text
stringlengths
9
9.74k
• wá ohun kan tí wàá fi máa mọ àkókò
• gbìyànjú láti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tóo lè máa tẹ̀ lé lójoojúmọ́
• máa ṣe eré ìmárale bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí o wà há
• fojú sílẹ̀ gbìyànjú láti há àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àti ìró nǹkan sórí kí o sì rántí òórùn àwọn nǹkan
mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn tó jí ọ gbé
• tó bá ṣeé ṣe fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú wọn kí o sì gbìyànjú láti bá wọn jíròrò
bí àwọn ajínigbé náà bá wò ẹ́ gẹ́gẹ́ bí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn wọ́n lè má ṣe ẹ́ léṣe tàbí kí wọ́n pa ọ́
• hùwà bí ọmọlúwàbí tí o bá fẹ́ béèrè ohun tí o nílò lọ́wọ́ wọn
• má ṣe gbìyànjú láti dúnàádúrà ìtúsílẹ̀ ara rẹ
• bó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n fẹ́ wá fipá gbà yín sílẹ̀ ńṣe ni kí o dọ̀bálẹ̀ láìmira kí o sì máa retí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
àpótí tó wà ní ojú ìwé 16
ìbánigbófò ìjínigbé — ọ̀ràn tó ń fa àríyànjiyàn
ilé iṣẹ́ tó tún ń rí ṣe nídìí ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé tó ń gbilẹ̀ sí i ni ilé iṣẹ́ ìbánigbófò
owó tó ń wọlé fún ilé iṣẹ́ lloyd’s of london lórí ọ̀ràn ìbánigbófò ìjínigbé lọ́dọọdún ti fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn ún pọ̀ sí i láàárín ọdún 1990 sí 1999
àwọn ilé iṣẹ́ púpọ̀ sí i ló ń fi irú ìbánigbófò yẹn lọni
ìbánigbófò náà kan ríran ẹni tó ń dúnàádúrà lọ́wọ́ sísan owó ìtúsílẹ̀ àti nígbà mìíràn ìsapá àwọn amọṣẹ́dunjú láti gba owó ìtúsílẹ̀ náà padà
bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ ọ̀ràn ti ìbánigbófò yìí ń fa awuyewuye gan an
àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òwò ìbánigbófò ìjínigbé ń sọ pé ó ń sọ ìwà ọ̀daràn náà di òwò ńlá ni àti pé kò bójú mu kí èèyàn máa fi ọ̀ràn ìjínigbé pawó
wọ́n tún sọ pé ẹni tí wọ́n ń bá gbófò lè wá jọ̀gọ̀ nù kó máà mú ọ̀ràn ààbò rẹ̀ lógìírí mọ́ àti pé ìbánigbófò á túbọ̀ mú kí iṣẹ́ bíbéèrè tí àwọn ajínigbé ń béèrè owó máa rọrùn sí i ni ìyẹn á sì jẹ́ kí ìwà ọ̀daràn yìí máa pọ̀ sí i
àwọn kan tilẹ̀ ń bẹ̀rù pé bí ọ̀ràn ìbánigbófò bá wà èyí lè mú kí àwọn èèyàn máa ṣètò pé kí a jí àwọn gbé kí àwọn lè rí owó ìbánigbófò gbà
wọ́n fòfin de ìbánigbófò ìjínigbé ní ítálì jámánì àti kòlóńbíà
àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òwò ìbánigbófò ìjínigbé sọ pé ó ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn san owó fún àdánù àwọn èèyàn kéréje bó ṣe rí ní ti àwọn ìbánigbófò mìíràn
wọ́n ronú pé ìbánigbófò ń fọkàn èèyàn balẹ̀ dé àyè kan níwọ̀n bí ó ti ń mú kí àwọn ìdílé àti ilé iṣẹ́ tí a mú wọnú ìṣètò náà lè sanwó fún ìrànlọ́wọ́ àwọn amọṣẹ́dunjú tó tóótun tí wọ́n lè fọkàn ẹni balẹ̀ tí wọ́n lè dúnàádúrà owó ìtúsílẹ̀ tí kò pọ̀ tí wọ́n sì lè mú kó rọrùn láti gbá àwọn ajínigbé náà mú
àpótí tó wà ní ojú ìwé 17
lọ́dún 1974 wọ́n jí patty hearst gbé ọmọ bàbá olówó tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ randolph a
hearst tó ni iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn kan àmọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà tí ọmọbìnrin náà wá gbè sẹ́yìn àwọn tó jí i gbé tó sì bá ẹgbẹ́ náà lọ digun jalè
nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn agbábọ́ọ̀lù kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ sípéènì dárí ji àwọn tó jí i gbé ó sì ṣàdúrà fún wọn pé wọ́n á ṣoríire
