category
large_stringclasses
7 values
headline
large_stringlengths
10
171
text
large_stringlengths
1
26.4k
url
large_stringlengths
13
180
lang
large_stringclasses
16 values
sports
Chelsea vs Manchester United: Ole ní Man United kò bá borí Chelsea ṣùgbọ́n rẹfirí kọ̀ láti fún wọn ní pẹnárítì
Man United kò bá lu Chelsea mọ́lé, àmọ́ rẹfirí jà wá lólè pẹnárítì- Ole yarí. Akọnimọọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ti fi aidunnu rẹ han lórí bi rẹfiri ṣe kọ lati fun Man U ni pẹnariti ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League ọjọ Aiku. Ole ni agbabọọlu Chelsea, Callum Hudson-Odoi fi ọwọ gbe bọọlu eyi to tumọ si pẹnariti. Ṣugbọn rẹfiri Stuart Atwell ko fun Man United ni pẹnariti lẹyin to tun iṣẹlẹ laarin Hudson-Odoi ati Mason Greenwood wo eyi to fihan pe bọọlu kọkọ kan oke ọwọ Greenwood ko to ba agbabọọlu Chelsea lọwọ. Amọ, Solskjaer ni ariwo tawọn alatako ẹgbẹ agbabọọlu n pa wi pe Man United ni awọn rẹfiri n fun ni pẹnariti julọ ni ko jẹ ki rẹfiri Attwell fun United ni pẹnariti. Ẹgbẹ agbabọọlu Man United ti ni pẹnariti mejilelogun ninu idije Premier League lati ibẹrẹ saa bọọlu to lọ titi di akoko yii. Eyi lo mu ki olukọni Liverpool, Jurgen Klopp ati akọnimọọgba Chelsea tẹlẹ, Frank Lampard sọrọ pe awọn rẹfiri n ṣegbe lẹyin Man United lori ọrọ pẹnariti. Ole ni eyi gan an ni ko jẹ ki awọn rẹfiri fẹ maa fun Man United ni pẹnariti mọ. Solskjaer ni ko gba ibikan ye oun idi ti rẹfiri ṣe kọ lati fun Man U ni pẹnariti. Solskjaer ṣalaye pe lai ṣe ani-ani, tẹlifisan VAR fihan pe o yẹ ki rẹfiri fun United ni pẹnariti ṣugbọn "ariwo tawọn Chelsea n pa ni pe Greenwood lo kọkọ fi apa gbe bọọlu." Àmọ́, akọnimọọgba Chelsea, Thomas Tuchel ti fesi si ọrọ Solskjaer. Tuchel ni ko si ohun to jọ pẹnariti rara ninu ohun to ṣẹlẹ laarin Hudson-Odoi ati Greenwood. Tuchel ni o ya oun lẹnu pe rẹfiri tiẹ lọ ṣ'ayẹwo iṣẹlẹ naa tẹlifísàn VAR nitori agbabọọlu Man United lo kọkọ fọwọ́ gbe bọọlu. Ami ayo mejila ni Manchester City to wa ni ipo kinni fi n ṣiwaju Man United bayii lori tabili EPL. Ipo karun un si ni Chelsea wa bayii lori tabili idije Premier League.
https://www.bbc.com/yoruba/56235725
yor
sports
Samuel Okwaraji: Ó pé ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n tí Samuel Okwaraji ṣubú lójú ìjà
Awaye ma lọ kan ko si, ọrun nikan lare mọbọ. O pe ọdun mọkanlelọgbọn lonii ọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 2020 ti gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Naijiria Samuel Sochukwuma Okwaraji ṣubu loju ija. Ṣe wọn ni iku ogun nii pa akinkanju, iku odo nii pa omuwẹ, oju ija, iyẹn lori papa ni Samuel Okwaraji ku si ninu ifẹsẹwọnsẹ fun ati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni ọdun 1990. Ifẹsẹwọnsẹ naa waye ni ọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 1989 pẹlu orilẹede Angola ni papa iṣere to wa ni Surulere niluu Eko. Ti o ba wa laye ni, Okwaraji ko ba ti pe ọmọ ọdun mẹrinlọgọta lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun ọdun 2020 yii. Ọpọ ọmọ Naijiria papaajulọ awọn ololufẹ ere bọọlu afẹsẹgba lo n ṣe iranti ẹni 're to lọ lori ayelujara. Ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF naa ko gbẹyin, niṣe ni NFF gboṣuba rabandẹ fun ẹni ire to lọ. Ajọ ni ohun ko le gbagbe ipa ribiribi ti Okwaraji ko ninu ere bọọlu ni Naijiria. NFF ni titi lai loun yoo maa ṣe iranti akọni agbabọọlu to re iwalẹ asa. Ǹjẹ́ o tilẹ̀ mọ Samuel Okwaraji, agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tó 'ṣubú lójú ìjà? Odu agbabọọlu orilẹede Naijiria ni Samuel Sochukwuma Okwaraji jẹ ni igba aye rẹ, o si ṣoju orilẹede Naijiria fun ọpọ ifẹsẹwọnsẹ. Agbẹjọro to kawe gboye ni o si tun ni iwe ẹri imọ ijinlẹ keji ninu imọ ofin ajọṣepọ ilẹ okeeere, (Masters in International Law) Ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun ọdun 1964, ni wọn bi Sam Okwaraji ni ilu Orlu ni ipinlẹ Imo, o si gba bọọlu jẹun lawọn ẹgbẹ agbabọọẹu to lorukọ ni ilẹ Yuroopu bi AS Roma (1984-1985), NK Dinamo Zagreb (1985-1986), Austria Klagenfurt (1986-1987), VfB Stuttgart (1987-1989) ati SSV Ulm 1846 (loan) (1987-1988) Ni ọdun 1988 ni Samuel Okwaraji kọkọ gba bọọlu fun orilẹede Naijiria ninu idije ife ẹyẹ Afrika ninu eyi ti o ti gba ọkan lara awọn goolu to yara wọle ju lọ ninu itan idije naa. Ka ni Okwaraji ko ku ni, oni yii, ni ko ba pe ọmọ ọdun marundinlọgọta lori oke erupẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/48325689
yor
sports
Unai Emery: Àwọn olólùfẹ́ Arsenal ní Emery gbọdọ̀ fipò rẹ̀ sílẹ̀ dandan
Ina ti jo dori koko bayii fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Unai Emery. Ọgọrọ awọn ololufẹ Arsenal ni wọn yabo oju opo ayelujara papaajulọ Twitter, nibi ti wọn ti sọ pe ki Emery kọwọ fipo rẹ silẹ tabi ki Arsenal juwe ile fun un. Agidi ni Arsenal fi gba ọmọ alayo meji si meji pẹlu ikọ agbabọọlu Southampton lopin ọsẹ to kọja ninu idije Premier League. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa lawọn ẹgbẹ alatilẹyin Arsenal kan sọ fun awọn alaṣẹ ikọ Arsenal pe ki wọm fọwọ osi juwe ile fun Emery. Ipo kẹjọ ni Arsenal wa bayii lori tabili idije Premier League eleyi to jẹ ki ọpọ alatilẹyin Arsenal maa kọminu. Ẹgbẹ naa ṣalaye pe awọn eeyan bi ọgọrun un mẹfa lo ti kọwọ bọwe pe ki Emery dagbere fun Arsenal. Bakan naa lọpọ eeyan loju opo Twitter n sọ pe o ti to asiko fun Emery lati fipo rẹ silẹ. Ọpọ lo n sọ pe kawọn alaṣẹ Arsenal gba Massimiliano Allegri tabi Mauricio Pochettino lati rọpo Emery gẹgẹ bi akọnimọọgba Arsenal.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50544644
yor
sports
Jose Mourinho: 3-2 ni Tottenham fi se àgbà fún West Ham
Ọpọ eniyan lo gboriyin fun akọnimọọgba tuntun Tottenham, Jose Mourinho pẹlu bi ikọ rẹ se na West Ham pẹlu ami ayo mẹta si meji. Son Heung-min lo kkọ fi bọọlu sinu awọn, lẹyin ti Dele Alli gba bọọlu fun un, ti o si wọ inu awọn. Ni se ni Jose n tọ soke sodo, ti inu re si n dun de di. Lucas Moura lo gba bọọlu keji wọnu awọn, nigbati Harry Kane si ran Serge Aurier lọwọ lati gba bọọlu naa wọ inu. Michail Antonio ti ikọ West Ham ati Angelo ogbonna lo gba bọọlu wọle fun ikọ naa ti ayo fi pari si 3-2. Igba akọkọ ni yii ti akọnimọọgba naa yoo ma a tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham lẹyin ti wọn le ni ikọ Chelsea ati Manchester United.
