẹsi ati agbọn ni agbegbe naa. Itan. Oludari dynasty naa ni Salim bin Abdallah wa si Nkhotakota ni ọdun 1840. Arakunrin naa jẹ́ larubawa lati Zanzibar to si kopa ninu owo ẹru ati Ivory ni Ujiji ati Tabora ta pe ni Tanzania ni aye isin. Salim sọfun awọn ijoye abẹle ti Chewa ki wọn fun oun ni ilẹ fun owo ṣiṣe. O kopa lati lagbara ni agbegbe naa lati kọ dhow eyi lo mu ki awọn óniṣowo lati taja lori odo ati pe ntoripe arakunrin naa ni oun ija, eyi lo jẹ ki o le dabobo awọn ara odo naa lati ọwọ ija awọn Ngoni. Awọn ara Jumbes ma n ra 20000 ẹru lọdun lọsi ibudo kilwa ni Tanzani aye isin. Awọn ti wọn ko lẹru ni wọn ma nfi pamọ si Nkhotakota titi di igba ti wọn mafipe ẹgbẹrun kan. Lẹyin naa ni wọn ma ko wọn si ọkọ oju omi Malawi ti wa si i pa muwọn lati rin fun óṣu mẹta tabi mẹrin titi wa fi de ọja Oko ẹru Kilwa nibi ti wa ti ta wọn. Missionary David Livingstone ri oko ẹru yi nigba to wa si Nkhotakota ni ọdun 1861. Ni ọdun 1864, Jumbes ṣe treaty pẹlu awọn ara Jumbe ati oloye chew lati fi opin ba oko ẹru. Eyi jasi pabo to si mu ki oko ẹru tẹsiwaju. Awọn Jumes tu ma nṣe oko owo Ivory. Wọn ma yan awọn ọlọdẹ lati bawọn gba ivory lati oke iwọ orun ti Nkhotakota. Ni ọdun 1889, oko ẹrun ti di oun afi sẹyin, jumbe ma rin ere ninu oko owo Ivory. Awọn ọlọde rẹ wa kakiri arin Malawi. Agbara awọn Jumbes dinku nigba ti Henry Hamilton Johnston lo agbara ti protectorate ti british ti arin ilẹ afrika ni agbegbe naa. Arakunrin naa gbiyanju lati fi opin si oko ẹru, o jagun ba Jumbe igbẹyin pẹlu ijagbara Sikh ni ọdun 1894 ti wọn si dajọ rẹ̀ ati pe wọn le lọsi Zanzibar.
Jumbes ti Nkhotakota
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74371
74371
Emmanuel Gomez, Agba Emmanuel Gomez jẹ ọmọ ilẹ Luso-Afrika to wa lati Bissau to da dynasty ti Luso-Afrika silẹ ni Bakia, Guinea, ni Century ti meji dinlógun. Arakunrin naa jẹ Baba fun Emmanuel Gomez, kekere ati Niara Bely.
Emmanuel Gomez, Agba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74372
74372
Mary Faber (Óniṣowo Ẹru) Mary Faber Ni a tuma npe ni Mary Faber de Sanger, (a bini c. 1798 si Freetown, Guinea-Conakry– to si ku lẹyin ọdun 1857), jẹ oniṣowo ẹru ilẹ Afrika. Lati ọdun 1830s titi di ọdun 1852, arabinrin naa jẹ eniyan pataki ninu owo ẹru ṣise ti Atlantic lati ilẹ Guinea ati fun ija rẹ pẹlu Roya Navy ti ilẹ British;Awọn ajọ yi jẹ Squadron to lo di owo ẹru ṣise. Itan Mary Faber. Mary Faber ni a bini ilẹ Freetown fun awọn ara Nova Scotian. Ni ọdun 1816, Mary fẹ ọlọkọ oju omi ilẹ Arika Paul Faber (d. 1851) to da owo oko ẹrun fun ra rẹ ni ọdun 1809 ni agbegbe Conakry. Ọkọ rẹ̀ da ibudo oko owo silẹ si Sangha ni odo Rio Pongp ni ibi ti awọn tọkọ taya ti di ilẹ iṣẹ ẹru silẹ. Eyi jẹ oko ẹru ti o lagbara latara awọn óniṣowo oko ẹru yoku to ni ẹru ni agbegbe naa. Ọkọ Mary lo dari ọkọ oju omi ẹru to maa nlọ si ilẹ Cuba ṣugbon Mary Faber ṣiṣẹ lori awọn oko owo to wa ni Rio Pongo. Mary ni awọn ẹru bi ẹgbẹrun lọna mẹfa to jẹ bi nkan ini fun ni ọdun 1827. Owo Oko Ẹru. Lati ṣọra fun ija awon squadron Royal Navy to lodi si oko ẹru eyi to maa jagun si ibudo oko ẹru. Lẹyin ti wọn ti fagile oko ẹru ti ilẹ british, Mary bẹ̀rẹ sini lo awọn ẹru rẹ fun óṣiṣẹ abẹ ile lẹyin to sọ ibudo oko ẹru rẹ di oko. Mary Faber ni awọn ọmọ ogun rẹ to maa nlo nigba ija. Larin ọdun 1838-1840, Mary kogun ba óniṣowo ẹru to jẹ orogun rẹ William Ormond ni Bangalan. Ni ọdun 1842,Mary Faber ati akẹgbẹ rẹ Bailey Gomez Lightburn da ọmọ ogun wọn papọ lati ṣè iranlowo fun awọn ọrẹ wọn, Fula lati kogun ba Susu, Thia ninu ija ade lati fi eyan ti wọn sibẹ eyi lo jẹ nkan pataki fun Fula, Faber ati Lightburn. Ọdun 1840 jẹ igba pataki fun oko owo ni agbegbe naa, eyi lo mu ki Faber ni oko ẹ̀pa ati Coffee ṣugbọn ó ṣi bẹrẹ̀ oko ẹ̀ru ni a bẹlẹ̀. Ni ọdun 1852, Mary Faber fi iṣẹ rè le ọmọkunrin rẹ William Faber to bẹrẹ owo oko ẹru titi di ọdun 1860. Awọn missionary darukọ Mary Faber sẹyin ni ọdun 1857 ni ipa rẹ̀ gẹgẹbi mama ilẹ rẹ ati iya William Faber.
Mary Faber (Óniṣowo Ẹru)
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74373
74373
Antera Duke Antera Duke (wa ni aye titi di ẹyin ọdun 1788) jẹ óniṣowo ẹru ati oloye Efik to wa lati Calabar atijọ ni Bight ti Biafra ni ila oorun ti ilẹ Naijiria (Agbegbe naa tidi ipinlẹ Cross River nisin) ni century meji dinlogun sẹyin. Antera yege to si di ọmọ ẹgbẹ awujọ ti Ekpe eyi to ni ipa pupọ ninu owo ẹru ṣiṣe. Arakunrin naa ma nṣeto isinku eyi to jẹ fifi awọn ẹru ṣe irubọ lati tẹle awọn ọga wọn to ku lọ si inu sare. Duke ati awọn óniṣowo ẹgbẹrẹ ti Efik maa n wọṣọ funfun ti wọn si ma ṣalejo awọn captains ọkọ oju omi awọn ẹru. Diary Antera ti wọn kọ ni ede gẹẹsi pidgin ni órilẹ ede Naijiria ni wọn ti ri ilẹ Scotland ti wọn si ti tẹ sita. Diary yi kọ igbaṣepọ Duke pẹlu awọn oniṣowo British ti o ma nta ẹru fun. Yatọ mi ma n ṣowo ẹru, Duke tun ma mu awọn ẹru fun rarẹ̀. Gẹgẹbi Diary rẹ, o daju fun óniṣowo Bakassi pẹlu mi mu oun ati awọn ẹru rẹ̀ meji to si ko wọn si ọkọ oju omi awọn ẹru. Fun ọdun mẹta to fi diary rẹ pamọ (1785-1788), o sọrọ nipa ọkọ oju omi ogun ti o ko lẹru lati ilu Liverpool.
Antera Duke
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74374
74374
Osman Digna Sudanese Ansar military commander (1836–1926) Osman Digna (Èdè larubawa: عثمان دقنة) (c. 1840 – 1926) jẹ olutẹle ilana ti Muhammad Ahmad,ẹni ti oun pe ara rẹ ni Mahdi ni sudan jẹ oludari ologun nigba ogun ti Mahdi. Gẹgẹbi ologun Mahdi to pegede julọ, Osman kopa pataki ninu igbesi aye Ọgagun Charles George Gordon ati ikuna sudan si idari ilẹ Turkey-Egypt. Igbèsi Àye Osman. Baba Osman Digna jẹ ẹya Kurd atipe iya rẹ wa lati ẹya Hadendoa lati ara Beja. A mọ arakunrin yi Osman Ali, oun gbe ni Alexandria, Egypt nibi to tin ṣe owo oko ẹru. Nigba ti ijọba fagile owo rẹ, arakunrin naa kopa ninu ija ti Ahmed 'Urabi'. Lẹyin ti ija Tel al-kebir (Ọjọ mẹ̀tala, óṣu September, ọdun 1882), arakunrin naa darapọ mọ ija ti Mahdi. Osman gẹgẹbi Oludari ti Mahdi. Osman gba órukọ Digna ni to ri irugbọn rẹ tokun. Arakunrin naa dari awọn ogun to lagbara ni agbegbe Suakin. Ogun rẹ akọkọ jẹ eyi to jaguba ba ibudo kan ni ilẹ turkey ni Sinkat ni ọdun 1883. Nì ọjọ kẹrin, óṣu February, ọdun 1884, Osman jagun ba awọn ọmọ ogun ti ilẹ̀ Egypt ti Baker Pasha jẹ̀ oludari wọn. Eyi lo mu ki ijọba ilẹ British-Egypt ran ọmọ ogun rẹ lati doju ija kọ ni El Teb pẹlu oludari ọgagun Graham. Osman Digna jẹ alẹjo oludari to ti doju ija kọ square Infantry ti ilẹ British, Osman gbajumọ larin ẹya British fun ijagbara rẹ. Nitori agbara oun ati awọn ọmọ ogun rẹ ni wọn yẹsi ninu iwe orin Kudyard Kipling "Fuzzy-Wuzzy". Osman ni a sọ ni órukọ ninu ijagun ti El-Teb, iwe órin ti William McGonagall. Kẹyin ti Khartoum jabọ si ọwọ awọn Mahdi lọwọ ati pe Ọgagun Gordon ku, wọn gbe ago ati ida Gordon le Osman lọwo lati fi ran awọn mahdi ni Suakin pe ógun ti ṣẹ. Ni ọdun 1899, Osmon ja ijagbara fun awọn ologun ti mahdi eyi ti agbara rẹ ti dinku ni ọdun 1888 ni ilẹ Omdurman. Ni ogun Umm Diwaykarat, Osman farapa to si fi ori pamọ. Ni ọdun 1900, Ọwọ ba Osman ni agbegbe Rosetta nibẹ loti ṣẹwọn fun ọdun mẹjọ ni lẹyin naa lo gba itusilẹ tosi morile ilẹ Egypt tosiku ni ọdun 1926.
