text
stringlengths
9
9.74k
7 máa rọra gbé nǹkan
8 máa gba tàwọn ẹlòmíì rò
9 rí i pé ara rẹ le
10 má fọ̀ràn ààbò ṣeré o
jíjí èèyàn gbé ti di òwò tó kárí ayé
ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé ṣẹlẹ̀ gan an káàkiri ayé láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá
ìròyìn kan sọ pé láàárín ọdún 1968 sí 1982 àwọn èèyàn tí iye wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan láti orílẹ̀ èdè mẹ́tàléláàádọ́rin ní a mú ní òǹdè
ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ọdún 1997 sí 1999 nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan 20,000 sí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ 30,000 èèyàn ni wọ́n ń jí gbé lọ́dọọdún
ó jọ pé òwò jíjí èèyàn gbé ló lòde báyìí láàárín àwọn ọ̀daràn lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé láti rọ́ṣíà títí dé philippines tí kò sì sí ẹ̀dá táwọn ajínigbé ò lè jí gbé
nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan wọ́n jí ọmọ jòjòló tí kò tíì lò tó ọjọ́ kan láyé gbé
ní guatemala wọ́n jí ìyá arúgbó tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin kan tó wà lórí àga aláìsàn gbé pamọ́ fún oṣù méjì
ní rio de janeiro àwọn ọmọọ̀ta kan bẹ̀rẹ̀ sí ki àwọn èèyàn mọ́lẹ̀ lójú pópó wọ́n sì sọ pé àfi báa bá fún àwọn ní ọgọ́rùn ún dọ́là péré làwọ́n máa tú àwọn èèyàn náà sílẹ̀
àwọn ẹran pàápàá ò ṣàìfara gbá nínú ọ̀ràn yìí
ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn àwọn ọ̀daràn amójú kuku kan ní thailand jí erin kan tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ tó wọ̀n tó tọ́ọ̀nù mẹ́fà gbé wọ́n wá ní àfi báa bá fún àwọn ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ dọ́là làwọ́n máa tú erin náà sílẹ̀
a gbọ́ pé àwọn ọ̀daràn ọmọọ̀ta ní mexico ń rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn kéékèèké láti máa fi jíjí ẹran ọ̀sìn àti ẹran agbéléjẹ̀ dánra wò kí wọ́n lè nírìírí tó nígbà tí wọ́n bá fi máa lọ jí èèyàn gbé
nígbà kan àwọn olówó làwọn tó ń jí èèyàn gbé ń ṣọdẹ kiri ṣùgbọ́n ìlù ti yí padà báyìí
ilé iṣẹ́ ìròyìn reuters sọ pé “ ojoojúmọ́ ayé yìí ni wọ́n ń jí èèyàn gbé ní guatemala níbi tí àwọn èèyàn ti ń rántí ìgbà táyé ṣì dáa tó jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn oníṣòwò tó rí ṣe nìkan làwọn ajàjàgbara ń jí gbé
láyé ìsinyìí àtolówó àtòtòṣì àtọmọdé àtàgbàlagbà làwọn ajínigbé ń kì mọ́lẹ̀ ”
èyí tó bá le gan an la sábà máa ń gbọ́ nípa rẹ̀ nínú ìròyìn àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìṣẹ̀lẹ̀ jíjí èèyàn gbé ló máa ń yanjú láìsí ariwo
kódà àwọn orílẹ̀ èdè ti pinnu pé nítorí àwọn ìdí kan “ kò sí ohun tó ń ṣí àwọn lórí tí àwọn á fi máa pariwo ọ̀ràn ìjínigbé síta ”
àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò gbé mélòó kan lára àwọn ìdí wọ̀nyẹn yẹ̀ wò
àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13
láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé wo ìtẹ̀jáde náà gan an
bó ti jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún méjì èèyàn ni wọ́n ń jí gbé lọ́dọọdún wọ́n ti wá fún òwò jíjínigbé ní orúkọ orúkọ náà ni “ iléeṣẹ́ kékeré ”
bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1990 iye àwọn tó wá ń ṣe ètò ìbánigbófò ní iléeṣẹ́ lloyd’s of london bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ajínigbé jí wọn gbé ti ń fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn ún pọ̀ sí i lọ́dọọdún
ní àgbègbè caucasus níhà gúúsù rọ́ṣíà nìkan iye àwọn tí a jí gbé pọ̀ sí i láti igba ó lé méjìléláàádọ́rin lọ́dún 1996 sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ lọ́dún 1998
ìwé ìròyìn “ asiaweek ” sọ pé “ ó jọ pé orílẹ̀ èdè philippines ni ibùdó ìjínigbé ní éṣíà ”