https://www.bbc.com/yoruba/50531633
yor
sports
Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Arsenal, Mikel Arteta náà ti fara káásá àrùn Coronavirus
Awọn alakoso idije Premier League ti wọgile ifẹsẹwọnsẹ to yẹ ko waye laarin ikọ naa ati Brighton lọjọ Abamẹta lẹyin ti akọnimọgba ikọ Arsenal, Mikel Arteta lugbadi arun Coronavirus, Iṣẹlẹ yi ti mu ki ikọ ọhun gbe kọkọrọ ṣẹnu ilẹkun papa iṣere ti wọn ti n ṣe igbaradi, lẹyin naa ni wọn ya awọn eeyan to ṣalabapade akọnimọgba naa sọtọ fun ayẹwo ati itọju. Ni bayii, awọn alakoso idije Premier League yoo ṣepade pajawiri lọjọ Ẹti lati jiroro lori ọjọ iwaju idije naa ni saa yi. Nigba ti esi ayẹwo rẹ fihan pe o ti Lugbadi arun ọhun, ẹni ọdunn ọdun mẹtadinlọgbọn naa ni "O ṣeni laanu." Arteta sọ pe oun lọ ṣayẹwo lẹyin ara oun rẹwẹsi, leyi to fi han pe Coronavirus lo n ba finra. Ṣugbọn o ti wa ni oun yoo fẹ lati pada sẹnu iṣe laipe ni kete ti awọn dokita ba ti fun ni aye ati ṣe bẹ. Ọkan lara awọn adari ikọ Arsenal, Vinai Venkatesham sọ fun awọn akọroyin pe ilera awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ati awọn ololufẹ wọn lo jẹ ikọ naa logun. Ikọ ọhun ti wa ni pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu naa ni wọn yoo fi si apapmọ fun ayẹwo.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51867378
yor
sports
Joshua vs Fury: Anthony Joshua bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti kojú Tyson Fury nínú ìjà tí yóò yeruku lálá
Ohun to ba ti ya kan, kii tun pẹ mọ, abẹṣẹ ku bi ojo, Anthony Joshua ti bẹrẹ igbaradi fun ija rẹ pẹlu Tyson Fury. Olukọni Joshua, Joby Clayton ṣalaye pe AJ ti n gbiyanju oriṣiiriṣii ọna lati gbaradi fun ija naa. Onigbọwọ Joshua, Eddie Hearn lo kede laipẹ yii pe AJ ti buwọlu ija meji pẹlu Fury lati le mọ ẹni to le ja ju ni ipele awọn akẹṣẹ to lagbara ju. Clayton sọ pe ati okeere ni olujinjin ti maa n mẹkun sun ni ọrọ igbaradi Joshua fun ija rẹ pẹlu Fury. Olukọni Joshua to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Rob McCracken ṣalaye pe iṣẹ oun ni lati rii pe Joshua wa ni igbaradi lati koju Fury. ''Fury kii ṣe ẹran rirọ, o ṣoro lati mọ oriṣiiriṣii ọgbọn ti o maa n lo ti o ba n ja,'' Clayton lo sọ bẹẹ. Clayton ni Joshua n ṣe daadaa ninu igbaradi rẹ nitori oun gan an mọ pe ija pẹlu Fury yoo nipa to lagbara lori rẹ gẹgẹ bi akẹṣẹ. ''A maa n ri pe AJ simin lasiko to ba yẹ ki o sinmin nitori gbogbo igba kọ ni o gbọdọ fi maa ṣe igbaradi,'' Clayton ṣalaye. Laipẹ yii ni onigbọwọ Joshua, Hearn kede ibi ti ija naa yoo ti waye. Hearn sọ pe AJ ko beṣu bẹgba lori igbaradi rẹ fun Fury nitori o mọ iru akẹṣẹ ti Fury jẹ. Amọ, Hearn ni gbogbo ohun ti Joshua n ro ni ọna lati jawe olubori ninu ija naa.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-56425948
yor
sports
Mikel Obi: Orílẹ̀èdè Egypt ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ayò, ibẹ̀ náà ló parí sí
Eyi ti mo ṣe to! Ọrọ yi ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ọkunrin Naijiria, John Mikel Obi sọ l'Ọjọbọ. Balogun Super Eagles, Mikel to fọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ, sọ pe, asiko ti to fun oun lati fi ikọ agbabọọlu Naijiria silẹ. Mikel fi fọto ara rẹ soju opo Instagram, o sọ pe orilẹede Egypt loun ti bẹrẹ si soju Naijiria, nibẹ naa si ni oun pari rẹ si. O sọ pe ni Egypt lọdun 2006 loun ti ṣoju Naijiria ninu idije AFCON fun igba akọkọ, bakan naa ninu idije AFCON 2019 loun ti fi adagba rọ bọọlu gbigba fun Naijiria si. Mikel dupẹ lọwọ Naijiria fun anfani lati ṣoju orilẹede rẹ ninu oniruuru idije ere bọọlu. Mikel ni oun gbe igbesẹ lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria silẹ lati fun awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu laaye. O ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles gbiyanju ninu idije AFCON 2019, lẹyin ti wọn gba ami ẹyẹ baba(Bronze) tii ṣe ipo kẹta. Naijiria na Tunisia pẹlu ami ayo kan sodo l'Ọjọru lati gba ipo kẹta.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49034370
yor
sports
Liverpool vs Arsenal: Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield
Ajura wa lọ, ti ijakandi kọ o! Liverpool kọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹkọ ti wọn ko le gbagbe ni papa iṣere Anfield lọjọ Abamẹta. A na sare ni Liverpool lu Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League nirọlẹ ọjọ Satide. Ami ayo meji sodo ni wọn fi fẹyin Arsenal gbi lẹ ni Anfield. Adilemu, Joel Matip lo kọkọ fori kan bọọlu wọ le Arsenal, ki David Luiz to fa Mohamed Salah laṣọ nigba to fẹ gbayo sawọn, ni rẹfiri ba fọn feere pẹnariti. Salah ko beṣu bẹgba, niṣe lo gba pẹnariti naa wọ le, eleyi to mu Liverpool siwaju pẹlu ami ayo meji sodo. Laipẹ lai jina, Salah tun gbayo sawọn eleyi to jẹ ki Liverpool siwaju pẹlu ami ayo mẹta sodo ti Arsenal ko si ri ọkankan da pada. Amọ, Lucas Torreira gbiyanju lati dayo kan pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju marun un ko pari. Pierre-Emerick Aubameyang ati Nicolas Pepper to ṣẹṣẹ rọpo mọ Arsenal lanfaani lati gba goolu sawọn fun Arsenal, ṣugbọn wọn ko lo anfaani ti wọn ni.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49462334
yor
sports
Barcelona vs Osasuna: Real Madrid gbadé ògo La Liga, Messi ní Barcelona ò lè ta pútú mọ́
Nibi ti ẹlẹkun ti n sunkun lalayọ ti n yọ. Bayii lọrọ ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona. Bi idunnu ti ṣubu layọ fun Madrid lẹyin ti wọn fagba han Villareal eyi to mu wọn gba ife ẹyẹ La Liga fun igba kẹrinlelọgbọn, nnkan ko ṣẹnu ire fun Barca ni ti wọn. Ẹgbẹ agbabọọlu Osasuna to bawọn lalejo lo dẹru iya le wọn lori eleyi lo mu Lionel Messi koro oju ti o si fi ibinu sọrọ. Messi ti juwe ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona gẹgẹ bi ikọ ti ko lagbara lẹyin ti ikọ Osasuna gbo ewuro si wọn loju pẹlu ami ayo meji si ọkan ni Nou Camp. Ibanujẹ dori agba Messi kodo lẹyin ti ijakulẹ Barcelona pẹlu Osasuna gba ife ẹyẹ La Liga mọ Barcelona lọwọ lalẹ Ọjọbọ. Ajẹkun iya ti Barcelona jẹ lọwọ Osasuna yii n tumọ si pe ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ni yoo gba ife ẹyẹ naa lai wo ohun ti ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu Villarreal yoo ba jade. Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Spanish TV sọrọ lẹyin ifẹṣwọnsẹ ọhun, Messi sọ pe "Esi ti a ri kọ la lero pe a o ri, ẹgbẹ agbabọọlu wa ko lagbara to." O tẹsiwaju pe "Awa gangan ni wọn n pe ni Barcelona, o si yẹ ki a maa bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ wa ni, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri bayii." José Arnaiz Diaz lo kọkọ sọ bọọlu sinu awọn Barcelona lẹyin iṣeju marundinlogun ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ṣugbọn Messi da pada ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Laarin iṣẹju diẹ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo pari ni Roberto Torres tun ri ẹyin awọn Barcelona nigba kan sii, eyi to mu ki goolu Osasuna di meji. Oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni idije La Liga gberasọ pada lẹyin ti wọn ti kọkọ da a duro nitori ajakalẹ arun Covid-19.
https://www.bbc.com/yoruba/53440887
yor
sports
Sergio Aguero: Ẹ̀rù n ba àwọn agbabọọlu láti padà sí ìdíje Premier League tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ padà
Atamatase fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester City, Sergio Aguero ti sọ pe ẹru a ti pada sori papa n ba awọn agbabọọlu pẹlu bi aarun coronavirus ṣe n tankalẹ.Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ni ireti wa pe idije Premier League yoo tẹsiwaju, eyi to tumọ si pe awọn agbabọọlu gbọdọ pada si papa igbaradi lọjọ kejidinlogun, oṣu Karun. Awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ṣe koko yoo si ṣe ipade lọjọ Ẹti lati jiroro lori ọna ti wọn yoo gbe e gba.Aguero sọ pe" ẹru n ba pupọ ninu awọn agbabọọlu nitori pe wọn ni ọmọ ati ẹbí." Lasiko to n ba ileesẹ amohunmaworan El Chiringhito sọrọ, ọmọ orilẹ-ede Argentina ọhun sọ pe: "Ẹru n ba mi, sugbọn emi ati ọrẹbinrin mi lajọ wa nibi, mi o si ni i ifarakanra pẹlu awọn eeyan miran. Inu ile mi ni mo wa, ọrẹbinrin mi si nikan ni mo le ko o ran."Wọn sọ pe awọn kan wà to ni Covid-19, sugbọn ti ko fi àpẹẹrẹ kankan han, tí wọn si le ko ran elomiran. Nitori naa ni mo ṣe duro sile, tori boya mo ni aarun naa ti mi o mọ."Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta ni wọn so idije Premier League rọ nitori coronavirus, sugbọn gbogbo awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu lo ṣetan lati gba ifẹsẹwọnsẹ mejilelaadọrun to ṣẹku.Wọn yoo si gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ naa lai si eero iworan. Bakanna ni wọn n gbeero lati fi awọn idije kan han lori amohunmaworan lọfẹ. Ẹwẹ, àwọn oludari eto ilera yoo sepade lọjọ Ẹti lati jiroro lori ilana ti wọn yoo gbe nkan gba.BBC Sport ri i gbọ wi pe wọn yoo ṣe ayẹwo aarun coronavirus fun awọn agbabọọlu lẹẹmeji lọsẹ, ti igbaradi ba bẹrẹ saaju ki ofin konile o gbele to kasẹ nilẹ. Bakan naa ni awọn agbabọọlu gbọdọ maa lo í ọmú ni gbogbo igba ti wọn ba wa ni papa. Wọn ko si gbọdọ si oúnjẹ jíjẹ tabi iwẹ ni ibudo naa.Awọn eleto ilera to ṣe koko nìkan si ni anfaani yoo wa fun lati wọle, wọn si gbọdọ wọ aṣọ idaabo bo. Gbogbo ipade ati ijiroro gbọdọ maa waye lori ayelujara. Sugbọn sa, atamatase ẹgbẹ́ agbabọọlu Brighton, Glenn Murray sọ pe awọn ilana kan ti wọn la kalẹ le ma a ṣíṣẹ, paapa ibomu lilo nitori pe "awọn agbabọọlu yoo ma a yọ sọnu lasiko ti wọn ba n gba bọọlu". O sọ pe "idi ti awọn eeyan fi fẹ́ ẹ pada sori papa ye mi, sugbọn wọn gbọdọ ṣe e ni ọna to mu ọgbọ́n dani, ati ni asiko to tọ́, ni ọna ti aabo yoo fi wa fun gbogbo eniyan, nitori pe kaakiri agbaye ni awọn agbabọọlu yoo ti wa, ko si si ẹni to mọ àwọn to ni i"."Mo ni awọn ọmọ nilẹ, mi o si ni i fẹ́ fi wọn sinu ewu. Awọn agbabọọlu kan ni ọmọ tuntun nile, bẹ ẹ làwọn kan si n gbé pẹlu arugbo wọn. Nitori naa, igbesẹ ti ko bojumu ni bi wọn ṣe sọ pe ki idije o bẹrẹ pada. Ẹgbẹ́ agbabọọlu Arsenal, Brighton ati West Ham ti si ibudo igbaradi wọn silẹ fun awọn agbabọọlu lati ma a da ṣe igbaradi.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-52514390
yor
sports
TUNNGR: Ta ló ṣe móríyá fún ọ jù lọ ní Super Eagles?
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria ti pari ifẹsẹwọnsẹ wọn ninu idije ilẹ Afirka, lẹyin ti wọn pari pẹlu ipo kẹta ninu idije Afcon 2019. Tunisia ni Super Eagles naijiria fi se ifajẹ ti wọn se ipo keta. Bi awọn kan se n sọ wi pe Ighalo lo fakọyọ julọ ninu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ni idije Afcon naa. Amọ, awọn miran ni Chukwueze ati Ighalo tiraka ṣugbon Etebo ni fun awọn, ti awọn miiran si ni ẹni miran lo se moriya fun wọn. Bakan naa ni awọn kan ni gbogbo igba ni ikọ Super Eagles ma n se ipo kẹta, eleyii ti wọn tilẹ pe ni "ogun ibi wa lorilẹede Naijiria".