Osman Digna
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74375
74375
Dame Portugaise Dame Portugaise (d. lẹyin 1634), jẹ oniṣowo ẹru Nhara ilẹ Afrika. Arabinrin naa jẹ ọmọbinrin ọkunrin ilẹ Portuguese ati arabinrin ilẹ Afrika. Dame da oko owo ẹru silẹ ni Rufisque nibi o ti jẹ alagata ti wọn maa n pe larin awọn oludari ilẹ Portuguese ati Afrika latari ẹya awọn obi rẹ̀. Eyi jẹ ki Dame dari owo ṣiṣè larin agbegbe mejèèji. Dame jẹ ọkan lara awọn obinrin óniṣowo ati alagata lari Awọn ẹya Europe ati Afrika titi di ẹyin century ti ọkan dinlogun.
Dame Portugaise
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74376
74376
Aurelia Correia Dona Aurelia Correia (d. circa 1875), ti a tumọ si Mae Aurelia, Mame Correia Aurelia ati Madame Oralia jẹ̀ óniṣowo oko ẹru ti Euro-Ilẹ Afrika. Igbesi Àye Aurelia. Aurelia jẹ eniyan pataki ninu owo ṣiṣe ti Guinea-Bissau ni century ti ọkan dinlogun. Arabinrin naa lo gbajumọ julọ ni agbègbè nhara ti wọn si wari fun ni ilẹ portuguese, a tun pe ni obinrin óniṣowo to ṣe pataki ni àṣa ilẹ Afrika. Aurelia jẹ mọlẹbi Julia da Silva Cardoso ati iyawo de facto ti óniṣowo Caetank Josè Nozolini (1800-1850), gomina ilẹ Portuguese ti Cape Verde. Aurelia jẹ óniṣowo oko ẹru lẹyin naa lo bẹrẹ sini gbin ẹ̀pa si inu oko ẹru nigba ti oko ẹru ilẹ̀ Afrika bẹ̀rẹ sini dinku ni ọdun 1830s. Arabinrin naa gbe awọn ẹpa naa lọsi awọn agbegbe Guinea eyi lo mu kodi agbẹ ẹpa to tobi julọ ni ilẹ Guinea nigbana. Ilo awọn ẹru fun nkan agbẹ lo di ija lati ọdọ rẹ ati Squadron British iwọ oorun ilẹ Afrila ti wọn ja lu oko rẹ ni Bolama ni ọdun 1839 ati freetown ti wọn si gbe kuro ni Bolama ni ọdun 1860. Ni ọdun 1850s, Aurelia ni ẹru ida mẹta to wa ni ilẹ̀ Guinea. Aurelia jẹ alagata larin ilẹ portuguese ati Guinea, larin portuguese ati British to si ko ipa pataki ninu óṣelu awọn agbegbe naa.
Aurelia Correia
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74377
74377
Francisca Chiponda Dona Francisca Josefa de Moura Meneses ni a tumọ si Francisca Chiponda jẹ ogboun tarigi ẹlẹya meji oniṣowo oko ẹru ti Agbegbe Tete ni Portuguese Mozambique to jẹ ọkan lara awọn to ṣe agba tẹru ina owo lati ilẹ Mozambique de Kazembe (Zambia nisin) ni ọdun 1790 de 1798 lati kọja si ilẹ Afrika lati ila oorun si iwọ oorun. Igbesi Aye Francisca. Chiponda tumọ si "arabinrin maa tẹ awọn eniyan mọlẹ pẹlu ẹsẹ rẹ", Francisca Chiponda gba orukọ rẹ latari bi arabinrin naa ṣe maa nlo awọn ẹru onija eyi lo jẹ ko di ọkan ninu awọn alagbara ti Dona. Francisca ni a bini ọdun 1738, ọmọ akọkọ pẹlu aburo óbinrin mẹta. Ọkọ Francisca akọkọ ni Joào Moreira Pereira to wa lati Ovar ni Portugal nibi to ti wa si colony ni ọdun 1749 to si bẹrẹ iṣẹ rẹ gẹgẹbi Ọgagun Captain ti Rios de Sena lẹyin lodi ọgagun gomina. Arakunrin naa ku ni ọdun 1776 eyi lo da gbesi Francisca lọrun. Ni ọdun to tẹ̀le, Arabinrin naa fẹ Josè Àlvares Pereira ọgagun gomina ti Rios de Sena ni ọdun mẹwa sẹyin ṣugbọn ti o ku laipẹ to bẹrẹ iṣẹ rẹ. Ni ọdun 1780s, fun idi aimọdi, Francisca doju ija kọ ọgagun gomina António Manuel de Melo e Castro. O ṣa awọn ọmọ ogun rẹ jọ, tosi ṣèlèri lati ba ile gomina naa jẹ ati pe arabinrin naa fẹ dana sun abule ti Tete. Koto dipe Francisca ṣè igbeyawo rẹ alakọkọ lo ti di olowo latari ilẹ nla ti iya rẹ agba ni (Prazo). Nigba to ṣe igbeyawo, baba rẹ̀ agba fun ni ilẹ labẹ ofin ilẹ portuguese. Chiponda fọwọ si ina gomina Francisco Josè de Lacerda e Almeida ni ọdun 1798 nigba to fẹ ṣe irin ajo lọ si Angola to si fun ni awọn ẹru ṣugbọn ọpọ ninu wọn ku nigba ti wọn kogun jawọn. Ọmọbinrin Chiponda ku ni igba kekere eyi lo mu ko ma tọju awọn ọmọ aburo rẹ. Ni ọdun 1798, Francisca di onile to tobi julọ ni ilẹ Tete. Awọn ilẹ yi gbin óriṣiriṣi nkan ọgbin cereals, cotton, ẹfọ ati nkan eso. Pupọ ninu awọn ẹ̀ru Francisca kopa ninu wiwu wura sita. Ni ila oorun afrika, wiwu alumọni sita jẹ iṣẹ awọn obinrin ti awọn ọkunrin si maa dabobo ilẹ naa. Francisca maa fun awọn ẹ̀bi rẹ ni ilẹ, fun wọni ọkọ tabi iyawọ nibi to ti maa nto eto ile aye wọn. Eyi lo mu ki o tubọ ni agbara si titi to fi ku ni ọdun 1825. Chiponda nlo irin iṣẹ awọn ẹya Afrika lati fi ṣe owo ti oun ọja. Francisca lekun owo awọn ọkọ rẹ. Agbara rẹ wa ni lilo awọn ẹru to bẹ gẹ to jẹ pe o maa nlo wọn lati ja ilẹ onilẹ gba.
Francisca Chiponda
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74378
74378
Betsy Gbo Betsy Heard (tí wọ́n bí ní1759, tí ó sì ṣaláìsí ní ọdún 1812) jẹ́ obìnrin oníṣòwò ẹrú àti oníṣòwò ará Africa kan. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò kan tó máa ń rin ìrìn àjò ní àwọn ọdún 1700 láti Liverpool, lọ England, sí Los Islands, èyí tó wá di Guinea báyìí. Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Africa. Ó ṣeé ṣe kí bàbá rẹ̀ tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, èyí tó sọ pé àjèjì kan gbọ́dọ̀ fìdí ipò rẹ̀ múlẹ̀ láwùjọ nípa fífẹ́ ẹrú onílé tàbí ọmọbìnrin ẹrúbìnrin kan. Bàbá Heard ran lọ sí England, nítòsí Liverpool (níbi tí àwọn oníṣòwò ilẹl Africa máa ń pọ̀ sí, àti àwọn òǹtàjà tó jẹ́ ẹlẹ́yàméjì, tí wọ́n sì gbẹ̀kọ́ àwọn aláwọ̀ funfun ). Nígbà tí ́ parí ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà lọ sí apá Ìwọ-oòrùn, ó sì ṣètò ilé-iṣẹ́ ìṣòwò kan, nítòsí Bereira River, láti tẹ̀lé òwò bàbá rẹ̀. Lákòótán, ó jogún òwò-ẹrú bàbá rẹ̀, àti àwọn àsopọ̀ tó ní. Ní ọdún 1794, ó ti fìdi òwò rẹ̀ múlẹ̀, ní agbègbè náà, ó sì ni ọkọ̀ ojú-omi ní Bereira, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó wà fún títà, àti ilé-ikọjá-sí. Àṣeyọrí yìí jẹ́ apá kan, nítorí àwọn Mùsùlùmí ti Jihad ní Futa Jallon; àwọn tí a ṣẹ́gun ti di ẹrú. Àwọn Mùsùlùmí gba Bereira fúnra wọn, ṣùgbọ́n èyí kò ní ipa búburú lórí ìṣòwò rẹ̀. Ó dì gbajúmọ̀, bí ọbabìnrin odò, títí wọ òpin sẹ́ńtúrì náà. Gẹ́gẹ́ bí àlejò kan ṣe sọ, ó kọ́ ilé rẹ̀, ó sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ ní àbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ará Europe. Ní ọdún 1807, ó kọ́ ilé mìírán.