ẹgbẹ́ àwọn ajínigbé tó wà níbẹ̀ lé ní ogójì
ní ọdún kan a gbọ́ pé àwọn ajínigbé gba iye tó lé ní bílíọ̀nù kan dọ́là bí owó ìràpadà níbẹ̀
ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n ń jí gbé lọ́dọọdún
ní oṣù may 1999 àwọn aṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba jí ọgọ́rùn ún olùreṣọ́ọ̀ṣì gbé nígbà kan tí wọ́n ń ṣayẹyẹ máàsì
mountain high maps ® copyright © 1997 digital wisdom inc
jíjí èèyàn gbé — òwò àwọn apanilẹ́kún jayé
“ ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé kò dà bíi jíjí ẹrù gbé
ó jẹ́ ìwà láabi ìwà ìkà àti àìlójú àánú sí ìdílé tó jẹ́ agbo tó ṣe pàtàkì jù lọ láwùjọ ẹ̀dá ” ni mark bles sọ nínú ìwé tó kọ tó pè ní the kidnap business
tí wọ́n bá jí ẹnì kan gbé ńṣe ni pákáǹleke máa ń bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀
ìṣẹ́jú kan ò ní lọ kí wọ́n máà jáyà pé bóyá ààyè ẹ̀ làwọ́n á rí tàbí òkú ẹ̀ bẹ́ẹ̀ kẹ̀ wọ́n á tún máa ronú pé ẹ̀bi àwọn ni inú á máa bí wọn ọwọ́ wọn ò sì ní ran nǹkan kan
wọ́n lè wà nínú ìpayà yìí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù tàbí nígbà míì fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá
àwọn ajínigbé náà máa ń lo bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára ìdílé onítọ̀hún láti fi béèrè owó lọ́nàkọnà
ẹgbẹ́ àwọn ajínigbé kan fipá mú ọkùnrin kan tí wọ́n jí gbé láti kọ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí sínú lẹ́tà kan tó kọ sí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ó kọ̀wé pé “ mo fún àwọn oníròyìn láṣẹ láti gbé ohun tí mo ń kọ yìí fáyé gbọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé bí ẹ̀mí mi bá lọ sí i ẹ̀bi àwọn tó jí mi gbé ni ṣùgbọ́n ìdílé mi yóò pín nínú ẹ̀bi náà nítorí wọ́n fẹ́ràn owó jù mí lọ ”
àwọn tó ń jí èèyàn gbé ní ítálì ti wá sọ ọ̀ràn gbígba owó ìtúsílẹ̀ di kàn ńpá nípa gígé ẹ̀yà ara ẹni tí wọ́n jí gbé wọ́n á wá fi ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí rẹ̀ tàbí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n
ajínigbé kan ní mexico tilẹ̀ máa ń dá àwọn tó bá jí gbé lóró nígbà tó bá ń dúnàádúrà owó ìtúsílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìdílé ẹni náà lórí tẹlifóònù
ní ti àwọn ajínigbé mìíràn ẹ̀wẹ̀ wọ́n máa ń gbìyànjú láti wá ojúure àwọn tí wọ́n jí gbé
fún àpẹẹrẹ ní philippines àwọn tó jí ọkùnrin oníṣòwò kan gbé fi í sí òtẹ́ẹ̀lì ńlá kan ní manila wọ́n tọ́jú ẹ̀ wọ́n ra ọtí fún un wọ́n sì kó àwọn aṣẹ́wó tì í láti máa fi tura títí wọ́n fi rí owó ìtúsílẹ̀ rẹ̀ gbà
ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n ń jí gbé ni wọ́n máa ń tì mọ́lé wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ìlera àwọn èèyàn náà
ọ̀pọ̀ ni wọ́n máa ń dá lóró
bó ti wù kó rí ẹni tí wọ́n jí gbé kò lè ṣàìfi ojú winá ìpayà tí yóò mú kó máa ronú ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí òun
kíkojú àìfararọ tó ń fà
kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá tú ẹni tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ ara irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè má tètè balẹ̀
ọmọ ilẹ̀ sweden kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tí wọ́n jí gbé ní sòmálíà sọ èrò rẹ̀ pé “ ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ
òun ni pé kí o bá àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí sọ̀rọ̀ kí o sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn tó mọ̀ nípa ìṣòro rẹ dunjú tó bá pọndandan ”
àwọn tí ń ṣètọ́jú àwọn tí a jí gbé ti ní ìlànà kan tí wọ́n fi ń tọ́jú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀
