url
stringlengths
37
41
id
stringlengths
1
5
text
stringlengths
2
134k
title
stringlengths
1
120
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74100
74100
Warri Times Warri Times ni aaye ayelujara ti Isaiah Ogedegbe ni Warri. Onkiwe nla Amurika kan Frederic Will mu nuba Warri Times ninu iwe 2017 ro. Awon itokasi. Yi ni a kukuru article. Jọwọ mu yi.
Warri Times
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74101
74101
Bola Tinubu
Bola Tinubu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74102
74102
Threads Thread jẹ́ ìkànnì ayélujára tí ó jẹ́ ìní ilé isé Meta. Ó dà bi àwọn ìkànnì ayélujára bi Twitter: Àwọn tí ó wà lórí ìkànnì náà le fi ọ̀rọ̀ àti fọ́tò léde, wọ́n le fi èsì sí ọ̀rọ̀. Ìkànnì náà wà lórí iOS àti Android. Àwọn tí ó ń lò ó dé iye mílíọ̀nù ọgọ́rin ní àárín wákàtí méjìdínládọ́tá. Wọ́n fi ìkànnì Threads lélẹ̀ ní ọjọ́ karùn-ún oṣù keje ní ọgọ́rùn-ún orílẹ̀ èdè, àwọn orílẹ̀ èdè bi United States, United Kingdom, Australia, New Zealand, Canada, àti Japan.
Threads
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74104
74104
Mai Mala Buni Mai Mala Buni tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kọkànlá ọdún 1967 jẹ́ olóṣèlú tí ó ti ṣe gómìnà eí ní ìpínlẹ̀ Yobe] ní ọdún 2019 ati ọm9 lrílẹ̀-èdè Nàìjíríà.Òun noi wọ́n dìbò yàn nínú ìdìbò tó wáyé ní ọdún 2019 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress. Ṣáájú kí ó di gómìnà ni ó tinwà nípò Akọ̀wé àgbà fún ẹgbẹ́ òṣèlé náà. Ibẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n bí Buni ní ọjọ́ kọkàndínlógún òṣù kọkànlá ọdún 1967 ní agbègbè Bínú Gàrí ní Ìpínlẹ̀ Yobe .Bínú bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìkẹ́kọ́ ilé-kéu láti kọ́nípa ìmọ̀ Àlùkùránì lábẹ́ olùkọ́ rẹ̀ tí ó tún jẹ́ bàbá rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Buni Gari níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1979. Ó wọlé ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wá ti ìjọba tí ó wà ní Goniri ní ọdún 1979, lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, tí ó jáde gbàwé ẹ̀rí ìwé mẹ́wá ní ọdún 1985. Buni tún wọlé ẹ̀kọ́ Fásitì Espan Formation tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Benin Republic láti kò nípa ìmọ̀ International Relation tí ó sì jáde ní ọdún 2014. Nìkan náà ni ó gba ìwé ẹ̀rí Master láì ilé-ẹ̀kọ́ Leeds Beckett University, ní United Kingdom.ọjọ́ Iṣẹ́ rẹ̀. Látàrí ìmọ̀ nípa iṣẹ́ Irinkerindo ọkọ̀, tí jẹ́ iṣẹ́ kan pàtàkì nínú ẹbí rẹ̀ ni ó jẹ́ kí ó tètè ji gìrì sí òwò síṣe. Èyí mu kí ó lọ kẹ́kọ́ọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ nílé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ti College of Vocation Science and Technology níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà ní ọdún 2012. Mai Mala Buni jẹ́ Alága fún àwọn ilé-iṣẹ́ wọ̀nyí: Ìṣèlú rẹ̀. Mala Buni bẹ̀rẹ̀ ìṣèlú rẹ̀ ní ọdún 1992 nígbà tí díje dupò lábẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ òṣèlú National Republican Convention (NRC) láti sojú fún ẹkùn Buni lábẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Gujba Local government council. Wón sì yanán gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún ìgbìmọ̀ náà. Ó di amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ aṣòfin àgbà ní National assembly ní ọdún 2000, àti ọdún 2004 tí wọ́n yanán gẹ́gẹ́ bí adarí fún ìgbìmọ̀ University of Uyo. Ní ọdún 2006, wọ́n dìbò yànán gẹ́gẹ́ bí Alága Advanced Congress of Democrats ní Ìpínlẹ̀Yobe. Ní ọdún 2007, wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Action Congress látinú ẹgbẹ́ ìṣèlú Advanced Congress of Democrats kí ẹgbẹ́ Action Congress lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ẹgbẹ́ náà yàná. Wọ́n yanán láìfọ̀tápè gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ ìṣèlú tuntun náà Action Congress party tí wọ́n sì dìbò yàná ẹ́gẹ́ bí Alága gbogbo gbò láti ọdún 2007 sí 2010. Buni darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú All Nigeria Peoples Party (ANPP) ní ọdún 2011 ní Ìpínlẹ̀ Yobe tí wọ́n sì yànán gẹ́gẹ́ bí olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí gómìnà Ìpínlẹ̀ Yobe Ibrahim Gaidam lórí ètò ìṣèlú àti ìṣòfin. Ní ọdún 2013, tí wọ́n da àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú papọ̀ láti da ẹgbẹ́ ìṣèlú All Progressives Congress (APC), Wọ́n fi Mai Mala Buni ṣe akọ̀wé ẹgbẹ́ ọ̀hún ní ìpínlẹ̀ Yobe tí Won sì padà yànán gẹ́gẹ́ bí Alága àgbà ẹgbẹ́ ọ̀hún ní ìpínlẹ̀ Yobe. Mai Mala Buni di Akọ̀wé agba fún ẹgbẹ́ ìṣèlú APC tí wọ́n dìbò yàn ánọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ ìṣèlú náà ní ọdún 2014. Lásìkò tí ń ṣiṣẹ́ bí Akọ̀wé àgbà yí ni wọ́n dìbò yan Muhammadu Buhari gẹ́gẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà ní ọdún 2015. Látarí ìfarajìn rẹ̀ fún ẹgbẹ́ ni wọ́n tún ṣe yànán sípò Akọ̀wé Àgbà ẹgbẹ́ ìṣèlú náà lẹ́ẹ̀kejì ní ọdún 2018. Pẹ̀lú ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ ìṣèlú APC ati Alága ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ Nigeria Shippers council, wọ́n yànán kí ó wá ṣe adíje dupò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Yobe lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú APC ní ọdún 2019. Nínú ìdìbò gbogbo gbo ọdún 2019, wọ́n dìbò yàn án gẹ́gẹ́ bí gómìnà kẹrin ní ìpínlẹ̀ náà lẹ́ni tí ó jáwé olúborí pẹ̀lú ìbò tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ri ati ọgbàọ́rinlé mẹ́rin ati mẹ́talá nígbà tí alátakò rẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Alhaji Bello Ìfòyà ní ìbò ẹgbẹ̀rún márùdínlọ́gọ́rún ati 73 ìbò péré. Wọ́n tu ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ ìṣèlú APC ka ní inú osù Kẹfà ọdún 2020, àmọ́ nígbà tí wọn yóò tun tò, Mai Mala Bunini wọ́n fi ṣe Alàga Àgbà yányán fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Buni sì ni ẹni akọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe àpérò gbogbo gbò fún ẹgbẹ́ náà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe yí ni wọ́n mojú tó ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ náà fún odidi òṣù mẹ́fa ṣáájú kí wọ́n tó ṣe àpérò gbogbo gbò ọ̀hún. Wọ́n sún àsìkò tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ẹgbẹ́ yí lábẹ́ adarí Buni siwájú si fún oṣùn mẹ́fà nínú ìpàdé ìgbìmọ̀ kan tí eọ́n ṣe ní ọjọ́ kája oṣù Kejìlá ọdún 2020 Ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ Gómìnà. Mai Mala Buni sọ wípé: "Ìjọba wa yóò mú sapá láti ri wípé ọwọ́ ajọ Universal Basic Education Commision (UBEC) tẹ owó ìrànwọ́ lásìkò, láti lè jẹ́ kí ètò ẹ̀kọ́ kẹ́sẹjárí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Bákan náà ni a ó gbìyànjú láti kọ́ àwọn iyàrá ìgbẹ̀kọ́ tuntun, a ó gba àwọn olùkọ́ tuntun tó dántọ́, tí a ó sì pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn olùkọ́. Bákan náà ni a ó pèsè ohun ìgbẹ̀kọ́ tí yóò mú ẹ̀kọ́ rọrùn fún àwọn olùkọ́ ati akẹ́kọ̀ọ́ láti lè fakọyọ bíi tàwọn akẹgbẹ́ wọn lágbàáyé. Bákan náà ni a ó ti ṣe nílé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì gbogbo. A ri wípé ètò ẹ̀kọ́ fanimọ́ra, wuyì kí ó lè ṣiṣẹ́ tí a ran. Sísan owó ìdánwò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò tẹ̀ siwájú bíi ti àtẹ̀yìnwá kí àwọn òbí ati alágbàtọ́ lè nífẹ́ọ̀kànbalẹ̀ lórí owó ẹ̀kọ́ sísan ní ìpínlẹ̀ Yobe. Láti lè ri wípé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fọkàn sí ẹ̀kọ́ wọn, a ó bá ìjọba apápọ̀ ní ìbáṣepọ̀ tà pinminrin lórí fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní òúnjẹ nílé ẹ̀kó wa gbogbo. Lábẹ́ ìṣàkóso Buni, ìjọba rẹ̀ ti na owó tí ó tó 2.1 billion títí di oṣù kẹrin ọdún 2020 láti fi kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìgbàlódé méje ní àwọn agbègbè orísiríṣi ní Ìpínlẹ̀ Yobe. Àtojúsùn ìgbésẹ̀ yí ni láti dí apọ̀jù akẹ́kọ́ kù nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọn gbogbo. Ìpínlẹ̀ Yobe wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn agbésùnmọ̀mí Boko Haram ti ṣọṣẹ́ jùlọ. Gómìnà Mai Mala Buni ti da àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ogúnléndé tí wọ́n gbé ní agọ́ ogúnléndé padà sílé wọn tí ó sì tún fi àwọn ohun amáyédẹrùn pẹ́pẹ̀pẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìjọba ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ ilé ìfowó-pamọ́ onídàgbà-sókè African Development Bank lábẹ́ Agro-Processing, Productivity Enhancement, and Livelihood Improvement Support, APPEALS, Project ni wọ́n ti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn náà tí wọ́ do ẹgbẹ̀rún márùún níye. Ìjọba rẹ̀ náà tún kọ́ ilégbèé fún àwọn ogúnléndé ní inú oṣù kẹsàán ọdún 2020. Iṣẹ́ àkànṣe yí ni ilé-iṣẹ́ elépo Nigerian National Petroleum Corporation (NNPC), Shell Petroleum Development Company of Nigeria Limited (SPDC) Joint Venture (JV), Shell Nigeria Exploration and Production Company Limited (SNEPCO) àti Total Nigeria Plc. ṣe agbátẹrù rẹ̀ pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Yobe Ní agbami ti ètò ìlera, ìjọba rẹ̀ ti kọ́ ilé-ìwòsan tí ó ní ilé ayẹ̀wò mẹ́tàléláàdọ́ta nínú ọgbàọ́rúnléméjìdínlọ́gọ́jọ tí ó ṣèlérí rẹ̀ fún ará ìlú, àwọn ilé-ìwòsan náà ni wọn yóò ma ṣe ayẹ̀wò fún àwọn aláìsàn tí wọn yóò sì ma fún wọn ní oògùn lọ́fẹ́, ó tún kọ́ ilé ìgbé fún àwọn takọ-tabo oníṣẹ́ ìlera nínú àwọn ilé-ìwòsan yí gbogbo kí wọ́n lè ma tọ́jú àwọn ènìyàn nígbà gbogbo tí wọ́n bá yọjú. Lágbọ́nrin ti ilégbèé, ìjọba rẹ̀ ti kọ́ ilé tí ó ẹgbẹ̀rún kan ó lé lọ́gọ́jọ láàrín ọdún méjì akọ́kọ́ tí ó gbàṣèjọba. Bákan náà ni ó tún fẹ́ ṣe nínú apákejì ìṣèjọba rẹ̀. Àwọn amì-ẹ̀yẹ rẹ̀. Ó gba amì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ìyẹn Commander Of The Order Of The Niger (CON) ní inú osù Kẹwàá ọdún 2022 láti ọwọ́ Ààrẹ àná Muhammadu Buhari.
