translation
dict |
---|
{
"en": "Whoever wins the 2019 elections will face enormous challenges like the strengthening the economy, internal security, restructuring power and power devolution, and ethnoreligious politics.",
"yo": "Ẹni yòówù tí ó bá gbégbá-orókè nínú ìdíje sí ipò ààrẹ ọdún 2019 ní iṣẹ́ ìmúgbòòrò ọrọ̀ Ajé, ààbò ní àárín ìlú, àtúntò agbára àti ìmúkárí agbára, àti ìṣèlú elẹ́yàmẹyà làti ṣe."
} |
{
"en": "Singled out for search at a Serbian supermarket, Roma opera superstar accuses the store of racism",
"yo": "Fún ìyọsọ́tọ̀ tí wọ́n yọ òun nìkan láti yẹ ara rẹ̀ wò ní ilé ìtajà ìgbàlódé kan ní Serbia, gbajúgbajà ìràwọ̀ òṣèré orí-ìtàgé Roma fi ẹ̀sùn ìwà elẹ́yàmẹyà kan ilé ìtajà náà"
} |
{
"en": "Nataša Tasić Knežević, photo by Dzenet Koko, used with permission.",
"yo": "Nataša Tasić Knežević, photo by Dzenet Koko, used with permission."
} |
{
"en": "Serbian opera star Nataša Tasić Knežević, photo by Dzenet Koko, used with permission.",
"yo": "Ìràwọ̀ òṣèré orí-ìtàgé ìlú Serbia Nataša Tasić Knežević, àwòrán láti ọwọ́ọ Dzenet Koko, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ."
} |
{
"en": "Serbian social networks were set ablaze after opera singer and local superstar Nataša Tasić Knežević, who is of Roma origin, accused a supermarket in the city of Novi Sad of racial profiling on a live broadcast on Facebook.",
"yo": "Àwọn gbàgede ìtàkùrọ̀sọ ẹ̀rọ-alátagbà ìlú Serbia gbaná lẹ́yìn tí olórin àti òṣèré ìbílẹ̀ Nataša Tasić Knežević, tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Roma fi ẹ̀sùn kan ilé ìtajà-ìgbàlóde kan tí ó wà ní ìgboro Novi Sad fún ìwà ìyàsọ́tọ̀ ẹ̀yà nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ojú-ẹsẹ̀ kan lórí Facebook."
} |
{
"en": "In the video, broadcast on December 29 right after the incident, Ms. Tasić Knežević explained that as she exited the Maxi supermarket store along with several other shoppers, the anti-theft sensor beeped.",
"yo": "Nínú fídíò náà, tí ó gbé-sórí-áfẹ́fẹ́ ní ọjọ́ 29, oṣù Ọ̀pẹ lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, arábìnrin Tasić Knežević ṣàlàyé pé bí òun ṣe ń jáde síta nínú ilé ìtajà ńlá náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn òǹrajà mìíràn ni ẹ̀rọ adènà àfọwọ́rá dún."
} |
{
"en": "While everyone else was allowed to leave, the store's security officers told her to stay and proceeded to search her in public while onlookers heckled her.",
"yo": "Bí àwọn ènìyàn yòókù ṣe ń jáde síta, àwọn ẹ̀ṣọ́-aláàbò ilé ìtajà náà ní kí ó dúró tí wọ́n sì tẹ̀síwajú láti yẹ ara rẹ̀ wò ní gbangba tí àwọn òǹwòran bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́."
} |
{
"en": "In her backpack, they only found sheet music, books, and a wallet.",
"yo": "Ìwé orin, ìwé àti àpò-àpawómọ́-ìléwọ́ ni wọ́n rí nínú àpò-àgbékọ́yìn-in rẹ̀."
} |
{
"en": "In the first days of January 2019, the video suddenly vanished from the platform along with Ms. Knežević's profile.",
"yo": "Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Ṣẹẹrẹ ọdún 2019, fídíò náà dédé pòórá pẹ̀lú àlàyé ránńpẹ́ nípa arábìnrin Knežević."
} |
{
"en": "Although she hasn't publicly explained what happened, many speculate that she has removed them herself to de-escalate the turmoil.",
"yo": "Bíótilẹ̀jẹ́pé kòì tíì wá sí gbangba kí ó ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé fúnra rẹ̀ ni ó yọ ọ́ kí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ lè tán bọ̀rọ̀."
} |
{
"en": "In just a few days, her video amassed over 60 thousand views, was shared around 350 times and received around 700 reactions.",
"yo": "Láàárín ọjọ́ díẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó tó bíi ẹgbẹ̀rún 60 ti wo fídíò rẹ̀, tí wọ́n sì pín in lọ́nà 350, tí ó sì gba èsì tí ó tó 700."
} |
{
"en": "Independent news portal Buka was the first to report the incident, followed by other Balkan media.",
"yo": "Ilé-iṣẹ́ Ìkóròyìnjọ Orí-ayélujára Olómìnira Bulka ni ó kọ́kọ́ ro ìyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣáájú àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn Bulka mìíràn."