láàárín ọdún 1970 sí 1974 orúkọ tí wọ́n pe ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí yìí ni rúkèrúdò ní stockholm ìdí tí wọ́n fi pè é bẹ́ẹ̀ ni jíjí tí wọ́n jí àwọn èèyàn gbé ní ọdún 1973 ní báńkì kan ní stockholm sweden
nígbà yẹn àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jí gbé náà wá di ọ̀rẹ́ àwọn tó jí wọn gbé
irú àjọṣe yẹn wá jẹ́ ààbò fún àwọn tí wọ́n ń jí gbé gẹ́gẹ́ bí ìwé criminal behavior ṣe ṣàlàyé pé “ bí àwọn tí a jí gbé àti àwọn tó jí wọn gbé bá ṣe wá mọ ara wọn dáadáa sí ni wọ́n á ṣe máa fẹ́ràn ara wọn sí i
ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wá fi hàn pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ kò jọ pé ọ̀daràn náà máa ṣe ẹni tó jí gbé ní jàǹbá ”
ọmọ ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì kan tí wọ́n jí gbé ní chechnya tí wọ́n sì fipá bá lòpọ̀ sọ pé “ mo mọ̀ pé nígbà tí ẹni tó ń ṣọ́ wa náà wá mọ irú ẹni tí a jẹ́ ó wá rí i pé kò dáa bí òun ṣe ń fipá bá mi lò
kò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ ó sì wá tọrọ àforíjì ”
àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14
jíjí ẹnì kan gbé ni ọ̀kan lára pákáǹleke tó máa ń dani lórí rú jù lọ tó lè bá ìdílé ẹni náà
àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15
àwọn tí a jí gbé nílò ìtùnú
àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17
èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n ń jí gbé ni wọ́n máa ń tì mọ́lé wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ìlera wọn
jíjí èèyàn gbé — lájorí ohun tó ń fà á
jíjí èèyàn gbé ti wá di nǹkan tó ń jà kálẹ̀ lóde òní
àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ìpànìyàn ìfipábáni lòpọ̀ olè jíjà híhùwà àìdáa sọ́mọdé àti ìpẹ̀yàrun pàápàá ń jà kálẹ̀
èé ṣe tí gbogbo ayé fi wá léwu tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn èèyàn fi máa ń bẹ̀rù láti jáde kúrò nílé wọn lálẹ́
lájorí ohun tó ń fa àjàkálẹ̀ ìwà ọ̀daràn tí jíjí èèyàn gbé jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àléébù tó rinlẹ̀ láàárín àwùjọ ẹ̀dá
ǹjẹ́ o mọ̀ pé ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn àkókò eléwu yìí
jọ̀wọ́ ṣàyẹ̀wò ohun tó sọ tẹ́lẹ̀ nínú 2 tímótì 3 2 5
“ àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn olùfẹ́ owó ajọra ẹni lójú onírera asọ̀rọ̀ òdì aṣàìgbọràn sí òbí aláìlọ́pẹ́ aláìdúróṣinṣin aláìní ìfẹ́ni àdánidá aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan afọ̀rọ̀ èké banijẹ́ aláìní ìkóra ẹni níjàánu òǹrorò aláìní ìfẹ́ ohun rere afinihàn olùwarùnkì awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ ọlọ́run àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀ ”
àfàìmọ̀ kí o má gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a ti kọ tipẹ́tipẹ́ ṣàpèjúwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́
nínú ayé wa yìí àwọn àléébù tí ń gbèèràn láwùjọ ẹ̀dá ti búrẹ́kẹ
ó yẹ fún àfiyèsí pé a bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe àwọn ìwà abaninínújẹ́ tí ẹ̀dá ń hù tó wà lókè wọ̀nyẹn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ inú bíbélì wọ̀nyí “ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn ín ”
ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò mẹ́ta péré lára àwọn àléébù pàtàkì láwùjọ tó fa àjàkálẹ̀ jíjí èèyàn gbé
“ nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú ìdí nìyẹn tí ọkàn àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú ” — oníwàásù 8 11
ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá ni kò ní èlò tó láti fi kojú àjàkálẹ̀ ìwà ọ̀daràn
ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè òwò tó pé ni ìwà ọ̀daràn jíjí èèyàn gbé
ní ọdún 1996 ìpín méjì péré nínú ọgọ́rùn ún lára gbogbo àwọn ajínigbé tó wà ní kòlóńbíà la ṣẹjọ́ wọn
ní mexico ó kéré tán igba mílíọ̀nù dọ́là ni àwọn èèyàn san bí owó ìtúsílẹ̀ ní ọdún 1997
àwọn ajínigbé kan ní philippines tilẹ̀ ti gba sọ̀wédowó rí láti lè tú èèyàn sílẹ̀
ní àfikún ìwà ìbàjẹ́ láàárín àwọn agbèfọ́ba tí ń gbófin ró máa ń mú kí ìgbéjàko ìwà ọ̀daràn lọ́nà tó gbéṣẹ́ forí ṣánpọ́n nígbà míì
a ti fẹ̀sùn jíjí èèyàn gbé kan àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ pàtàkì tí ń gbógun ti ìjínigbé ní mexico kòlóńbíà àti orílẹ̀ èdè olómìnira soviet tẹ́lẹ̀ rí
nínú ìwé ìròyìn asiaweek ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin gíga ilẹ̀ philippines blas ople sọ pé ìròyìn tó dọ́wọ́ ìjọba fi hàn pé ìpín méjìléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn ún lára àwọn tí a jí gbé ní philippines ni kò ṣẹ̀yìn àwọn tí wọ́n ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá àti iṣẹ́ ológun tàbí àwọn tó ti fẹ̀yìn tì
a gbọ́ pé ajínigbé kan tí òkìkí ẹ̀ kàn ní mexico máa “ ń sá di àwọn agbèfọ́ba nítorí ó ń fún àwọn ọlọ́pàá àdúgbò àwọn ti ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀ àti àwọn agbẹjọ́rò ìjọba ní ẹ̀gúnjẹ ”
ipò òṣì àti ìyannijẹ láwùjọ
“ èmi alára sì padà kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára tí a ń hù lábẹ́ oòrùn sì wò ó
omijé àwọn tí a ń ni lára ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà ” — oníwàásù 4 1
ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ipò ọrọ̀ ajé àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ kò gbè àwọn ni wọ́n sì máa ń lọ jí èèyàn gbé
nítorí náà nínú ayé tí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì ń pọ̀ sí i láìdábọ̀ tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti rí owó láìṣàbòsí òwò jíjí èèyàn gbé yóò ṣì máa fajú àwọn kan mọ́ra
níwọ̀n bí a bá ṣì ń ni àwọn èèyàn lára òwò jíjí èèyàn gbé yóò ṣì jẹ́ ọ̀nà ìjìjàgbara àti ọ̀nà àtipàfiyèsí sí ipò tí wọ́n gbà pé àwọn ò lè fara mọ́
“ ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo ”
“ nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù ” — mátíù 24 12
látijọ́ táláyé ti dáyé ni ìfẹ́ owó ti ń mú kí àwọn èèyàn hùwà ibi
bóyá ni ìwà ọ̀daràn mìíràn wà tó ń fi ohun tó ń fa làásìgbò ìbànújẹ́ àti àìnírètí fún ẹ̀dá pawó tó òwò jíjí èèyàn gbé
ohun tó ń sún ọ̀pọ̀ èèyàn sí i ni ìwọra — ìfẹ́ owó — tó ń mú kí wọ́n máa hùwà àìláàánú sí àjèjì kí wọ́n sì dá a lóró kí wọ́n sì kó ìdílé rẹ̀ sínú làásìgbò fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ọ̀pọ̀ oṣù àti nígbà mìíràn ọ̀pọ̀ ọdún
ó ṣe kedere pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ tí kò dára rárá láwùjọ wa tó jẹ́ ọ̀rọ̀ owó ṣáá la máa ń sọ ṣùgbọ́n tí a ń gbé ìwà ọmọlúwàbí jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan
láìsí àní àní ipò yìí ló ń fà á tí onírúurú ìwà ọ̀daràn títí kan jíjí èèyàn gbé fi ń ráyè gbilẹ̀
ṣé ohun tí a wá ń sọ ni pé àkókò wa yìí ni bíbélì pè ní “ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ”
bó bá rí bẹ́ẹ̀ kí ni èyí yóò túmọ̀ sí fún ilẹ̀ ayé àti àwa alára