Mai Mala Buni
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74105
74105
Umo Eno Umo Bassey Eno tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù kẹrin ọdún 1964, jẹ́ olùṣọ́ àgùtàn ilé-ìjọsìn All Christain Ministary International àti olóṣèlú tí ó tún jẹ́ gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom nínú ìdìbò tó wáyé ní ọdún 2023., ó sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni kọmíṣánà tẹ́lẹ̀ rí fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti omi àlùmọnì fún ìpínlẹ̀ Akwa Ibom. Ibẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀. wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù kẹrin ọdún 1964, ní ìlú rẹ̀ Ikot Ekpene Ìró tí ó wà ní abẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Nsit-Ubium. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Local Authority Primary School tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ akọ́bẹ̀rẹ̀ He attended Local Authority primary school in Lagos State, where he got his first school leaving certificate. Ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì ti St. Francis tí ó wa ní ilú Eket tí ó sì parí ìpele ẹ̀kọ́ yí ní Victoey High School tí ó wà ní Ìkẹjà ní ípínlẹ̀ Èkó . Ó gba ìwé-ẹ̀rí ẹ̀kọ́ agba jáde nínú ìmọ̀ Ìbáṣepọ̀ Àwùjọ ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Uyo tí ó sì gba ìwé ẹ̀rí Masters jáde nínú ẹ̀ka ìmọ̀ yí kan náà. Iṣẹ́nṣe rẹ̀. Wọ́n gbàá sisẹ́ ní ilé-iṣẹ́ Union Bank lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ̀ndìrì rẹ̀ ṣáájú kí ó tó lọ ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ Bertola Machine Tools Nigeria Limited àti Norman Holdings Limited, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà ṣáájú kí ó tó lọ dá ilé-iṣẹ́ Royalty Group tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ rẹ̀. Wọ́n yànán sí ipò kọmíṣánà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ati omi àlùmọ́nì ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ní ọdún 2021 lábẹ́ gómìnà Udom Emmanuel Ó kọ̀wé dupò náà sílẹ̀ láti díje du ipò Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ náà ní ọdún 2023.
Umo Eno
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74106
74106
Andrés Iniesta Andrés Iniesta Luján (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá Oṣù karùn-ún ọdún 1984) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀ èdè Spain. Ó wà lára àwọn tí ọ̀pọ̀ kà sí agbábọ́ọ̀lù àárín tí ó da jù ní àgbáyé. Iniesta lọ ọ̀pọ̀lopọ̀ ọdún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi agbábọ́ọ̀lù ní Barcelona, ní ibi tí ó ti jẹ́ adarí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà fún ṣáà mẹ́ta. Iniesta ran orílẹ̀ èdè Spain lọ́wọ́ láti jáwé olúborí nínú UEFA Euro 2008. Iniesta tún agbábọ́ọ̀lù gbòógì tí ó ran ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Spain láti jáwé olúborí nínú 2010 FIFA World Cup.
Andrés Iniesta
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74107
74107
Andrea Pirlo Andrea Pirlo (tí a bí ní ọjọ́ kọkàndínlógún 1979) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀ èdè Italy tí ó jẹ́ olùtoni àgbà ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Serie B Sampdoria. Ó wà lára àwọn tí ọ̀pọ̀lopọ̀ kà sí agbábọ́ọ̀lù ipò àárín tí ó da jùlọ. Pirlo bẹ̀rẹ̀ sí ń gba bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ Brescia ní ọdún 1995, ó jáwé olúborí borí Serie B ní ọdún 1997. Ó fọwọ́ síwẹ̀ fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Serie A ti Inter Milan lẹ́yìn ọdún kan, ṣùgbọ́n ó padà lọ sí ẹgbẹ́ AC Milan ní ọdún 2001. Ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ní Pirlo ti di ògbóòntarìgì agbábọ́ọ̀lù, ó jáwé olúborí nínú ipò Serie A méjì, UEFA Champions League méjì, UEFA Super Cup méjì, FIFA Club World Cup méjì, Coppa Italia méjì, àti Supercoppa Italiana kan.
Andrea Pirlo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74108
74108
Tom Holland Thomas Stanley Holland (tí a bí ní ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ọdún 1996) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain. Ara àwọn àmì ẹyẹ rẹ̀ ni British Academy Film Award àti saturn awards mẹ́ta. Àwọn àtẹ̀jáde míràn ti pèé ní òṣèré tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní ìran rẹ̀. Holland jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ erẹ́ ṣíṣe, ó darapọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ijó kan nígbà náà, ọkàn lára àwọn oníjó sì kíyèsí, èyí mú kí ó ràn lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ hàn sí jíjẹ́ ara àwọn òṣèré nínú eré "Billy Elliot the Musical" ní Victoria Palace Theatre. Holland bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré ní pere wu nígbà tí ó ṣeré nínú fíìmù "The Impossible" (2012) gẹ́gẹ́ bi ọ̀dọ́kùnrin tí ó sọnù sínú tsunami. Lẹ́yìn èyí, Holland tí ṣeré nínú àwọn eré bi "How I Live Now" (2013), "In the Heart of the Sea" (2015) àti "Wolf Hall" (2015). Holland di gbajúmọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè nígbà tí ó ṣeré gẹ́gẹ́ bi Spider-Man/Peter Parker nínú eréMarvel Cinematic Universe (MCU) mẹ́fà, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ' (2016). Ní ọdún tó tẹ̀le, Holland gba àmì-ẹ̀yẹ BAFTA Rising Star Award, ó tún ṣeré nínú ', ' (2019), ' (2021), "Uncharted" (2022), "The Devil All the Time" (2020), "Cherry" (2021).
Tom Holland
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74109
74109
Tom Hiddleston Thomas William Hiddleston (tí a bí ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejì ọdun 1981) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain. Ó gbajúmọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa gẹ́gẹ́ bi Loki nínú àwọn eré Marvel Cinematic Universe (MCU), ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú "Thor" ní ọdún 2011, ó sì ti farahàn nínú àwọn eré mìíràn bi Avengers, "" tí ó jáde ní ọdún 2023, àti "Loki" tí ó jáde ní ọdún 2021. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nínú àwọn fíìmù ní ere Joanna Hogg tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Unrelated" (2007) àti nínú"Archipelago" (2010). Ní ọdún 2011, Hiddleston kópa F. Scott Fitzgerald nínú fíìmù Woody Allen tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Midnight in Paris", àti ere Steven Spielberg tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "War Horse." Ní ọdún kan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Empire Award for Best Male Newcomer. Àwọn eré míràn tí ó ti kópa ni m Terence Davies' "The Deep Blue Sea" (2012), Jim Jarmusch's romantic vampire film "Only Lovers Left Alive" (2013) àti Guillermo del Toro's "Crimson Peak" (2015).
Tom Hiddleston
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74110
74110
Samuel L. Jackson Samuel Leroy Jackson (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1948) jẹ́ òṣèré ọmọ orilẹ̀-èdè actor Amerika. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣèré tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní ìran rẹ̀ a, àwọn fíìmù tí ó ti ṣeré ti pa iye owó tí ó lé ní bílíọ́nù mẹ́tàdínlógún dọ́là ($27 billion), èyí mú kí ó jẹ́ òṣèré kejì tí àwọn eré rẹ̀ ti pa owó jù.. Ní ọdún 2022, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Honorary Award. Jackson bẹ̀rẹ̀ isẹ́ òṣèré perewu ní ọdún 1980 nígbà tí ó ṣeré nínú "Mother Courage and her Children" ní The Public Theatre. Láàrin ọdún 1981 sí ọdún 1983, ó ṣeré "A Soldier's Play" off-Broadway. Ó tún ṣeré nínú fíìmù "The Piano Lesson" ní ọdún 1987 ní Yale Repertory Theatre. Ó kópa Martin Luther King Jr. nínú fíìmù "The Mountaintop" (2011). Àwọn eré tí Jackson kọ́kọ́ ṣe ni "Coming to America" (1988), "Juice" (1992), "True Romance" (1993), "Menace II Society" (1993), àti "Fresh" (1994).
Samuel L. Jackson
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74111
74111
Chess Ayò Chess jẹ́ ayò tí a ma ń ta lórí tábìlì lábẹ́lé láàrín ònta ènìyàn méjì. Ònta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ma dá ayo wọn mọ̀ pẹ̀lú kí ìkan apá ilé kan dúdú kí ìkejì sì funfun. Àwọn ònta wọ̀nyí ni wọn yóò ma darí àwọn ayò tí wọ́n jẹ́ ikọ̀ ọmọ ogun ilé kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń pè ní chess pieces. Gbogbo ète àti èrò ònta kọ̀ọ̀kan ni kí ó fi ikọ̀ ọmọ ogun ayò tirẹ̀ pa ẹnìkejì rẹ̀ láyò tí wọ́n ń pè ní checkmate. Ṣáájú kí èyí tó wáyé, wọ́n gbọ̀dọ̀ dé tàbí pa Ọba tí ó jẹ́ olórí. Ibi tí ayò yí ti ṣẹ̀wá ni agbègbè chaturanga, tí ó wà ní ibi tí ó di orílẹ̀-èdè India lóní ní nkan bí ọ̀rùndún karùn ún sẹ́yìn. Àmọ́ òfin àti ìlànà títa ayò náà tí a ń ló títí di òní ni wọ́n gbé kalẹ̀ ní Yúróòpù ní nkan ní ọ̀rùndún keje sẹ́yìn tí gbogbo ayé sì tẹ́wọ́ gba òfin ati ìlànà yí títí di ìparí ọ̀rùndún kọkàndínlógún . Lóní, Chess jẹ́ ayò tí ó gbajú-gbajà jùlọ káàkiri àgbáyé tí ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn sì ń fi ayò náà ṣeré ọpọlọ. Ayò Chess jẹ́ ayò tí a ń fi ọgbọ́n inú ta tí ó sì nííṣe pẹ̀lú ìlànà tó mọ́yánlórí tí kò sì ní ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí kankan. Lórí àyà ayò ni a ti ma ń rí àwọn ọmọ ayò tí wọ́n jẹ́ mẹ́rìndínlógún ní apá ikọ̀ kọ̀ọ̀kan ma ń tó ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní ìwọ̀n 8×8. Ònta kọ̀ọ̀kan ma ń darí ọmọ ayò mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ń pè ní Chess piece. Nínú àwọn ọmọ ayò yí ni a ti ma ń rí Ọba, Olorì, róòkù méjì, báàọ́ọ́bù méjì, náìtì méjì, àti àwọn ọmọ ogun kékèké mẹ́jọ tí wọ́n ń pè ní pawns. Nínú ìlànà títa ayò yí, ònta tí ó bá mú ikọ̀ funfun ni yóò kọ́kó bẹ̀rẹ̀ títa ayò kí ònta kejì tí ó mú ikọ̀ ọmọ ogun dúdú ó tó ta tẹ̀le. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ònta méjèjì yí ní ó lè pa Ọba pẹ̀lú dídẹ pàkúté láti fi pa Ọba ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lójú ọpọ́n. Ayò yí lè pari pẹ̀lú pípa ọba tàbí kí wọ́n ta ọ̀mì níparí ìdíje ayò. Gbígbé ìdíje ayò Chess kalẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ ní àárín ọ̀rùndún kọkàndínlógún nígbà tí àjọ FIDE (the International Chess Federation) ń ṣe àbójútó ìdíje eré ìdárayá yí. Ẹni akọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ gba adé World Chess Champion, ni Wilhelm Steinitz ní ọdún 1886; nígbà tí ẹni tí ó di amì-ẹ̀yẹ náà mú lọ́wọ́ báyi ni Ding Liren. Orísiríṣi àjọ ni wọ́n ti gbérasọ láti ma ṣe agbátẹrù fún ìdíje eré ìdárayá Chess lágbàáyé, àwọn ènìyàn kan rí eré ìdárayá Chess gẹ́gẹ́ bí ọnà, ọ̀nà yí ni kò tún dúró lásán tí ó jàsí wípé ò nííṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ bíi: mathematics, computer science, àti psychology. Lára àfojúsùn àwọn òníọ̀ sayẹ́nsì láyé àtijọ́ ni kí wọ́n ṣẹ̀dá kọ̀mpútà tí yóò ma ta ayò Chess (chess-playing machine). Ní ọdún 1997, Deep Blue ni ó jẹ́ kọ̀mpútà akọ́kó tí yóò gbadé ẹni tí ó mọ ayò chess ta jùlọ lágbàáyé nígbà tí ó fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ Garry Kasparov tí òun náà jẹ́ kọ̀pútà gbolẹ̀. Láyé òde òní, ẹ̀rọ kọ̀mpútà ti di agbaọ̀jẹ̀ nínú kí á ta ayò Chess ju ọmọnìyàn lọ lágbàáyé. Èyí náà sì mú ìdàgbà-sókè bá ìlànà, agbékalẹ̀, títa ayò náà lágbàáyé. Àwọn òfin rẹ̀. Ofin ati ìlànà tí ó de títa ayò yí ni àjọ FIDE (Fédération Internationale des Échecs; "International Chess Federation"), tí wọ́n ṣe agbátẹrù fún eré ìdárayá yí lágbàáyé ti gbé kalẹ̀ nínú ìwé kan tí wọ́n pe ní "Handbook". Òfin yí ni wọ́n tún tari síta tí wọ́n sì tún ṣe àtúnyẹ̀wò rẹ̀ ní ọdún 2023. Àtòpọ̀ rẹ̀. Chess sets Èyí wá ní Àrà oríṣiríṣi : fún ìdíje, Staunton Chess Set ní ìlànà tí a máa ṣàmúlò rẹ̀ tàbí lò. Ọ̀nà méjì ní a máa ń gbà dá àwọn ọmọ inú Chess mọ ní wíwọ onírúurú èyí tí ó jẹ́ tàbí àwọ̀; èyí ní àwọ̀ funfun àti àwọ̀ dúdú, tí a tún lè pé ní Ṣẹ́ẹ̀sì Aláwọ̀ Dúdú àti funfun. Àwọn ẹni tí wọn ń tá Chess ni alè lé ní olúta Ṣẹ́ẹ̀sì tàbí aláyò, bákan náà ní àwon Ọmọ inú Ṣẹ́ẹ̀sì jẹ́ funfun tàbí dúdú. Tí Sẹ́ẹ̀tì Sẹ́ẹ̀sì jẹ́ mẹ́rìndínlógún tí àwọn ọmọ inú rẹ sí jẹ: Ọba kan, Olórí kan, Rúùkù méjì, Bíṣọ́bù méjì, Knight méjì, àti Pawns mẹ́jọ. A máa ń ta ayo ṣẹ́ẹ̀sì lórí pákó onígun Mẹ́rin tí ó ní Row Méjọ, Column mẹ́jọ. Nípa àpéjọpọ̀, àwọn onigun mẹrin tí ojú líla rẹ jẹ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ní àwọ̀ oríṣi méjì tí ó jẹ́ Funfun àti Dúdú; àwọn àwọ̀ tí ó wọ́pọ̀ fún Ayò Ṣẹ́ẹ̀sì jẹ́ funfun àti brown, tàbí funfun àti àwọ̀ ewé. Àwọn ọmọ inú ayò Ṣẹ́ẹ̀sì ni ó wà ní ojú àwòrán yìí ní òkè. Amò láti ipò kíní tí ó jẹ́ àwọ̀ Funfun, láti apá òsì dé ọ̀tún: àwọn ọmọ náà sì ni: Rook, Knight, Bíṣọ́bù, Olorì, Ọba, Bíṣọ́bù, Knight àti Rook. Pawn méjọ ní o wà ní ipò Kejì. Àwọn àwọ̀ dúdú sí wà ní òdìkejì bí àti to fúnfún, tí ó sí jẹ́ ìkanáà . Pákó Sẹ́ẹ̀sì náà wà ní apá òtún tí ó súnmọ́ ọwọ́ Aláyò. Ipò tí Ọba àti Olorí gbọ́dọ̀ wà ìbamu pẹlú ọ̀rọ̀ kàn tí wọn máa ǹ so pé "Olorì lórí aye rẹ̀", tí ó túmọ̀ sí pé Olorì funfun lori àwọ̀ funfun, Olorì dúdú lórí àwọ̀ dúdú). Nínú ìdíje, àwọn Olùsètò ìdíje ní wọn yóò fún àwọn Olùdíje ní ọmọ ayò Ṣẹ́ẹ̀sì; tí ó bá jẹ́ fún ìdárayá lásán, àwọn olùta a máa lo sísọ Coin sókè, tàbí kí wọn fí pawn dudu àti fúnfún sí ọwọ́ méjẹ̀jjì kí àwọn olùta mú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, èyí tí oníkálukú bá mú ní wọn yóò fi ta ayò náà. Bí a ṣe ń gbé ayò. Funfun ni yó kókó gbéra, lẹyìn tí àwọn ìyókù ó sì tẹ̀le, wọ́n sì ma n gbéra ní kọ̀kan. Àwọn tí ó ta ayò yìí le gbé ayò náà sí ojúgun tí ayò míràn kò sí tàbí ibi tí ayò olùtakò wà, eléyìí á sì mú kí a yọ ayò náà kúrò. Kí kúrò láti ojúgun kan sí òmíràn ṣe pàtàkì; ẹni tí ó tayò gbọ́dọ̀ gbé ọkàn lára àwọn ayò rẹ̀ síbò míràn lẹ́yìn tí olùtakò rẹ̀ tí gbé ayò. Oríṣiríṣi ayò ní bí wọ́n ṣe ma ń gbe. Pípa ọmọ ayò. <ns>10</ns> <id>16733</id> <revision> <id>534273</id> <parentid>122075</parentid> <timestamp>2020-05-17T15:21:13Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Nígbà tí ọba bá wà ní inú ewu, wọn á sọ wípé Check. Ọ̀nà tí ọba lè gbà bọ́ lọ́wọ́ ewu ni kí ó ó kúrò ní ojú ibi tí ó wà kí ẹ̀mí rẹ̀ lè dè. Ọ̀nà mẹ́ta ni wọ́n lè gbà bò lọ́wọ́ ewu kí ó sì jà padà. check". A move in response to a check is legal only if it results in a position where the king is no longer in check. There are three ways to counter a check: Castling is not a permissible response to a check. The object of the game is to checkmate the opponent; this occurs when the opponent's king is in check, and there is no legal way to get it out of check. It is never legal for a player to make a move that puts or leaves the player's own king in check. In casual games, it is common to announce "check" when putting the opponent's king in check, but this is not required by the rules of chess and is usually not done in tournaments.
Chess
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74112
74112
Josh Brolin Josh James Brolin (; tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejì ọdún 1968) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Josh jẹ́ ọmọ James Brolin, ó sì di gbajúmọ̀ nígbà tí ó ṣeré nínú fíìmù "The Goonies" (1985). Lẹ́yìn òpò ọdún, Brolin tún ṣeré nínú fíìmù "No Country for Old Men" (2007). Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Award for Best Supporting Actor fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Dan White nínú "Milk" (2008). Brolin gbajúmọ̀ si nígbà tí ó kó ipa Thanos nínú àwọn fíìmù Marvel Cinematic Universe, àwọn bi ' (2018) àti ' (2019), àti gẹ́gẹ́ bi Cable fún "Deadpool 2" (2018). Àwọn fíìmù míràn tí ó ti ṣeré ni "W." (2008), gẹ́gẹ́ bi Jonah Hex nínú fíìmù "Jonah Hex (2010)", "True Grit" (2010), "" (2010), "Men in Black 3" (2012) gẹ́gẹ́ bi Agent K, "Oldboy" (2013), "Inherent Vice" (2014), "Everest" (2015), "Sicario" (2015), "Hail, Caesar!" (2016), àti nínú "Dune" (2021). Ní ọdún 2022, Brolin ṣeré nínú fíìmù "Outer Range".
Josh Brolin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74113
74113
Letitia Wright Letitia Michelle Wright (tí a bí ní ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ̀wá ọdún 1993) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Guyana mọ́ Britain. Ó bẹ̀rẹ̀ isẹ́ òṣèré pẹ̀lú àwọn fíìmù bi "Top Boy", "Coming Up", "Chasing Shadows", "Humans", "Doctor Who", àti "Black Mirror". Wọ́n yàn sí ara àwọn tí ó tó sí àmì-ẹ̀yẹ Primetime Emmy Award. Ó di gbajúmọ̀ nígbà tí ó ṣeré nínú fíìmù "Urban Hymn tí ó jáde ní ọdún 2015," èyí tí ó sì gba àmì ẹyẹ British Academy of Film and Television Arts (BAFTA) fún. Ní ọdún 2018, ó di gbajúmọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè nígbà tí ó kó ipa Shuri nínú fíìmù Marvel Cinematic Universe, "Black Panther", èyí tí ó sì gba àmì ẹyẹ NAACP Image Award àti SAG Award fún. Ó tún kó ipa náà nínú fíìmù ' (2018), ' (2019), àti "" (2022). Ní ọdún 2019, ó gba àmì-ẹ̀yẹ BAFTA Rising Star Award. Ó tún kó ipa nínú "Small Axe", èyí tí ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Satellite Award fún.
Letitia Wright
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74114
74114
Youtube YouTube jẹ pinpin fidio ori ayelujara ti Amẹrika ati ipilẹ ẹrọ awujọ awujọ ti o wa ni San Bruno, California, Amẹrika. Wiwọle si agbaye, ti ṣe ifilọlẹ ni Kínní 14, 2005, nipasẹ Steve Chen, Chad Hurley, ati Jawed Karim. O jẹ ohun ini nipasẹ Google ati pe o jẹ oju opo wẹẹbu keji ti a ṣabẹwo julọ, lẹhin wiwa Google. YouTube ni diẹ ẹ sii ju 2.5 bilionu awọn olumulo oṣooṣu, ti o n wo awọn fidio ti o ju bilionu kan lọ lojoojumọ. Ni Oṣu Karun ọdun 2019, awọn fidio ti n gbejade ni iwọn diẹ sii ju awọn wakati 500 ti akoonu fun iṣẹju kan. Ni Oṣu Kẹwa Ọdun 2006, Google ra YouTube fun $1.65 bilionu. Ohun ini Google ti YouTube faagun awoṣe iṣowo aaye naa, ti n pọ si lati jijẹ owo-wiwọle lati awọn ipolowo nikan si fifun akoonu isanwo gẹgẹbi awọn fiimu ati akoonu iyasọtọ ti YouTube ṣe. O tun funni ni Ere YouTube, aṣayan ṣiṣe alabapin sisan fun wiwo akoonu laisi ipolowo. YouTube tun fọwọsi awọn olupilẹṣẹ lati kopa ninu eto AdSense Google, eyiti o n wa lati ṣe ina owo-wiwọle diẹ sii fun ẹgbẹ mejeeji. YouTube royin wiwọle ti $29.2 bilionu ni ọdun 2022. Ni ọdun 2021, owo-wiwọle ipolowo ọdọọdun YouTube pọ si $28.8 bilionu, ilosoke ninu owo-wiwọle ti 9 bilionu lati ọdun iṣaaju. Niwon rira rẹ nipasẹ Google, YouTube ti fẹ siwaju si oju opo wẹẹbu pataki sinu awọn ohun elo alagbeka, tẹlifisiọnu nẹtiwọọki, ati agbara lati sopọ pẹlu awọn iru ẹrọ miiran. Awọn ẹka fidio lori YouTube pẹlu awọn fidio orin, awọn agekuru fidio, awọn iroyin, awọn fiimu kukuru, awọn fiimu ẹya, awọn orin, awọn iwe itan, awọn tirela fiimu, awọn teasers, awọn ṣiṣan ifiwe, awọn vlogs, ati diẹ sii. Pupọ akoonu jẹ ipilẹṣẹ nipasẹ awọn ẹni-kọọkan, pẹlu awọn ifowosowopo laarin YouTubers ati awọn onigbọwọ ajọ. Awọn ile-iṣẹ media ti iṣeto bi Disney, Paramount, NBCUniversal, ati Warner Bros. Awari ti tun ṣẹda ati faagun awọn ikanni YouTube ajọ wọn lati polowo si olugbo nla. YouTube ti ni ipa awujọ ti a ko tii ri tẹlẹ, ni ipa lori aṣa olokiki, awọn aṣa intanẹẹti, ati ṣiṣẹda awọn olokiki oloye-pupọ. Laibikita idagbasoke ati aṣeyọri rẹ, o ti ṣofintoto pupọ fun ẹsun ni irọrun itankale alaye ti ko tọ ati pinpin akoonu ti aladakọ, ilodi si ni igbagbogbo awọn aṣiri awọn olumulo rẹ, ṣiṣe ihamon muu, ati fifi aabo ati alafia ọmọ lewu, ati fun awọn itọsọna rẹ ati bii wọn ṣe ṣe imuse.