Betsy Gbo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74379
74379
Betsy Heard Betsy Heard (tí wọ́n bí ní1759, tí ó sì ṣaláìsí ní ọdún 1812) jẹ́ obìnrin oníṣòwò ẹrú àti oníṣòwò ará Africa kan. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò kan tó máa ń rin ìrìn àjò ní àwọn ọdún 1700 láti Liverpool, lọ England, sí Los Islands, èyí tó wá di Guinea báyìí. Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Africa. Ó ṣeé ṣe kí bàbá rẹ̀ tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, èyí tó sọ pé àjèjì kan gbọ́dọ̀ fìdí ipò rẹ̀ múlẹ̀ láwùjọ nípa fífẹ́ ẹrú onílé tàbí ọmọbìnrin ẹrúbìnrin kan. Bàbá Heard ran lọ sí England, nítòsí Liverpool (níbi tí àwọn oníṣòwò ilẹl Africa máa ń pọ̀ sí, àti àwọn òǹtàjà tó jẹ́ ẹlẹ́yàméjì, tí wọ́n sì gbẹ̀kọ́ àwọn aláwọ̀ funfun ). Nígbà tí ́ parí ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà lọ sí apá Ìwọ-oòrùn, ó sì ṣètò ilé-iṣẹ́ ìṣòwò kan, nítòsí Bereira River, láti tẹ̀lé òwò bàbá rẹ̀. Lákòótán, ó jogún òwò-ẹrú bàbá rẹ̀, àti àwọn àsopọ̀ tó ní. Ní ọdún 1794, ó ti fìdi òwò rẹ̀ múlẹ̀, ní agbègbè náà, ó sì ni ọkọ̀ ojú-omi ní Bereira, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó wà fún títà, àti ilé-ikọjá-sí. Àṣeyọrí yìí jẹ́ apá kan, nítorí àwọn Mùsùlùmí ti Jihad ní Futa Jallon; àwọn tí a ṣẹ́gun ti di ẹrú. Àwọn Mùsùlùmí gba Bereira fúnra wọn, ṣùgbọ́n èyí kò ní ipa búburú lórí ìṣòwò rẹ̀. Ó dì gbajúmọ̀, bí ọbabìnrin odò, títí wọ òpin sẹ́ńtúrì náà. Gẹ́gẹ́ bí àlejò kan ṣe sọ, ó kọ́ ilé rẹ̀, ó sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ ní àbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ará Europe. Ní ọdún 1807, ó kọ́ ilé mìírán.
Betsy Heard
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74380
74380
Little Ephraim Robin John àti Ancona Robin John Little Ephraim Robin John àti Ancona Robin Robin John jọ jẹ́ àwọn oníṣòwò ẹrú ilẹ̀ Afirika ní sẹ́ńtúrì kejìdínlógún, tí wọ́n padà fún àwọn ẹrúkùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ ti Old Town Calabur, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní òmìnira ọrundun 18th, ẹrú nigbamii, ati nikẹhin awọn ọkunrin. Ancona ò kì í ṣe ọmọ tàbí ọmọ àbúrò Little Ephraim. Wọ́n rí àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ ìdílé Efik, gẹ́gẹ́ bí i ohun-ìní tó ṣọ̀wọ́n, nítorí wọ́n ń sọ èdè púpọ̀ (pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì), wọ́n mọ̀ ọ́n kọ, wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà, wọ́n le ṣe ìtàkurọ̀sọ dáadáa, àti pé wọ́n ní òye kíkún nípa òwò-ẹrú. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin méjì yìí lẹ́rú nígbal tí wọ́n ń kópa nínú ìrìn-àjò òwò-ẹrú kan. Wọ́n tà wọ́n fún àwọn olówò ẹrú ti ilẹ̀ Britain, nígbà tí ọba ti Old Town, ìyẹn Grandy King George ń ṣe ìdúnàdúra ìṣòwò pẹ̀lú Duke ti New Town.
Little Ephraim Robin John àti Ancona Robin John
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74381
74381
John Cabess African merchant John Cabess (tí àwọn míràn ma ń kó bi John Kabes tàbí John Cabes) (c. 1640s – 1722) jẹ́ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀ èdè Áfíríkà tí ó gbajúmọ̀ nígbà ayé rẹ̀, ìlú Komenda, ara àwọn ìlú ìjọba Eguafo, ni ó ti ṣòwò. Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ orílẹ̀ èdè Britain, ó sì ń ta ọjà fún ilé iṣẹ́ Royal African Company. Gẹ́gẹ́ bi oníṣòwò, ó gbajúmọ̀ ní ìlú Komenda ní àwọn ọdún 1700s, ó kó ipa gbòógì ní ogun Komenda, ìdìde ìjọba Ashanti, ìtàn kálẹ̀ ìjọba Britain ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, àti Atlantic slave trade. Ó fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1722.
John Cabess
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74382
74382
Victoria Albis Victoria Albis (d. "after" 1777), jẹ́ obìnrin ọmọ Senagal tí ó alágbára nítorí ó fẹ́ àwọn aláṣẹ àwọn òyìnbó tí ó sì jogún wọn. Ó wà lára àwọn gbajúmọ̀ obìnrin tí ó lágbára nítorí ó fẹ́ àwọn òyìnbó alágbára ní erékùṣù Gorée láàárín àwọn elédè Faransé Senegal. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn gbajúmọ̀ alágbára obìnrin lásìkò náà ni Senegal. Òun ni ó kọ́ Henriette-Bathily Women's Museum.
Victoria Albis
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74383
74383
Akinsemoyin Oba Akinsemoyin jẹ́ Oba Èkó láti ọdún 1704 sí 1749. Bàbá rẹ̀ ni Oba Ado, àwọn ẹbí rẹ̀ sì ni Erelu Kuti àti Oba Gabaro, ẹni tí ó jọba ṣáájú Akinsemoyin. Gégé bí Justice J. O. Kassim ṣe fi léde ní ọjọ́ kàndínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1978, ọmọ ọkùnrin mẹ́fà ni Akinsemoyin ní, orúkọ wọn ni, Sadeko, Amore/Olukokun, Abisako, Jolasun, Gbosebi àti Aina Egbe. Díè tí ó gbajúmọ̀ nínú àwọn ọmọ ọmọbìnrin Akinsemoyin ni: Onisiwo, Oniru, Oluwa, àti Akogun.
Akinsemoyin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74384
74384
Julia da Silva Cardoso Julia da Silva Cardoso (d. "after" 1840) tí a tún mọ̀ sí "Mae Julia" ati "Na Julia" ('Senhora Julia'), jẹ́ òyìnbó ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ oníṣòwò ẹrú "nhara". Ọmọ orílẹ̀ èdè Portugal tí ó ń jẹ́ José da Silva Cardoso ti Cap Verde ni ó tọ́ ọ dàgbà, ó ṣe é ṣe kó jẹ́ ọmọ rẹ̀. Ó fẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Portugal kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joaquim Antonio de Matto (d. 1843). Ó kópa pàtàkì nínú okoòwò láàárín àwọn òyìnbó Portugal àti àwọn ọmọ Africa, pàápàá jùlọ nínú okoòwò ẹrú ṣíṣe. Bẹ́ẹ̀ náà o jẹ́ gbajúmò aṣojú àti agbódegbà nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú láàárín wọn. Ó jẹ́ àbúrò ìyá àti ẹni tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìyá fún Aurelia Correia.