wọ́n á máa ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn díẹ̀díẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ amọṣẹ́dunjú kó tó di pé wọ́n lọ bá ìdílé wọn kí wọ́n sì tó máa bá ìgbésí ayé wọn lọ
rigmor gillberg ọmọ ẹgbẹ́ alágbèélébùú pupa tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú títọ́jú àwọn tó níṣòro ìmọ̀lára sọ pé “ ìtọ́jú tí a ń fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ní jẹ́ kí ìṣòro náà máa wà lọ kánrin ”
àwọn ohun mìíràn tó lè ṣẹlẹ̀
ẹni tí wọ́n jí gbé àti ìdílé rẹ̀ nìkan kọ́ ló ń fara gbá ìdààmú tó ń tìdí jíjínigbé wá
ìbẹ̀rù pé a lè jíni gbé lè dí ìrìn àjò afẹ́ lọ́wọ́ kó sì ṣèdíwọ́ fún ìdókòwò kì í tún jẹ́ kí ọkàn àwọn èèyàn balẹ̀
láàárín oṣù díẹ̀ péré ní ọdún 1997 ilé iṣẹ́ ńlá mẹ́fà tí òwò wọn nasẹ̀ jákèjádò ayé ló kógbá wọn kúrò ní orílẹ̀ èdè philippines nítorí ewu jíjí èèyàn gbé
obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ philippines tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní aráàlú tí ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn sọ pé “ ọkàn wa ò balẹ̀ rárá ”
àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn the arizona republic sọ pé “ ìbẹ̀rù jíjínigbé ń fa ṣìbáṣìbo lágbo àwọn lọ́gàálọ́gàá ní mexico kò sì lè ṣàìrí bẹ́ẹ̀ ”
ìwé ìròyìn brazil náà veja sọ pé àwọn gbọ́mọgbọ́mọ àti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà ti rọ́pò àwọn ológòmùgomù tó máa ń dẹ́rù ba àwọn ọmọdé ní brazil
ní taiwan wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ iléèwé lọ́gbọ́n tí gbọ́mọgbọ́mọ ò fi ní jí wọn gbé ní orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà pẹ̀lú wọ́n ti gbé àwọn kámẹ́rà amóhùnmáwòrán tí ń ṣọ́ èèyàn sí ilé ìwé àwọn ògowẹẹrẹ kí àwọn gbọ́mọgbọ́mọ má bàa gbé wọn
ìjẹ ni fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò
ọ̀ràn jíjí àwọn èèyàn gbé tó ń pọ̀ sí i àti àwọn ọ̀nà ẹlẹgẹ́ tí a ń gbà yanjú rẹ̀ ti mú kí àwọn iléeṣẹ́ elétò ààbò máa rí ṣe
ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta irú ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tó wà ní ìlú rio de janeiro lórílẹ̀ èdè brazil wọ́n sì ń pa iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjì dọ́là
àwọn ilé iṣẹ́ elétò ààbò tó ń pọ̀ sí i kárí ayé ló ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́gbọ́n tí wọn ò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé wọ́n ń tẹ ìròyìn nípa àwọn àgbègbè tó léwu jáde wọ́n sì ń dúnàádúrà fún ìtúsílẹ̀
wọ́n máa ń gba àwọn ìdílé àti ilé iṣẹ́ nímọ̀ràn nípa kíkọ́ wọn ní ọgbọ́n tí àwọn ajínigbé máa ń lò wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè fọkàn balẹ̀
àwọn ilé iṣẹ́ kan tilẹ̀ ń gbìyànjú láti mú àwọn tó ń jí èèyàn gbé kí wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n san padà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tú ẹni tí wọ́n jí gbé sílẹ̀
àmọ́ ọ̀fẹ́ kọ́ ni wọ́n ń ṣe é
pẹ̀lú gbogbo ìsapá wọ̀nyí ńṣe ni ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè
nígbà tí richard johnson tó jẹ́ igbákejì ọ̀gá pátápátá nílé iṣẹ́ seitlin company ń sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí ní látìn amẹ́ríkà ó sọ pé “ kàkà kí ìwà jíjí èèyàn gbé dín kù ṣe ni á túbọ̀ máa pọ̀ sí i ”
ìdí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi ń pọ̀ sí i
àwọn ògbógi ṣàlàyé ìdí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi pọ̀ sí i lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí
ọ̀kan lára ìdí náà ni ipò ọrọ̀ ajé tó ń burú ní àwọn àgbègbè kan
òṣìṣẹ́ kan tó máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tí àjálù dé bá tó ń gbé ìlú nal’chik ní rọ́ṣíà sọ pé “ ọ̀nà tó yá jù lọ téèyàn lè tètè gbà rí owó ni ọ̀nà tó lókìkí yìí ìyẹn ni jíjí èèyàn gbé ”