Youtube
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74115
74115
Simu Liu Simu Liu ( ; ; tí a bí ní ọjọ́ kandínlógún oṣù Kerin ọdún 1989) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Kanada. Ó gbajúmọ̀ fún kíkọ́ ipa Shang-Chi nínú fíìmù Marvel Cinematic Universe, "Shang-Chi and the Legend of the Ten Rings" tí ó jáde ní ọdún 2021. Ó tún kó ipa gẹ́gẹ́ bi Jung Kim nínú fíìmù CBC Television "Kim's Convenience" ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ ACTRA Award àti Canadian Screen Awards fún ipa rẹ̀ nínú "Blood and Water". Ní ọdún 2022, Liu ko ìwé "We Were Dreamers", "Time" sì pè é ní ará àwọn òṣèré ọgọ́rùn-ún tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní àgbáyé.
Simu Liu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74116
74116
Ben Affleck Benjamin Géza Affleck (tí a bí ní ọjọ́ keedógún oṣù kẹjọ ọdún 1972) jẹ́ òṣèré àti aṣe fíìmù ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó tì gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Awards fún àwọn fíìmù rẹ̀. Affleck bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré láti ìgbà èwe nígbà tí ó ṣeré nínú eré PBS tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "The Voyage of the Mimi" (1984, 1988). Ó tún padà ṣeré nínú "Dazed and Confused" (1993) àti àwọn eré àwàdà míràn tí Kevin Smith ṣe, àwọn eré bi "Chasing Amy" (1997). Affleck tún gbajúmọ̀ si nígbà tí òun àti Matt Damon gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Award for Best Original Screenplay fún kíkọ "Good Will Hunting" (1997). Ó tún ṣeré nínú àwọn fíìmù bi "Armageddon" (1998), "Pearl Harbor" (2001), "The Sum of All Fears" àti "Changing Lanes" (both 2002). Lẹ́yìn ìgbà tí ó dàbí pé isẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré fẹ́ ma lọlẹ̀, ó tún padà sọ jí nígbà tí ó kó ipa George Reeves nínú fíìmù "Hollywoodland" (2006), ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Volpi Cup for Best Actor. Àwọn eré tí ó ti dárí ni "Gone Baby Gone" (2007), "The Town" (2010) àti "Argo" (2012).
Ben Affleck
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74117
74117
Àgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Abadam Abadam jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Ìjọba ìbílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Borno, Nàìjíríà, ní apá ìwọ oòrùn Lake Chad. Àwọn àlà rẹ̀ ni Chad àti Niger, ó sì sún mọ́ Cameroon, ní ọdún 2016, àwọn olùgbé rẹ̀ tó 140,000 Olú ìlú rẹ̀ wà ní Malumfatori. Ètò àbò àti ìlera ara wà lára àwọn ìdojúkọ ní agbẹ̀gbẹ̀ ìjọba ìbílẹ̀ Abadam. Abadam ní ilẹ̀ tí ó tó 3,973 km2
Àgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Abadam
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74118
74118
Àgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀
Àgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74119
74119
Jared Leto Jared Joseph Leto ( ; tí a bí ní ọjọ́ kẹrindínlógbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1971) jẹ́ òṣèré àti olórin ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ nínú iṣẹ́ òṣèré tí ó ti ń ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn àmì ẹyẹ bi Academy Award àti Golden Globe Award. Pẹ̀lú pẹ̀lú, ó gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ orin kíkó gẹ́gẹ́ bi ara àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rock band Thirty Seconds to Mars. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré nínú fíìmù "My So-Called Life" (1994), Leto ṣeré nínú "How to Make an American Quilt" (1995), ó sì gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù "Prefontaine" (1997). Ó tún ṣeré nínú àwọn fíìmù bi "The Thin Red Line" (1998), "Fight Club" (1999), "Girl, Interrupted" (1999) àti "American Psycho" (2000). Leto gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyìn ipa rẹ̀ nínú "Requiem for a Dream" (2000). Lẹ́yìn èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí ń gbajúmọ́ isẹ́ orin kí ó tó padà sí isẹ́ òṣèré pẹ̀lú "Panic Room" (2002), "Alexander" (2004), "Lord of War" (2005), "Chapter 27" (2007), àti "Mr. Nobody" (2009). Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Award for Best Supporting Actor fún ipa rẹ̀ nínú "Dallas Buyers Club" (2013). Láàrin ọdún 2016 sí 2022, ó ṣeré nínú àwọn fíìmù bi "Suicide Squad" (2016), "Blade Runner 2049" (2017), "The Little Things" (2021), "House of Gucci" (2021), àti "Morbius" (2022).
Jared Leto
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74120
74120
Terence Stamp Terence Henry Stamp (tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù keje ọdún ) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi alátakò nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe Award, Cannes Film Festival, àti Silver Bear wọ́n sì yán kún ara àwọn tí ó tó fún àmì-ẹ̀yẹ Academy Award àti BAFTA Awards méjì. Lẹ́yìn ìgbà tí ó kó ẹ̀kọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ eré Webber Douglas Academy of Dramatic Art ní London, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré ní ọdún 1962. Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀, mú kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Award àti BAFTA fún Best Newcomer. Ó ṣeré pẹ̀lú òṣèré Christie nínú eré "Far from the Madding Crowd" (1967). Ọ́ tún gbajúmọ̀ sí nígbà tí ó kó ipa General Zod nínú eré "Superman" (1978) àti "Superman II" (1980). Ipa rẹ̀ nínú eré "The Adventures of Priscilla, Queen of the Desert" (1994) mú kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ BAFTA Award ó sì tún mú kí wọ́n yán mó ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Golden Globe Award. Lẹ́yìn èyí, ó ṣeré nínú eré "The Limey" (1999) èyí tí ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Independent Spirit Award fún. Àwọn fíìmù míràn tí ó ti ṣeré ni "" (1999), "The Haunted Mansion" (2003), "Elektra" (2005), "Wanted" (2008), "Get Smart" (2008), "Yes Man" (2008), "Valkyrie" (2008), "Big Eyes" (2014) àti "Last Night in Soho" (2021).
Terence Stamp
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74121
74121
Brandon Routh Brandon James Routh (; tí a bí ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kẹ̀wá ọdún 1979) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ṣeré Superman nínú fíìmù 2006 film "Superman Returns", èyí tí ó mú kí ó gbajúmọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè. Ní ọdún 2011, ó ṣeré nínú fíìmù "". Ó tún kó ipa Daniel Shaw nínú fíìmù NBC tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Chuck". Ara àwọn eré míràn tí Routh ti kópa ni "Zack and Miri Make a Porno" àti "Scott Pilgrim vs. the World". Ní ọdún 2014, ó kó ipa Ray Palmer / The Atom nínú eré "Arrow". Ó tún kó ipa kan náà nínú Arrowverse shared universe: "The Flash" àti "Legends of Tomorrow".
Brandon Routh
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74122
74122
Antje Traue Antje Traue (]; tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kínní ọdún 1981) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Jámánì. Ó ṣeré nínú fíìmù Gẹ̀ẹ́sì fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí ó ṣeré nínú "Pandorum". Ó di gbajúgbajà káàkiri àgbáyé nígbà tí ó ṣeré nínú gẹ́gẹ́ bi Faora nínú fíìmù "Man of Steel" (2013) àti "The Flash" (2023), àti gẹ́gẹ́ bi Agnes Nielsen nínú eré Netflix kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Dark".
Antje Traue
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74123
74123
Billy Crudup William Gaither Crudup (; tí a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù keje ọdún 1968) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ-èdè Amẹ́ríkà. Ipá rẹ̀ nínú fíìmù "Jesus' Son" (1999) jẹ́ kí wón yàn mọ́ àwọn tí ó tó sí Independent Spirit Award for Best Male Lead. Ó tún ṣeré nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bi "Almost Famous" (2000), "Big Fish" (2003), ' (2006), "Watchmen" (2009), "Public Enemies" (2009), "The Stanford Prison Experiment" (2015), "Jackie" (2016), àti ' (2017). Crudup gba àmì-ẹ̀yẹ Tony Award fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù Tom Stoppard tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "The Coast of Utopia" (2007). Ó tún ti ṣeré nínú àwọn eré bi "Gypsy" (2017), "The Morning Show" (2019), èyí tí ó mú kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ Primetime Emmy Award àti Critics' Choice Television Award.
Billy Crudup
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74124
74124
Adewale Akinnuoye-Agbaje Adewale Akinnuoye-Agbaje ( ; tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1967) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Simon Adebisi nínú eré "Oz", Mr. Eko nínú "Lost", Lock-Nah nínú "The Mummy Returns", Nykwana Wombosi nínú "The Bourne Identity", Heavy Duty nínú ', Kurse nínú ', Killer Croc nínú "Suicide Squad", Malko nínú "Game of Thrones", Dave Duerson nínú "Concussion", àti Ogunwe nínú "His Dark Materials". Eré àkọ́kọ́ tí Akinnuoye-Agbaje's dárí ni "Farming", wrapped production in 2017.
Adewale Akinnuoye-Agbaje
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74125
74125
Laurence Fishburne Laurence John Fishburne III (tí a bí ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù keje ọdún 1961) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ Emmy Award ní ẹ̀mẹ́ta tí àti àmì ẹyẹ Tony Award. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Morpheus nínú "The Matrix" series (1999–2003), Jason "Furious" Styles nínú eré John Singletontí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Boyz n the Hood" (1991), Tyrone "Mr. Clean" Miller nínú eré Francis Ford Coppola tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Apocalypse Now" (1979), àti gẹ́gẹ́ bi "The Bowery King" nínú "John Wick" film series (2017–títí I di ìsinsìnyí). Fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Ike Turner nínú "What's Love Got to Do With It" (1993), Fishburne wà lára àwọn tí wọ́n yàn pé ó tó sí àmì ẹyẹ Academy Award for Best Actor. Ó tún gba àmì-ẹ̀yẹ Tony Award for Best Featured Actor in a Play fún ipa rẹ̀ nínú "Two Trains Running" (1992), àti Emmy Award for Outstanding Guest Actor in a Drama Series fún ipa rẹ̀ ní "TriBeCa" (1993).
Laurence Fishburne
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74126
74126
Joel Olaniyi Oyatoye Ọmọ Ọba Joel Ọláníyì Ọyátóyè tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Bàbá Àṣà", jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Kánádà, ó jẹ́ akọ ewì, olùgbóhùnsafẹ́fẹ́, oníṣẹ́ ara-ẹni, ajíyìnrere, olùpolongo àti olùgbélárúgẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá. Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀. Wọ́n bí Ọláníyì ní Ìpínlẹ̀ Kwara ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni 27 January, 1984 níbi tí ó ti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ṣáájú kí ó tó lọ sí orílẹ̀-èdè Canada láti lọ tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ọyátóyè tí ó jẹ́ ọmọọba nífẹ́ sí gbígbé àṣà Yorùbá lárugẹ jákè-jádò agbáyé, pàá pàá jùlọ bí ó ṣe ma ń wọ aṣọ ìbílẹ̀ tí ó sì ń lo gbogbo ohun èlò ìbílẹ̀ Yorùbá láti fi pàtàkì àṣà Yorùbá hàn fáyé rí. Ọyátóyè jẹtọ́ àṣà òun ìgbéga Yorùbá láti kékeré láti ara bàbá rẹ̀ Olóyè Titus Ọyátóyè Títíloyè tí ó ti dolóògbé. Iya re Cicilia Oyatoye Iṣẹ́ rẹ̀. Ọyátóyè ṣàkíyèsí wípé iná àṣà àti ìṣe Yorùbá ti ń jó àjórẹ̀yìn, èyí kò sì bójúmu, àìbìkítà sí ìgbéga àṣà òun ìṣe Yorùbá lè ṣakóbá fún láti ròkun ìgbagbé. Èyí ni ó múmú láyà rẹ̀ tí ó fi ń gbé àdá Yorùbá lárugẹ. Ifẹ́ rẹ̀ sí èdè Yorùbá ni ó mu kọ́ṣẹ́ nípa ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ láti lè ma polongo ohun ina àjogúnbá Yorùbá lórí afẹ́fẹ́. Ó ti ṣe àwọn ìṣeẹ́ àkànṣe nípa èdè, àṣà Yorùbá gẹ́gẹ́ olùgbóhùnsafẹ́fẹ́ pàá pàá jùlọ lórí àwọn ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ bíi: Paramount FM tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta, Radio Lagos tí ó wà ní ìlú Ìkẹjà, Choice FM . Ó gbajúmọ̀ fún [[ewì][ kíké, [[Rárá]] sísun, [[ìjálá]], [[ẹkún ìyàwó]] sísun àti [[oríkì]] kíké. Láti lè mú èrò àti àlá rẹ̀ ṣẹ, ó gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè Canada láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ mọ. Ó lọ ilé ẹ̀kọ́ Red River College, àti Academic College tí àwọn méjèjì wà ní agbègbè Winnipeg ní ìlú Canada, O ko eko nipa Eto isiwa (Immigration Consultant) ni Ashton College British Columbia Canada. Ó ti ṣisẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ààbò "Impact Security láàrín ọdún 2013 sí 2015, bákan náà ni ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú St Amant láàrín ọdún 2013 sí 2020 ní orílẹ̀-èdè Canada. Lati 2020 o ti n sise Ara re. O je Aare ati Oludasile Egbe ti a n pe ni Asa Day Worldwide Inc. Canada, ti n se igbe laruge Asa Yoruba kakiri agbaye, Oun si tun ni Oludasile ati alamojuto Asa Day Museum ni Canada.