} |
{
"en": "Ms. Tasić Knežević is a soprano at the Serbian National Theatre, located in Novi Sad, the country's second largest city.",
"yo": "Akọrin-olóhùn-òkè ni arábìnrin Tasić Knežević ní Gbọ̀ngan Eré-ìtàgé ti orílẹ̀-èdè Serbia tí ó wà ní Novi Sad, ìlú kejì tí ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà."
} |
{
"en": "Previously, she worked in the Belgrade theater Atelje 212.",
"yo": "Tẹ́lẹ̀ rí, ó ṣiṣẹ́ ní Belgrade Atelje 212."
} |
{
"en": "She is also a choir performer and a soloist of popular music and often sings of her own Roma heritage.",
"yo": "Ó tún jẹ́ akọrin-ṣeré àti àdánìkànkọrin tí ó gbajúmọ̀, ó sì máa ń kọ orin àdánìkànkọ nípa àṣà Roma tí ó jẹ́ orírun rẹ̀."
} |
{
"en": "In the video, Ms Knežević says the store manager apologized to her after she complained about the maltreatment, but that she was still hurt by the mob's harassment.",
"yo": "Nínú fídíò náà, arábìnrin Knežević sọ pé alábòójútó ilé ìtajà náà bẹ̀bẹ̀ lẹ́yìn tí òun ṣe àròyé nípa ìwọ̀sí náà, ṣùgbọ́n pé inú òun kò dùn sí bí àwọn èrò tí ó pé jọ lé òun lórí ṣe yẹ̀yẹ́ òun."
} |
{
"en": "She says one older man shouted that they \"should pack that garbage out\", meaning that employees should throw her out of the store, supposedly for her being Roma.",
"yo": "Ó ní ọkùnrin àgbàlagbà kan pariwo pé kí wọ́n \"kó pàǹtí yẹn jáde\", ìyẹn túmọ̀ sí wípé kí àwọn òṣìṣẹ́ ó ju òun jáde síta nínú ilé ìtajà náà nítorí pé òun jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Rome."
} |
{
"en": "\"It is known who likes to steal around here!\" is a sentence from the movie \"Who's Singin’ Over There?\" about events taking place on 5 April 1941.",
"yo": "\"A mọ ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa jalè níbí\" jẹ́ gbólóhùn kan láti inú eré \"Ta ni ó ń kọrin níbẹ̀ yẹn!\" nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ 5, oṣù Èbìbí ọdún 1971."
} |
{
"en": "77 years later this [discriminatory stereotype] is not rooted out from our mentality.",
"yo": "Lẹ́yìn ọdún 77, èyí [èrò ìyàsọ́tọ̀] ò tí ì kúrò ní ìrònúu wa."
} |
{
"en": "The company [owning Maxi markets] is Dutch-Belgian but the employees are our people! For shame!",
"yo": "Ilé-iṣẹ́ [tí ó ni ilé ìtajà Maxi] náà jẹ́ ti àwọn Dutch-Belgian ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn-an wa ni àwọn òṣìṣẹ́ẹ wọn!"
} |
{
"en": "Support for the wonderful woman and artist @NatasaTasicKnez.",
"yo": "Ohun ìtìjú! Àtìlẹyìn fún obìnrin gidi àti òṣèré yìí @NatasaTasicKnez."
} |
{
"en": "\"Who's Singin’ Over There?\" is a 1980s Yugoslavian movie that has achieved cult status in the Balkans.",
"yo": "\"Ta ni ó ń kọrin níbẹ̀ yẹn?\" jẹ́ eré Yugoslavia ayé ìgbà 1980 tí ó sì di ipò ẹgbẹ́-ìmùlẹ̀ láàárín àwọn Balkan."
} |
{
"en": "In the story, two Roma musicians are wrongfully accused of theft and barely manage to escape alive from a lynching attempt.",
"yo": "Nínú ìtàn náà, wọ́n ṣèṣì fẹ̀sùn olè kan àwọn olórin Roma méjì, orí ni ó kó wọn yọ lọ́wọ́ ìjìyà láìsí ìdájọ́."
} |
{
"en": "The parent company of Maxi supermarkets, Delez Srbija, issued an official apology on the same day.",
"yo": "Ilé-iṣẹ́ tí ó ni ilé ìtajà-ìgbàlóde Maxi, Delez Srbija, ṣe àgbéjáde àkọsílẹ̀ ìtúúbá lọ́jọ́ kan náà."
} |
{
"en": "It stated that it \"believes that this would remain an isolated incident of inappropriate individual reaction and that there won't be similar situations in the future\".",
"yo": "Ó sọ pé àwọn “gbàgbọ́ pé èyí á wà bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìyàsọ́tọ̀ tí ó mú ìfura ẹni tí kò yẹ dání pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́ lọ́jọ́ iwájú."