Julia da Silva Cardoso
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74385
74385
Kòsọ́kọ́ Kòsọ́kọ́ (ó wàjà ní 1872) ó jẹ́ ọmọ ilé oyè Ológun Kétere, ó sì jẹ gẹ́gẹ́ bí i Ọba ìlú Èkó láti 1845 títí di 1851. Ọba Oṣìnlokùn ni bàbá rẹ̀, nígbà tí àwọn bàbá rẹ̀ ń ṣe Ìdéwu Ojúlarí (tí ó jẹ́ bí Ọba Èkó láti 1829 títí di 1834/35), Olúfúnmi, Ọdúnsì, Ládéga, Ògúnbámbí, Akínsànyà, Ogunjobi, Akimosa, Ìbíyẹmí, Adébánjọ, Matimoju, Adéníyì, Ìsíyẹmí, Ìgbàlú, Ọrẹ́sànyà, àti Ìdéwu-Ojúlarí. Ìgòkè. Jíjẹ Kòsọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ìlú Èkó ni 1845 níṣe pẹ̀lú onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹmọ́ran. Aáwọ̀ láàrin ìdílé oyè Oṣìnlokùn àti Àdèlé. Nígbà tí Ọba Ológun Kútere wàjà ní (1800 àti 1805), ìṣòro arọ́pò wáyé láàárín ọmọ rẹ̀ àgbà (Oṣìnlokùn) àti àbíkẹ́yìn rẹ̀ (Àdèlé). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọba jíjẹ kò rọ̀gbọ̀ lé ètò ìbí ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àwọn afọbajẹ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bẹ Ifá wò. Oṣìnlokùn àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí i lòdì sí ìjọba Àdèlé. Èyí fà á kí òpin wá sí ìjọba Àdèlé ní 1819 nípasẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Oṣìnlokùn. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà ni ó fà á kí Àdèlé sí kúrò ní Èkó lọ sí Badagry tí ó sì jẹ gẹ́gẹ́ bí olórí níbẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ aáwọ̀ Kòsọ́kọ́ pẹ̀lú Elétùú Òdìbò. Kòsọ́kọ́ ṣẹ alàgbà tí ń ṣe èkejì Ọba (Elétùú Òdìbò) àti Afọbajẹ nípa pé ó lọ gbé obìnrin tí Olóyè Elétùú Òdìbò fẹ́ níyàwó. Elétùú Òdìbò gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn olóyè Àkárígbèré ni àṣẹ láti máa ṣàkóso àti fi Ọba jẹ ní ìlú Èkó. Ṣùgbọ́n nítorí ìwà ìgbéraga Kòsọ́kọ́ àti ìpinnu rẹ̀ láti gba obìnrin Elétùú Òdìbò mú kí Olóyè afọbajẹ jẹ́ yìí ni sínú. Èyí ni ó bí aáwọ̀ láàárin wọn, tí kò sì fà á kí Kòsọ́kọ́ le jẹ nígbàkigbà tí ó bá jáde fún ipò Ọba tí àyè bá ṣí sílẹ̀. Nítorí náà, ìṣẹ̀lẹ̀ fi àyè sílẹ̀ fún ìdásí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ní 1851. Oṣìnlokùn papòdà, ìgbà díẹ̀ tí Ìdéwu Ojúlarí jẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba, àti aáwọ̀ láàárin Elétùú àti Kòsọ́kọ́. Lẹ́yìn tí Oṣìnlokùn wàjà ní 1819, ọmọ bàbá Kòsọ́kọ́ Ìdéwu Ojúlarí jẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba Kòsọ́kọ́ láti 1819 títí di 1834/5. Síbẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò gbajúmọ̀ àti pé Ọba Bìní ni ó ń ṣe àkóso tàbí ni ó ń gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà náà. Ní ìgbẹ̀yìn Ìdéwu Ojúlarí ṣígbá wò. Yàtọ̀ sí èyí, ìlú Èkó wà lábẹ́ àṣẹ àwọn ará Bìní títí di ìjọba Ọba Kòsọ́kọ́ tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì yọ nípò ní 1851. Lẹ́yìn náà, Ọba Akítóyè tó jẹ́ arọ́pò rẹ̀, Ọba Dòsùnmú, kọ́ ọ̀ láti máa san ìṣákọ́lẹ̀ ọdọọdún fún Ọba Bìní. Nítorí Elétùú Òdìbò kò tẹ́wọ́ gba Kòsọ́kọ́, àwọn afọbajẹ tún pe Àdèlé láti Badagry wá sí Èkó láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí i Ọba fún ìgbà kejì. Ìgbà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Ọba wá sí òpin lẹ́yìn ikú rẹ̀ ní 1837 àti pé ní ẹ̀ẹ̀kan si Elétùú Òdìbò kò fàyè gba Kòsọ́kọ́ láti jọba nítorí ó fi Olúwọlé tí ń ṣe ọmọ Àdèlé jẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba Èkó. Ìrúsókè ìjà láàárin Kòsọ́kọ́, Elétùú Òdìbò àti àwọn alábáṣe rẹ̀. Kíkankíkan aáwọ̀ láàárin Elétùú Òdìbò àti Kòsọ́kọ́ túbọ̀ ru sókè nípasẹ̀ pé Elétùú Òdìbò nawọ́ ìbínú rẹ̀ sí Opo Olú tí ń ṣe arábìnrin Kòsọ́kọ́ tí ó fi ẹ̀sùn àjẹ́ kàn án. Àwọn aláawo ṣe ìwádìí tí ó fi hàn pé Opo Olu kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n, Ọba Olúwọlé ṣí ìdí obìnrin náà kúrò ní Èkó. Èyí fà á kí Kòsọ́kọ́ àti àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ Ogun Ewé Kókò tí ó kùnà, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà ni ó sọ Kòsọ́kọ́ àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di èrò Ẹ̀pẹ́ Elétùú Òdìbò tún ru àwọn ìkórìíra àárín wọn sókè nípa wíwú òkú ìyá Kòsọ́kọ́ tó kù sókè tí ó sì sọ sínú òkun ní Èkó. Ìpapòdà Ọba Olúwọlé àti Ìgòkè Akítóyè. Ọba Olúwọlé papòdà nígbà tí àra kan sán tí ó fa kí ààfin Ọba gbaná. Èyí fà á kí gbogbo ẹ̀ya ara Olúwọlé fọ́ káàkiri tí ó jẹ́ pé àwọn ilẹ̀kẹ̀ oyè rẹ̀ ni wọ́n fi dá a mọ̀. Àwọn afọbajẹ kò bá ti pé Kòsọ́kọ́ láti wá jọba ṣùgbọ́n ibi tí ó wà wọ́n kò mọ. Fún ìdí èyí, Akítóyè, àbúrò bàbá Kòsọ́kọ́, àbúrò sí Oṣìnlokùn àti Àdèlé, ọmọ Ológun Kútere ni ó jẹ gẹ́gẹ́ bí i Ọba Èkó. Àìmọ̀ Akítóyè àti ẹ̀san Kòsọ́kọ́. Láti le da ohun gbogbo sípò (bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóyè lòdì sí èyí, pàápàá Elétùú Òdìbò) pẹ̀lú ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Ọba Akítóyè láìmọ̀ pe Kòsọ́kọ́ padà sí Èkó. Kòsọ́kọ́ padà sí Èkó, ó gba ọkọ̀ ojú-omi olówò ẹrú tó gbajú-gbajà Jose Domingo Martinez lọ. Akítóyè gbìyànjú láti rẹ Kòsọ́kọ́ lọ́kàn pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn kí ó sì tún bùn ún ní oyè Ọlọ́jà Eréko. Kòsọ́kọ́ yára gba ipò yìí ó sì rí àtìlẹ́yìn láàárin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóyè olóogun àti láàárin àwùjọ àwọn Mùsùlùmí. Ìrònú dé bá Elétùú Òdìbò nípa agbára tó ti rí gbà yìí ó sì mú orí lé Badagry. Èyí mú kí Akítóyè ránṣẹ́ sí Elétùú Òdìbò láti padà wálé láti Badagry. Ṣùgbọ́n, èyí mú kí Kòsọ́kọ́ fi ohùn lélẹ̀ pé bí Elétùú Òdìbò bá fi le padà sí Èkó, òun yóò sọ ara rẹ̀ di Ọba. Ogun bẹ́ sílẹ̀ láàárin Ọba Akítóyè àti Kòsọ́kọ́ tí ó rán Akéde rẹ̀ káàkiri ìlú Èkó láti máa kọrin pé "Ẹ sọ fún ọmọ kékeré náà kí ó ṣọ́ra; nítorí tí kò bá ṣọ́ra ìyà rẹ̀ yóò jẹ̀ ẹ́". Akítóyè náà rán Akéde rẹ̀ láti kọrin pé "Abẹ́rẹ́ tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ni mí, tí ó ṣòro láti fà yọ", Kòsọ́kọ́ náà dáhùn pé "Agbẹ́lẹ̀ ni mí tí ó ń fà abẹ́rẹ́ jáde". Ìkẹ́ẹ̀mísókè yìí ni ó bí Ogun Olómiyọ̀ láti apá ìpín Kòsọ́kọ́ ní oṣù kèje 1845. Kòsọ́kọ́ àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ gbógun ti ààfin Ọba fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Akítóyè gba ìṣẹ́gun Kòsọ́kọ́, ó sì gba òkun sá lọ sí àríwá, ó rí orí omi Agboyi gbà nípasẹ̀ olórí ogun Kòsọ́kọ́ Oṣòdì Tápà, tí ó ṣàlàyé fún Kòsọ́kọ́ pé Èdì ni Akítóyè di àwọn ọ̀tá rẹ tí ó fi rí ọ̀nà lọ. Lẹ́yìn èyí Akítóyè forí lé Abẹ́òkúta níbi tí ó ti rí ààbò. Kòsọ́kọ́ rí ṣíṣá pamọ́ Akítóyè yìí gẹ́gẹ́ bí i ewu. Èyí mú u bí àwọn Ẹ̀gbá fún orí rẹ̀ tí wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe bí ó ti bèrè. Ní oṣù kẹrin 1841, àwọn ará Ègbá fi àwọn ẹ̀sọ́ sin Akítóyè lọ sí Badagry, ìlú tí àwọn ará Èkó tó ń wá ààbò máa ń sábà lọ. Ibẹ̀ ni ó ti rí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bá àwọn ajíyìnrere Europe àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì ṣe nípasẹ̀ Consul John Beecroft. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Kòsọ́kọ́ rí Elétùú Òdìbò gbá mú, ó sì gbẹ̀san egungun ìyá rẹ̀ tó túká sínú òkun nípa pé ó fi Elétùú Òdìbò sínú garawa epo, ó tì í pa, ó sì sọ́ sínú òkun ní ìlú Èkó.
Kòsọ́kọ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74386
74386
Adele Ajosun Oba Adele tàbí Adele Ajosun (ó fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1837) jọba ní Èkó fún ṣáà méjì; àkọ́kọ́ , láti ọdún c1811 sí 1821, àti ẹlẹ́kejì láti ọdún 1835 sí 1837. Bàbá rẹ̀ ni Oba Ologun Kutere, àwọn ẹbí rẹ̀ sì ni Oba Osinlokun àti Ọba Akitoye, ìran Ologun Kutere ti gun orí oyè ọba Èkó fún ọ̀pọ̀ ìgbà láti ìgbà náà. Dídé ori oyè. Adele gun orí ìtẹ́ ọba Èkó lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí bàbá rẹ̀, Ologun Kutere, fi ayé sílẹ̀. Àwọn ìtàn àti àkọọ́lẹ̀ kòkan fihàn pé ète Ologun Kutere ni pé kí Adele di Oba Èkó nítorí iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe fún Ologun Kutere. Onítàn John. B. Losi kọ́ pé Adele tọ́ju àwọn ohun ìní Ologun Kutere. Nígbà ìjọba Adele, ẹ̀sìn Mùsùlùmí gba ilẹ̀ ní Èkó.
Adele Ajosun
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74387
74387
Chief Kivoi Mwendwa Chief Kivoi Mwendwa (tí wọ́n bí ní ọdún 1780) fìgbà kan jẹ́ oníṣòwò ọlọ́nà jínjìn, tó ń gbé ní ìlú tí wọ́n ń pè ní Kitui, ní òde-òní. Kivoi gbajúmọ̀ jù lọ fún ṣíṣe amọ̀nà àwọn ajínhìnrere lọ sí ìlú Kenya, lẹ́yìn tó ṣamọ̀nà àwọn ajíhìnrere ti ilẹ̀ Germany, ìyẹn Johann Ludwig Krapf àti Johannes Rebmann ti ìjo Anglican Church Missionary Society (CMS). Lásìkò àwọn ìrìn-àjò náà ni Rebmann àti Krapf ní ìfojúkojú pẹ̀lú Mount Kenya. Ìsọníṣókí. Kivoi ṣalábàápàdé àwọn ará ilẹ̀ Europe méjì náà ní Mombasa, ó sì rin ìrìn-àjò pẹ̀lú wọn lọ sí Ukambani. Ní ọjọ́ 3 December ọdún 1849, wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun àkọ́kọ́ tó máa kọ́kọ́ rí. Àmọ́ ní Europe, àwọn ènìyàn ò gbàgbọ́ pé wọ́n rí orí-òkè yìí, wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Chief Kivoi ṣe ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Lárúbáwá ní ìlú Voi, tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pe ìlú náà, nítorí ibẹ̀ ló kọ́kọ́ ti dúró, kí ó tó wọ Mombasa.