Joel Olaniyi Oyatoye
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74127
74127
Joel Olaniyi Owatoye
Joel Olaniyi Owatoye
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74128
74128
Joel Olaniyi Ọyátóyè
Joel Olaniyi Ọyátóyè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74129
74129
Peter Sarsgaard John Peter Sarsgaard (; tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1971) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ṣeré fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú eré "Dead Man Walking" ní ọdún 1995. Ó tún ṣeré nínú fíìmù independent tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Another Day in Paradise" àti nínú "Desert Blue". Ní ọdún kan náà, Sarsgaard kópa Raoul nínú eré "The Man in the Iron Mask" (1998). Sarsgaard padà di gbajúmọ̀ nígbà tí ó kópa John Lotter nínú eré "Boys Don't Cry" (1999). Fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Charles Lane nínú erẹ́ "Shattered Glass", wọ́n yan Sarsgaard mọ́ ara àwọn tí ó tọ́sí àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe Award for Best Supporting Actor. Sarsgaard ti ṣeré nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré, bí àpẹẹrẹ: "" (2002), "Garden State", "Kinsey" (both 2004), "Jarhead" (2005), "Flightplan" (2005), "Elegy" (2008), "An Education" (2009), "Lovelace" (2013), "Night Moves" (2013), "Blue Jasmine" (2013), "Black Mass" (2015), "Jackie" (2016), àti "The Lost Daughter" (2021). Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú àwọn eré "Green Lantern" (2011), "Knight and Day" (2010), "The Magnificent Seven" (2016) àti "The Batman" (2022).
Peter Sarsgaard
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74130
74130
Jeffrey Dean Morgan Jeffrey Dean Morgan (tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹrin ọdún 1966) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Negan nínú fíìmù AMC horror drama tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "The Walking Dead" (2016–2022), àti nínú "" (2023-present), ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríyìn fún ipa rẹ̀ nínú eré yìí. Àwọn eré míràn tí ó ti farahàn ni gẹ́gẹ́ bi John Winchester ní eré the CW tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ "Supernatural" (2005–2007; 2019), gẹ́gẹ́ bi Denny Duquette nínú eré ABC tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Grey's Anatomy" (2006–2009), gẹ́gẹ́ bi Jason Crouse nínú eré CBS tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ gẹ́gẹ́ bi "The Good Wife" (2015–2016), aláwadà nínú "Watchmen" (2009), àti nínú àwọn eré bi "P.S I Love You (2007)", "The Losers" (2010), "Red Dawn" (2012),àti "Rampage" (2018).
Jeffrey Dean Morgan
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74131
74131
Hilarie Burton Hilarie Ros Burton (tí a bí ní ọjọ́ kínní oṣù keje ọdún 1982), tí àwọn mìíràn mọ̀ sí Hilarie Burton Morgan, jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti fi ìgbàkan jẹ́ olótùú fún ètò MTV tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Total Request Live", ó ṣeré gẹ́gẹ́ bi Peyton Sawyer nínú eré WB àti CW tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "One Tree Hill" (2003–2009). Lẹ́yìn "One Tree Hill", Burton ṣeré nínú "Our Very Own", "Solstice", àti "The List". Ó tún kó ipa Sara Ellis nínú eré "White Collar" (2010–2013), Dr. Lauren Boswell nínú ABC medical drama "Grey's Anatomy" (2013), Molly Dawes nínú eré ABC pẹ̀lú àkọ́lé "Forever" (2014), àti gẹ́gẹ́ bi Karen Palmer nínú Fox, bákan náà ó farahàn nínú "Lethal Weapon" (2016). Burton jẹ́ ara àwọn olóòtú ètò "Drama Queens" òun pẹ̀lú Sophia Bush àti Bethany Joy Lenz.
Hilarie Burton
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74132
74132
Amy Adams Amy Lou Adams (tí a bí ní ọjọ́ ogún oṣù kẹjọ ọdún 1974) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó gbajúmọ̀ fún apepe àti àwàdà nínú àwọn eré tí ó ma ń ṣe, ó wà lára àwọn òṣèrébìnrin tí wọ́n ń san owó fún jùlọ ní àgbáyé. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ, àmì-ẹ̀yẹ bi Golden Globe Awards méjì, wọ́n sì yán ní emefà mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Academy Awards, ní emeje mọ́ ara àwọn tí ó tó sí British Academy Film Awards, àti ní emejì mọ́ ara àwọn tí ó tó sí Primetime Emmy Awards. Adams bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi oníjó ní gbọ̀ngán oníjó láàrin ọdún 1994 sí 1998, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré nígbà àkọ́kọ́ nínú eré "Drop Dead Gorgeous" (1999). Láti ìgbà náà, ó ti ṣeré nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bi "mean girl", "Catch Me If You Can" (2002), "Junebug" (2005) - èyí tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ Academy Award fún. Àwọn eré míràn tí ó ti farahàn ni "Enchanted" (2007), "Doubt" (2008), "The Fighter" (2010), "The Master" (2012), "American Hustle" (2013), "Big Eyes" (2014), "Arrival" (2016), "Sharp Objects" (2018), "Vice" (2018). Láàrin ọdún 2017,ó kó ipa Lios Lane nínú àwọn eré DC extended universe.
Amy Adams
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74133
74133
Cillian Murphy Cillian Murphy ( ; tí a bí ní ọjọ́ kàrúnlélógún oṣù Kàrún ọdún 1976) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Ireland. Ó ṣeré fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú eré Enda Walsh ltí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Disco Pigs" ní ọdún 1996. Àwọn eré míràn tí ó ti farahàn ni "28 Days Later" (2002), nínú "Intermission" (2003), "Red Eye" (2005), "The Wind That Shakes the Barley" (2006), "Sunshine" (2007). Ó seré nínú eré Breakfast on Pluto" (2005), èyí tí ó mú kí wọ́n yán kún ara àwọn ti ó tó sí Golden Globe Award. Murphy bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Christopher Nolan ní ọdún 2005, ó kó ipa Dr. Jonathan Crane / Scarecrow nínú eré "The Dark Knight Trilogy" (2005–2012), nínú "Inception" (2010), "Dunkirk" (2017), àti gẹ́gẹ́ bi J. Robert Oppenheimer nínú "Oppenheimer" (2023). Ó gbajúmọ̀ si nígbà tí ó ṣeré gẹ́gẹ́ bi Tommy Shelby nínú eré BBC tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Peaky Blinders" (2013–2022) àti nígbà tí ó ṣeré nínú "A Quiet Place Part II" (2020).
Cillian Murphy
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74134
74134
Aaron Eckhart Aaron Edward Eckhart (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹta ọdún 1968) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n bi ní Cupertino, California, Eckhart lọ sí orílẹ̀ èdè United Kingdom nígbà tí ó wà ní èwe. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nígbà tí ó sì wà ní ilé ìwé kí ó tó lọ sí Australia. Ó fi Ilé-ìwé High School kalẹ̀ láì gba ìwé ẹrí ṣùgbọ́n ó padà gba àmì-ẹ̀yẹ diploma, ó sì kàwé gboyẹ̀ ní Yunifásitì Brigham Young (BYU) ní Utah, U.S., ní ọdún 1994 pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ Bachelor of Fine Arts nínú eré ṣíṣe. Nígbà tí ó sì jẹ́ ọmọ ilé ìwé ní BYU, Eckhart pàdé adarí eré Neil LaBute. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn ìgbà náà, Eckhart nínú eré LaBute tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ black comedy ní "In the Company of Men" (1997), ó sì padà farahàn nínú eré mẹta míràn tí Neil dárí. Eckhart gbajúmọ̀ sí nígbà tí ó kó ipa George nínú eré "Erin Brockovich" (2000), àti ní 2006, wọ́n yán mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Golden Globe fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Nick Naylor nínú "Thank You for Smoking". Ní ọdún 2008, ó ṣeré nínú eré Christopher Nolan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Batman "The Dark Knight" gẹ́gẹ́ bi Harvey Dent / Two-Face. Ní ọdún 2019, ó ṣeré nínú eré Roland Emmerich tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Midway".
Aaron Eckhart
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74135
74135
Guosa Guosa jẹ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí a kọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ látọwọ́ Alex Igbineweka ní 1965. A ṣe é láti jẹ́ àkópọ̀ àwọn èdè ìbílẹ̀ Nàìjíríà àti láti sìn gẹ́gẹ́ bí èdè kan sí Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.
Guosa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74136
74136
Morena Baccarin Morena Silva de Vaz Setta Baccarin (]; tí a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kẹfà ọdún 1979) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Inara Serra nínú eré "Firefly" àti "Serenity", gẹ́gẹ́ bi Vanessa nínú eré "Deadpool", Jessica Brody nínú eré Showtime tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Homeland", Dr. Leslie "Lee" Thompkins nínú eré Foxtí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Gotham", àti gẹ́gẹ́ bi Elena Federova "The Endgame". Fún ipa rẹ̀ nínú "Homeland", ó wà lára àwọn tí wọ́n yàn pé ó tó sí ọ̀kan lára àwọn àmì ẹyẹ Primetime Emmy Award ní ọdún 2013.
Morena Baccarin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74137
74137
Malin Akerman Malin Maria Åkerman (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù karùn-ún ọdún 1978) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè Sweden. Ní àárín ọdún 2003 sí 2004, ó farahàn nínú eré "The Utopian Society" (2003) àti "Harold & Kumar Go to White Castle" (2004). Lẹ́yìn ìgbà tí ó farahàn nínú eré HBO tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "The Comeback" (2005), ó farahàn nínú àwọn eré bi "The Heartbreak Kid" (2007), "27 Dresses" (2008), "The Invasion" (2007). Ó kó ipa Silk Spectre II nínú eré "Watchmen" (2009), èyí sì mú kí wọ́n yàn án mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Saturn Award Ní ọdún 2009, Åkerman ṣeré nínú "The Proposal" àti "Couples Retreat". Láàrin ọdún 2010 sí 2016, ó ṣeré nínú eré àwàdà Adult Swim tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Childrens Hospital". Àwọn eré míràn tí ó ti farahàn ni "Wanderlust", "Rock of Ages", "Trophy Wife" (2013–2014), "I'll See You in My Dreams" (2015), "Rampage" (2018) àti nínú "Billions" gẹ́gẹ́ bi Lara Axelrod.
Malin Akerman
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74138
74138
Liam Neeson William John Neeson (born 7 June 1952) jẹ́ òṣèré ọmọ orilẹ̀-èdè Northern Ireland. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríyìn bi àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe Awards mẹ́ta àti Tony Awards méjì. Ní ọdún 2020, ó jẹ́ ipò keje nínú àwọn òṣèré tí "The Irish Times" so wípé ó gbajúmọ̀ jùlọ. Wọ́n fún Neeson ní ipò Officer of the Order of the British Empire (OBE) ní ọdún 2000. Ní ọdún 1976, Neeson darapọ̀ mọ́ Lyric Players' Theatre ní ìlú Belfast fún ọdún méjì. Àwọn eré tí ó ti kọ́kọ́ farahàn ni "Excalibur" (1981), "The Bounty" (1984), "The Mission" (1986), "The Dead Pool" (1988), and "Husbands and Wives" (1992).