} |
{
"en": "The company has added that it will conduct formal training of their employees on appropriate conduct upon suspicion of theft.",
"yo": "Ilé-iṣẹ́ náà fi kún un pé àwọn á ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn lórí bí a ṣe ń hùwà bí wọ́n bá fura sí olè jíjà."
} |
{
"en": "The next day, Miloš Nikolić, the Director of Office for Roma Inclusion of Novi Sad, officially condemned the incident.",
"yo": "Ní ọjọ́ kejì, Miloš Nikolić tí ó jẹ́ adarí ọ́fíìsì tí ó ń ṣe àfikún Novi Sad mọ́ Roma sọ̀rọ̀ tako ìṣẹ̀lẹ̀ náà."
} |
{
"en": "He said: All available research shows that Roma men and women are the most discriminated groups in our country.",
"yo": "Ó ní; gbogbo ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn ará Roma lọ́kùnrin lóbìnrin ni ẹ̀yà tí a yà sọ́tọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdèe wa."
} |
{
"en": "We have to work together to change it!",
"yo": "A ní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ láti yí i padà!"
} |
{
"en": "On December 31, Serbian Deputy Prime Minister and President of the Gender Equality Coordination Body, Zorana Mihajlović, also decried the behavior of Maxi store employees as “scandalous and for condemnation.",
"yo": "Ní 31 oṣù Ọpẹ, Igbá-kejì Alákòóso Ìgbìmọ̀ Ìjọba àti Ààrẹ Àjọ-tí-ó-ń-fètò-sí Ìmúdọ́gba Akọ-àtabo ní àwùjọ, Zorana Mihajlović náà sọ̀rọ̀ tako àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtajà Maxi pé “ìwà ìbanilórúkọjẹ́ ni wọ́n hù àti pé wọ́n jẹ̀bi."
} |
{
"en": "She did not announce any concrete measures to address the broader issue of discrimination against people of Roma descent in Serbia.",
"yo": "Kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe sí ìyàsọ́tọ̀ àwọn ọmọ Roma ní Serbia."
} |
{
"en": "While Ms. Knežević seems to have removed her profile from Facebook, possibly to de-escalate the turmoil, she has retained her Twitter profile.",
"yo": "Bíótilẹ̀jẹ́pé ó dàbí ẹni pé arábìnrin Knežević ti yọ ara rẹ̀ kúrò lórí Facebook, bóyá láti lè jẹ́ kí ọ̀ràn náà ó silẹ̀, ó fi àlàyé-nípa-ara rẹ̀ orí Twitter sílẹ̀."
} |
{
"en": "On New Year's Eve, she posted a short message referring to the incident.",
"yo": "Ní alẹ́ ọjọ́ tí ó ṣíwájú Ọdún Tuntun, ó fi àtẹ̀jáde ṣókí sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà."
} |
{
"en": "Dear friends, a very unpleasant situation took place few days ago, but I hope all such situations will remain in 2018 and that similar event won't occur any more.",
"yo": "Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ẹ̀ mi ọ̀wọ́n, ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò dùn mọ́ni nínú kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n mo nírètí pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ náà á pín pẹ̀lú ọdun 2018 àti pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́."
} |
{
"en": "Let us all be human beings, that is the only good thing on this world. <3",
"yo": "Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ènìyàn ẹlẹ́ran ara, ohun tí ó dára jù ní ayé yìí nìyẹn. <3"
} |
{
"en": "The beef between two Trinidad and Tobago soca stars is a nod to age-old musical traditions",
"yo": "Ìjà láàárín ìràwọ̀ akọrin soca Trinidad àti Tobago jẹ́ àmì tí ó dára fún orin àtijọ́"
} |
{
"en": "Trinidadian soca star Machel Montano performing at OVO Fest in Toronto in 2016. PHOTO: The Come Up Show (CC BY-ND 2.0)",
"yo": "Ìràwọ̀ akọrin soca ìlú Trinidad Machel Montano ń ṣeré ní Àjọ̀dún OVO ní Toronto ní ọdún 2016. ÀWÒRÁN: The Come Up Show (CC BY-ND 2.0)"
} |
{
"en": "Private grouses have a funny way of becoming public feuds — especially in the music industry.",
"yo": "Gbólóhùn asọ̀ láàárín ẹni méjì ní ọ̀nà àrà tí ó gbà di ìjà ìgboro — papàá nínú iṣẹ́ orin kíkọ."
} |
{
"en": "From high-profile beefs like the ones between Kanye West and Taylor Swift and Jamaica's Mavado and Vybz Kartel, to the more local but equally infamous 2004 fight between Trinidadian soca stars Destra and Denise Belfon, celebrity quarrels often end up bringing attention to the artists and drawing new audiences to their music.",
"yo": "Ìjà mo jù rẹ́ lọ láàárín àwọn ọ̀jẹ̀ bíi ti Kanye West àti Taylor Swift àti ọmọ Jamaica Mavado àti Vybz Kartel, títí kan ìjà ìbílẹ̀ ọdún 2004 ní àárín-in akọrin soca ìlú Trinidad méjì Destra àti Denise Belfon, ìjà mo jù ọ́ lọ àwọn gbajúgbajà sábà máa ń já sí ìpolongo fún akọrin àti orin wọn."
