text
stringlengths
9
9.74k
egbe oselu ohun so pe, awon ti padanu omo odun marundinladorin naa lasiko ti o ku osu kan pere ki eto idibo waye, amo, bi won n kedun naa ni won n ronu eni ti yoo gbapo ologbe naa.
elias mudzuri ti o je okan lara igbakeji aare ati awon agbaagba egbe oselu naa ni won ko wa sibi ipade igbimo amusese egbe naa.
won koi so pato igba ti won yoo gbe oku ologbe naa wa sorile-ede zimbabwe ronke osundiya.
igbakeji aare yemi osinbajo ti ro awon onile-ise nla-nla lati dale-ise sile si orile-ede nigeria, bi o se n se ifilole ile-ise nestle ti yoo maa pese ohun mimu milo, ti iye owo re to bilionu merinnaira sile nilu agbara, ti o wa nipinle ogun.
osinbajo so pe, o ye ki awon eniyan wo awokose ile-ise nestle bi o se n da awon ile-ise sile lorile-ede nigeria, gege bi a se mo pe, orile-ede nigeria nikan nibi ti o rorun julo lati da idokowo sile.
igbakeji aare oun so pe, “a dupe pupo lowo ile-ise nestle fun anfaani yii, ni paapaa julo bi won da ile-ise sile si awon igberiko ati bi won se n ra ohun elo won latodo awon agbe, eyi yoo tun mu idagbasoke ba orile-ede nigeria”.
osinbajo tun fi mule pe, erongba ijoba apapo ni lati pese awon ayika to rewa fun idokowo, ni iyanju ati je ki erongba ijoba lori ona ati mu igberu ba eto oro-aje orile-ede nigeria wa si imuse.
oga agba ile-ise nestle, ogbeni mauricio alarcon so ninu oro re pe, idasile ile-ise tuntun ohun ni lati pese ise ati lati maa ra awon ohun elo ti o to iko ogorin ninu ida ogorun awon ohun ipese ohun mimu milo naa latodo awon agbe, bakan naa ki a si se idasile awon ile-ise si awon igberiko.
gomina ipinle ogun, ibikunle amosun so pe, idasile ile-ise ohun je erongba ile-ise nestle lati mu igberu ba eto oro-aje lorile-ede nigeria.
gomina amosun, eni ti igbakeji re yetunde onanuga soju fun, ro awon onile-ise nipinle naa lati fowosowopo pelu ijoba lati mu igberu ba awon ohun amayederun, igberu ba eto eko, ati sisan owo ori won lore-koore.
alaga tuntun fun ajo isokan ile afriika, a.
aare paul kagame to n tuko orile ede rwanda lowo fi aidunnu re han lori bi ina idagbasoke ile adulawo se n jo ajoreyin.
aare kagame soro yii ninu oro iside re leyin ti won dibo yan an nibi apero awon olori ile adulawo to waye ni addis ababa ni ethiopia.
o ni awon adari orile-ede nile afriika ti kuna lati mu idagbasoke to ye ba ona ola awon eniyan won.
o fi idagbasoke ti koowa n ri to n sele lowo ni eka ile ise nlanla ni asia sapere to ye gege bii awokose rere bayii.
alaga tuntun fun ajo a.
ni pe gbogbo olori orile ede kookan ni lati ji dide si ise to ye ni sise, nipa gbigbe awon igbese akoni laifigbakan bokan ninu ki ile afrika le ba egbe pe lagbaye.
o soro lori nini oja kan lapapo ati ninu ajosepo to dan moran lati gbogun tiwa ibaje to n sele kaakiri ile afrika.
osise ile-ejo kan so lojo-ru (wednesday) ile-ejo kan lorile-ede egypt se idaduro ewon odun kookan fun awon eniyan merindilogun sewon odun kan, latari ikolu ile-ijosin kan to waye ninu osu kejila, ni abule kan ti o wa ni apa gusu ilu cairo lorile-ede egypt.