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49027665
yor
sports
Kareem Benzema, atamátàsé Real Madrid gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or 2022
Gbajumọ agbabọọlu ọmọ orilẹede France, Kareem Benzema to n gba bọọlu jẹun ni ikọ Real Madrid lorilẹede Spain ni o gba ami ẹyẹ Ballon d’Or ti ọdun yii. Igba akọkọ rẹ ree lati gba ami ẹyẹ yii. Goolu mẹrinlelogoji ni Benzema gba sinu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlaadọta to gba ni saa bọọlu ọdun 2021-22 to kọja nibi to ti lewaju ikọ Real Madrid lati gba ife ẹyẹ Champions league ilẹ Yuroopu ati ife ẹyẹ La liga ti liigi orilẹede Spain. Lionel Messi ni agbabọọlu to gba ami ẹyẹ yii nigba to pọju. Igba meje ọtọọtọ lo ti gba a. Lẹyin rẹ ni Christiano Ronaldo to gba a fun igba marun un ọtọọtọ, Michel Platini, Johan Cruyff ati Marco van Basten ti gba a nigba mẹta ọtọọtọ. Sadio Mane, ọmọ Senegal to n gba bọọlu  jẹun ni ikọ Bayern Munich bayii lẹyin to fi ikọ Liverpool to to wa ni saa to kọja silẹ lo ṣe ipo keji ti Kevin de Bruyne, ọmọ Belgium to n gba bọọlu jẹun ni Manchester city nilẹ Gẹẹsi ṣe ipo kẹta. Putellas, agbabọọlu obinrin fun ikọ obinrin Barcelona lo ṣi di ife ẹyẹ Ballon d’Or ti Obinrin mu gẹgẹ bi agbabọọlu to ta sansan julọ lọdun 2022. Beth Mead, ọmọ ilẹ Gẹẹsi to n gba bọọlu jẹun ni ikọ obinrin Arsenal lo ṣe ipo keji si. Beth Mead wa lara ikọ England to gba ife ẹyẹ Euro 2022 fawọn obinrin ilẹ Yuroopu loṣu diẹ sẹyin. Ipo kẹrindinlogun ni Asisat Oṣoala ọmọ Naijiria wa gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to pegede lagbaye. Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city lo gba ife ẹyẹ ẹgbẹ agbabọọlu to ta sansan julọ lọdun 2022. Agbabọọlu Manchester city mẹfa ọtọọtọ lo wọ aṣekagba ipele n pele nibi ami ẹyẹ naa. Kevin de Bruyne, Joao Cancelo, Riyad Mahrez, Erling Haaland, Phil Foden fun ipele  ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ, nigba ti aṣọle wọn Ederson ṣe ipo kẹta ni ipele aṣọle to pegede julọ. Liverpool lo gba ami ẹyẹ naa lọdun to kọja. Ọkọ ere idaraya ere sisa racing car ni wọn fi gbe ife ẹyẹ Ballon d’Or wọ gbagede ibudo ami ẹyẹ naa lọjọ Aje. Gbajumọ awakọsaregbayi ni torukọ rẹ n jẹ Esteban Ocon lo si wa ọkọ na wọ ibudo Theatre du Chatelet ti ayẹyẹ naa ti waye. Benzema ni yoo jẹ ọmọ orilẹede France ti yoo tun gba ami ẹyẹ yii lẹyin ti Zinedine Zidane gba a lọdun 1998. “Ami ẹyẹ to wa niwaju mi yii fun mi layọ gidigidi. Nigba ti mo wa ni kekere, alaa rere ti mo n ni nigba ewe ni. Mi o tẹti ninu ileoa rẹ. Ko si ohun ti ko ṣe e ṣe.” Ni ọr Benzama lẹyin to gba mi ẹyẹ yii. 1. Karim Benzema (Real Madrid, France). 2. Sadio Mane (Bayern Munich, Senegal). 3. Kevin de Bruyne (Manchester City, Belgium). 4. Robert Lewandowski (Barcelona, Poland). 5. Mohamed Salah (Liverpool, Egypt). 6. Kylian Mbappe (Paris St-Germain, France). 7. Thibaut Courtois (Real Madrid, Belgium). 8. Vinicius Junior (Real Madrid, Brazil). 9. Luka Modric (Real Madrid, Croatia). 10. Erling Haaland (Manchester City, Norway). 11. Son Heung-min (Tottenham Hotspur, South Korea) 12. Riyad Mahrez (Manchester City, Algeria). 13. Sebastien Haller (Borussia Dortmund, Ivory Coast). 14. Fabinho (Liverpool, Brazil) ati Rafael Leao (AC Milan, Portugal). 16. Virgil van Dijk (Liverpool, Netherlands). 17. Luis Diaz (Liverpool, Colombia) ati Dusan Vlahovic (Juventus, Serbia) ati Casemiro (Manchester United, Brazil). 20. Cristiano Ronaldo (Manchester United, Portugal). 21. Harry Kane (Tottenham Hotspur, England). 22. Trent Alexander-Arnold (Liverpool, England) ati  Phil Foden (Manchester City, England) ati Bernardo Silva (Manchester City, Portugal). 25. Joao Cancelo (Manchester City, Portugal) ati Joshua Kimmich (Bayern Munich, Germany), Mike Maignan (AC Milan, France), Antonio Rudiger (Real Madrid, Germany), Darwin Nunez (Liverpool, Uruguay) ati Christopher Nkunku (RB Leipzig, France). Ami ẹyẹ Ballon d’Or wa fun agbabọọlu to ba ta sansan julọ laarin ọdun kan. Iṣedede wọn ni saa liigi ọdun 2021 si 2022 ni wọn fi ṣe igbelewọn wọn. Ede faranse ni wọn fi pe e, itumọ rẹ si ni bọọlu ti a fi wura ṣe. Ami ẹyẹ ti ileeṣẹ iwe iroyin kan ti orukọ rẹ n jẹ France Football bẹrẹ si ni fun awọn agbabọọlu ni. Lọdun 1956 ni akọkọ rẹ kọkọ waye. Laarin ọdun 2010 si 2015,  pẹlu adehun pẹlu ajọ ere bọọlu lagbaye, wọn da ami ẹyẹ naa pọ mọ ami ẹyẹ ami ẹyẹ bọọlu agbaye ti FIFA ti wọn da silẹ lọdun 1991. Amọṣa ajọṣepọ naa pari lọdun 2016, wọn si da ami ẹyẹ naa pada si orukọ to n jẹ lati ibẹrẹ, iyẹn Ballon d’Or ti FIFA naa si pada si orukọ ti oun naa n jẹ tẹlẹ. Ayẹyẹ ami ẹyẹ Ballon d’Or tọdun 2022 ni ẹlẹkẹrindinlaadọrin iru ẹ ti yoo waye. Stanley Matthews, ọmọ orilẹede England to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Blackpool nigba naa lo kọkọ gba a lọdun 1956; Alfredo Di Stéfano lo gba a lọdun 1957 ti Raymond Kopa tẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid kan naa si gba a lọdun 1958. Awọn yooku to ti gba ami ẹyẹ naa niwọnyii: Alfredo Di Stéfano                            Real Madrid                        1959 Luis Suárez                                         Barcelona                              1960 Omar Sívori                                        Juventus                                1961 Josef Masopust                                 Dukla Prague                        1962 Lev Yashin                                         Dynamo Moscow                1963 Denis Law                                           Manchester United             1964 Eusébio                                              Benfica                                   1965 Bobby Charlton                                Manchester United              1966 Flórián Albert                                   Ferencvarós                           1967 George Best                                       Manchester United               1968 Gianni Rivera                                    Milan                                       1969 Gerd Müller                                       Bayern Munich                      1970 Johan Cruyff                                      Ajax                                         1971 Franz Beckenbauer                          Bayern Munich                     1972 Johan Cruyff                                      Barcelona                               1973 Johan Cruyff                                      Barcelona                               1974 Oleg Blokhin                                      Dynamo Kyiv                         1975 Franz Beckenbauer                           Bayern Munich                     1976 Allan Simonsen                                   Borussia Mönchengladbach 1977 Kevin Keegan                                     Hamburger SV                        1978 Kevin Keegan                                     Hamburger SV                        1979 Karl-Heinz Rummenigge                   Bayern Munich                    1980 Karl-Heinz Rummenigge                   Bayern Munich                    1981 Paolo Rossi                                        Paolo Rossi                            1982 Michel Platini                                     Juventus                                1983 Michel Platini                                     Juventus                                1984 Michel Platini                                     Juventus                                1985 Igor Belanov                                       Dynamo Kyiv                          1986 Ruud Gullit                                         Milan                                        1987 Marco van Basten                              Milan                                       1988 Marco van Basten                              Milan                                       1989 Lothar Matthäus                                Internazionale                       1990 Jean-Pierre Papin                              Marseille                                 1991 Marco van Basten                              Milan                                       1992 Roberto Baggio                                 Roberto Baggio                     1993 Hristo Stoichkov                                Barcelona                               1994 George Weah                                     Milan                                       1995 Matthias Sammer                               Borussia Dortmund               1996 Ronaldo                                              Internazionale                        1997 Zinedine Zidane                                Juventus                                  1998 Rivaldo                                               Barcelona                               1999 Luís Figo                                           Real Madrid                            2000 Michael Owen                                    Liverpool                                2001 Ronaldo                                              Real Madrid                            2002 Pavel Nedvěd                                    Juventus                                2003 Andriy Shevchenko                           Milan                                       2004 Ronaldinho                                       Barcelona                               2005 Fabio Cannavaro                               Real Madrid                            2006 Kaká                                                   Milan                                       2007 Cristiano Ronaldo                             Manchester United                2008 Lionel Messi                                      Barcelona                               2009 Lionel Messi                                       Barcelona                               2010 Lionel Messi                                       Barcelona                               2011 Lionel Messi                                       Barcelona                               2012 Cristiano Ronaldo                             Real Madrid                            2013 Cristiano Ronaldo                             Real Madrid                            2014 Lionel Messi                                       Barcelona                               2015 Cristiano Ronaldo                             Real Madrid                            2016 Cristiano Ronaldo                             Real Madrid                            2017 Luca Modric                                       Real Madrid                            2018 Lionel Messi                                       Barcelona                               2019 Ami ẹyẹ naa ko waye lọdun 2020 nitori ajakalẹ arun COVID-19 Lionel Messi                                       Barcelona                               2021 Kareem Benzema                               Real Madrid                            2022
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cw57vrkg4g4o
yor
sports
Manchester United vs Arsenal: Ta ni yóò borí nínú ìjà arọ méjì yìí?