} |
{
"en": "Now, thanks to a burgeoning battle between Trinidad and Tobago entertainers Machel Montano and Neil “Iwer” George, soca music officially has its first spat of 2019.",
"yo": "Wàyí, ọpẹ́ fún asọ̀ tí ó wà ní àárín-in akọrin adìde Trinidad àti Tobago méjì Machel Montano àti Neil “Iwer” George, orin soca wọ ìròyìn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 2019."
} |
{
"en": "Trinidad and Tobago's annual Carnival celebrations take place this year on March 4 and 5, and the lead up is peak time for soca music.",
"yo": "Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba ọlọ́dọọdún Trinidad àti Tobago tí ọdún yìí wáyé ní ọjọ́ 4 àti 5 oṣù Ẹrẹ́nà, tí ó sì jẹ́ àkókò fún orin soca."
} |
{
"en": "Popular soca performers like Montano and George are booked for Carnival events months in advance.",
"yo": "Ọ̀jẹ̀ olórée soca bíi Montano àti George ti gba ìpè láti ṣeré níbi ètò ijó ìta-gbangba kí ọjọ́ ó tó kò rárá."
} |
{
"en": "They're releasing new music in a bid to win the coveted Road March title, which offers a substantial monetary prize to the artist whose song plays the most during Carnival.",
"yo": "Wọn yóò gbé orin tuntun jáde ní ìpalẹ̀mọ́ fún ẹni tí yóò gbégbáorókè nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúná, tí ó ń gbé ẹ̀bùn owó sílẹ̀ fún akọrin tí a bá kọ orin rẹ̀ jù lọ nínú Ijó ìta-gbangba."
} |
{
"en": "Screenshot from a Vimeo video of Trinidadian soca star Iwer George performing at Return Fête in Toronto in 2018.",
"yo": "Àwòrán ìràwọ̀ akọrin soca ti Trinidad Iwer George ní Ìdápadà Fête ní Toronto ní ọdún 2018 tí a mú láti fídíò orí Vimeo."
} |
{
"en": "Soca music lovers first noticed tension between the two musicians when George released his first song of 2019, \"Road March Bacchanal 2\".",
"yo": "Àwọn olólùfẹ́ẹ orin Soca ṣe àkíyèsí àròyé ọ̀tẹ̀ láàárín-in akọrin méjèèjì nígbà tí George gbé orin àkọ́ṣe ọdún 2019 jáde, \"Ìwọ́de Ojúná Bacchanal 2\"."
} |
{
"en": "The song's lyrics makes it clear that George holds a grudge after losing the 2018 Road March battle to Montano.",
"yo": "Orin náà kò fi igbákanbọ̀kan nínú nípa ìkùnsínú tí ó wà nílẹ̀ látàrí ìpàdánù ìfigagbága ọdún 2018 tí Montana jáwé olúborí."
} |
{
"en": "His composition, \"Savannah\", was a strong contender, but Montano had teamed up with soca veteran Superblue to release \"Soca Kingdom\", which copped the coveted 2018 Road March title.",
"yo": "Orin rẹ̀ tí a pè ní \"Savannah\", bá ti ẹnìkejì figagbága, ṣùgbọ́n Montana tí pàdí-àpò-pọ̀ pẹ̀lú ògbóǹtarigi akọrin soca Superblue wọ́n sì ṣe àgbéjáde \"Soca Kingdom\", tí ó gba oyè orin Ìwọ́de Ojúná ọdún 2018."
} |
{
"en": "\"Soca Kingdom\" was played 336 times, and \"Savannah\" 140.",
"yo": "Iye ìgbà 336 ni a kọ orin “Soca Kingdom”, a sì kọ \"Savannah\" fún iye ìgbà 140."
} |
{
"en": "Bringing his personal disappointment into the public domain, George's lyrics accused the \"soca mafia\" — ostensibly a group of deejays and radio station owners — of conspiring to play \"Soca Kingdom\" at the all judging points.",
"yo": "Ìpàdánù oyè yìí ni ó fa ìbínú ní ìta-gbangba, George fi orin fẹ̀sùn kan “jàndùkú soca” – ìyẹn àkójọpọ̀ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti olùdaríI wọn – fún ìpàdíàpòpọ̀ tí ó mú wọn kọ orin “Soca Kingdom” ní àsìkò ìdájọ́ láti yan ẹni tí ó jáwé olúborí."