gbogbo awon ti ajere iwa odaran naa simo lori ni won san owo itanran: dida laasigbo sile, sise akoba fun isokan orile-ede ati jiji awon dukia ara-ilu ko, won le pejo kotemilorun bi won ba fe.
ile-ejo giza ohun tun so pe, ki onile naa ti o je elesin kriteni tun sanwo itanran, eyi ti o je ojidinnirinwo pounds owo orile-ede egypt fun siso ile gbigbe re di ile-ijosin lai gba iwe ase.
ogunlogo awon elesin islam lati abule kafr al-waslin kolu ile-ijosin kan leyin adura jimo ojo-eti lojo kejilelogun osu kejila, ninu eyi ti won fo gbogbo ferese, bakan naa ni won ba gbogbo nnkan ti o wa ninu ile-ijosin naa je.
alufa ijo naa ti kowe lati gbawe ase fun ile-ijosin naa ti awon eniyan ti n josin lati bi odun meedogun, leyin ti won ti sofin fifi ile se ile-ijosin ni odun 2016.
awon elesin krisiteni ti n saroye fun igba pipe lori ideye awon latodo awon elesin islam lorile-ede naa, eyi ti won si n fi igba gbogbo se ikolu si won.
awon alase lorile-ede egypt naa ko sai foju wina awon alakatakiti elesin islam naa, eyi ti won gbogun ti awon eniyan ti o wa ni agbegbe sinai peninsula, ronke osundiya.
omowe tedros je eni akoko ninu omo ile afrika ti yoo di ipo oga agba ajo eleto ilera ninu ajo isokan orile ede agbaye mu leyin ti o jawe olubori ninu eto idibo pelu ibo mẹ́rìndínláàdọ́wàá ninu egbe.
tedros dipo margaret chan ti saa re yoo tan ni ipari osu kefa odun ti a wa yii, leyin ti o ti dipo naa mu fun odidi odun mewaa gbako.
lasiko re ni awon awuyewuye kan jeyo pe, ikobi-ara ajo eleto ilera lagbaaye lori aarun ebola ko ja fafa.
won fi esun kan ajo naa pe, won ko lati se ojuse won nipa sise ikilo ati ipolongo lori ajakale aarun naa to waye ni osu kejila odun 2013 ti awon eniyan bi egberun mokanla si padanu-emi won.
nigba to n ba ajo-igbimo eleto ilera soro, ki o ti di akoko idibo, omowe tedros seleri lati maa gbe igbese kiakia lori awon ajakale aarun pajawiri to le waye lojo iwaju.
o tun seleri lati maa se atileyin fun awon alaini.
“ gbogbo ona lo ye ki awon orile-ede maa gba je anfaani eto ilera agbaye.
emi ko ni simi, ayafi igba ti mo ba mu ipnnu mi se “ nipa omowe tedrosomowe tedros je minisita fun eto ilera ati oro ile okeere, alaga fun igbimo to n sakoso eto owo iranwo fun igbokun ti aarun eedi, iko ife ati aarun iba.
yiyan sipo re ko mu ariyanjiyan lowo rara.
won ti fesun kan tele pe, o n dowobo awon ajakale aarun onigbameji to n sele ni orile-ede ethiopia, sugbon awon to n se alatileyin re so pe iro pata ni esun naa.
egbe alatako orile-ede ethiopia ti fi esun kan ijoba orile-ede ethiopia pe, o n tapa si eto omo eniyan, won si ni igbagbo pe, yiyan omowe tedros si ipo naa yoo je ki orile-ede naa tun ni idagbasoke laarin orile-ede yoku lagbaye.
omowe tedros so pe, ipinnu oun gege bi giwa tuntun naa ni lati je ki ” bogbo omo orile-ede agbaye gbe igbe aye alaafia ati eyi ti o mu idagbasoke wa”.
bakan naa ni omowe tedros tun salaye fun awon asoju orile-ede nibi ipade igbimo ajo agbaye ohun pe” ipinnu oun ni gbogbo igba ni lati mu ileri oun se nipa nimu iyato wa lasiko isakoso oun naa”.