Ẹgbẹ agbabọọlu meji ti muṣemuṣe wọn ko da muṣemuṣe to, Manchester United ati Arsenal lo fẹ koju ara wọn lalẹ ọjọ Aje ni papa iṣere Old Trafford ninu idije English Premier League. Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ni wọn kọ lati ṣe iwuri fawọn ololufẹ lati igba ti saa bọọlu tuntun yii ti bẹrẹ. Ikọ Man U ni tiẹ ti fidi rẹmi nigba meji, bẹẹ ni wọn ta ọmi lẹẹmeji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti wọn gba ninu idije EPL ti saa yii. Ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Manchester UNited ti jawe olubori ninu ere bọọlu mẹfa ti wọn kopa ninu rẹ. Arsenal tun gbe pẹẹli diẹ ni ti wọn nitori ipo kẹjọ lawọn wa nigba ti Man U wa ni ipo kọkanla lori tabili idije EPL. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ni Arsenal ti fakọyọ ninu meje ti wọn ti gba ni saa bọọlu yii. Arsenal fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kan, bẹẹ ni ni wọn ta ọmi ninu ere bọọlu meji.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49875301
yor
sports
Ẹgbẹ́ agbẹjọ́rò NBA fọnmú lórí bí ọlọ́pàá ṣe pa ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ l‘Eko
Ẹgbẹ Agbẹjọro nilẹ Naijiria, NBA, tí koro oju sì bí awọn ọlọpaa ṣe ṣekupa ọkan lara ọmọ ẹgbẹ wọn, Omobolanle Raheem lọjọ ọdun keresimesi ni agbegbe Ajah nilu Eko. NBA ni kiakia, ki ileeṣẹ ọlọpaa kede orúkọ ọlọpaa to ṣe kọlu naa sita. Iṣẹlẹ ọhun waye nigba ti oloogbe ati awọn mọlẹbi rẹ n ti ile jọsin bọ lọjọ Aiku to jẹ ọjọ keresimesi. Ninu atẹjade to fi lede, Aarẹ NBA, Yakubu Chonoko ni ẹgbẹ naa n ṣe akitiyan lati ba awọn mọlẹbi ọhun kẹdun lori iku ọmọ ẹgbẹ. O ni awọn si ti pinnu lati dìde iranlọwọ fun mọlẹbi ọhun. Chonoko ni awọn ti bẹrẹ iwadi lori ọlọpaa to ṣe iṣẹ buruku ọhun, ti awọn si ti kan si Kọmisona fun Ileeṣẹ ọlọpaa fun ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi. O tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi idi rẹ mulẹ fun awọn pe orúkọ afurasi ọlọpaa to ṣekupa oloogbe naa ni ASP Drambi Vandi, ẹni to ti wa lẹnu isẹ ọlọpaa fun ọpọlọpọ ọdun. "A rọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lati kede orúkọ awọn ọlọpaa wọnyi fun gbogbo ọmọ Naijiria. "Ẹ kede wọn fun wa, gbogbo nnkan to yẹ ka mọ ni kí ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko kede fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria." Bakan naa ni Gomina Ipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi oloogbe Omobolanle Raheem. Sanwo-Olu wa n fi da awọn mọlẹbi loju pe ijọba yoo ri pe idajọ òdodo waye lori isẹlẹ naa. Sanwo-Olu ni o ṣe ni laanu pe awọn to yẹ ko da bobo awọn araalu naa lo tun ṣekupa wọn, sugbọn ijọba oun ko ni fi ọwọ lẹran lori ọrọ naa. O ni inu oun dun pupọ pe afurasi apaniyan ti wa ni atimọle ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn si ti gba gbogbo ohun ija lọwọ re. Gomina wa ro awọn eeyan ipinlẹ Eko lati ṣe suuru lori ọrọ naa atipe ìjọba ìpinlẹ Eko ti setan lati ri pe idajọ jẹyọ lori iku Omobolanle Raheem Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti paṣẹ pe ki iwadii to ya kanmọ-kanmọ waye lori iku Amofin Ọmọbọlanle Raheem, ti ọlọpaa kan yinbọn pa. Ọga ọlọpaa Alkali Baba tun paṣẹ pe ohunkohun ko gbọdọ di fifi kọlọransi ọlọpaa naa jofin ni kiakia. O ṣalaye ninu atẹjade kan, eyi ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi fọwọsi, pe iṣẹlẹ buruku naa kii ṣe afihan ihuwasi ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria. Bakan naa lo tun ba awọn ẹbi oloogbe naa kẹdun ẹni wọn to lọ. O si tun kilọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn maa fi iwa ọmọluabi kun iṣẹ wọn ni gbogbo igba. Ọga agba ọlọpaa ni Naijiria naa tun fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe gbogbo ika to ba ṣẹ lori ọrọ naa ni ida ofin yoo ge. Ọlọpaa kan ti wọn ko darukọ rẹ ti yinbọn pa obinrin agbẹjọro kan, Bolanle Raheem, lagbegbe Ajah, nipinlẹ Eko. Iroyin ni asiko ti oloogbe naa atawọn ẹbi rẹ n bọ lati ijọsin ọjọ ọdun Keresimesi ni iṣẹlẹ naa waye. Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ọlọpaa ọhun atawọn akẹgbẹ rẹ gbiyanju lati mu ọkọ Bolanle duro ki iṣẹlẹ naa to waye. Asiko ti ọkọ ti Bolanle wa ninu rẹ n gbiyanju lati yi obiripo to wa labẹ afara Ajah ni ọlọpaa naa ṣina ibọn bolẹ. Amọ nigba ti wọn yoo fi gbe dele iwosan Bolanle ti jade laye. Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hudeyin ti sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to ṣeni laanu. Ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, ọwọ awọn ti tẹ ọlọpaa to yinbọn pa oloogbe naa, yoo si foju wina ofin. Hundeyin sọ pe “A ti fi ọlọpaa to yinbọn atawọn meji mii si atimọle.” O fi kun pe awọn yoo tun tare ẹjọ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọhun to n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti fun iwadii ni kikun. Lẹyin naa lo ni ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kan si awọn mọlẹbi oloogbe ọhun. O ni “Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ba awọn ọrẹ ati mọlẹbi agbẹjoro Bolanle Raheem kẹdun.” “Kọmiṣọna ọlọpaa, CP Abiodun Alabi ti kan si awọn ẹbi oloogbe naa ati ẹgbẹ awọn agbẹjọro, NBA lana, o si fi da wọn loju pe wọn yoo ri idajọ ododo gba.” Wayi o, ọpọ awọn araalu lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ileesẹ ọlọpaa fun bi awọn oṣiṣẹ rẹ ṣe n dukoko, ti wọn si maa n fi iya jẹ araalu lọna ti ko ba ofin mu.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c9xwyz7xdgdo
yor
sports
Messi fi ìtàn lélẹ̀, Ife ẹ̀yẹ àgbáyé di ti Argentina lẹ́yìn ọdún 36
Orílẹ̀ èdè Argentina ti borí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 2022 èyí tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Qatar. Orílẹ̀ èdè France ni Argentina lù láti fi gba ife ẹ̀yẹ náà. Aago mẹ́rin ìrọ́lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejìlá ní àṣekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ní ogúnjọ́, oṣù Kọkànlá wáyé ní pápá ìṣéré Lusail ní orílẹ̀ èdè Qatar. Góòlù mẹ́ta mẹ́ta ni France àti Argentina fi parí ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ náà kí wọ́n tó gbá pẹnáritì. Messi ló jẹ góòlù méjì fún Argentina tí Angel Di Maria sì fi ẹyọ̀kan le. Kylian Mbappe ló jẹ góòlù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún orílẹ̀ èdè France. Nígbà tí ìdíje náà parí sí ọ̀mì ni wọ́n gbá pẹnáritì àmọ́ France pàdánù sọ́wọ́ Argentina. Góòlù mẹ́rin sí méjì ni Argentina fi fàgbà han France láti fi gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé. Orílẹ̀ France ló gba ipò kejì nígbà tí Croatia gba ipò Kẹta lẹ́yìn tí wọ́n ná Morocco ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c979zlp9l7go
yor
sports
Carabao cup: Iheanacho gba góòlù wọlé láti ra Leicester city padà lọ́wọ́ ìfìdírẹmi
Ipele to kangun si aṣekagba ni idije Carabao cup waye ni ilẹ Gẹẹsi ṣugbọn ori lo ko ikọ agbabọọlu Leicester city yọ lọwọ idojuti ni kọọrọ iyara wọn ni papa iṣere Kings power. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ lo ti wo o pe irọrun ni ifẹsẹwọnsẹ ọhun yoo ba de fun ikọ naa amọṣa omi fẹrẹ t'ẹyin wọ igbin wọn lẹnu. Ọpẹlọpẹ goolu kan ti Kelechi Iheanacho gba wọle ni ko jẹ ki Aston villa na Leicester city mọle lẹyin ti Frederic Guilbert ti kọkọ fi ori gbe goolu wọle fun Villa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejidinlogun. Abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa ni wọn gbe Iheanacho wọle ti o si jẹ goolu naa. Ninu ọrọ rẹ, olukọ ẹgbẹ agbabọọlu Leicester city, Brendan Rodgers ṣapejuwe Kelechi gẹgẹ bii agbabọọlu ti ẹbun rẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin. O ni lootọ ni pe Iheanacho kii fi bẹẹ ri aye gba bọọlu ki oun to de gẹgẹ bi olori ikọ naa ṣugbọn lati igba ti oun ti de loun ti bẹrẹ si nii fun un ni aye lati maa dabira lori papa, eleyi to ni o si ti n so eso rere. Bakan naa lo ni agbabọọlu ọmọ Naijiria naa a maa ṣe iṣẹ takuntakun ni gbogbo igba to si jẹ pe eyi ti n fara han ninu ayo to n gba bayii.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51044377
yor
sports
Lionel Messi: Ronaldinho ní Messi kọ́ ni agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ lágbàáyé
Ọrọ yii dabi ẹni pe ko ni tan nilẹ bọrọ. Ọpọ lo ti n sọ pe aramọnda agbabọọlu Barcelona ati Argentina, Lionel Messi ni agbabọọlu to dara julọ ninu itan. Bakan naa, ọpọ ni wọn ko gba pe Messi ni agbabọọlu to dantọ julọ lagbaaye. Agbabọọlu Brazil tẹlẹ ri orilẹede Brazil to jẹ akẹgbẹ Messi ni ikọ Barcelona, Ronaldinho wa lara awọn to gbagbọ pe Messi kọ ni agbabọọlu to dantọ julọ ninu ere bọọlu. Laipẹ yii ni Messi gbami ẹyẹ Ballon D'or nilẹ Faranse fun igba kẹfa, amọ Ronaldinho t'oun naa gbami ẹyẹ Ballon d'or lọdun 2005 sọ pe oun ko le pe Messi ni agbabọọlu to dara julọ lagbaaye ninu itan. Ronaldinho ni idunnu lo jẹ fun oun pe Messi gbami ẹyẹ Ballon fun igba kẹfa loṣu yii amọ agbabọọlu bi Pele, Maradona, ati Ronaldo ko le jẹ ki sọ wi pe Messi lo dara julọ ninu itan. "Ohun ti mo le sọ ni pe Messi lo dantọ julọ laarin gbogbo awọn agbabọọlu to wa lasiki tirẹ,'' Ronaldinho lo woye bayii. Cristiano Ronaldo lo ṣi keji lẹyin ti oun naa ti gba ami ẹyẹ Ballon d'or fun igba marun un.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50784072
yor
sports
Ballon D'or 2019: Ronaldo ló dáńtọ́ jùlọ (GOAT), bó tilẹ̀ jẹ́ pé Messi ló gb'àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or
Lootọọ ni aramọnda agbabọọlu Lionel Messi gba ami ẹyẹ Ballon D'or fun igba kẹfa bayii, ṣugbọn aṣoju orogun rẹ, Jorge Mendes faake kọri. O ni Cristiano Ronaldo lagbabọọlu to dantọ julọ laye ninu itan. Ronaldo kọ lati lọ si ibi ayẹyẹ naa to waye lalẹ ọjọ Aje niluu Paris lorilẹ-ede Faranse, koda oun lo gba ipo kẹta nigba ti adẹyinmu ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil van Dijk ṣe ipo keji mọ Ronaldo lọwọ. Ko si agbabọọlu to tii gba ami ẹyẹ naa to Messi, ẹni to ti gba a fun igba kẹfa bayii, lati igba ti wọn ti bẹrẹ fifi ami ẹyẹ naa dawọn agbabọọlu to fakọyọ julọ lọla. Ronaldo lo tun tẹle Messi lẹyin t'oun naa ti gba ami ẹyẹ Ballon D'or fun igba marun un ọtọọtọ. Ilu Milan lorilẹ-ede Italy lo wa nibi ti wọn ti fami ẹyẹ agbabọọlu to dara julọ ni idije liigi Serie A fun saa 2018-2019 daa lọla. Eyi ni igba akọkọ ti Messi yoo gba ami ẹyẹ Ballon D'or lati ọdun 2015, Ronaldo lo gbami ami ẹyẹ naa lọdun 2016 ati 2017, nigba ti Luka Modric Real Madrid gba a lọdun 2018. Ọpọ lo gbagbọ pe Messi ni ami ẹyẹ t'ọdun yii tọ si lẹyin to gba goolu mọkanlelaadọta ninu ifẹsẹwọnsẹ aadọta to gba ni saa bọọlu 2018-19. Ija ilara ko le tan laelae, ajuwọn lọ ko ṣee wi lẹjọ, Virgil van Dijk to ṣe ipo keji ni Messi ni Eleduwa gbade ere bọọlu fun un. Van Dijk ni o yẹ kawọn tubọ maa gbaṣoba rabandẹ fun anjannu agbabọọlu ti wọn n pe ni Messi.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50640233
yor
sports
UFC 243: Isreal Adesanya sán bàǹtẹ́ ìyà fún Robert Whittaker pẹlu 18-0
Ọdun meji ati ija meje pere ni Afẹsẹkubiojo Isreal Adesanya to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ati Australia lo lati gba Ami Ẹyẹ UFC. Adesanya ti wọn n pe ni "Last Stylebender" lo gba Ami Ẹyẹ naa lẹyin to la Robert Whittaker mọlẹ, ni asekagba Idije UFC Middleweight Champion to waye ni Australia. Adesanya na ikeji rẹ pẹlu 3:33 ni iwaju awọn eniyan to to ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọta ni papakọ ere idaraya naa. Lasiko to n sọrọ nipa aseyori rẹ, Adesanya ni ọpọ igba ni awọn eniyan ti ma n mu imu oun sẹjẹ, sugbọn ni bayii oun ti mu imu Whittaker naa sẹjẹ. Aseyori yii jẹ ko jẹ igba mejidinlogun (18-0) ti afẹsẹkubiojo Adesanya ti jawe olubori to si fi gba Ami Ẹyẹ UFC Middleweight Champion.