} |
{
"en": "He sings:",
"yo": "Ó kọrin:"
} |
{
"en": "On the stage was a next set of drama, the DJs and them playing \"Savannah\"",
"yo": "Lórí ìtàgé ni eré tí ó kàn-án wà, àwọn DJ àti wọn ń kọ \"Savannah\""
} |
{
"en": "But when the mafia come, they switching from \"Savannah\" to ‘Kingdom’",
"yo": "Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn jàndùkú dé, wọ́n sún láti \"Savannah\" sí ‘Kingdom’"
} |
{
"en": "They join forces to win the big fight... this year you have to team up with Jesus Christ",
"yo": "Wọ́n pawọ́pọ̀ láti borí ìjà ńlá náà... lọ́dún yìí ẹ ní láti pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Jésù Kristì ọmọ Màríà"
} |
{
"en": "In another version of the song, George accuses Montano of \"bad talking\" him, and belittles the honorary doctorate Montano recently received from the University of Trinidad and Tobago for his contribution to soca music.",
"yo": "Nínú ẹ̀dà orin náà mìíràn , George fi ẹ̀sùn kan Montana pé ó ń \"sọ ọ̀rọ̀ àlùfànṣá\" sí òun, ó sì fi ẹnu tẹ́ oyè ọ̀mọ̀wé tí Montano ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ní Ifásitì Trinidad àti Tobago látàrí ipa tí ó kó ní ti ìgbélárugẹ orin soca."
} |
{
"en": "Soon after George’s song was released, Montano responded with \"Dr. Mashup\", in which he directly addressed allegations of rigging the Road March contest:",
"yo": "Kò pẹ́ tí a gbé orin George jáde, Montano fèsì pẹ̀lú orin tí a pe àkọlée rẹ̀ ní \"Dr. Mashup\", nínúu rẹ̀ ni ó ti sọ màdàrú tí wọ́n ṣe níbi ìdíje Ìwọ́de Ojúná:"
} |
{
"en": "That was not the end of it: at a new Carnival party, \"Hydrate\", on January 13, both artists performed. George included his new verse and Montano supposedly had the last word:",
"yo": "Kò tán síbẹ̀: níbi ayẹyẹ Ijó ìta-gbangba tuntun, \"Hydrate\", ní ọjọ́ 13 oṣù Ṣẹrẹ, àwọn akọrin méjèèjì ṣeré. George lé orin rẹ̀ tuntun Montano náà sọ ọ̀rọ̀ ìkẹyìn:"
} |
{
"en": "After their performances, Montano’s manager, Anthony Chow Lin On, posted a photo to Instagram in which he comically holds the two apart:",
"yo": "Lẹ́yìn eré, alábòójútó Montano, Anthony Chow Lin On, tari àwòrán kan sí orí Instagram tí ó fi ara jọ ẹ̀fẹ̀ ìtúká ẹni méjì tí ó ń jà:"
} |
{
"en": "The post left fans to wonder if the feud was real or simply a publicity stunt:",
"yo": "Àtẹ̀jáde náà mú ìfura dání bóyá ìjà tòótọ́ ni tàbí ète lásán-làsàn:"
} |
{
"en": "Stunt or not, many social media users following the feud have pointed out that this type of lyrical sparring (known as a \"sound clash\") is not new; in fact, it is intricately woven into the origins of calypso music, and its modern-day hybrid, soca.",
"yo": "Ète tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òǹlo ẹ̀rọ-alátagbà tó ń tẹ̀lé awuyewuye náà ti tọ́ka sí irúfẹ́ àríyànjiyàn orin báyìí (tí a mọ̀ sí \"orin ìjà\") kò jẹ́ tuntun; àti pé, ó bá orísun orin calypso mu, ó sì jẹ́ àmúlùmálà, soca."
} |
{
"en": "In a recent interview, George himself addressed the fact that he was just \"documenting the history\" as he \"always does\", following the path of legendary calypsonians who did the same.",
"yo": "Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan, George fúnra rẹ̀ sọ òtítọ́ ibẹ̀ wípé òun kàn ń \"ṣe àkópamọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ \" gẹ́gẹ́ \"bí ó ṣe máa ń ṣe\", títọpa àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí ó ti kọ orin calypso sẹ́yìn."
} |
{
"en": "While calypso music is well known for its social and political commentary, an early form of the music involved verbal dueling similar to the war of words taking place between George and Montano.",
"yo": "Orin calypso jẹ́ ìlúmọ̀nánká tí ó máa ń sọ nípa àwùjọ àti ìṣèlú, ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ orin náà ni ìsọ̀rọ̀ síra ẹni méjì tí ó fi ara pẹ́ ogun ọ̀rọ̀ tí ó ń lọ ní àárín-in George àti Montano."