Liam Neeson
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74139
74139
Mark Strong Mark Strong (orúkọ àbísọ rẹ̀ ni Marco Giuseppe Salussolia;tí a bí ní ọjọ́ Kàrún-ún oṣù kẹjọ ọdún 1963) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britian tí ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Prince Septimus ní "Stardust" (2007), Archibald ní "RocknRolla" (2008), Lord Henry Blackwood nínú "Sherlock Holmes" (2009), Frank D'Amico nínú "Kick-Ass" (2010), Jim Prideaux nínú "Tinker Tailor Soldier Spy" (2011), Sinestro in "Green Lantern" (2011), George in "Zero Dark Thirty" (2012), Major General Stewart Menzies nínú "The Imitation Game" (2014), Merlin nínú ' (2014) àti ' (2017), Dr. Thaddeus Sivana nínú "Shazam!" (2019) àti "Shazam! Fury of the Gods" (2023), àti gẹ́gẹ́ bi John nínú "Cruella" (2021).
Mark Strong
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74140
74140
Temuera Morrison Temuera Derek Morrison (tí a bí ní ọjọ́ kẹríndínlógbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1960) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè New Zealand tí ó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀ èdè fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Dr. Hone Ropata nínú eré "Shortland Street". Ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Jake "The Muss" Heke nínú eré "Once Were Warriors" tí ó jáde ní ọdún 1994 àti "What Becomes of the Broken Hearted?" tí ó jáde ní ọdún 1999. Ní àwọn orílẹ̀ èdè míràn Morrison gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ Jango Fett àti Boba nínú àwọn eré "Star Wars". Òun ni ó kọ́kọ́ kó ipa Jango nínú eré "Attack of the Clones" tí ó jáde ní ọdún 2002. Àwọn eré míràn tí Morrison ti ṣeré ni "The Empire Strikes Back", gẹ́gẹ́ bi Boba nínú "The Mandalorian" (2019–títí di ìsinsìnyí), "The Book of Boba Fett" (2021–2022), "Echo 3", gẹ́gẹ́ bi Tom Curry nínú "Aquaman" (2018), "The Flash" àti "Aquaman and the Lost Kingdom".
Temuera Morrison
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74141
74141
Carla Gugino Carla Gugino ( ; tí a bí ní ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1971) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó farahàn nínú eré "Troop Beverly Hills" (1989) àti "This Boy's Life" (1993), ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Ingrid Cortez nínú eré Spy Kids (2001–2003), Rebecca Hutman nínú "Night at the Museum" (2006), Laurie Roberts nínú "American Gangster" (2007), Det. Karen Corelli nínú "Righteous Kill" (2008), Dr. Alex Friedman nínú "Race to Witch Mountain" (2009), Sally Jupiter in "Watchmen" (2009), Dr. Vera Gorski nínú "Sucker Punch" (2011), Amanda Popper nínú "Mr. Popper's Penguins" (2011), Emma Gaines nínú "San Andreas" (2015), àti gẹ́gẹ́ bi Jessie Burlingame nínú "Gerald's Game" (2017). Gugino tún kó ipa nínú eré the "Karen Sisco" (2003), "Threshold" (2005–2006), "The Haunting of Hill House" (2018), nínú "Jett" (2019), ó sì tún farahàn nínú "The Haunting of Bly Manor" (2020).
Carla Gugino
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74142
74142
Yusuf Lule Yusuf Kironde Lule (10 April 1912 – 21 January 1985) fìgbà kan jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti orílẹ̀-èdè Uganda, àti òṣìṣẹ́ ìjọba tó sìn gẹ́gẹ́ bí i ààrẹ Uganda kẹrin láàárín oṣù kẹrin àti oṣù kẹfà ọdún. Ìgbésí ayé rẹ̀. Wọ́n bí Yusuf Lule ní 10 Aprilm ọdún 1912 ní Kampala. Ó kàwé ní King's College Budo (1929–34), Makerere University College, Kampala, ní ọdún (1934–36), Fort Hare University ní Alice, South Africa (1936–39) àti ní University of Edinburgh. Ẹlésìn Mùsùlùmí ni tẹ́lẹ̀ kí ó tó gbẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì nígbà tó wà ní King's College Budo. Ní ọdún 1947, Lule fẹ́ Hannah Namuli Wamala ní ilé-ìjọsìn Kings College Budo, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ bí i olùkọ́, tí arábìrin náà sì jẹ́ olórí àwọn obìnrin.
Yusuf Lule
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74143
74143
Juan O'Donojú Juan de O'Donojú y O'Ryan tí a bí ní ọjọ́ 30 oṣù July, ọdún 1762, tó sì ṣaláìsí ní ọjọ́ 8 oṣù October, ọdún 1821) jẹ́ ológun ọmọ ilẹ̀ Spain tó tu n jẹ́. Òun sì ni Viceroy ilẹ̀ Spain tó kẹ́yìn, láti ọjọ́ 21 oṣù July, ọdún 1821 wọ ọjọ́ 28 oṣù September, ọdún 1821 lásìkò ogun òmìnira ti Mexico.
Juan O'Donojú
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74144
74144
Agustín de Iturbide Agustín de Iturbide (27 September 1783 – 19 July 1824), tí orúkọ rẹ̀ ní kíkún jẹ́ Agustín Cosme Damián de Iturbide y Arámburu tí wọ́n padà pè ní Emperor Agustín I of Mexico jẹ́ ológun ti ilẹ̀ Spain. Wọ́n fi Iturbide sípò ààrẹ ní ọdún 1821. Òun lo ṣẹ̀dá àsíá ti ìlú Mexico.
Agustín de Iturbide
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74145
74145
José Mariano Michelena José Mariano Michelena (July 14, 1772 – May 10, 1852) jẹ́ ààrẹ ìlú Mexico tẹ́lẹ̀ rí, láti oṣù kẹrin ọdún 1823 wọ oṣù kẹwàá ọdún 1824.
José Mariano Michelena
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74146
74146
Miguel Domínguez José Miguel Domínguez Alemán (January 14, 1756 most likely in Mexico City – April 22, 1830 in Mexico City) jẹ́ ológun ti ilẹ̀ Spain tó kó ipa ribiribi nínú ìgbòmìnira i ̀lú náà. Ó ti fìgbà kan darí ìlú Spain.
Miguel Domínguez
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74147
74147
Tunde Olukotun Oyekunle Ayinde "Kunle" Olukotun jẹ́ ọmọ Britain tó tún tan mọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ, tó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti Cadence Design Systems Professor ní Stanford School of Engineering, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Electrical Engineering àti Computer Science ní Stanford University, àti olùdarí láàbù Stanford Pervasive Parallelism.
Tunde Olukotun
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74148
74148
Winston Wole Soboyejo Winston Wole Soboyejo tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí "Wole" jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti orílẹ̀-èdè America, tí àwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Yorùbá. Ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọl iṣẹ́ lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Òun ni adele wọn ní Worcester Polytechnic Institute.
Winston Wole Soboyejo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74149
74149
Deji Akinwande Nigerian-American professor of Electrical and Computer EngineeringDeji Akinwande jẹ́ ọmọ orílẹ̀ Naijiria tó sì tún tan mọ́ ilẹ̀ America. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Electrical and Computer Engineering tó sì tún ní àsopọ̀ mọ́ Materials Science ní University of Texas at Austin. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Presidential Early Career Award for Scientists and Engineers ní ọdún 2016 láti ọwọ́ Barack Obama. Ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ American Physical Society, African Academy of Sciences, Materials Research Society (MRS), àti IEEE.
Deji Akinwande
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74150
74150
John Dabiri John Oluseun Dabiri jẹ́ ọmọ Naijiria tó tún tan mọ́ ilẹ̀ America. Ó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ tó ń rí sí ọkọ̀ òfurufú, òun sì ni ọ̀jọ̀gbọ́n alága ní California Institute of Technology (Caltech).
John Dabiri
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74151
74151
Alexander Animalu Alexander Obiefoka Enukora Animalu (tí a bí ní 28 August 1938) jẹ́ ọ̀mọ̀wé ti orílẹ̀-èdèNaijiria, tó sì jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà tí ìmọ̀ Physics ní University of Nigeria, Nsukka. Ó gboyè BSc (London), M.A. (Cantab.) àti PhD (Ibadan), FAS, NNOM, IOM.
Alexander Animalu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74152
74152
Lola Eniola-Adefeso Omolola (Lola) Eniola-Adefeso jẹ́ onímọ̀ chemical engineer àti ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Chemical Engineering, Biomedical Engineering, àti Macromolecular Science àti Engineering ní University of Michigan. Eniola-Adefeso jé ọ̀kan lára àwọ olùdásílẹ̀ àti onímọ̀ sáyéǹsì àgbà ní Asalyxa Bio. She was going to attend medical school but became interested in chemical engineering.
Lola Eniola-Adefeso
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74153
74153
Ndubuisi Ekekwe Ndubuisi Ekekwe (tí a bí ní July 1975) jẹ́ oníṣòwò orílẹ̀-èdè Naijiria. Òun ni olùdásílẹ̀ First Atlantic Semiconductors & Microelectronics. Ní ọdún 2020, ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn The Guardian (Nigeria) tò ó pọ̀ mọ́ ọ̀kan lára àwọn ọgọ́fà ọmọ Nàìjíríà tó ń ṣịṣẹ́ ribiribi.
Ndubuisi Ekekwe
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74154
74154
Unoma Ndili Okorafor Unoma Ndili Okorafor jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà àti oníṣòwò. Okorafor ṣe ìdásílẹ̀ Working to Advance African Women ní ọdún 2007, WAAW is a 501(c) not-for-profit which promotes STEM education to African women. èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ àìlérè lórí tó ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ àwọn obìnrin nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ, ṣáyẹ́ǹsì àti ìṣirò. They have over one hundred volunteer university fellows and reach several thousand girls a year. Òun ni adarí àgbà ní Herbal Goodness àti Fairview Data Technologies. Ó jẹ́ ọmọ karùn-ún ti Frank Nwachukwu Ndili, ẹni tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó máa ní ìmọ̀ nípa anuclear physics, tó sì tún jẹ́ gíwá keje ti University of Nigeria, Nsukka.
Unoma Ndili Okorafor
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74155
74155
Philip Emeagwali Philip Emeagwali (tí a bí ní 23 August 1954) jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Gordon Bell Prize ní 1989.
Philip Emeagwali
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74156
74156
Latunde Odeku E.Latunde Odeku (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́, "Emanuel Olatunde Alaba Olanrewaju Odeku", ni a bí ní ọdún 1927, sí Ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀-èdè Naijiria tó sì ṣaláìsí ní ìlú, London, ní ọdún 1974) jẹ́ oníṣẹ́abẹtọpọlọ àkọ́kọ́ tó máa jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. United States ni ó ti gbẹ̀kọ́, ó sì fi ìdì iṣẹ́ yìí sọlẹ̀ sí ilẹ̀ Africa.
Latunde Odeku
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74157
74157
Chidi Chike Achebe Chidi Chike Achebe (tí a bí ní ọjọ́ 24 oṣù May, ọdún 1967) jẹ́ oníṣègùn. Òun ni alagá àti olùdarí àgbà fún AIDE (African Integrated Development Enterprise). Òun ni ọmọ kẹta ti Chinua Achebe, ìyẹn òǹkọ̀wé tó kọ àwọn ìwé bí i "Things Fall Apart" (1958); "No Longer at Ease" (1960); àti "Arrow of God" (1964).
Chidi Chike Achebe
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74158
74158
Charles Rotimi Charles Nohuoma Rotimi (tí wọ́n bí ní ọdún 1957) jẹ́ olùdarí àgbà ní National Institutes of Health (NIH) Ó ṣe ìdásílẹ̀ African Society of Human Genetics ní ọdún 2003. Rotimi kó ipa ribiribi nínú ìṣẹ̀dá Human Heredity and Health in Africa (H3Africa) pẹ̀lú ìrànwọ́ NIH àti Wellcome Trust. Wọ́n yàn án sínú ẹgbẹ́ National Academy of Medicine ní ọdún 2018.
Charles Rotimi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74159
74159
Olawale Sulaiman Nigerian philanthropist, neurosurgeonProfessor Olawale Sulaiman, MD.,PhD., FRCS(C), CON jẹ́ oníṣẹ́abẹtọpọlọ tó gba ẹ̀kọ́ ní Canada àti America. Ó sì tún jẹ́ onímọ̀ àti oníṣegùn àgbà ní Nigerian heritage. Òun sì ni olùdarí àgbà ní RNZ Global Ltd, èyí tí wọ́n ṣèdásílẹ̀ ní ọdún 2010. Ní ọdún 2019, wọ́n yàn án sípò olùdámọ̀ràn fún gómíná Ìpínlẹ̀ Kwara, lórí ọ̀rọ̀ ìlera.