https://www.bbc.com/yoruba/media-49949984
yor
sports
Ìgbà ọ̀tun! Lampard kó ìyà lọ, Tuchel kó ire de Chelsea
Igba kan n lọ, igba kan n bọ, aye duro titi lae. Eyi lo difa akọnimọọgba Chelsea tẹlẹri, Frank Lampard ti o ti idi itan bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu naa. Olori ẹgbẹ agbabọọlu naa, Roman Abramovich jawe gbẹle ẹ fun Lampard lẹyin ti nkan ko ṣẹnu 're mọ fun Chelsea ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn n kopa ninu rẹ. Ṣugbọn ni bayii, omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ lẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin ti Tomas Tuchel di akọnimọọgba tuntun fun Chelsea. Ọmi ni Chelsea gba pẹlu Wolves ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti Chelsea ti gba lẹyin ti Tuchel de. Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fakọyọ lọjọ Aiku, lẹyin ti bo Burnley mọlẹ nile wọn pẹlu ami ayo meji sodo. Balogun ikọ Chelsea, Cesar Azpilicueta lo gbayo akọkọ sawọn fun Chelsea ki Marcos Alonso to fọba lee nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari. Ipo kẹsan ni Chelsea wa bayii lori tabili idije English Premier League.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-55879368
yor
sports
UFC245: Kamaru Usman, f'ẹ̀ṣẹ́ borí ààyò Trump, Colby Covington ní ìjà UFC
Bii bara ni abẹṣẹkubiojo ọmọ orilẹede Naijiria, kamaru Usman lu Colby Covington ti wọn jọ koju ija lowurọ ọjọ aiku lati ṣi wa nipo to ni akọle rẹ, welterwwight ni idje UFC 245. Ija naa waye ni gbagede T-Mobile Arena ni Las Vegas, orilẹede Amẹrika. Laarin idije ija naa, bi Colby ṣe n ta a ni Kamaru n gbakuru mọ ọ koda o tun fi ẹṣẹ fọ Colby leyin isalẹ ti gbogbo oju rẹ si kun fun ẹjẹ. Lati idaji ni gbogbo eniyan lori ayelujara ti n reti ohun ti ija yii yoo bi. Ni bayii, Kamaru náà ni yóò tún jẹ́ ọmọ Afíríkà àkọ́kọ́ tó fẹ̀ṣẹ́kùbíòjò gbaigbanu ẹyẹ idije Ultimate Fighting Championship. Ni kete ti Covington could barely stand to listen to Usman's victory speech, charging out of the Octagon to the back as soon as the Nigerian's hand was raised. But even in defeat, "Chaos" established himself as one of the greatest fighters on the planet with an excellent display that will surely still see his stock rise. It was an extremely close fight that could have gone either way had it gone the distance, as both men met in the middle of the Octagon and traded blows from start to finish, eschewing their world-class wrestling abilities in favour of an all-out brawl. But Covington's fortunes changed when Usman broke his jaw at the end of the third round with a hard right.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50798795
yor
sports
Liverpool vs Manchester City: Gbé bọ́dì ẹ! Ajá Liverpool gbéra pakuru mọ́ Manchester City.
Liverpool ti fi sọ àmì ayò tí wọ́n fi jù Manchester City lọ nínú ìdíje EPL di mẹ́sàn lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n dá aṣọ ìyàn fún City. Fabínho ló fi bọ́ọ̀lù olóyì sẹ City lọ́wọ́ lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́fà [(6) sí ìgbà tí wan bẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀. Ìṣẹ́jú mẹ́tàlá (13) sí ìgbà tí eré bẹ̀rẹ̀ ni Mohamed Salah fi orí gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n City. Liverpool ò dékun àti fi ìyà jẹ Manchester City títí di ìṣẹ́jú mọ́kànléláàádọ́ta (51) nígbà tí Sadio Mane gbá bọ́ọ̀lù kẹẹ̀ta sí àwọ̀n Manchester City. Pep Guardiola yọ atamátàsẹ́ Man City, Sergio Aguero jáde nígbà tí eré di àádọ́rin (70) ìṣẹ́jú tó sì fi Gabriel Jesus rọ́pò rẹ̀. Man City ráyè dá góòlù kan padà nìgbà tí Bernado Silva gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n Liverpool ní ìṣẹ́jú keèjìdílọ́gọ́rin (78).
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50339118
yor
sports
Arsenal vs Newcastle: Ọba àwọn góòlù! Aubameyang àti Saka ṣá Newcastle pa lálẹ́ ọjọ́ Ajé
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal rọ bajinatu fun Newcastle ni papa iṣere Emirates lalẹ ọjọ Aje ninu idije Premier League. Balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang gba goolu meji sawọn nigba ti Bukayo Saka naa gba goolu kan si awọn lẹyin Arsenal lu Newcastle pẹlu ayo mẹta sodo. Aubameyang lo kọkọ gbayo sawọn ni iṣẹju marun un lẹyin ti ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ. Saka gba goolu keji sawọn nigba ti ere bọọlu naa pe ọgọta iṣẹju ọgọta. Aubameyang fi ọba lee nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju mẹtala ti yoo pari. Nibayii, Arsenal ti goke lọ si ipo kẹwaa lori tabili idjije Premier League. Akọnimọọgba Arsenal, Mikel Arteta ko ṣai fi idunnu rẹ han si Aubameyang to gba goolu meji sawọn lẹyin to n tiraka lati fakọyọ lawọn ifẹsẹwọnsẹ ti Arsenal ti sẹyin. Bakan naa lo gboṣuba fawọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu bii Bukayo Saka ati Emile Smith-Rowe ti wọn fakọyọ bakan naa.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-55715025
yor
sports
FIFAWWCUP: Wo ohun mẹ́rin tó jẹ́ ki America tún gbá ife ẹ̀yẹ àgbáyé
Èyí ni ìgbà kẹrin tí America yóò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé nínú ìdíje tàwọn obìnrin tí kò ṣẹ̀yìn Rapinoe tó gba bàtà gòólù. Megan Rapinoe ni Balogun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin fun orilẹ-ede America lọdun 2019. Repinoe lo gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayo bata goolu, bọọlu goolu àti agbabọọlu to fakọyọ julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin to pari ni France yii. Igba ikeji ni yii ti Megan maa gba ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin lọ sile gẹgẹ bii balogun ikọ USA. Oun lo kọkọ gba bọọlu sáwọ̀n Netherland ninu idije aṣekagba naa ni papa iṣere Lyons eleyii to sọ USA di olu ọmọ ninu idije naa. Ọpọ ṣẹṣẹ gbagbọ nipa imọsilara rẹ pẹlu ajọṣepọ akọ si akọ ati abo si abo nigba ti o kigbe pé " Go Gays" - Akọ si akọ; abo si abo, ẹ tẹsiwaju. Irun alawọ rẹsurẹsu ni aawọ irun ori ẹlẹsẹ ayo Megan eyi ti ọpọ obinrin si ti ni wọn yoo sọ aawọ irun ori wọn da lẹyin idije naa. Megan Rapinoe jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn to ti wa lẹnu owo bọọlu gbigba lọdun melo sẹyin. O ti gba bọọlu fun ẹgbẹ oriṣii meje ni ọpọlọpọ orilẹ-ede agbaye. Megan ti gba ami ẹyẹ bii ti NWSL Sheild pẹlu Reign FC lẹẹmeji yatọ si ti goolu olimpiiki ati ti ife ẹyẹ agbaye ẹẹmeji bayii. Megan jẹ ẹni to fẹran lati maa ṣe nkan tawọn eniyan a maa sọrọ le lori lẹyin idije. Bi apẹẹrẹ ninu idije tọdun 2011, o gba ẹrọ gbohungbohun lori papa ni kete to gba bọọlu sáwọ̀n Columbia ki wọn to koju Japan nibi to ti kọrin nipa ibi rẹ ni Amerika. Megan ni awọn amohunmaworan ṣafihan rẹ pe ko kọ orin ogo ilẹ Amerika jade ṣaaju idije wọn. O wa lara awọn ti wọn n ja pe ki ajọ FIFA sọ owo idije obinrin di iye kan naa pẹlu ti ọkunrin ni agbaye nitori bi a ṣe bi ẹru ni abi ọmọ. Wo ohun mẹ́rin tó jẹ́ ki America tún gbá ife ẹ̀yẹ àgbáyé Orilẹ-ede America ati Netherland ni wọn jọ gbena woju ara wọn ninu idije aṣekagba ti awọn obinrin lagbaye lọdun 2019. Ami ayo meji sodo ni wọn fi gbe ifẹ ẹyẹ lọ ti wọn fi na Netherland. Orilẹ-ede France lo gba alejo idije tọdun 2019 naa. America naa lo gba ife ẹyẹ naa lọdun 2015, fun idi eyi ilé ni wọn tun gbe e pada si. Ẹkọ mẹ́rin ti a lè kọ́ lára America: 1) Ko si ìgbà ti a ko le da aṣọ ki a tun fi wọ́lẹ̀ pẹlu iyì: Kii ṣe dandan ko jẹ pe ninu abala idije akọkọ ni ẹgbẹ agbabọọlu ti le yege ninu idije. Abala keji idije aṣekagba laarin Netherlands ati America ni Megan Rapinoe ati Rose Lavelle ti jẹ goolu to mu ki America gbe igba oroke ninu idije naa. 2) O ṣe pataki fun ẹgbẹ agbabọọlu to ba fẹ ṣe aṣeyọri lati ni adilemu to gbounjẹfẹgbẹ gba awo bọ. Sari Van Veenendaal to jẹ adilemu fun America mọ iṣẹ rẹ bii iṣẹ. Ẹẹmẹrin ọtọọtọ lo mu bọọlu ti ko ba di goolu mọ wọn lọwọ ni eyi ti wọn ko ba fi di apẹrẹ ajaṣẹ ninu idije ife ẹyẹ agbaye naa. 3) Ọpọ igba ni eeyan le goke ọla to ba ni ipinnu lai wo aṣeyọri latẹyinwa. Ẹgbẹ agbabọọlu Amerika ko roo pe awọn ti gbe ife ẹyẹ naa lọ ri lọdun 1991, 1999 ati 2015. Wọn tẹpa mọṣẹ lati ibẹrẹ idije naa pẹlu ipinnu lati tun gba ife ẹyẹ naa lọdun yii, eyi to pada wa si imuṣẹ fun wọn ni papa iṣere Lyon ni orilẹ-ede France. 4) Agbajọwọ la fi n sọya, ajoji ọwọ kan kò gbéru dori lo n di aṣeyọri ẹnikọọkan ninu idije. Rapinoe to pada jẹ ọkan ninu goolu to mu ki Amerika na Netherland ko deede ri goolu naa jẹ, awọn kan ni wọn gba bọọlu naa titi to fi de ẹsẹ tirẹ. Goolu yii lo jẹ ki Rapinoe pada gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayo goolu ninu idije todun 2019 yii. Eyi jẹ ki goolu rẹ pe mẹfa ti oun funra rẹ si ran awọn meta lọwọ lati jẹ goolu ninu idije ife ẹyẹ agbaye naa. Bakan naa ni Rapinoe gba ami ẹyẹ bọọlu oni goolu pe oun lo mọ ọ gba julọ ninu idije ọdun 2019. Sibẹ ọpọlọpọ gba pe amulumala agbara ọdọ ati awọn to ti ni iriri ni akọnimọọgba Amerika lo to fi gba ife ẹyẹ tọdun 2019.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-48905096
yor
sports
Kelechi Iheanacho ẹlẹ́sẹ̀ ayò tún ti dábírà fún Leicester City
Kelechi Iheanacho, ogbontarigi ninu awọn ọdọ agbabọọlu Naijiria tun ti jẹwọ orukọ rẹ. Eemeji ọtọọtọ lo sọ bọọlu sáwọn ẹgbẹ agbabọọlu Rotherham nigba ti Leicester City pade wọn lọjọ Abamẹta. Bi ẹ ko ba gbagbe, o ti le ni oṣu mẹwaa ti Iheanacho ti gba ami ẹyẹ goolu sẹyin ti ko si ri bọọlu kankan gba si awọn. Inu awọn agbabọọlu Leicester City dun pupọ ni eyi ti o n fi ọkan wọn balẹ de idije Premier league to maa bẹrẹ lọjọ kẹsan an, oṣu kẹjọ, ọdun yii.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49143927
yor
sports
Chelsea vs Crystal Palace: Chelsea bínú gbẹ̀san ìyà Tottenham lára Crystal Palace
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Frank Lampard ti fi idunnu rẹ han pẹlu bi wọn ṣe na Crystal Palace lalubami pẹlu ami ayo mẹrin si odo. Lampard ni aṣeyọri awọn ko ṣẹyin agbabọọlu tuntun, Ben Chilwell ti wọn ra fun miliọnu marundinlaadọta pọun. Chilwell to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun lo gba bọọlu wọ inu awọn, nigba ti Zouma ṣe iranwọ fun goolu keji, Jorginho gba penariti wọ inu awọn ni igba kẹta ati ikẹrin. Amọ, Frank Lampard ti rọ awọn agbabọọlu rẹ lati farabalẹ nitori ere ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Laipẹ yii ni Liverpool lu Chelsea ni alubami, ko to di wi pe wọn gberasọ pada. Bakan naa naa ni Everton naa Brighton ni ami ayo mẹrin si meji , nibi ti Rodriguez ti gba ami ayo meji wọ ni awọn, ti CalverLewin ati Mina naa gba bọọlu wọ inu awọn.