} |
{
"en": "Calypso tents, where calypsonians perform during the Carnival season, were hugely popular for their \"extempo wars\", live contests in which singers would improvise lyrics on the spot mocking each other, or on a specific theme.",
"yo": "Abẹ́ àtíbàbà orin Calypso, níbi tí àwọn eléré calipso ti máa ń ṣeré ní àsìkò Ijó ìta-gbangba, gbajúmọ̀ fún \"ogun àìròtẹ́lẹ̀ \", ìdíje tí àwọn akọrin yóò kọrin èébú sí ara wọn láì rò tẹ́lẹ̀ lójú ẹsẹ̀, tàbí lórí àkọ́lé kan."
} |
{
"en": "The banter between the performers is locally referred to as \"picong\".",
"yo": "Ìfigagbága àwọn akọrin wọ̀nyí ni a mọ̀ sí \"picong\"."
} |
{
"en": "Such performances are typically interactive, with audiences echoing one of several refrains, the most common of which is \"Santimanitay!\", a derivative of the French phrase “sans humanité”, or “without pity”.",
"yo": "Irúfẹ́ eré wọ̀nyí máa ń fi àyè gba ìdásí, tí àwọn olùwòràn yóò máa gbe orin, ọ̀kan tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni \"Santimanitay!\", tí ó jẹ́ ẹ̀dà àbọ̀-ọ̀rọ̀ Faransé “sans humanité”, tàbí “àìláàánú”."
} |
{
"en": "But audiences have rarely witnessed a back-and-forth like this in recorded soca music.",
"yo": "Àmọ́ àwọn òǹwòrán kò ì tíì rí irú èyí rí nínú orin soca tí a ti ká sílẹ̀."
} |
{
"en": "And real or not, the George/Montano feud has listeners as engaged as any extempo wars audience, both at Carnival events and online.",
"yo": "Ó jẹ́ òtítọ́ tàbí kò jẹ́ òtítọ́, àwọn olólùfẹ́ẹ George/Montano dá sí ogun àìròtẹ́lẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí olùwòràn, ní Ijó ìta-gbangba àti lórí ayélujára."
} |
{
"en": "George and Montano will, very likely, both in the running for the 2019 Road March title and at the very least, the added drama makes for good entertainment and more music.",
"yo": "George àti Montano yô, láì sí àní-àní, nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúná ọdún 2019 àti èyí tí ó kéré jù lọ, awuyewuye ìjà gẹ́gẹ́ bí ìdárayá gidi àti orin."
} |
{
"en": "Soca lovers could ask for nothing more.",
"yo": "Àwọn olólùfẹ́ẹ Soca kò le è béèrè ju bẹ́hẹ̀ lọ."
} |
{
"en": "The Spiny Babbler, Nepal's only endemic bird, fascinates ornithologists and bird lovers alike",
"yo": "Spiny Babbler, ẹyẹ orílẹ̀-èdè Nepal, fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ mọ́ra"
} |
{
"en": "Spiny Babbler",
"yo": "Spiny Babbler"
} |
{
"en": "Spiny Babbler, the bird found only in Nepal. Photo by Sagar Giri. Used with permission.",
"yo": "Spiny Babbler, ẹyẹ tí a kò le è rí níbòmìrán àyàfi ní Nepal. Àwòrán láti ọwọ́ọ Sagar Giri. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ."
} |
{
"en": "Although more than 800 bird species are found in Nepal, the Spiny Babbler (Turdoides nipalensis) is the only bird that is endemic to the country.",
"yo": "Bí-ó-ti-lẹ-jẹ́-pé ẹ̀yà ẹyẹ orílẹ̀ èdè Nepal ju 800 lọ, ẹyẹ Spiny Babbler (Turdoides nipalensis) jẹ́ ẹ̀dá tí kò sí ní ibòmíràn àyàfi orílẹ̀ èdè náà."
} |
{
"en": "The greyish-brown bird, called Kaande Bhyakur in Nepali, lives in dense scrub and can be spotted more easily at elevations ranging from 500 meters to 2135 meters.",
"yo": "Ẹyẹ aláwọ̀ eérú-àti-pupa-rẹ́súrẹ́sú náà, tí à ń pè ní Kaande Bhyakur ní èdè ìbílẹ̀ Nepali, ń fi igbó ṣe ìtẹ́ a sì lè fi ojú bà á bí ó bá ń fò lókè lálá láti ìwọ̀n mítà 500 sí mítà 2135."
} |
{
"en": "Although the Spiny Babbler has been fascinating ornithologists the world around for years, environmental degradation is threatening this unique, much-loved bird.",
"yo": "Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé Spiny Babbler náà ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àgbáyé mọ́ra fún ọdún pípẹ́, ìbàjẹ́ àyíká ti ń ṣe ìdẹ́rùbà àkàndá, ẹyẹ tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn yìí."
} |
{
"en": "The book The Status of Nepal’s Birds: The National Red List Series states:",
"yo": "Ìwée nì The Status of Nepal’s Birds: The National Red List Series sọ wípé:"
} |
{
"en": "It seeks insects almost entirely on the ground among low bushes, appearing only occasionally.",
"yo": "Ó máa ń wá kòkòrò nínú koríko ilẹ̀, ẹ̀kànànkan ni a sì máa ń rí i."