Chief Kivoi Mwendwa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74388
74388
Ghezo Ghezo, tí sípẹ́lì rẹ̀ tún jẹ́ Gezo, jẹ́ ọba ilẹ̀ Dahomey, (èyí tó ti di ìlú Benin báyìí) láti ọdụ́n1818 títí wọ 1859. Ghezo rọ́pò ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ń jẹ́ Adandozan (tó jọba láti ọdún 1797 títí wọ ọdún 1818) gẹ́gẹ́ bí i ọba látàri ìsọ̀tè tó wáyé pẹ̀lú ìànlọ́wọ́ àwọn olówò ẹrú ilẹ̀ Brasil, ìyẹn Francisco Félix de Sousa. Ó jọba lóri ìlú náà lásìkò tí rúdurùdu gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú ìdíwọ àwọn èbúté lóríṣiríṣi tó ti ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun wá, láti dẹ́kun Atlantic slave trade. Ghezo ló fòpin sí sísan ìṣákọọ́lẹ̀ sí Oyo Empire. It is quite likely that the initial struggle was more violent than this story relates. Lẹ́yìn náà, ó gbógun ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówò ẹrú, ní ìbámu láti dẹ́kùn òwò náà. Wọ́n pa Ghezo ní ọdún 1859, ọmọ rè Glele sì jọba.
Ghezo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74389
74389
Sa'id ti Egypt Wāli of Egypt and Sudan (1822–1863) Mohamed Sa'id Pasha (Ède Larubawa: محمد سعيد باشا, Èdè Turkey: Mehmed Said Paşa, ọjọ mẹta dinlogun, óṣu March, ọdun 1822 – ọjọ mẹta dinlogun.January, ọdun 1863) jẹ Wāli ti Egypt ati Sudan lati ọdun 1854 de 1863, eyi ni to ri fealty ti arakunrin naa mi si Ottoman Sultan ṣugbọn pẹlu óminira ti a ko fojuri. Iṣẹ Suez Canal bẹrẹ lati oludari Sa'id. Itan Igbesi Àye Sa'id. Sa'id jẹ ọmọkunrin kẹrin ti Muhammad Ali Pasha, Sa'id jẹ ọmọ ilẹ french to si kawe ni ilẹ Paris. Labẹ idari Sa'id, óriṣiriṣi ofin, ilẹ ati owo ilẹ lowa.Sa'id fi ọwọ si dida ati kikọ canal ni ọjọ kaarun, óṣu January, ọdun 1856. Iwadi ọdun 1886 royin Sa'id gẹgẹbi onifari, ẹni to gbafẹ ati ọlọgbọn, arakunrin naa maa ṣalejo awọn arinrin ajo. Baba Sa'id kogun ja Sudan ni 1821 to si ma ko ẹru pẹlu Awọn ologun. Ikogu ja awọn ẹru yii yatọ si Sudan, Kordofan ati Ethiopia. Sa'id fin ofin lelẹ lori fifagile kikogun ja ilu. Awọn óniṣowo oko ẹru kọ ti ikun si ofin yi. Nigbati iyan owu bẹrẹ, owu ti ilẹ Egypt labẹ idari Sa'id jẹ ibi ta lo fun mills ti Europe. Labẹ idari Sa'id, agbara awọn Sheikh dikun ti awọn ikogun ja nkan isin ti Bedouin dinkun. Ni ọdun 1854, Sa'id da ile ifowopamọ ti Egypt silẹ́, lẹyin naa loda line ti Khedivial Mail. Ni ọdun 1863, Sa'id ku ti Nephew rẹ Ismail ṣe lede toripe ọmọ rẹ Ahmed ku latari iṣẹlẹ jamba. Mediterranean port ti Port Said Ni a sọ lóruko Sa'id. Sa'id fẹ̀ iyawọ meji, Inji Hanim pẹlu ọmọkunrin Ahmed Sherif Pasha ati Melekber Hanim pẹlu ọmọkunrin meji Mahmoud Bey, ati Mohamed Toussoun Pasha. Sa'id ni wọn sin si Hosh al-Basha the Royal Mausoleum ti Imam al-Shafi'i, Cairo, Egypt.
Sa'id ti Egypt
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74390
74390
People smuggling Gbígbé èniyàn kúrò nínú ìlú kàn lọsí ibòmíràn lọnà èèrú.
People smuggling
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74391
74391
Rosa de Carvalho Alvarenga Rosa de Carvalho Alvarenga ni a tumọ si Dona Rosa de Cacheu ati Na Rosa ('Senhora Rosa') (1780s – d. lẹ̀yin ọdun 1857) jẹ oniṣowo oko ẹru ti ilẹ Euro-Afrika. Itan Igbèsi Àye Rosa. Rosa jẹ ọmọbinrin Portuguese Manuel de Carvalho Alvarenga lati Cape Verde ati pe iya rẹ jẹ ilẹ́ Afrika, ọmọ iya gomina Francisco de Carvalho Alvarenga. Rosa fẹ́ Joao Pereira Barreto (1772–1829) to si di iya Honorio Pereira Barreto (1813-1859) tosi di gomina ni ọdun 1830–1859. Rosa ṣe owo ẹru, cotton, irẹsi ati oyin, o tun ṣe agbatẹru owo larin ilẹ portuguese ati ilẹ Afrika. Rosa jẹ alagata óṣèlu larin ilẹ Portuguese ati ilẹ Afrika papa julọ ninu ija ogun ti ọdun 1840s. Ni gba kan ni ọdun 1850s, Rosa di ọkan ninu oko owo ni agbegbe naa.
Rosa de Carvalho Alvarenga
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74392
74392
Human trafficking Trade of humans for exploitation Ìjínigbé káàkiri tí àwọn elédè gẹ̀ẹ́sì ń pè ní Human trafficking jẹ́ Ìfì ènìyàn ṣòwò fún ète iṣẹ́ àfipámúṣe, ìfipápábánilò-ẹ̀ṣẹ̀, tàbí ìṣòwò ìfipábánilòpọ̀.Èyí lè wáyé tàbí ṣẹlẹ láàrín Orílè èdè kàn, ìlú kan tàbí agbègbè kan. Ìfípá jínigbé yatọ pátápátá sí gbígbé èniyàn lọ́nà èèrù kúrò ní ìlú kan lọsí ìlú mìírà á lè pè ní gbígba àṣẹ lọ́wọ ẹnití wọ́n fẹ́ fí ọ̀nà èèrú gbé kúrò ní ìlú kan sí ibòmíràn.. Ní gbogbo àgbayé ni won tí òfin lòdì sí fífipá gbéni lónà àìtọ́, o sí lòdì sí àwọn ẹ̀tọ́ ènìyàn nípasè àwọn àpéjọ àgbáyé, sùgbón ààbò òfin yàtọ̀ ní àwọn ìlú lágbayé. Ìwà náà ní àwon mílíọ̀nù àwọn olùfaragba àti àwọn tí ìrù èyí ti sẹlẹ́ sí káàkiri àgbáyé.
Human trafficking
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74393
74393
Abdallah of Morocco Sultan of Morocco six times from 1729 to 1757 Moulay Abdallah (1694 – títí di ọjọ́ kẹwàá oṣù kọkànlá ọdún 1757) (Lárúbáwá: ‎) jẹ́ Sultan orílẹ̀ èdè Morocco lẹ́mẹfà láàrin 1729 sí 1757. Ó gun orí ìtẹ́ ní àwọn ọdún 1729–1734, 1736, 1740–1741, 1741–1742, 1743–1747 àti 1748–1757. Òun ni ọmọ Sultan Ismail Ibn Sharif. Ìtàn ayé rẹ̀. Wọ́n bi ní ọdún 1694 sínú ìdílé Sultan Moulay Ismail àti ọkàn lára àwọn ìyàwó rẹ̀,Lalla Khanatha bint Bakkar. Ó gun orí ìtẹ́ ní òpò ìgbà, tí ó sì ń bá àwọn arákùnrin rẹ̀ jà. Òun ni ó kọ́kọ́ pe ara rẹ̀ ní sultan lẹ́yìn ikú òjìji tí ó pa arákùnrin rẹ̀, Sultan Moulay Ahmad ní ọjọ́ kàrún oṣù kẹta ọdún 1729. Àwọn Abid, Udaya, àti gbogbo àwọn caid kóra jọ wọ́n sì fìmọ̀sọ̀kan láti pèé ní sultan Morocco. Wọ́n rán àwọn ológun pẹ̀lú ẹṣin láti mu wá láti ibi tí ó ń gbé, Sijilmasa. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, wọ́n sín sí ibi ìsìnkú ti Moulay Abdallah Mosque tí ó kọ́ ní Fes el-Jdid.