https://www.bbc.com/yoruba/media-54404206
yor
sports
Premier League: Liverpool fẹ́ gbafe yìí ṣá! Premier League yóò bẹ̀rẹ̀ padà lóṣù kẹfà
Gbogbo eto ti to bayii lati bẹrẹ idije Premier League lọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun yii lẹyin to ti wa nin idaduro nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ohun ti awọn alaṣẹ idije naa n gbero ni lati gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to ku tan laarin ọsẹ mẹfa ni kete ti idije naa ba ti bẹrẹ pada. Inu ọpọlọ awọn ololufẹ idije Premier lo dun pe idije naa yoo pada laipẹ ọjọ. Ijọba ilẹ Gẹẹsi rọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ogun to wa ninu idije naa lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku lawọn papa iṣere mii yatọ si ti wọn. Ṣugbọn awọn ikọ agbabọọlu kọ jalẹ, wọn ni o wu awọn lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku nile awọn. Liverpool lo wa loke tente tabili EPL, nigba ti ifẹsẹwọnsẹ to ku si jẹ mọkanla.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-52626973
yor
sports
Crystal Palace vs Manchester United: Crystal Palace pàkúta sí gaàrí Manchester United ní Old Trafford
Ajẹtun iya ni Manchester United jẹ lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Crystal Palace lọjọ Abamẹta ninu idije Premier League. Crystal Palace lo kọkọ gba bọọlu sawọn ṣugbọn Manchester United dayo naa pada. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nigba ti Crystal Palace gbayo mii wọ le Man U nigba to ku diẹ ki ere bọọlu naa pari. Tamọtiye! Tammy ta Norwich pa mọ́ lé, bí Chelsea ti gbéra Lẹyin ọ rẹyin, ẹrin gba ẹkẹ akọnimọọgba Chelsea, Frank Lampard lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea gbegba oroke fun igba akọkọ lati igba to ti gori aleefa gẹgẹ bi akọnimọọgba tuntun ni papa iṣere Stamford Bridge. Chelsea fẹyin Norwich City gba lẹ nile wọn ni Carrow Road lẹyin ti wọn ti ta ọmi kan ti wọn si jawe olubori ninu omiran ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba lati igba ti idije Premier League ti bẹrẹ ni saa yii. Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni Tammy Abraham gba bọọlu sawọn fun Chelsea. Ṣugbọn Todd Cantwell dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹta mii lo ba di ọmi alayo kọọkan. Ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Chelsea, Mason Mount gbayo wọ le eleyi ti Chelsea fi tun wa niwaju ṣugbọn ẹlẹsẹ ayo Teemu Pukki sọ ere bọọlu ọhun ọmi alayo mejimeji. Ẹlẹsẹ ayo Tammy Abraham lo gba mii wọ le fun Chelsea eleyi to jẹ ẹlẹẹkeji rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. Lampard gbéra sọ!Chelsea run Norwich mọ́ lẹ̀ jégéjégé
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49460043
yor
sports
NFF fi #30,000 kún #10,000 owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini àti Samuel Okwaraji
Ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti fi ẹgbẹrun un lọna ọgbọn naira kun ẹgbẹrun mẹwaa ti ẹka ijọba to n ri si ere idaraya ṣeto gẹgẹ bi owo iranwọ oṣooṣu fawọn iya oloogbe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Rashidi Yekini ati Samuel Okwaraji. L'Ọjọru ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ kede eto naa lati maa fun awọn mama oloogbe agbabọọlu Naijiria mejeeji tẹlẹ ni ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu gẹgẹ bi owo iranwọ. Olaitan Shittu to jẹ aṣoju minisita ere idaraya lo fọrọ naa lede l'Ọjọru nigba to ṣabẹwo si Alhaja Yekini niluu Ijagbo nipinlẹ Kwara. Bakan naa ni ijọba tun fun mọmọ Yekini ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ ẹbun fun awẹ Ramadan to n lọ lọwọ. O ti pe ọdun mẹjọ ti ẹlẹsẹ ayo, Rashidi to gba goolu sawọn julọ fun Naijiria di oloogbe. Okwaraji ṣubu lori papa, o si gba ibẹ ku nigba to n kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ati yege fun idije ife ẹyẹ Italian '90 to waye laarin Naijiria ati Angola niluu Eko lọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 1989. Ìjọba buwọ́lu ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini Rashidi Yekini: Ìjọba buwọ́lu ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini Ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ ti ṣeto lati maa fun mama oloogbe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Rashidi Yekini ni ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu gẹgẹ bi owo iranwọ. Olaitan Shittu to jẹ aṣoju minisita ere idaraya lo fọrọ naa lede l'Ọjọru nigba to ṣabẹwo si Alhaja Yekini niluu Ijagbo nipinlẹ Kwara. Bakan naa ni ijọba tun fun mọmọ Yekini ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ ẹbun fun awẹ Ramadan to n lọ lọwọ. O ti pe ọdun mẹjọ ti ẹlẹsẹ ayo, Rashidi to gba goolu sawọn julọ fun Naijiria di oloogbe.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-52570213
yor
sports
US Open 2019: Bianca júwe ilé fún Serena Williams nínú ìdíje l'America
Idije to gbogo fun Bianca Andreescu naa waye ni Flushing Meadows ni New York laarin ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 2019. Bianca Andreescu jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun lati orilẹ-ede Canada lo koju agbaọjẹ Serena Williams ọmọ ọdun mẹtadinlogoji naa ninu idije aṣekagba. 6-3; 7-5 ni wọn pada jọ gba ninu idije aṣekagba naa ni New York. Bianca fo fun ayọ, o ni: Odun yii ni àlá mi wa sí imuṣẹ. O ni: inu mi dun gidi, mo mọ oore nitori mo ti n tiraka tipẹ ti mo ti n woye ọjọ ti maa pade Serena Williams ninu idije. Serena ni gbajugbaja ti gbogbo wa n wo loke ninu ere idaraya yii. Si iyalẹnu gbogbo ero iworan to wa lori papa ni Bianca fidi Serena janle ti o si jẹ ki Serena padanu ife ẹyẹ yii lẹẹkẹrin bayii. Serena funra rẹ gboriyin fun ọdọmọde Bianca, o ni: Inu mi dun fun Bianca, o ṣiṣẹ bi ọmọ akin nitootọ ninu idije yii. Bianca jẹ ọmọ orilẹ-ede Canada. Oun ni ọdọmọde ẹni akọkọ ni Canada to maa gba ami ẹyẹ idije nla bọọlu ẹlẹyin ori tabili. Oun ni ọdọmọde ti ko tii pe ogun ọdun akọkọ to maa gba goolu Grand slam lẹyin Maria Sharapova lọdun 2006. Oun lo tun kọkọ gba Akọkọ ṣe Slam lẹyin ọmọ Russia to gbaa lọdun 2004 ni Wimbledon Bianca jẹ ọdọmọde to ni igbooya ati ọkan akin ninu gbogbo idawọle rẹ, eyi to han ninu idije naa. Andreescu ni ti ẹnikẹni ba sọ fun oun pe oun a koju Serena Williams ninu idije oun maa sọ pe ẹni naa ti ya were ni. Oun ni gbogbo aye n sọrọ nipa rẹ lori ayelujara lasiko yii pe ko si ohun ti ọdọmọde ko le ṣe yanju! Lọdun to lọ ni Bianca ja nibẹrẹ idije ti ko si si lara awọn igba akọkọ to ṣaaju ninu gbigba bọọlu ọhun. Awọn ara Romania ni obi Bianca jẹ. Nicu ni orukó baba rẹ nigba ti iya rẹ n jẹ Maria. Wọn lọ ṣe atipo ni orilẹ-ede Canada nibẹre ọdun 1990. Lati kekere ni Bianca ti n gba bọọlu ẹlẹyin ori tabili ni eyi to si ti gba ami ẹyẹ bii WTA Premier ni Indian Wells ati Toronto to si gba ẹbun owo rẹpẹte si. Bayii, Bianca n lọ ẹni karun un ni agbaye to si n lọ sile pẹlu ẹbun owo $3.85 miliọnu. Ẹkọ nla ti Bianca fẹ ki awọn ọdọ kọ ni pe ki wọn maa di eti wọn si ariwo ọja ati pe ki wọn ma bẹru ogbontarigi ti wọn ba fẹ koju lẹnu iṣẹ wọn. O ni oun di eti oun si ariwo ọja awọn eniyan ni bi awọn ero lori papa naa ṣe n pariwo orukọ Serena ki oun to le bori.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49624895
yor
sports
Ṣé Nigeria yóò fìyà jẹ Morocco bí ti àtẹ̀yìnwá láti dé àṣekágba WAFCON 2022?