} |
{
"en": "Spiny Babbler mounts branches of bushes or small trees to sing, bill pointed upward and tail down. It is a good mimic, with squeaks, chuckles and chirps.",
"yo": "Spiny Babbler máa ń bà lé ẹ̀ka koríko àti igi kéékèèké láti kọrin, àgógó ẹnu ẹyẹ yóò wà ní òkè irú ní ìsàlẹ̀."
} |
{
"en": "It is most easily located by its song and occasionally sings as late as September and October. The species is subject to seasonal altitudinal movements.",
"yo": "Ó dára ní wíwò, iké oríṣiríṣi. Orin rẹ̀ ni a fi ń mọ ibi tí ó wà, àárín oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ àti Ọ̀wàrà. Ẹ̀dá ẹyẹ yìí máa ń fò sókè lálá nínú àwọn àkókò kan nínú ọdún."
} |
{
"en": "The Spiny Babbler, found only in Nepal, has fascinated ornithologists and bird lovers from around the world. Don Messerschmidt writes about ornithologist S. Dillon Ripley’s account of the bird in his book Search for the Spiny Babbler:",
"yo": "Ẹyẹ Spiny Babbler, tí a lè rí ní Nepal nìkan, ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ káríayé mọ́ra. Don Messerschmidt kọ nípa àkọsílẹ̀ tí onímọ̀-nípa-ẹyẹ S. Dillon Ripley ṣe nípa ẹyẹ náà nínú ìwée rẹ̀ Ìṣàwárí ẹyẹ Spiny Babbler:"
} |
{
"en": "It was a species that had defied scientists for years, since 1843 or 1844.",
"yo": "Ó jẹ́ ọ̀wọ̀ ẹyẹ tí kò ka àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì sí fún ọdún gbọgbọrọ, láti ọdún 1843 tàbí 1844."
} |
{
"en": "At that time Brian Hodgson’s Nepali collectors working for him in the unknown vastnesses of Nepal had secured several specimens, he writes.",
"yo": "Ní ìgbà yẹn àwọn aṣiṣẹ́ fún Brian Hodgson tí ó jẹ́ aṣèwádìí Nepali tí ṣe àkójọ onírúurú àpẹẹrẹ, ó kọ."
} |
{
"en": "The Spiny Babbler had remained a mystery ever since, one of the five species of Indian birds, which, along with the Mountain Quail, had apparently vanished from the face of the earth.",
"yo": "Ẹyẹ Spiny Babbler ti jẹ́ ẹranko tí ó ju ìmọ̀ ènìyàn lọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́, ọ̀kan nínú ọ̀wọ̀ ẹyẹ márùn-ún ní India, pẹ̀lú Àparò Òkè gíga, kò sí lórílẹ̀ ayé mọ́n."
} |
{
"en": "But not quite, for if my guess was right, here it was hopping about large as life on the wooded slopes above Rekcha.",
"yo": "Ṣùgbọ́n bí èrò mi bá jẹ́ òtítọ́, ó ń fò kiri níbi ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Rekcha."
} |
{
"en": "Likewise, former-American ambassador to Nepal Scott DeLisi spent years trying to spot and photograph this bird.",
"yo": "Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ikọ̀-ọba orílẹ̀-èdè America tẹ́lẹ̀ sí ìlú Nepal Scott DeLisi fi ọ̀pọ̀ ọdún wá ẹyẹ yìí àti láti ya àwòrán-an rẹ̀."
} |
{
"en": "The bird is threatened by the clearance of scrub for agriculture and expansion of urban areas.",
"yo": "Ẹyẹ náà ti ń dínkù látàrí ìgbẹ́ pípa fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìtẹ́lọ ìgbèríko di ìgboro."
} |
{
"en": "Outside protected areas, it is sometimes threatened by hunting, and the hills surrounding the Kathmandu Valley have seen a decline in Spiny Babbler numbers.",
"yo": "Bí a bá yọ ti agbègbè ààbò kúrò, nígbà mìíràn pípa ẹyẹ yìí fún oúnjẹ, ní òkè kékeré tí ó yí àfonífojì Kathmandu ká ti mú kí ẹyẹ Spiny Babbler dínkù ni iye."
} |
{
"en": "However, the same habitat loss that is destroying the Spiny Babbler's habitat in some areas might actually be creating more in others.",
"yo": "Síbẹ̀, ohun tí ó ń fa àdánù ní agbègbè kan náà lè mú wọn pọ̀ ní agbègbè mìíràn."
} |
{
"en": "As the forest continues to thin due to deforestation throughout the country, the scrub-dominated habitat that they call home is being created in its wake.",
"yo": "Bí igbó ṣe ń dínkù látàrí ìgbẹ́ pípa àti igi gẹdú gígé jákèjádò orílẹ̀ èdè náà, igbó tí wọ́n fi ṣe ilé ti di ti nǹkan mìíràn."