Abdallah of Morocco
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74394
74394
Ilé-iṣẹ́ Senegal Ilé-iṣẹ́ Senegal, tí kíkọ rẹ̀ ní èdè Faranse jẹ́ Compagnie du Sénégal jẹ́ ilé-iṣẹ́ sẹ́ńtútì kẹtàdínológún ti ìlú Faranse tó ń rí sí ìṣe àwọn agbègbè bí i Saint-Louis àti Gorée island tó jẹ́ apá kan ilẹ̀ Faranse ti Senegal. Ilé-iṣẹ́ àkọ́kọ́. Ilé-iṣẹ́ náà gbilẹ̀ sí àwọn agbègbè kan ní French West India Company, ní ọdún 1672, ìyẹn lẹ́yìn ìwọgbèsè wọn àti fífagilé ìwé-àdéhùn rẹ̀ ní ọdún 1674. Sieur de Richemont sìn gẹ́gẹ́ bí i Gómínà agbègbè náà, láti ọdún 1672 wọ ọdún 1673, ti Jacques Fuméchon, sì jẹ́ olùdarí lẹ́yìn rẹ̀, tó sìn títí wọ ọdún1682. Compagnie royale d'Afrique àti Compagnie de Guinea gba ìṣàkóso ètò ọrọ̀-ajé ilé-iṣẹ́ náà. Ilé-iṣẹ́ kejì. Ní ọdún 1696, wọ́n ṣèdásílẹ̀ Compagnie royale du Sénégal, Jean Bourguignon sì jẹ́ alákòóso rẹ̀ láti oṣù kẹta ọdún 1696 wọ oṣù kẹrin ọdún 1697, léyìn náà ni André Brue gbàjọba, ó sì ṣàkóso títí wọ ọdún oṣù karùn-ún ọdún 1702. Wọ́n ṣe òwò ẹrú pẹ̀lú àwọn ará Hausa, ní Mali, àti Mauritania. Ilé-iṣẹ́ kẹta. Ní ọdún 1709, wọ́n ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Compagnie du Sénégal, ẹlẹ́ẹ̀kẹta.
Ilé-iṣẹ́ Senegal
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74395
74395
Ana Joaquina dos Santos e Silva Ana Joaquina dos Santos e Silva (1788–1859) jẹ óniṣowo oko ẹru ti ilẹ Euro-Afrika, ayanilowo, ati agbẹ ti ilẹ Angola. Arabinrin naa jẹ óniṣowo oko ẹru to tobi julọ ni Angola nibi ti o tin ṣè oko owo pẹlu brazil ni ọdun 1830s to si na owo fun inawo ti Joaquim Rodrigues Graça. Igbèsi Àye Ana. Ana Joaquina dos Santos e Silva jẹ ọmọ ẹgbẹ ti class ti ilẹ Afro-Portuguese to ni ipo àṣiwaju si owo ṣiṣe agbegbe ti Portuguese Luanda nibi ti ara Europe alawọ funfun wọn ju ẹgbẹrun kan lọ. Arabinrin naa jẹ óniṣowo oko ẹru larin ilẹ Angola ati Afin ti Brazil ni ọdun 1830s-1840s. Owo ẹku ṣise ni wọn fagile ni ọdun 1836 ṣugbọn iṣẹ naa tẹsiwaju nibi ti awujọ ti fi aye gba. Ana dos Santos e Silva ni óriṣiriṣi oko fun sugar, cofee ati ile alaja mẹta ni Luanda to pada wa di oun a pewo. Nigbati Brazil fagile oko owo ẹru ni 1850, owo naa kuna lati ṣiṣẹ eyi lo mu ki ana di oṣiṣe ile ifowopamọ, olowo oko owo ati iṣẹ owo irin ati awọn amofin.
Ana Joaquina dos Santos e Silva
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74396
74396
Rasad Rasad (fl. 1078), tí wọ́n tún máa ń pè ní Sayyida Rasad, fìgbà kan jẹ́ obìnrin olóṣèlú ti ilẹ̀ Egyptian Caliph mother. Òun ni adelé Fatimid Egypt gẹ́gẹ́ bí i obìnrin olókìkí, tó tún jẹ́ ìyá ọmọ rẹ̀, Fatimid caliph al-Mustansir Billah, láàárín ọdún 1044 wọ 1071. Orúkọ yìí, Rasad túmọ̀ sí "ìwòye".
Rasad
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74397
74397
Emina Ilhamy Wife of Khedive Tewfik Pasha and Walida Pasha to her son Abbas II (1858-1931) Emina Ilhamy (Lárúbáwá: ‎; ọjọ́ kẹrìnlẹ́lógún oṣù 1858 – ọjọ́ kàn dínlógún oṣù kẹ́fà ọdún 1931) tí àwọn míràn mọ̀ sí Amina Ilhami, jẹ́ ọmọbabìnrin Ìjíptì àti ọmọ ìran Muhammad Ali Dynasty. Òun ni Khediva àkọ́kọ́ ní Íjíptì láti 1879 títí di 1892, gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Khedive Tewfik Pasha. Lẹ́yìn ikú Khedive Tewfik, ó di Walida Pasha ọmọ wọn, Khedive Abbas Hilmi II láti 1892 sí 1914. Ìpìlẹ̀ rẹ̀. Wọ́n bí Emina Ilhamy ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1858 ní Constantinople (ibi tí a wá mọ̀ sí Istanbul). Ó ni ọmọbìnrin àkọ́kọ́ Lieutenant General Prince Ibrahim Ilhami Pasha àti ìyàwó rẹ̀, Nasrin Qadin (tí ó fayé sílẹ̀ ní ọdún 1871). Ó ní arábìnrin méjì, Ọmọbabìnrin Zeynab Ilhamy àti Ọmọbabìnrin Tevhide Ilhamy. Ọmọbabìnrin Zeynab fẹ́ Mahmud Hamdi Pasha, ọmọkùnrin karùn-ún Isma'il Pasha àti Jihan Shah Qadin. Ó jẹ́ ọmọ-ọmọ Abbas I àti Mahivech Hanim.
Emina Ilhamy
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74398
74398
Muhammad Ali Pasha Muhammad Ali Pasha (Lárúbáwá: ‎; tí a bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹta ọdún 1769 tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kẹjọ ọdún 1849) jẹ́ gomina Ottoman àti adarí orílẹ̀ èdè Ìjíptì láàrin ọdún 1805 sí 1848, ọ̀pọ̀ káà mọ́ ara àwọn tí ó kọ́ Íjíptì òde òní. Nígbà tí ìjọba rẹ̀ tàn, ó dárí Egypt, Sudan, Hejaz, Najd, Levant, Cyprus àti apá kan Greece. Ó jẹ́ olórí ogun nínú àwọn ọmọ ológun Albania tí wọ́n rán láti gba Íjìptì lọ́wọ́ ìjọba France lábẹ́ Napoleon. Lẹ́yìn ìgbà tí Napoleon fi ilé náà sílẹ̀, Muhammad Ali di gómìnà "Wāli" (gọ́minà) Ìgìptì, ó sì di Pasha.
Muhammad Ali Pasha
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74400
74400
Idris Akọkọ ti Morocco Idris (akọkọ) ibn Abd Allah (Èdè larubawa: إدريس بن عبد الله, Èdè Roman: Idrīs ibn ʿAbd Allāh) ni a tumọ si Idris Agba (Èdè Larubawa: إدريس الأكبر, Èdè Roman: Idrīs al-Akbar), (d. 791) jẹ ara larubawa Hasanid Sharif ati oludari Idrisid dynasty ti northern Morocco pẹlu ajọṣèpọ ẹya Berba ti Awraba, lẹyin ti wọn sa ni Hejaz latari ogun ti Fakhkh. Igbesi Àye Idris Akọkọ. Idris akọkọ jẹ ọmọ ọmọ Hasan, ọmọ Fatima ati Ali, ọmọ ọmọ anọbi Muhammad. A bisi ilẹ Arabia. Idris fẹ Kenza ti Awraba tosibi ọmọ kan, Idris keji ti Morocco. Eyi lo mu idasilẹ Idrisid dynasty, ipinlẹ musulumi kẹrim ni Morocco lẹyin Nekor (710–1019), Barghawata (744–1058), ati Midrar (757–976). Idris I jagun ba awọn apa ibi to tobi ni ariwa ilẹ Morocco to si da agbegbe ti Fez silẹ. Ni ọdun 1789 AD, Idris jagun ba Tlemcen lati Sufrite Ifranid Abu Qurra eyi lo mu ki Abbasid caliph Harun al-Rashid gbẹsan to si awọn agbenipa si. Idris akọkọ ku ni ọdun 1791 ni Walīlī. Idris keji, ọmọ rẹ ni a bini óṣu melo kan sẹyin ti Awraba si re dagba ni abẹ̀ adele baba rẹ Rashid. Ni ọdun 1808, o kuro ni Walīlī lọ si Fes, nigba idari rẹ̀ (791–828), o sọ Fez di ilu nla Wọn si Idris akọkọ si oke kan ti ko jina si Walīlī. Tubu rẹ gun lọsi Abulè kan ti a n pè ni Moulay Idriss Zerhoun. Ilè ẹsin Zawiya ni agbegbe mausoleum gboro ni bẹ fun aimoye ọdun to si pada di ilè ẹsin pataki ni ilẹ Morocco.
Idris Akọkọ ti Morocco
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74401
74401
Idris keji ti Morocco Idris bin Idris (Èdè Larubawa: إدريس بن إدريس) ni a tumọsi Idris Keji (Èdè Larubawa: إدريس الثاني) (Óṣu August, Ọdun 1791 – Óṣu August, Ọdun 1828) jẹ ọmọn was the son of Idris Akọkọ, oludari Idrisid dynasty ni Morocco. Idris keji ni a bisi Walīlī óṣu meji lẹ̀yin iku baba rẹ. O dele baba rẹ ni ọdun 1803. Igbesi Àye Idris Keji. Idris keji ni a bini óṣu august, ọdun 791, óṣu meji ti Idris akọkọ ku. Iya rẹ jẹ Kenza, ọmọbinrin oloye ti ilu Awraba, Ishaq ibn Mohammed al-Awarbi. Idris kẹji ni a tọ larin awọn ẹya Berber Awraba ti Volubilis. Ni ọdun 803, arakunrin naa di imam moṣalaṣi ti Walila. Lara awọn oba ti Idrisid, Idris keji lo kawe julọ, lẹyin idari idris keji, afin idrisid fẹ si agbegbe arin odo ti Shalif ati Sus ni iwọ oorun Morocco. Idris keji ku ni Volubilis ni ọdun 828. Itẹ rẹ wa ni Zawiyya Moulay Idri ni Fez. Itẹ naa ni a tunri nigba idari Marinid Sultan Abd al-Haqq keji (1420–1465) ni 1437, to si di ibi pataki ati mimọ ni ilẹ Fez.