Ẹgbẹ agbaboolu obinrin Naijiria, Super Falcons yoo wako pẹlu ikọ Atlas Lionesses ti orlẹede Morocco. Loni, ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ni ifigagbaga naa yoo waye fun ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kangun si asekagba idije WAFCON 2022. Papa ìṣeré Prince Moulay Abdellah ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo tì waye laago mẹsan-an alẹ n'ilu Rabat. Iko Super Falcons lo gbọdọ bori ifẹsẹwọnsẹ yii lati wọ ipele aṣekagba idije naa. Lionesses of Atlas ile Morocco ni o bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti kopa ninu idije naa, ti iko Super Falcons si padanu ẹyọ kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn ti wọn gba pẹlu iko Bayana Bayana ti ile South Africa. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yii ni yoo gbe ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons de ipele aṣekagba idije naa, ti wọn ba fi borí Morocco. Bakan naa ni yoo jẹ fun Morocco, to ba jẹ pe awọn lo bori. Ki wọn o to koju ẹlòmíì ni aṣekagba idije. Orile-ede Naijiria n ja lati gba ife idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, WAFCON, fun igba kẹwaa, ninu ìgbà mejila to ti waye. Morocco n jà lati gba a fun igba akọkọ. Botilẹ jẹ pe Super Falcons ni ọpọ n fi ojú si lara gẹgẹ bi akọni, ẹgbẹ́ agbabọọlu Atlas Lionesses naa kò ṣe e fi ọwọ rọ́ sẹyin. Idi ni pe lati igba ti idije WAFCON 2022 ti bẹ̀rẹ̀, ni wọn ti n fakọyọ. Wọn ò si tíì padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kankan. Yatọ si eyi, Morocco lo gbalejo idije naa, wọn o si ni fẹ ki ife ẹyẹ bọ wọn lọwọ. Nitori naa ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons nilo lati fi ọkàn si nkan ti wọn n ṣe lori papa lati ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa. Iye igba ti Morocco ati Super Falcons ti pade lori papa Ọdun 1998 ni ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji kọkọ pade ni WAFCON 1998. Iya kekere kọ ni Super Falcons fi jẹ Atlas Lionesses ni ilẹ baba wọn. Ami ayo mẹjọ si odo ni wọn fun wọn. Ọdun 2000 ni wọn tun pade ni WAFCON 2022 to waye ni South Africa. Ami ayo mẹfa si odo ni Naijiria tun fi lù wọ́n ni aludojubolẹ. Sugbọn laarin ìgbà naa si asiko yii, ẹgbẹ́ agbabọọlu Morocco fihan pe nkan ti yatọ, paapaa lati igba ti WAFCON 2022 ti bẹ̀rẹ̀. Nigba ti o gba ni yanju, Aarẹ, ajọ to risi kokari ere bọọlu nile wa, NFF, Amaju Pinnick ni gbogbo nkan ni iko Super Falcons ni lati ṣe lati gba ifẹyẹ ijide naa gba kẹwa. Amaju ni oun kọkọ ki awọn agba bọọlu naa fun bi wọn ṣe fakọyọ ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti ko pa ninu, ti wọn si bori awon akẹẹgbẹ wọn. “Mo kọkọ ki awọn agbabọọlu naa fun bi wọn fakọyọ ninu ifẹsẹọnsẹ pẹlu awọn akẹẹgbẹ wọn.” “Wọn ti fi ran wa pe orilẹede Naijiria ni oga ti a ba sọrọ ere bọọlu obinrin ni ile adulawọ, bi wọn ṣe fakọyọ ninu awọn ifesewọn wọn,” “Ifẹsẹweọnsẹ pẹlu ikọ Morocco ko le yipada sugbọn yoo lagbara pupọ gan nitori ikọ Morocco naa jẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti muṣemuṣe wọn da muṣe.” “Mo ni igbagbọ pe a bori wọn, mo ti sọ fun awọn agbabọọlu naa lati ranti ibi ti wọn wa, ki wọn si fi ọkan gbe orilẹede Naijiria larug\]e nibi ijide WAFCON.” “Ninu mi dun si awọn agbabọọlu pupọ.” Aarẹ, ajọ to risi kokari ere bọọlu nile wa, NFF, Amaju Pinnick ni oun ni igbagbọ ninu iko Super Falcons lati bori orilẹede Morocco to ba di ago mẹsan oni ni papa iṣerẹ Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat lorilẹede Morocco. Amaju ni awọn agbabọọlu Naijiria ti sẹtan lati jẹ orilẹede Naijiria bọ si oke nibi ti o ko wa. O ni o ti ṣeṣe fun Ikọ agbabọọlu Super Facons lati kopa ninu ifẹsẹwọmsẹ aṣe kagba to ba di ọjọ aiku ọse to bo yi Bi ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ṣe n gbaradi lati koju Swallow ti Burundi lonii, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo ipa ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni eyi to kẹhin ni abala akọkọ fun awọn orile-ede to the wa ni ipin C ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco. Ẹgbẹ agbabọọlu to ṣe ipo kinni, ikeji, ati ikẹta ni ipin C, yoo bọ si ipele quarter finals. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu Burundi si ni yoo sọ ibi ti ori n gbe Super Falcons lọ, ti Burundi ba fi lu wọn. South Africa ati Botswana lo na Burundi. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ti ọjọ́ Aiku, ti yoo waye ni papa ìṣeré Prince Moulay El Hassan, Rabat, ni igba àkọ́kọ́ ti orile-ede mejeeji koju ara wọn nilẹ okeere. Orile-ede Burundi ti padanu ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn meji akọkọ, Naijiria padanu ẹyọkan sọwọ South Africa. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ laarin orile-ede mejeeji la le fi we ija laarin Dafidi ati Golayaati. Igba àkọ́kọ́ re e ti Burundi n kopa ni idije WAFCON, àmọ́ Naijiria ti kopa ninu mọkanla, o si ti gba ife ni igba mẹsan-an. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹta ni orile-ede kọọkan to n kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco, WAFCON 2022, gbá ni abala akọkọ. Ninu meji to ti kọkọ gbá, Naijiria padanu ẹyọkan sọwọ South Africa, o bori ikeji nigba to na Botswana ni ami ayo méjìlá si odo. Lọwọlọwọ, Naijiria lo wa ni ipo keji ni ipin kẹta (C), pẹlu ami mẹta. Orile-ede Burundi lo wa ni ipo to kẹhin, ko ni ami kankan lẹyin ti South Africa ati Botswana lu u. Botilẹ jẹ pe ami mẹta ni Naijiria àti Botswana ni lori tabili igbelewọn, wọn fi Naijiria si ipo kejì, nitori 'iru' goolu ti wọn gbá wọ awọn. Sugbọn o, dandan ni fun wọn lati bori Burundi, ki wọn o le bọ si ipele quarter final. Olukọni ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin Naijiria, Randy Waldrum, sọ fun awọn akọroyin n'ilu Rabat, lọjọ Abamẹta pe, àwọn ko le foju kere Burundi. O ni "ao le foju di ẹgbẹ́ agbabọọlu Burundi." A n gbaradi lati tun ṣe daadaa ju bi a ṣe ṣe lọ ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wa to kọja. Erongba wa si ni lati wọ ipele quarter finals lọjọ Aiku."
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cg6zd1nxzkwo
yor
sports
Angel Gomes: Angel Gomes, agbábọ́ọ̀lù Manchester United ṣàlàyé ohun gan tó gbé e dé ṣọ́ọ̀ṣì T. B Joshua
Ọmọ agbábọ̀ọ̀lù Manchester United Angel Gomes ti fèsì fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára ìdí tó fi sàbẹ̀wò sí ìjọ T.B Joshua lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Gomes bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò bọ́ọ̀lù gbígbá nígbà tó ti wà ni ọmọ ọdún mẹ́fà, wọ́n yan láti gbáradà ní ilé ẹ̀kọ́ ọmọ wẹ́wẹ́ Manchester United tí ó sì lo ọdún mọ́kanlá gbáko kí o tó lé darapọ̀ mọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà lọ́dun 2017. Láti ìgbà náà, ó ti farahàn tó ìgbà mẹ́wàá nínú ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Red Devils tí ó sì ti n pinu láti búwọ́ lùwé láti fikún àsìkò rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Manchester United. Ẹ̀wẹ̀, fónrán iṣẹ́jú meji kan ṣẹ́yọ lórí ayélujára, èyí tó sàfihàn ìtiràka rẹ̀ lórí bi yóò ṣe gba ìwòsàn lórí ìṣòro ẹsẹ̀ tó n bá fíra lásìkò ọ̀ún. Fọ́nran náà sàfihàn Gomes nibi to ti n ṣi ojú egbò rẹ̀ nínú ìjọ T.B Joshua, Synagouge Church of All Nation. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sàlàyé pé òun gbé ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn ti àwọn òbí òun gbà òun nímọ̀ràn láti gbìyànjú rẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ nínú fídíò náà': "Orúkọ mi ni Angel Gomes, mó wá láti Manchester, ọmọ ọdun mẹ́rìndílógún ni mi. Àlàyé tó fí síta rèé O ní àwọn isòrò ẹṣẹ̀ tó ń yojú yìí ń kan òun lóminú lásìkò tí ó yẹ ki òun maa gbádún ayé òun nínú eré bọ́ọ̀lù Mó n gbá bọ́ọ̀lù fún Manchester United, mo sì ń sojú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù England gẹ́gẹ́ bíi balọ́gun ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà, mo sì ti mọ ijọ synagogue láti kékeré. Àwọn obí mi fẹ́ràn T.B Joshua púpọ̀ à sì maa n wòó fídíò rẹ lóòrèkóòrè. Gomes fèsì lójú òpó Twitter rẹ, tó sì tẹpẹlẹ mọọ pé ẹsìn òun kìí ṣe ǹkan ti ó yẹ kí àwọn ènìyàn máa fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ lé lórí, pàápàá jùlọ nínú ìṣòrò ààùn Corornavirus yìí ati ìfẹhónúhàn "ayé ènìyàn dúdú ṣe pàtàkì"(BLM) tó n jà ká gbogbo àgbáyé. O ní: Ni ti fọ́nrán to jẹyọ láti ọdún 2016. Ìdílé onígbàgbọ́ ni mo ti wá, ni àsìkò náà olólùfẹ́ pásítọ ọ̀un ni maami jẹ́, ó sì fẹ́ ki n lọ nítórí àwọn ìṣòrò ti mo ní. " Mó kéré lásìkò náà àwọn òbí mi ǹkan yìí dára fún mi láti ṣe, ìṣòro pọ̀ gàn ni lágbàyé báyìí tó yẹ kí a mójú tó"
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53067405
yor
sports
CAF kéde Asisat Oshoala, Rasheedat Ajibade, Chiamaka Nnadozie lára àwọn agbábọ́ọ̀lu obìnrin fún àmì ẹ̀yẹ 'CAF Awards' tọdún 2022
Ajọ ere bọọlu nilẹ Afirika, CAF ti kede orukọ awọn agbabọọlu obinrin ti yoo kopa fun ami ẹyẹ awọn agbabọọlu obinrin ni Afrika ti ọdun 2022. Lara awọn ipele ami ẹyẹ ti wọn yoo kede awọn agbabọọlu obinrin to bori fun ni agbabọọlu obinrin  to pegede julọ laafirika, agbabọọlu obinrin fun ẹgbẹ agbabọọlu to pegede julọ, agbabọọlu ọdọbinrin  to pegede julọ l’Afirika, pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu obinrin to pegede julọ ni Afrika. Atẹjade ti Ajọ CAF fi sita tun sọ pe, wọn yoo kede awọn oludije fun ami ẹyẹ akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Obinrin to pegede julọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹede to pegede julọ laipẹ. Ajọ naa ni ijafafa awọn agbabọọlu obinrin nibi idije ife ẹyẹ bọọlu awọn Obinrin ni Afirika, WAFCON yoo wa lara awọn ohun ti wọn yoo gbe yẹwo lati yan awọn oludije ti yoo bori ọkọọkan awọn ipele ami ẹyẹ kọọkan. Ni ọjọ kọkanlelogun oṣu keje ọdun 2022 ni wọn yoo kede orukọ awọn agbabọọlu obinrin to ba pegede lawọn ẹka naa ni ilu Rabat lorilẹede Morocco. Ayẹyẹ ami ẹyẹ naa yoo waye ṣiwaju ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ife ẹyẹ bọọlu awọn obinrin nilẹ Afirika, WAFCON to n lọ lọwọ lorilẹede Morocco. Awọn oludije fun ami ẹyẹ agbabọọlu obinrin to pegede julọ ni Afirika Awọn oludije fun ami ẹyẹ agbabọọlu obinrin to pegede julọ ni Afirika
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c726qxd784do
yor
sports
Kò rọrùn rárá láti dàgbà ní agbègbè bíi Mushin, àànú Ọlọ́hun ló sọ mi di agbábọ́ọ̀lù Super Falcons - Rasheedat Ajibade
Ṣaaaju ifsẹwọnsẹ ti yoo waye laarin awọn agbabọọlu obinrin orilẹede Naijiria ati Cameroon lonii ni papa isere Stade Mohamed V Stadium ni Casablanca lẹyin ti wọn lu awọn agbabọọlu Burundi lalubami lọjọ Aiku to kọja, BBC Yoruba mu iroyin nipa igbaradi awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti Naijiria wa. Ọkan lara wọn to jẹ agbabọọlu aarin to si jẹ ọmọ Yoruba, Rasheedat Ajibade kẹnu bọ ọrọ nipa ibẹrẹpẹpẹ rẹ ni agbegbe Mushi ni ipinlẹ Eko, Naijiria.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/clkvepv1mveo
yor
sports
National Sports Festival: Ìjọba àpapọ̀ ní kò sí ohun tó jọ pé ìdíje náà yóò párí l'Ọ́jọ́bọ̀
Ijọba apapọ ti sọ pe idije oriṣiiriṣii ere idaraya, National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo ko ni wa sopin lojiji lonii Ọjọbọ mọ. Ọrọ yii jade lẹyin ti igbimọ abẹnu lori idije naa, LOC ti kọkọ kede pe idije naa yoo pari lọsan Ọjọbọ nitori aisowo. Ṣugbọn igbakeji oludari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ, Ramon Balogun lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ. O ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe ẹka ijọba to n ṣakoso ere idaraya ati ajọ MOC to n ṣiṣẹ lori agbekalẹ idije naa ko gbọ ohun kan nipa ọrọ ti igbimọ LOC ipinlẹ Edo sọ pe idije naa ko ni le tẹsiwaju mọ. Atẹjade naa ṣalaye pe ko si ipade kankan tabi apero kan lori ati da idije naa duro. Ọgbẹni Balogun sọ pe Minisita ere idaraya, Sunday Dare, akọwe agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ ere idaraya atawọn lọgalọga lo wa ni Benin fun idije National Sports Festival. O ṣalaye pe ojuṣe ipinlẹ Edo tabi igbimọ LOC ni lati fi to wọn leti ti ipenija kan tabi omiran ba wa lori idije to n lọ lọwọ. Igbakeji oludari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ tun sọ pe ipinlẹ Edo tiẹ beere iranwọ owo lori ati gbalejo idije ọhun lẹyin ti ijọba sun un siwaju nitori ajakalẹ arun covid-19. Ọgbẹni Balogun ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ti gbe ọrọ naa de iwaju ijọba apapọ, o si yẹ ki owo iranwọ naa jade laipẹ. Ẹwẹ, alakoso ọrọ iroyin lori idije National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo, Ebomhiana Musa lo sọ lalẹ Ọjọru pe igbesẹ lati da idije naa duro waye nibi ipade ti igbimọ LOC ṣe eleyii ti igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Philip Shaibu wa nibẹ. O sọ pe igbimọ LOC gbe igbesẹ yii nitori ijọba apapọ ko tii mu ileri iranwọ owo to ṣe fun ipinlẹ Edo ṣẹ lẹyin ti wọn ti kọkọ sun idije naa siwaju tẹlẹ. O kere tan ẹgbẹrun mẹjọ awọn elere idaraya lo n kopa ninu idije National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56672265
yor
sports
Liverpool fi àwìn ṣẹ Man city lọ́wọ́ pẹ̀lú 3-1 ní Community Shield
Manchester city gba idagiri akọkọ ni saa bọọlu tuntun ti yoo bẹrẹ nilẹ Gẹẹsi lọsẹ to nbọ pẹlu bi Liverpool ṣe ko bo wọn ni ifẹsẹwọnsẹ ife ẹyẹ Community Shield to waye lọjọ Abamẹta. Goolu mẹta si ẹyọ kan ni Liverpool na Manchester city lati gba ife ẹyẹ Community Shield, eyi to jẹ ife ẹyẹ akọkọ lati ṣide saa bọọlu Premier league lọdọọdun lorilẹede England. Liverpool padanu ife ẹyẹ Premier league saa to kọja si ọwọ Manchester City to gba ife ẹyẹ naa lẹyin to fi ami kan la Liverpool. Idije naa to waye ni papa iṣire King power stadium dipo Wembley nitori ifẹsẹwọnaẹ aṣekagba idije ife ẹyẹ Euro tawọn obinrin ti yoo waye nibẹ. Agbabọọlu Liverpool, Trent Alexander-Arnold lo gba goolu akọkọ wọle lẹyin ti bọọlu gba soju ile ba ara Nathan Ake, agbabọọlu Manchester city wọle. Julian Alvarez, ọkan lara awọn agbabọọlu tuntun ti Manchester city ṣẹṣẹ ra lo gba goolu wọle lati daa pada fun Liverpool. Agbabọọlu ọmọ orilẹede Egypt ni, Mohammed Salah lo tun sun Liverpool siwaju pẹlu pẹnariti lẹyin ti ọkan lara awọn adilemu Manchester city, Ruben Dias fi ọwọ kan bọọlu loju ile rẹ. Agbabọọlu tuntun ti Liverpool ṣẹṣẹ ra, Darwin Nunez lo de gbogbo rẹ lade.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c848g9n2440o
yor
sports
AFCON 2019: Wo àbájáde èsì àsọtẹ́lẹ̀ rẹ
.