ǹjẹ́ ojútùú kan wà sí àwọn ìṣòro bíbanilẹ́rù títí kan jíjí èèyàn gbé tó ń bá aráyé fínra
àpótí àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18
ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣááju sànmánì tiwa òfin mósè sọ pé pípa ni kí wọ́n pa ajínigbé
wọ́n jí júlíọ́sì késárì gbé ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju sànmánì tiwa wọ́n sì gba owó kí wọ́n tó tú u sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gbé richard kìíní aláyà bíi kìnnìún tó jẹ́ ọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ní ọ̀rúndún kejìlá ní sànmánì tiwa
ohun ìtúsílẹ̀ tó pọ̀ jù tí wọ́n tíì san rí ni tọ́ọ̀nù mẹ́rìnlélógún góòlù àti fàdákà tí àwọn quechuan tí ń gbé peru fún ajagunmólú ará sípéènì náà francisco pizarro láti fi gba baálẹ̀ wọn atahuallpa tí wọ́n jí gbé ní ọdún 1533
síbẹ̀síbẹ̀ àwọn aṣẹ́gun náà fún un lọ́rùn pa ni
àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19
pẹ̀lú gbogbo ìsapá àwọn ọlọ́pàá òwò jíjí èèyàn gbé ò kásẹ̀ ńlẹ̀
jíjí èèyàn gbé — ǹjẹ́ ojútùú kan tiẹ̀ wà
“ ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé ti wá le débi tí ara gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè yìí ò gbà á mọ́ o gbogbo wa pátá la ó sì gbógun ti ìwà ibi yìí ” igbe tí olórí orílẹ̀ èdè chechnya fi bẹnu nìyẹn nígbà tó ń ṣèlérí pé òun á mú ìṣòro jíjí èèyàn gbé tó ń bá ìpínlẹ̀ rẹ̀ ní rọ́ṣíà fínra kúrò
ṣé pé ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé ṣeé mú kúrò
ì bá mà dára o ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká bi wọ́n léèrè pé báwo ni wọn ó ti ṣe é
ipá tí wọ́n ti sà
àwọn aláṣẹ ilẹ̀ kòlóńbíà ti da ẹgbàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ agbẹjọ́rò ìjọba mẹ́rìnlélógún àti àkànṣe olùṣekòkáárí ìgbógunti ìjínigbé síta nítorí àtigbógun ti jíjí èèyàn gbé
ní ìpínlẹ̀ rio de janeiro ní brazil nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn ún èèyàn ló tú síta tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nítorí jíjí tí wọ́n ń jí àwọn èèyàn gbé lemọ́lemọ́ nílùú náà
ní brazil àti kòlóńbíà àwọn ẹgbẹ́ tí iṣẹ́ wọ́n jọ ti ológun pẹ̀lú ti ń lọ jí àwọn ẹbí àwọn ajínigbé náà gbé
díẹ̀ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ philippines sì ń dá ẹgbẹ́ ojúlalákàn fi ń ṣọ́rí sílẹ̀ láti gbèjà ara wọn — wọ́n ń pa àwọn ajínigbé
àwọn aláṣẹ ilẹ̀ guatemala ti gbé òfin kalẹ̀ pé pípa ni wọn yóò máa pa àwọn ajínigbé ààrẹ ilẹ̀ náà sì ta àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jí láti dá àjàkálẹ̀ jíjí èèyàn gbé dúró
ní ítálì ìjọba gbé àwọn òfin tó lágbára kalẹ̀ láti dènà jíjí èèyàn gbé wọ́n fòfin de sísan owó ìtúsílẹ̀ wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé owó àti dúkìá àwọn ẹbí ẹni tí wọ́n jí gbé kí wọ́n má bàa lọ san owó náà
àwọn lọ́gàálọ́gàá ní ítálì ń yangàn pé àwọn òfin wọ̀nyí ti dín ìṣẹ̀lẹ̀ jíjí èèyàn gbé kù
àmọ́ àwọn olùṣelámèyítọ́ ń sọ pé ìyọrísí rẹ̀ ni pé àwọn ìdílé ẹni tí wọ́n jí gbé máa ń gbìyànjú láti yanjú ọ̀ràn náà ní bòókẹ́lẹ́ àti pé èyí ń dín iye ìjínigbé tí ìjọba gbọ́ nípa rẹ̀ kù
àwọn ilé iṣẹ́ àdáni tí n ṣètò ààbò fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye àwọn èèyàn tí wọ́n ń jí gbé ní ítálì ti di ìlọ́po méjì láti ọdún 1980 sí 1989
àbá pọ̀ — ṣùgbọ́n ojútùú ò tó nǹkan
lójú àwọn ìdílé ẹni tí a jí gbé ojútùú kan ṣoṣo ló jọ pé ó gbéṣẹ́ — láti fowó gba èèyàn wọn sílẹ̀ bó bá ṣe lè yá tó