Idris keji ti Morocco
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74402
74402
Oko Ẹru ni Etikun ti Barbary Oko Ẹru ni Etikun ti Barbary (Owo Oko Ẹru ni Etikun Barbary) jẹ iṣẹ labira ti kin ṣè ọfẹ to waye larin century ti mẹrin dinlogun ati meji dinlogun ni agbegbe Etikun Barbary ni apa ariwa ti ilẹ Afrika. Ija ogun ti Barbary. Gẹgẹbi iwadi Robert Davis, ọpọlọpọ awọn ara ilẹ Europe ni awọn ole abẹ omi ti Barbary ko ti wọn si ta wọn lẹru ni ariwa ilẹ Africa ati Afin ti Ottoman larin century ti mẹrin dinlogun ati ọkan dinlogun. Lati iṣalẹ ti Etikun ti Barbary, ariwa ilẹ Afrika, awọn ole abẹ omi ja ọkọ oju omi gba eyi to ṣe irin ajo lọ si Mediterranean, ariwa ati iwọ oorun etikun ti ilẹ Africa ti wọn si ko awọm ero bẹ lẹru. From at least 1500, the Awọn ole abẹ omi yi tun kogun ja awọn ilu etido to wa ni ilẹ Italy, Spain, France, England, Netherlands ati Iceland ti wọn si ko óbinrin, ọkunrin ati ọmọde lẹru. Larin ọdun 1609 ati 1616, England pofo ọpọlọpọ ọkọ oju omi si olè abẹ̀ ọmi ti Barbary lọwọ. Ọrọ nipa Oko Ẹru. Ninu afiwe ọrọ nipa ẹru ti ariwa ilẹ America ati ọrọ nipa ẹru ilẹ Caribbean ni ede gẹẹsi ni awọn ẹru alawọ funfun ti ilẹ America ati British kọ. Ọrọ yii lo yatọ si iṣọkam ti awọn óniṣowo ẹru ti ẹlẹsin musulumi, ṣugbọn ọrọ awọn ẹru ti Africa-America maa npe awọn óniṣowo ẹru ni ẹlẹsin christaini. Ọrọ to da lori ominira to jẹ oun iwuri lati ilẹ America.Nigba to jẹ̀ pe awọn ọrọ yi wọnu ara wọn, awọn onimimọ gbagbọ pe pupọ ninu awọn ọrọ yii ju ti awọn ti wọn ko lẹru lọ. Awọn obinrin ti wọn ko lẹru ni wọn lo ni Gothic fiction to tumọ si imọlẹ imonira ti awọn ara ti oun wo gbagbọ.
Oko Ẹru ni Etikun ti Barbary
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74403
74403
Etikun ti Oko Ẹru ti iwọ oorun ilẹ Afrika Historical name of region in West Africa Etikun Oko Ẹru yi jẹ oruko Adayeba ti a ti lo tẹ̀lẹri fun apa Etikun iwọ oorun ni Agbegbe Bight ti Biafra ati Bight ti Benin to wa ni arin odo Volta ati lagoon ti eko.Órukọ yi ni a yọ latari itan agbegbe naa gẹgẹbi ọna kan gbogi ti awọn ẹya Afrika ma nko lẹru ni owo oko ẹru ti Atlantic lati century mẹrin dinlogun lọsi century ti ọkan dinlogun.
Etikun ti Oko Ẹru ti iwọ oorun ilẹ Afrika
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74404
74404
Etikun ti Barbary Coastal region of North Africa inhabited by Berber people Etikun ti Barbary (A tun mọ si Barbary, Berbery tabi Etikun ti Berber) jẹ orukọ ta fun agbegbe etikun ti ariwa ilẹ Afrika tabi Mahhreb papa julọ Ibudo Ottoman pẹlu rẹ ni adele to wa ni Algiers, Tripoli, Beylik ti Tunis ati Sultanata ti Morroco lati century ti mẹrin dinlogun de ọkam dinlogun. Órukọ yii ni a fayọ lati exonym ti awọn Berber.
Etikun ti Barbary
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74405
74405
Ija Ikonilẹru ti Suðuroy Barbary slave raids against the Faroe Islands Ija Ikonilẹru ti Suðuroy jẹ́ ija ti awọn afigba ọkọ oju omi lai ariwaiwọ oorun ilẹ́ Afrika to ṣẹlẹ ni Suðuroy ni Erekusu Faroe ni summer ti ọdun 1629. Eyi lo jasi ijinigbe awọn eniyan ọgbon ti wọn obinrin ati ọmọde ti wọn kogbe ni Etikun ti Barbary ti Ariwa ilẹ Afrika.
Ija Ikonilẹru ti Suðuroy
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74406
74406
Turkish Abductions Barbary slave raids against Iceland Turkish Abductions (tí ó túmọ̀ sí "Àwọn ìjínigbé ní orílẹ̀ èdè Turkey-àgbègbè Mediterranean nígbà náà) jẹ́ oríṣi ìkónilẹ́rú tí àwọn jàndùkú ojú omi láti àríwá ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ṣe ní orílẹ̀ èdè Iceland ní ìgbà oru ọdún 1627. Àwọn jàndùkú ojú omi náà wá láti ìlú Algiers àti Salé. Wọ́n ya wọ Grindavík, East Fjords, àti Vestmannaeyjar. Ènìyàn bi àádọ́ta ni wọ́n pa àwọn ènìyàn irínwó ni wọ́n kó tí wọ́n sì tà ní ọkọ ẹrú. Wọ́n padà san owó fún wọn ní òpò ọdún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, láti dá ènìyàn tí ó tó àádọ́ta padà.
Turkish Abductions
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74407
74407
Ismail Ibn Sharif Moulay Ismail Ibn Sharif (Lárúbáwá: ‎), tí a bí ní 1645 ní Sijilmassa tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta oṣù 1727 ní Meknes, jẹ́ Sultan Morocco láti ọdún 1672 sí 1727, gẹ́gẹ́ bi adarí kejì 'Alawi dynasty. Òun ni ọmọkùnrin keje Moulay Sharif ó sì fi ìgbà kan jẹ́ Gómìnà àgbègbè Fez àti àríwá Morocco láti ọdún 1667 títí di ìgbà ikú arákùnrin rẹ̀, Sultan Moulay Rashid ní ọdún 1672. Wọ́n kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ sultan ní Fez, ṣùgbọ́n òun àti Moulay Ahmed ben Mehrez, ẹni kejì tí ó pe ara rẹ̀ ní Sultan jà fún ọ̀pọ̀ ọdún, Moulay Rashid padà fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1687. Moulay Ismail wà lórí oyè fún ọdún márùnléládọ́ta, èyí sì mú kí ó jẹ́ Sultan tí ó pẹ́ lórí oyè jù ní Morocco. Nígbà ayé rẹ̀, Moulay ní ìyàwó tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹta àti ọmọ tí ó tó ẹgbẹ̀rin.
Ismail Ibn Sharif
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74408
74408
Ọkọ ẹrú Barbary Oko ẹrú Barbary jẹ́ àwọn ọjà ẹrú tí ó wà ní àwọn Ìpínlẹ̀ Barbary. Àwọn jàndùkú odò tí ó jẹ́ ọmọ Barbary ya wọ àwọn ọkọ̀ ojú omi, ìlú ẹgbẹ́ odò láti Italy dé Netherland, Ireland àti gúúsù apá ìwọ̀ oòrùn Britain, títí dé àríwá Iceland àti Ìlà-Oòrùn Mediterra. Apá ìlà-oòrùn Mediterranean Ottoman ni ìṣẹ̀lẹ̀ yí wọ́sí jùlọ. Títí di àwọn ọdún 1700s, ìwà jàndùkú jẹ́ ǹkan tí ó sì ń da Aegean láàmú.
Ọkọ ẹrú Barbary
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74411
74411
John Ezzidio John Ezzidio (c. 1810 – October 1872) jẹ́ ẹrú Nupe tí ó gba òmìnira tí ó sì padà di oníṣòwò àti olóṣèlú ńlá ní orílẹ̀ èdè Sierra Leone. Wọ́n tu sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ẹrú tí ó ń lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil, ó kọ́ iṣẹ́ lábé ọmọ orílẹ̀ èdè Faransé kan, ẹni tí ó kọ bí a ṣe ń kọ àti kàwé. Ezzidio padà dé ipò mayor ìlú Freetown ó sì padà di ara àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ Gómìnà ìgbà náà. Ìjígbé rẹ̀. Wọ́n jí Ezzidio, ọmọ ẹ̀yà Nupe gbé fún ẹrú ní agbègbè tí a wá mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Niger lóni, wọ́n sì gbe wá sí ibi tí ẹ̀yà Yoruba wọ́pọ̀ sí. Ní ọdún 1827, wọ́n tá fún àwọn fún àwọn òyìnbó, àwọn òyìnbó sì fi sínú ọkọ̀ omi tí ó ń lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil. Royal Navy dá ọkọ̀ náà dúró wọ́n sì tú Ezzidio àti àwọn ẹrú tí ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta míràn kalẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú tí ó yẹ̀ sálọ Freetown, Sierra Leone ní oṣù kẹwàá ọdún 1827.