https://www.bbc.com/yoruba/48745614
yor
sports
Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì UNILAG ṣubúlulẹ̀ níbi tó ti ń gbá bọ́ọ̀lù, ó gba ibẹ̀ kú
Akẹkọọ onipele kini lẹka eto ìmọ nipa ato ilu ni fasiti Eko, Simon Adokwu ti jade laye lasiko to n gba bọọlu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ logba ile ẹkọ fasiti naa to wa niAkoka niluu Eko Iroyin kaakiri awọn ileeṣẹ iroyin abẹlẹ ni Naijiria sọ pe akẹkọọ naa ṣẹṣẹ ti ile ijọsin de loun ati awọn akẹgbẹ rẹ ba gbe bọọlu sita lati fi ṣe ere ni papa isere to wa nitosi ibudo idagbasoke oṣiṣẹ Human Resource Development Center nile ẹkọ naa ko to di pe omodekunrin naa ṣa dede ṣubululẹ to si ku. Nigba ti awọn akẹgbẹ rẹ yoo fi gbe e de ileewosan to wa nile ẹkọ giga fasiti naa, dokita fìdí rẹ mulẹ pe o ti jade laye. Alukoro ile ẹkọ fasiti naa, Alagba Ibraheem sọ pe ẹni ọdun mejilelogun ni akẹkọọ naa ko ro dagbere fun aye. O ni o ṣalaye fun awọn akẹgbẹ rẹ ṣaaju pe ara oun ko ya ko to lọ si papa lọ gba bọọlu. Arabinrin Ibraheem ni sibẹ o sọ fun wọn pe oun ṣi fẹ lati gba bọọlu pẹlu wọn. “Ibi ti wọn ti n ba ere bọọlu lọ lọwọ ni wọn ti wo ẹyìn wo ti wọn ri pe oti ṣubu lulẹ. “Awon akẹgbẹ rẹ gbe e lọ si ileewosan, wọn si gbiyanju lati raa pada nibẹ ṣugbọn epa ko boro mọ, ọmọ naa ti ku.” Alukoro UNILAG ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ fasiti naa ti kan sí awọn obi akẹkọọ naa, wọn si ti ni awọn yoo wa gbe oku rẹ. Amọṣa o ni ile ẹkọ naa ṣi kọkọ fẹ ṣe ayẹwo oku rẹ lati mọ bi ọrọ iku rẹ ṣe jẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/crg9zl43x11o
yor
sports
Coronavirus and sport: Paul Onuachu ni agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó lùgbàdì Covid 19
Ẹlẹsẹ ayo, ọmọ Naijiria to n gbabọọbu jẹun fun ìkọ Genk lorilẹ-ede Belgium, Paul Onuachu ti ko aarun coronavirus. Ni Ọjọru ni ayẹwo fihan pe Onuachu nikan lo ni arun covid-19 ninu gbogbo awon agbabọọlu Genk ti wọn ṣe ayẹwo coronavirus. Amọ, ayẹwo naa tun fihan pe awọn akẹgbẹ rẹ ọmọ Naijiria ti wọn jọ wa ni Genk, Stephen Odey ati Cyrul Dessers ko ni arun ọhun. Nigba ti Ẹgbẹ agbabọọlu Genk pinnu lati ṣe ayẹwo fun gbogbo agbabọọlu wọn ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọọrẹẹ kan ni ayẹwo naa ti fihan pe Onuachu ti farakasa. Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun un ni Onuachu rinrin ajo lati Belgium lọ si Naijiria. Ọjọ kejidinlọgbon, oṣu kẹfa lo lanfaani lati pada si Belgium lẹyin ti o ha si ilu Eko fun ọsẹ kan ti ko ri baalu wọ nitori ajakalẹ arun coronavirus.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-53353115
yor
sports
Super Eagles: Bi Yisa Sofoluwe ṣe di olóògbé ni Luth
A bí Yisa Sofoluwe ni ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejílá, ọdún 1967 to si gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi a dile ẹyin mú. Ẹyìn ni apá òsì ni ìròyìn sọ pé ó máa ń gbá láàrin ọdún 1983 si ọdun 1988, bákan náà ló gbá Nation's Cup ọdún 1984 àti ti 1988 Sofoluwe jẹ góòlù kan fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò náà. Ó farahàn nínú idíje bọ́ọ̀lù Nàìjíríà fún ìgbà ogójì lásìkò tó n gbá bọ́ọ̀lù Bákan náà ni Sofoluwe ti fi igba kan jẹ́ agbábọ́ọ̀lù Abiola Babes nílùú Abeokuta, IICC ti Ibadan àti Gatew+ay Abeokuta. Ṣááju ni ìròyìn kàn pé, àgbà ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù náà ṣe àìsàn to sì gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn LUTH. Ọ̀kan ninu àwọn ọrẹ́ rẹ̀ Waidi Akanni sàlàyé pé, àwọn ń gbìyànJÚ láti wá owó tí yóò fi ṣe iṣẹ́ abẹ̀ tó nílò, ṣùgbọ́n ẹpa kò bóró mọ́. Ìròyin sọ pé mínísítà fún eré ìdárayá àti ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ lọ́sàn ọjọ́ Iṣẹgun gbé ìgbésẹ̀ láti ran Sofoluwe lọ́wọ́ láti bá gómìnà ìpínlẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ kí wọ́n lé ràn an lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ abẹ náà. Mínísítà fí owó ránṣẹ́ pẹ̀lú láti fi ran ìtọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́ sùgbọ́n kò dúró ṣe iṣẹ́ abẹ náà tó fi gbekuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra. Agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles tẹ́lẹ̀rí Yisa Sofoluwe jáde láyé Agbabọọlu ikọ Super Eagles tẹlẹri, Yisa Sofoluwe ti jade laye ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, lẹyin to ṣe aisan. Opin ọsẹ yii ni iroyin jade nipa aisan rẹ lẹyin ti wọn lo ni aisan ninu agbari, cerebral atrophy to niiṣe pẹlu ọpọlọ. Aisan yii ma n jẹ ki gbogbo sẹẹli ọpọlọ ni ifasẹyin, ti ọpọlọ ko si ni lee ṣiṣẹ mọ bi o ṣeyẹ. Sofoluwe ni agbabọọlu ẹyin to n dile mu nigba aye rẹ, ti gbogbo aye si mọ ọ si "Dean of Defence". Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kejila, ọdun 1967 ni wọn bi akọni naa to si gba bọọlu si awọn lẹẹkan fun orilẹede Naijiria. O gba bọọlu pẹlu ikọ to de aṣekagba idije AFCON ni ọdun 1984 ati ọdun 1988. Awọn akẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn ti n ṣe idaro rẹ lẹyin to papoda pe ki Edua de ilẹ fun ẹni ire to lọ.
https://www.bbc.com/yoruba/56006915
yor
sports
Chelsea vs Manchester City: Man City gba fújà lọ́wọ́ Chelsea n'íbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun
Awọn Yoruba maa n gbadura kan wi pe ''aye ko ni gba fuja lọwọ rẹ.'' Amọ iru adura yii gan ni Chelsea nilo lasiko yii ninu idije Premier League lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ṣe wọn bi ọṣẹ ṣe maa n ṣe oju lọjọ Aiku. Ṣebi aileja lojude ile baba mi ko de bi. Nile ni Chelsea kuku wa ti Man City ko igbaju igbamu bo wọn bi ole to ji ike owo. Agbabọọlu aarin gbungbun Ilkay Gundogan lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea fun Manchester City lẹyin isẹju mejidinlogun ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ ni papa iṣere Stamford Bridge. Ka to wi, ka to fọ, Phil Foden gba goolu keji wọle fun City, lo ba di ami ayo meji sodo. Ẹlẹsẹ ayo, Kevin De Bruyne lo gba goolu kẹta sawọn fun Man City, lọrọ ba di họ fun Chelsea. Chelsea gbiyanju lati da goolu kan pada amọ ẹpa ko boro mọ. Ipo kẹjọ ni Man City wa bayii lori tabili idije Premier League nigba ti Liverpool si wa loke tente. Ti ẹ ko ba gbagbe, Arsenal lo kọkọ digbaju ru Chelsea laipẹ yii pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọkan.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-55522685
yor
sports
AFCON 2019: Bí Nàìjíríà ṣe gbá eyí tó lọ, mi ò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ti tònìí
Gẹgẹ bi awọn agbabọọlu Naijiria ṣe ti n gbara di fun ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹ̀lú ikọ agbabọọlu ti Cameroon, ọkan awọn ọmọ Naijiria naa ti wa loke. Ṣe ni ọpọlọpọ ti n gbiyanju lati Sọ àsọtẹ́lẹ̀ orílẹ̀èdè tí yóò borí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ t'òní Awọn ololufẹ ikọ super Eagles to n gbe orillẹ̀ede wọn larugẹ ni o yẹ ki awọn agbabọọlu gan ni imọ lara eyi ki wọn si lo gbogbo ọgbọn ati agbara ti wọn ba ni lati mu ori awọn ololufẹ wọn wu. Bi awọn kan ṣe n sọ idi ti wọn ko fi ro pe Naijiria yoo bori Cameroon bẹẹ ni awọn mii n ṣa n fẹ́ẹ̀ ki Naijiria bori.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-48891798
yor