Olawale Sulaiman
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74160
74160
Segun Toyin Dawodu Segun Toyin Dawodu (tí wọ́n bí ní ọjọ́ 13 oṣù October, ọdún 1960) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiriató sì jẹ́ oníṣègùn àrùn-ọpọlọ àti agbẹjọ́rò pẹ̀lú WellSpan Health. Ó ṣịṣẹ́ bí i ọ̀jọ̀gbọ́n pẹ̀lú Albany Medical College.
Segun Toyin Dawodu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74161
74161
Samuel Dagogo-Jack Samuel E. Dagogo-Jack jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria tó sì tún tan mọ́ ìlú American. Ó jẹ́ oníṣègùn.
Samuel Dagogo-Jack
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74162
74162
Obioma Paul Iwuanyanwu Obioma Paul Iwuanyanwu (tí wọ́n bí ní ọdún 1962) tí orúkọ rè ní kúkurú sì jẹ́ Obiwu, jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America. Ó jẹ́ òǹkòwé àti ọ̀jọ̀gbọ́n. Ó jẹ́ olùkọ́ àgbà ní Central State University.
Obioma Paul Iwuanyanwu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74163
74163
Wendy Osefo Wendy Onyinye Osefo (tí wọ́n bí ní May 21, 1984) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America. Ó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ sí ètò òṣèlú, àti gbajúmọ̀ orí èrọ̀-amóhùnmáwòrán. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Johns Hopkins School of Education. Ó ṣàfihàn nínú fíìmù àgbéléwò "The Real Housewives of Potomac".
Wendy Osefo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74164
74164
Kalu Ndukwe Kalu Kalu Ndukwe Kalu jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ oníṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ Political Science àti National Security Policy ní Auburn University Montgomery, àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní University of Tampere, Finland
Kalu Ndukwe Kalu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74165
74165
Saheed Aderinto Saheed Aderinto (tí wọ́n bí ní January 22, 1979) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ History and African and African Diaspora Studies ni Florida International University. Bákan náà ló jẹ́ òǹkọ̀wé tó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmi-ẹ̀yẹ. Òun ni olùṣẹ̀dásílẹ̀ Lagos Studies Association. NÍ oṣù February, ọdún 2023, Aderinto gba ẹ̀bùn $300,000, èyí tó jẹ́ ti Dan David Prize. Ó ti ṣàtẹ̀jáde ìwé mẹ́jọ, jọ́nà mẹ́rìndínlógójì, átíkú ogójì àti ìríwísí sí ìwé ogún.
Saheed Aderinto
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74166
74166
Elechukwu Njaka Mazi Elechukwu Nnadibuagha Njaka (23 June 1921 – 14 January 1975) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria, àti onímọ̀ ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ó gbajúmọ̀ fún ìwé rẹ̀ "Igbo Political Culture".
Elechukwu Njaka
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74167
74167
Olu Oguibe Olu Oguibe (tí wọ́n bí ní14 October 1964) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America. Ó jẹ́ ayàwòrán àti onímọ̀. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní University of Connecticut, Storrs, ó sì tún jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ àgbà ní Vera List Center for Art and Politics, ní New York City, àti Smithsonian Institution ní Washington, DC.
Olu Oguibe
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74168
74168
Nkechi Agwu Nkechi Madonna Adeleine Agwu (tí wọ́n bí ní October 8, 1962) jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ ìṣirò ní Borough of Manhattan Community College, èyí tó jẹ́ apá kan ti City University of New York.
Nkechi Agwu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74169
74169
Abba Gumel Abba Gumel jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìṣirò ní University of Maryland, College Park. Iṣẹ́-ìwádìí rẹ̀ dálé lórí ètò ìṣirò. Gumel fìgbà kan kọ́ ìṣirò ní Arizona State University, kí ó tó di alága The Michael and Eugenia Brin Endowed E-Nnovate, ní University of Maryland, College Park, ní ọdún 2022.
Abba Gumel
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74170
74170
Benjamin Akande Benjamin Ola Akande jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó sì tún jẹ́ onímọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n àti oníṣòwò ńlá. Ní oṣù May, ọdún 2021, wọ́n fi sípò ìgbá-kejì ààrẹ, Director Human Resources, Head of Diversity and Inclusion, Stifel Financial, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìfowópamọ́ tó ń rí sí ìdókòwò. Òun ni ààrẹ kọkànlélógún ti Westminster College ní Fulton, Missouri.
Benjamin Akande
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74171
74171
Joseph Abiodun Balogun Joseph Abiodun Balogun, FAS, (tí wọ́n bí ní January 1, 1955) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ onímọ̀, àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní College of Health Sciences ní Chicago State University, Illinois àti University of Medical Sciences, ní Ipinle Ondo, Nàìjíríà. Ó wà nípò díìnì College of Health Sciences ní Chicago State University (CSU), láti ọdún 1999 wọ 2013. Lásìkò tó wà ní ipò yìí, ó ṣịṣẹ́ ìwádìí lórí àrùn HIV/AIDS.
Joseph Abiodun Balogun
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74172
74172
Johnson O. Akinleye Johnson O. Akinleye jẹ́ olórí-ẹ̀kọ́-gíga kejìlá ti North Carolina Central University. Wọ́n yàn án sípò yìí ní ọjọ́ 26 oṣù June, ọdún 2017.
Johnson O. Akinleye
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74173
74173
Okwui Enwezor Okwui Enwezor (23 October 1963 – 15 March 2019) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jẹ́ olùtọ́jú mùsíọ́ọ̀mù, aṣàríwísí sí iṣẹ́-ọnà, òǹkọ̀wé, akéwì àti onímọ̀. Ó fìgbà kan gbéní New York City àti Munich. Ní ọdún 2014, wọ́n tò ó pọl mọ́ ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tó ń ṣịṣẹ́ ọnà.
Okwui Enwezor
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74174
74174
Opeoluwa Sotonwa Opeoluwa Sotonwa (tí wọ́n bí ní Ijebu-Ode) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America. Arákùnrin yìí jẹ́ agbẹjọ́rò fún àwọn odi, ajàfẹ́tọ̀ọ́ àwọn odi àti òǹkọ̀wé ìwé lítíréṣọ̀. Ní oṣù February, ọdún 2021, Gómínà Charles Baker yàn án sípò Kọmíṣọ́nà àti olórí Massachusetts Commission fún àwọn odi. KÍ wọ́n tó yàn án sípò yìí, ó jẹ́ adarí àgbà fún Missouri Commission fún àwọn odi.
Opeoluwa Sotonwa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74175
74175
Ayọ Tometi Ayọ Tometi (tí wọ́n bí ní August 15, 1984), tó fìgbà kan jẹ́ Opal Tometi, jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America. Ó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn, òǹkọlwé, àti olùṣètò ìlú. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùṣèdásílẹ̀ Black Lives Matter (BLM). Ó sì fìgbà kan jẹ́ olùdarí àgbà Black Alliance for Just Immigration (BAJI), níbi tó ti ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́sàn-án.
Ayọ Tometi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74176
74176
John O. Agwunobi John O. Agwunobi jẹ́ ọmọ Scotland, tó sì tún tan mọ́ orílẹl-èdè Nàìjíríà, tó jẹ́ oníṣègùn àwọn ọmọdé, ó sì fìgbà kan jẹ́ adarí agbà àti alága Herbalife Nutrition. Òun sì ni igbákejì ààrẹ ti Walmart, àti ààrẹ retailer health and wellness business láti ọdún 2007 wọ 2014.
John O. Agwunobi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74177
74177
Tayo Oviosu Tayo Oviosu jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ oníṣòwò, tó tún ṣèdásílẹ̀ Paga, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó fàyè gba sísan owó láti orí ẹ̀rọ-alágbèéká wa. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni Paga kọ́kọ́ gbòde.
Tayo Oviosu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74178
74178
Adebayo Alonge Adebayo Alonge jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria tó jẹ́ olóògùn àti oníṣòwò. Òun ló jáwé olúborí fún ìdíje tí ọdún 2019 ti Hello Tomorrow Global Deeptech Challenge, èyí tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí BNP Paribas Group Deep Tech Award. Ó gba àmì-èyẹ yìí látàri irinṣẹ́ kan tó lè ṣàwárí oògùn ẹbu tí ó ṣẹ̀dá. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùṣèdásílẹ̀ RxAll Inc.
Adebayo Alonge
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74179
74179
Tiffany Trump Tiffany Ariana Trump (tí wọ́n bí ní October 13, 1993) jẹ́ ọmọ kẹrin ti ààrẹ U.S ìgbà kan, èyí tí í ṣe Donald Trump. Tiffany sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ìyàwó kejì Donald bí.
Tiffany Trump
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74180
74180
Patrick Wilson Patrick Joseph Wilson (tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣù keje ọdún 1973) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré ní ọdún 1995, nígbà tí ó ṣeré nínú Broadway musicals. Wọ́n yán mọ́ ara àwọn tí ó tó sí Tony Awards ní ẹ̀mejì fún ipa nínú eré "The Full Monty" (2000–2001) àti "Oklahoma!" (2002). Ó tún ṣeré nínú eré HBO tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Angels in America" (2003), èyí tí ó mú kí wọ́n yán lé mejì mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Golden Globe Award àti Primetime Emmy Award. Wilson farahàn nínú àwọn eré bi "The Phantom of the Opera" (2004), "Hard Candy" (2005), "Little Children" (2006), "Watchmen" (2009), àti "The A-Team" (2010). Ó gbajúmọ̀ si nígbà tí ó farahàn nínú eré Insidious film (2010–2023) àti gẹ́gẹ́ bi Ed Warren nínú eré "The Conjuring" universe (2013–títí di ìsinsìnyí). Òun ló dárí eré "" (2023).
Patrick Wilson
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74181
74181
Ken Watanabe Ken Watanabe (渡辺 謙, tí a bí ní ọjọ́ kanlélógún oṣù Kẹ̀wá ọdún 1959) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Japan. Ó gbajúmọ̀ láàrin àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí General Tadamichi Kuribayashi nínú eré Letters from Iwo Jima àti gẹ́gẹ́ bi Lord Katsumoto Moritsugu nínú eré The Last Samurai, èyí tí ó mú kí wọ́n yán kún àwọn tí ó tó sí Academy Award for Best Supporting Actor. Àwọn àmì ẹyẹ míràn tí ó ti gbà ni Japan Academy Film Prize for Best Actor lẹ́mejì, àkọ́kọ́ ní ọdún 2007 fún Memories of Tomorrow àti èkejì ní ọdún 2010 fún Shizumanu Taiyō. Ọ̀pọ̀ tún mọ́ fún ipa rẹ̀ nínú eré Christopher Nolan pẹ̀lú àkọ́lé Batman Begins àti Inception, pẹ̀lú pẹ̀lú Memoirs of a Geisha, àti Pokémon Detective Pikachu. Ní ọdún 2014, ó ṣeré nínú eré Godzilla gẹ́gẹ́ bi Dókítà Ishiro Serizawa àti nínú . Ní ọdún 2022, ó ṣeré nínú eré HBO Max tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Tokyo Vice.
Ken Watanabe
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74182
74182
Adebayo Ogunlesi Adebayo "Bayo" O. Ogunlesi CON (tí a bí ni December 20, 1953) jẹ́ agbẹjọ́rò àti oní-ìdókòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria. Òun ni olùdarí àgbà fún Global Infrastructure Partners (GIP). Ogunlesi fìgbà kan jẹ́ olórí wọn ni Credit Suisse First Boston kí wọ́n tó yàn án sípò alága.
Adebayo Ogunlesi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74183
74183
Maya Horgan Famodu Maya Horgan Famodu jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ oníṣòwò, àti olùdásílẹ̀ Ingressive. Ó ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ High Growth Africa Summit, àti Tech Meets Entertainment Summit. Maya pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ (Sean Burrowes àti Blessing Abeng) tún ṣe ìdásílẹ̀ Ingressive for Good.
Maya Horgan Famodu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74184
74184
Magnus L. Kpakol Magnus Lekara Kpakol ni adarí àgbà àti alága fún Economic and Business Strategies, ìyẹn ilé-iṣẹ́ tó ní ẹ̀ka iṣẹ́ ní ìlú òyìnbó àti orílẹ̀-ède Nàìjíríà. Ó jẹ́ olùdarí àgbà àti akọ́nímọ̀ọ́ṣòwò ní Economic and Business Strategies Ltd. Ní ọdún 2001, Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ yàn án sípò olùdámọ̀ràn fún ọ̀rọ̀ ajé.