} |
{
"en": "But only time will tell what is in store for the population of Nepal's only endemic bird.",
"yo": "Àmọ́ ṣá ìgbà àti àkókò ni yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹyẹ ìlú Nepal tí kò sí ní ibòmíràn."
} |
{
"en": "Nigeria's retired military generals battle for influence in 2019 presidential elections",
"yo": "Àwọn ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wọ̀yáàjà láti nípa lórí ètò ìdìbò ọdún-un 2019"
} |
{
"en": "Olusegun Obasanjo, former President of Nigeria.",
"yo": "Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, Ààrẹ àná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà."
} |
{
"en": "As Nigeria prepares for another presidential election in February, retired military generals turned politicians are key to understanding Nigeria's political space.",
"yo": "Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń múra fún ètò ìdìbò sí ipò Ààrẹ nínú Oṣù Èrèlé, àwọn ọ̀gágun tí ó ti jagun fẹ̀yìntì tí wọn di olóṣèlú, jẹ́ igi gbòógì fún òye ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà."
} |
{
"en": "Nigeria has been ruled by either former generals or those who have their support since 1999 when democratic governance returned.",
"yo": "Àwọn ọ̀gágun tí ó ti fẹ̀yìntì tàbí àwọn tí wọn ṣe àtìlẹ́yìn fún láti dé orí ipò ni ó ti ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 tí ìjọba tiwantiwa ti padà."
} |
{
"en": "The recent public feud between former President Olusegun Obasanjo and the incumbent President Muhammadu Buhari — both retired military dictators — has a great impact on next month's elections.",
"yo": "Asọ̀ tí ó wáyé láìpẹ́ yìí láàárín Ààrẹ àná, Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ àti Ààrẹ tí ó wà lórí àlééfà, Ààrẹ Muhammadu Buhari – tí àwọn méjèèjì jẹ́ ajagun fẹ̀yìntì afipásèjọba ológun –ní ipa tí ó pọ̀ lórí ètò ìdìbò oṣù tí ó ń bọ̀."
} |
{
"en": "In a rare open letter to Buhari, Obasanjo has accused him of plans to rig the 2019 elections. He wrote:",
"yo": "Nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí a kò rí irúu rẹ̀ rí tí ó kọ ránṣẹ́ sí Buhari, Ọbásanjọ́ fi ẹ̀sùn kàn-án wípé ó ní ètè láti ṣe èrú ìbò. Ó kọ ọ́ sínú ìwé náà wípé:"
} |
{
"en": "Democracy becomes a sham if elections are carried out by people who should be impartial and neutral umpires, but who show no integrity, acting with blatant partiality, duplicity and imbecility.",
"yo": "Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ìjọba tiwantiwa, bí ètò ìbò tí o yẹ kí ó lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀ láì fi ti apá kan ṣe, ṣùgbọ́n tí ìṣesíi wọn kò fi ìṣedéédé hàn, àìmúdọ́gba tí ó hàn kedere, ẹ̀tàn àti ìjòye àwòdì máà le è gbẹ́dìẹ."
} |
{
"en": "Obasanjo insisted that Buhari would not deliver \"free, fair, credible and peaceful elections\" and warned that what \"is happening under Buhari’s watch can be likened to what we witnessed under Gen. Sani Abacha.",
"yo": "Ọbásanjọ́ tẹnu mọ́ ọn wípé Buhari kò leè \"ṣe ètò ìbò tí ó kẹ́sẹjárí\", àti wípé ìsèjọba tiwantiwa ní abẹ́ ìṣàkóso Buhari ni a lè fi wé tí ìjọba ológun fàmílétè-kí-n-tutọ́ọ ti Gen. Sani Abacha."
} |
{
"en": "In 1998, Sani Abacha, a military dictator, had called for general elections but it became obvious that Abacha had no intention of handing power over to civilians.",
"yo": "Ní ọdún 1998, Sani Abacha, tí ó jẹ́ ológun apàṣẹwàá ní ìgbà náà, pè fún ìbò gbogboògbò ṣùgbọ́n tí ó hàn ketekete pé Abacha kò ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀ fún alágbádá."
} |
{
"en": "The five political parties at the time endorsed Abacha as their sole presidential candidate.",
"yo": "Ní àsìkò tí à ń sọ̀rọ̀ọ rẹ̀ yìí, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó fọwọ́ síi wípé kí Abacha ó jẹ́ olùdíje fún ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlúu wọn."
} |
{
"en": "Now deceased, Abacha became infamous for his repression of human rights and corruption.",
"yo": "Ní báyìí ó ti ṣípò-padà, òkìkí Abacha tàn káàkiri ó sì di ìlú-mọ̀-ọ́-ká nípa ìtẹrí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn mọ́lẹ̀ àti ìjẹgùdùjẹrà."
} |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.