ní àwọn orílẹ̀ èdè olómìnira kan tó wà lábẹ́ soviet tẹ́lẹ̀ rí a gbọ́ pé wọ́n ń fi owó tó ń wá láti inú jíjí èèyàn gbé ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun àdáni ti àwọn aláṣẹ ológun tí ń fipá ṣàkóso níbẹ̀
ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ ọ̀pọ̀ èèyàn ń rìnrìn àjò nítorí àtilọ ṣòwò tàbí nítorí àtigbafẹ́ èyí sì ń ṣínà tuntun fún àwọn ajínigbé tí ń wá ẹni tí wọ́n fẹ́ gbé
iye àwọn àjèjì tí wọ́n ń jí gbé ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún márùn ún
láàárín ọdún 1991 sí 1997 wọ́n jí àwọn arìnrìn àjò afẹ́ gbé ní orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n
ibo ni gbogbo àwọn tó ń jí èèyàn gbé wọ̀nyí ti ń wá
àwọn ogun mélòó kan ti ń parí èyí sì túmọ̀ sí pé àwọn sójà tẹ́lẹ̀ rí ò ní ríṣẹ́ ṣe mọ́ wọn ò sì ní lówó lọ́wọ́
àwọn èèyàn yìí sì mọ gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n lè fi ṣe iṣẹ́ tó ń mówó wọlé yìí
bákan náà lílo àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ tó mú kó ṣòro láti ja báńkì lólè àti ṣíṣẹ́pá òwò oògùn olóró ti mú kí àwọn ọ̀daràn ṣí sí iṣẹ́ jíjí èèyàn gbé láti fi rọ́pò ọ̀nà tówó ń gbà wọlé fún wọn
mike ackerman tó jẹ́ ògbógi nípa ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé ṣàlàyé pé “ bí a ti túbọ̀ ń dí ọ̀nà táwọn ọ̀daràn fi lè jí ohun ìní láwùjọ ni àwọn ọ̀daràn wá ń hùwà ipá sí èèyàn fúnra rẹ̀ ”
pípolongo owó gọbọi tí a san fún ìràpadà pẹ̀lú lè sún àwọn kan láti fẹ́ ṣí sí iṣẹ́ jíjí èèyàn gbé
owó ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń jí èèyàn gbé ń wá kì í ṣe nǹkan míì
owó tí wọ́n máa ń béèrè máa ń yàtọ̀ síra ó lè jẹ́ owó díẹ̀ tàbí èyí tó pọ̀ bíi ọgọ́ta mílíọ̀nù dọ́là tí àwọn kan gbà bí owó ìtúsílẹ̀ ọ̀gbẹ́ni ọlọ́rọ̀ jìngbìnnì kan tó jẹ́ oníṣòwò ní hong kong àmọ́ tí wọn kò tú sílẹ̀
ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀ àwọn kan tó ń jí èèyàn gbé máa ń lo ẹni tí wọ́n jí gbé láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú lè mọ̀ nípa wọn kí wọ́n lè rí oúnjẹ oògùn rédíò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbà kí a sì lè pèsè ilé ẹ̀kọ́ tuntun ọ̀nà àti ilé ìwòsàn fún wọn
àwọn ajínigbé tú ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n jí gbé ní éṣíà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n fún wọn ní aṣọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ àti àwọn bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀
àwọn mìíràn máa ń lo ìjínigbé láti dẹ́rù ba àwọn olùdókòwò àti àwọn arìnrìn àjò afẹ́ láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn kí wọ́n sì kó wọn láyà jẹ kí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè yìí lè ṣíwọ́ fífi ilẹ̀ wọn àti ohun àmúṣọrọ̀ wọn ṣèjẹ
nítorí náà wọ́n ní ète tó pọ̀ ọ̀nà àtiṣe é kò sì wọ́n wọn bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tó ń ronú àtidi ajínigbé àti àwọn tí wọ́n máa jí gbé pọ̀ rẹpẹtẹ
ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ojútùú ìṣòro náà pọ̀
kí ni díẹ̀ lára ojútùú rẹ̀ àti pé ṣé wọ́n lè yanjú ìṣòro náà ní tòótọ́
ká tó dáhùn irú ìbéèrè wọ̀nyẹn ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn okùnfà pàtàkì tó fara sin tó ń jẹ́ kí òwò jíjí èèyàn gbé máa gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀
àpótí tó wà ní ojú ìwé 15
bí wọ́n bá jí ọ gbé
àwọn tí wọ́n ti ṣèwádìí nípa ọ̀ràn yìí dá àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí fún àwọn tí wọ́n bá jí gbé
• ṣe ohun tí wọ́n bá ní kí o ṣe má ṣagídí
wọ́n sábà máa ń fojú àwọn òǹdè tó bá ń ṣagídí gbolẹ̀ wọ́n sì lè pa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n fi ìyà jẹ òun nìkan
rántí pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a ń jí gbé ló ń là á já