John Ezzidio
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74412
74412
John Jea John Jea (1773 – lẹ́yìn 1817) jẹ́ ònkọ̀wé, oníwàásù àti awakọ̀ ojú omi ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà mọ́ Áfíríkà. Ó gbajúmọ̀ fún ìwé rẹ̀ tí ó kọ ní ọdún 1811 "The Life, History, and Unparalleled Sufferings of John Jea, the African Preacher." Jea di ẹrú láti ìgbà tí ó sì jẹ́ èwe, lẹ́yìn ìgbà tí ó sì gbòminira ní 1790s, ó bẹ̀rẹ̀ sí ń rìrìn àjò àti wàásù káàkiri. Ìpìlẹ̀ rẹ̀. Díè ni a mọ̀ nípa ìpìlẹ̀ John Jea yàtò sí òun tí ó kọ nínú ìwé rẹ̀, "The Life, History, and Unparalleled Sufferings of John Jea, the African Preacher" (1811). Jea sọ pé wọ́n bi ohun ní Africa ní ọdún 1773 lẹ́gbẹ̀ẹ́ Calabar ní Bight of Biafra, àti pé àwọn akónilẹ́rú jí òun, àwọn òbí òun, Hambleton Robert Jea àti Margaret Jea, àti àwọn ẹbí òun gbé, wọ́n sì ta àwọn fún ẹrú sí New York City, ìṣẹ̀lẹ̀ sí ṣẹ̀ nígbà tí ó sì jẹ́ ọmọ ọdún méjì àti àbọ̀. Ìdílé Dutch kan, Oliver and Angelika Triebuen, ra Jea. Àwọn olówó rẹ̀ jẹ́ ọmọ ìjọ Conservative Dutch Reform, tí ó lòdì sí yíyí ẹrú sí ẹ̀sìn Krìtẹ́nì. Àwọn olówó rẹ̀ ma ń lọ sí ilé ìjọsìn láti ba wí ṣùgbọ́n Jea di Krìstẹ́nì, a sì ṣe ìrìbọmi fun ní 1780s.
John Jea
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74413
74413
S'Nabou African interpreter Alima S'Nabou (tí a bí ní ọdún 1880) jẹ́ atúmọ̀ èdè (tí ó wá láti ibi tí Nàìjíríà wà lónìí) tí ó tẹ́lèé arìnrìn-àjò Faransé kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Lieutenant Mizon. Ìtàn rẹ̀. A bí Alima S'Nabou sínú ìdílé olóyè Konanki, nínú ìlú Igbobé, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Lokoja níbi tí odò Benue àti Niger ti pàdé. Ó gbó èdè Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, àti àwọn èdè Niger míràn. S'Nabou wà ní Assaba, nígbà tí ó pàdé Mizon tí ìyá rẹ̀ sì sọ pé kí ó tẹ̀lé Mizon nínú ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Lokoja kí ó bà le rí bàbá rẹ̀, nítorí Mizon ń lọ sí Lokoja nígbà náà, S'Nabou jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá sí mọ́kànlá nígbà náà. Ní Lokodja, S'Nabou sọ fún bàbá àti ìyá bàbá rẹ̀ pé òun fẹ́ tẹ̀lé Mizon nínú ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí Yola, olú-ìlú of Adamawa.
S'Nabou
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74414
74414
Oshodi Tapa Chief Oshodi Landuji Tapa (c. 1800 – 1868) jẹ́ Balógun Oba Kosoko àti ara àwọn olóyè tí ó lágbára jù lọ ní ààfin Oba Èkó. Ìpìlẹ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé Oshodi Tapa wá láti ẹ̀yà Nupe ní Bida tí ó wà lábé Oba Osinlokun. Ìdílé Oshodi sọ wípé nígbà tí Tapa jẹ́ ọmọdé, àwọn olóko ẹrú pinu láti gbe sínú ọkọ omi Portugal tí ó ń lọ Amẹ́ríkà ṣùgbọ́n ó sá ó sì lọ sí àfin Oba Osinlokun fún àbò. Ìdìde rẹ̀. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn tí ó ní, Oshodi Tapa di adúnàdúrà fún Oba Osinlokun. Ọba Osinlokun rán ohun àti ẹrú míràn (Dada Antonio) lọ sí Brazil láti kọ́ èdè Portuguese, àti láti ní ìmò tí ó ṣe pàtàkì láti gba owó orí lọ́wọ́ àwọn òní òwò ẹrú Portugal. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣiṣẹ́ fún Osilokun, Oshodi Tapa di ọ̀lùmọ̀ràn àti Balógun Oba Kosoko.
Oshodi Tapa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74415
74415
Selim Aga Sudanese writer and critic (1826–1875) Selim Aga (c. 1826 – tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1875) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Sudan kan tí àwọn olókowò ẹrú Arab jígbé nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, tí wọ́n sì mú wá sí Scotland ní ọdún 1836, níbi tí wọ́n ti tọ dàgbà gẹ́gẹ́ bi ọkùnrin llómìnira. Selim kọ ìwé nípa ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹrú, ó sì sọ nípa "Ode to Britain" ní ọdún 1846. Ó ma ọ̀pọ̀ ní Great Britain nípa Áfíríkà, ó sì tẹ̀lé William Balfour Baikie ní 1857 láti lọ Niger River. Lẹ́yìn náà, ó tẹ̀lé John Hawley Glover àti Richard Francis Burton nínú ìrìn àjò wọn káàkiri Áfíríkà. Ní àwọn ọdún 1860s, Selim lọ sí Liberia, àwọn jàndùkú Grebo pá ní ọdún 1875. Ìgbà èwe rẹ̀. A bí Selim Aga, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nípa ara rẹ̀, sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Taqali. Àwọn ènìyàn Taqali ń ṣíṣẹ́ àgbẹ̀ àti olùṣọ́ àgùntàn, ẹ̀sìn wọn ni Islam àti sísin Oòrùn. Àwọn akónilẹ́rú jí Selim gbé nígbà tí ó ń da nǹkan ọ̀sìn bàbá rẹ̀. Ó sìn lábé olówó mẹ́wàá, ẹni kẹwàá ni Robert Thurburn ("Mr. R. T."), British consul in Alexandria. Robert kọ́ Selim ní èdè Ínglísì, wọ́n sì mu lọ Cataracts of the Nile.
Selim Aga
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74416
74416
Simon Deng Simon Aban Deng jẹ́ ajàfẹ́tọ́ ènìyàn ọmọ orílẹ̀ èdè Sudan tí United States. Wọ́n jí Simon gbé nígbà tí ó wà ní èwe. Ó jẹ́ ọmọ bíbí ìjọba Shilluk ní gúúsù Sudan, Deng lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bi ẹrú ní gúúsù Sudan. Ìtàn. Wọ́n kó Simon lẹ́rú nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn nígbà tí aládùúgbò rẹ̀ kan sọ pé kó tẹ̀lẹ́ òun lọ ìrìn-àjò kan. Deng tẹ̀le, ó sì fi Deng gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ìdílé rẹ̀. Láti ìgbà tí ó yọbọ́ tí ó sì lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ó ti ń rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀ èdè láti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ àti láti kó lòdì sí Ìsìnrú. Nínú ìwé rẹ̀, Deng sọ pé: ""... Mo fìgbà kan jẹ́ ẹrú. ... Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, àwọn ọmọ ogun Arab ya bo abúlé mi. Tí mo ṣe ń sáwọ igbó ni mò rí tí wọ́n yin àwọn ọ̀rẹ́ mi kan, wọ́n sì dáná sun àwọn àgbàlagbà tí kò le sáré nínú ilé wọn. Wọ́n jí mi gbé wọ́n sì fi mí fún ìdílé Arab kan gẹ́gẹ́ bí "ẹ̀bùn"."" Nígbà tí Deng jẹ́ ẹrú, ojú rẹ̀ rí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ní òun rántí bí wọn ṣe nà òun nítorí kò pariwo tó, bí àwọn ọmọdé tó kù ṣe náà. Wọ́n fi ipá mu láti sọ bẹ́ẹ̀ni sí oun gbogbo, pẹ̀lú ìyà. Ó ní pé "nǹkan eyokan tí mo le bèrè fún nígbà mìíràn ni àánú... Àánú kìí sì fi gbogbo ìgbà sí."
Simon Deng
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74417
74417
Trans Sahara trade ìṣòwò láàrín àwọn èèyàn ilé Afíríkà àti Mediterranean Trans-Saharan trade tàbí ìṣòwò láàrín Sahara nílò ìrìn-àjò kọjá Sahara láàrín Ìwọ̀-oòrùn, Central, Ìlà-orùn àti Àríwá Áfíríkà. Lákòkò tí ó ti ń wà lati àwọn àkókó tí wọ́n pè ní Prehistoric times, àwọn àkókó ìṣààjúu, èyí tí ó jẹ́ ìgbà kàn ti iṣowo gbòòrò wà ní òkè tente láti ọ̀rúndún kẹ́jọ títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọrúndun kẹ́tàdínlógún. Sahara yìí tí fi igba kan ri bíí Sahara Aláwọ̀ ewé rí, agbègbè tí ó yàtọ púpọ̀ sí Sahara òde òni. Ní igbà kàn rí, ní Ẹgbẹ̀rún ọdún méje sẹ́yìn kí a tó bí Jésù ní ìṣẹ́ daran-daran àwọn ohun Ọ̀sìn bí Ẹran ewúrẹ, Àgùntàn, tí wà ní àwọn orílé èdè bí Libya àti Algeria, pẹ̀lú isẹ́ fífi Amọ̀ mọ nǹkan. Lèyìn Ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin sí Mẹ́ta àbọ̀ ní iṣẹ́ dída ẹran Màálù ni Central Sahara ní Ahaggar bẹ̀rẹ̀. Àwọn àwòrán àpatà ìyàlẹ́nu (ní 3500 si 2500 BC) ní àwọn ààyè tí ó gbẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣe àfihàn àwọn òdòdó àti àwọn ẹranko tí kò sí ní agbègbè aginjù Òde òní.
Trans Sahara trade
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74418
74418
Charlesi Kẹta
Charlesi Kẹta
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74419
74419
Charlesì Kẹta Charles III (Charles Philip Arthur George; ti a bi 14 November 1948) jẹ Ọba ti Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan ati 14 miiran Commonwealth ijọba.
Charlesì Kẹta
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74420
74420
William, Alade ti Wales William, Alade ti Wales, (William Arthur Philip Louis; tí a bí 21 June 1982) ni ajogún gbangba si Itẹ Britani. Oun ni ọmọ agba ti Charles III ati Diana, Ọmọ-binrin ọba ti Wales.
William, Alade ti Wales
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74421
74421
G33 (awọn orilẹ-ede to sese) Le G33 (tabi Ọja Pataki Awọn ọrẹ ti Ogbin
G33 (awọn orilẹ-ede to sese)
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74422
74422
G8
G8