Magnus L. Kpakol
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74185
74185
Angelica Nwandu Angelica Nwandu (tí wọ́n bí ní May 10, 1990) ni olùdásílẹ̀ the Shade Room (TSR), èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára tó níṣe pẹ̀lú ṣíṣe òfófó àwọn gbajúmọ̀. Iye àwọn ènìyàn tó ń wo ètò yìí ń lọ bí i 20 million. Ní ọdún 2016,"The New York Times" to the Shade Room sábẹ́ àwọn ètò tó gbajúmọl jù lọ ní orí ẹ̀rọ-ayélujára.
Angelica Nwandu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74186
74186
Yinka Faleti Adeyinka Faleti (tí wọ́n bí ní June 20, 1976) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ olúṣèlú àti ológun fún ìlú America. Ó gboyè Bachelor of Science láti United States Military Academy ní West Point àti Juris Doctor láti Washington University in St. Louis.
Yinka Faleti
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74187
74187
Oye Owolewa Adeoye "Oye" Owolewa (tí wọ́n bí ní ọdún 1989) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ olóṣèlú, olóògùn, àti ọmọ-ẹgbẹ́ Democratic Party. Ní oṣù November, ọdún 2020, wọ́n yàn án sípò ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti orílẹ̀-èdè America.
Oye Owolewa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74188
74188
Ochai Agbaji Ochai Young Agbaji (tí a bí ní April 20, 2000) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rè fún Utah Jazz èyí tó jẹ́ ti National Basketball Association (NBA). Gẹ́gẹ́ bí i ọ̀gá àgbà ní University of Kansas, wọ́n fún Agbaji lórúkọ, wọ́n sì dìbò fun ní ọdún 2022, gẹ́gẹ́ bí i Big 12 Player of the Year. Ó darí ẹgbẹ́ Jayhawks nínú ìdíje, títí wọ́n fi wọ ìpele tó kẹ́yìn, wọ́n sì sọ wọ́n ní Final Four Most Outstanding Player (MOP).
Ochai Agbaji
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74189
74189
Suleiman Braimoh Suleiman Okhaifoede Braimoh Jr. (tí a bí ní October 19, 1989) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ìlu America. Ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsápẹ̀rẹ̀, tó gbá bọ́ọ̀lù fún Maccabi Tel Aviv, èyí tí í ṣe ti Israeli Basketball Premier League àti Euroleague. Ó tún gbábọ́ọllù fún ilé-ìwé gíga ti Rice University, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sím máa gbá bọ́ọ̀lù fún NBA Development League, ní Qatar, Japan, New Zealand, Mexico, Germany, Russia, France, Israel, àti Turkey.
Suleiman Braimoh
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74190
74190
Chamberlain Oguchi Chamberlain "Champ" Nnaemeka Oguchi (tí a bí ní April 28, 1986) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria, tó tan mọ́ ìlú America, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsápẹ̀rẹ̀, tó gbá bọ́ọ̀lù náà fún Boulazac Basket Dordogne, ti LNB Pro B. Orúkọ rẹ̀ "Emeka" jẹ́ àgékúrú orúkọ Igbo rẹ̀, tí ń ṣe "Chukwuemeka", (tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ "Ọlọ́run ti ṣeun púpọ̀").
Chamberlain Oguchi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74191
74191
John Malkovich John Malkovich (tí a bí ní ọjọ́ kẹsán oṣù Kejìlá ọdún 1953) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ, àwọn bi Primetime Emmy Award, wọ́n sì ti yán mọ́ àwọn tí ó tó sí àmì-ẹ̀yẹ Academy Awards lémejì, BAFTA Award, Screen Actors Guild Awards, àti àmì ẹyẹ Golden Globe Awards lẹ́meta. Malkovich bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré gẹ́gẹ́ bi nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Steppenwolf Theatre Company ní Chicago ní ọdún 1976. Àwọn fíìmù tí ó ti ṣeré ni "True West" (1980), "Death of a Salesman" (1984), "The Caretaker" (1986), àti ní "Burn This" (1987), "Places in the Heart" (1984), "In the Line of Fire" (1993), "The Killing Fields" (1984), "Empire of the Sun" (1987), "Dangerous Liaisons" (1988), "Of Mice and Men" (1992), "Con Air" (1997), "Rounders" (1998), "Being John Malkovich" (1999), "Shadow of the Vampire" (2000), "Ripley's Game" (2002), "Burn After Reading" (2008), and "Red" (2010). Ó ti ṣe àgbéjáde àwọn fíìmù bi "Ghost World" (2001), "Juno" (2007), àti "The Perks of Being a Wallflower" (2012).
John Malkovich
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74194
74194
Mark Hamill Mark Richard Hamill (; tí a bí ní ọjọ́ karúndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án ọdún 1951) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti olùkọ̀wé. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Luke Skywalker nínú àwọn eré "Star Wars. Ó" bẹ̀rẹ̀ ní original 1977 film wọ́n sì fun ní àmì ẹ̀yẹ Saturn mẹ́ta fún ipa rẹ̀ nínú "The Empire Strikes Back" (1980), "Return of the Jedi" (1983), àti "" (2017). Ó ṣeré nínú àwọn eré míràn bi "Corvette Summer" (1978) àti "The Big Red One" (1980). Ó tún farahàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré láàrin ọdún 1980 sí 1989. Hamill ti kó ipa gẹ́gẹ́ bi Joker nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tí DC Comics ṣe, ọkàn lára wọn ni ' in 1992. Ó jẹ́ ọ̀kanj lára òṣèré, tí o jẹ́ Hobgoblin nínú eré "Spider-Man," Fire Lord Ozai nínú , àti Skips nínú "Regular Show".
Mark Hamill
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74195
74195
Harrison Ford Harrison Ford (tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje ọdún 1942) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti farahàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré, ọ̀pọ̀ sì mọ́ sí cultural icon orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Àwọn eré tí ó ti ṣeré ti pa tó iye owó tí ó lé ní bílíọ́nù márùn-ún dọ́là ní Àríwá Amẹ́ríkà àti iye tí ó lé ní bílíọ́nù mẹ́sán dọ́là káàkiri àgbáyé, Ó ti gba ọ̀pọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bi AFI Life Achievement Award ní ọdún 2000, Cecil B. DeMille Award ní ọdún 2002, Honorary César ní ọdún 2010, àti Honorary Palme d'Or ọdún 2023, wọ́n sì ti yàn rí mọ́ ara àwọn tí ó tọ́ sí àmì ẹyẹ Academy. Díè nínú àwọn eré tí ó ti ṣeré ni "American Graffiti" (1973), "The Conversation" (1974), "Star Wars" (1977), "Raiders of the Lost Ark" (1981), "Blade Runner" (1982) àti "Blade Runner 2049" (2017), "Patriot Games" (1992), "Clear and Present Danger" (1994). Wọ́n yan Ford mọ́ ara àwọn tí ó tọ́ sí àmì ẹyẹ Academy Award for Best Actor fún ipa rẹ̀ nínú eré "Witness" (1985).
Harrison Ford
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74196
74196
Anthony Daniels Anthony Daniels ( ; tí a bí ní ọjọ́ kanlélógún oṣù kejì ọdún 1946) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain, tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ fún ipa gẹ́gẹ́ bi C-3PO nínú eré "Star Wars" mẹ́wàá. Daniels ni ó fọ ohùn fún Legolas nínú eré Ralph Bakshi bẹ̀bí tí wọ́n ṣe fún "The Lord of the Rings" (1978). Ó ti farahàn nínú àwọn Britain kọ̀kan. Daniels jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Entertainment Technology Center ti Yunifásitì Carnegie Mellon. Ìpìlẹ̀ rẹ̀. Wọ́n bí Daniels ní ìlú Salisbury, Wiltshire, England. Ó kàwé ní ilé ìwé Giggleswick School ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin fún ọdún méjì ní Yunifásitì, ṣùgbọ́n ó kúrò láti kópa nínú "amateur dramatics" lẹ́yìn tí ó padà lọ Rose Bruford College. Lẹ́yìn ìgbà tí ó kàwé gboyẹ̀ ní Burford College ní ọdún 1974, Daniels ṣiṣẹ́ ní on BBC Radio àti fún gbọ̀ngán erẹ́ National Theatre ti Great Britain ní The Young Vic. Níbi tí ó ti ń sisẹ́ ní gbọ̀ngán náà ni wọ́n ti pé láti pàdé George Lucas, ẹni tí ó ń wa àwọn ènìyàn láti ṣeré nínú "Star Wars".
Anthony Daniels
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74197
74197
Crystal Clarke Crystal Clarke (tí a bí ní ọdún 1993 tàbí ọdún 1994) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀pọ̀ mọ́ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Tina Argyll nínú eré BBC àti Amazon Prime tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Ordeal by Innocence" (2018) àti gẹ́gẹ́ bi Georgiana Lambe nínú eré ITV àti PBS tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Sanditon" (2019–). Ìpìlẹ̀. Wọ́n bí Clarke ní Essex County, New Jersey, sínú ìdílé àwọn òbí Caribbean;¡ wọ́n to dàgbà nínú ìlú kan náà; ìyá rẹ̀ wá láti Trinidad, bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmo Guyana. Ó ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan. Clarke lọ ilé ìwé Newark Arts High School, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 2011.
Crystal Clarke
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74198
74198
Billie Lourd Billie Catherine Lourd (tí a bí ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù keje ọdún 1992) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi l Chanel #3 nínú eré Fox tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Scream Queens" (2015–2016) àti ipa rẹ̀ nínú FX tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "American Horror Story" (2017–títí di ìsinsìnyí). Ó farahàn gẹ́gẹ́ bi Lieutenant Connix nínú àwọn eré Star Wars sequel (2015–2019). Lourd nìkan ni ọmọ òṣèrébìnrin Carrie Fisher.
Billie Lourd
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74199
74199
Judah Friedlander Judah Friedlander (tí a bí ní ọjọ́ kẹríndínlógún oṣù kẹta ọdún 1969) jẹ́ òṣèré àti aláwadà ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé Frank Rossitano nínú NBC sitcom "30 Rock". Friedlander tún gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Toby Radloff nínú eré "American Splendor", ipa tí ó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbóríyìn fun, ó sì mú kí ó wà lára àwọn tí wọ́n yàn pé ó tó sí àmì ẹyẹ 2004 Independent Spirit ti ọdún 2004. Nígbà tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, ọ̀pọ̀ ma ń pè é ní "the hug guy" nítorí ipa rẹ̀ nínú eré tí Dave Matthews Band ṣe fún orin rẹ̀ "Everyday".
Judah Friedlander
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74200
74200
Thomas Brodie-Sangster Thomas Brodie-Sangster (tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1990) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Britain. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Sam "Love Actually" (2003), Simon nínú "Nanny McPhee" (2005), Ferb nínú "Phineas and Ferb" (2007–2015), Jojen Reed nínú "Game of Thrones" (2013–2014), Newt nínú Maze Runner film (2014–2018), àti Benny Watts nínú eré Netflix tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "The Queen's Gambit" (2020), èyí tí ó sì mú kí wọ́n yán mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Primetime Emmy Award. Brodie-Sangster tún gbajúmọ̀ si nígbà tí ó ṣeré nínú àwọn eré bi "Death of a Superhero" (2011), "Bright Star" (2009), àti gẹ́gẹ́ bi Paul McCartney nínú "Nowhere Boy" (2009). Jake Murray "Accused" (2010–2012). Ó farahàn nínú eré "" (2015), ó sì kópa gẹ́gẹ́ bi Whitey Winn nínú eré Netflix tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Godless" (2017).
Thomas Brodie-Sangster
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74201
74201
Ilaje Ìlàje jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní Ìpínlẹ̀ Òndó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Olú-ìlú náà wà ní Igbokoda. Ẹ̀yà Yorùbá yìí dá yàtọ̀, nínú èdè ẹnu wọn, àkójọpọ̀ ìlú bí i Ondo, Ogun àti Delta ló bí ìlú yìí.
Ilaje
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=74202
74202
Ada Ada jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Boripe, ní Ipinle Osun, ní orílẹ̀-èdè Naijiria. Oba Oyetunde Olumuyiwa Ojo (The Olona of Ada) ni olórí ìlú náà.Lára àọn ọjà tó wà ní ìlú náà ni Ile Oba Oludele, ile oba Adeitan, Ile oba Olugbogbo, Ile Aro, Ile Alagbaa, Ojomu Oteniola, Alade, Eesa, Jagun, Osolo, Oke Baale, Asasile, Oluode, Agba Akin, àti Ile Odogun.
Ada