yo_review sentiment Fíìmù ìgbà dé gba tí ó ń șọ́ra sọ ìtàn tí ó ń kọ́ni lọ́gbọ́n tí ó sì ń rán wa létí pé ní Nàìjíríà bí àyípadà ṣe ń dé náà ni gbogbo ǹkan ń dàrú sí i. positive Íṣe takuntakun àti àyẹ̀wò lọ sí inú iṣẹ yìí, iṣẹ takuntakun, àmì rẹ dára yàtọ̀ bákannáà, òtítọ́ ati ìgbé kalẹ̀ rẹ ya ní lẹ́nu gídígán positive Fíìmù My Village People jẹ́ èyí tí ó jẹ́ pé á mú ẹ sọ ẹ̀kọ́ ìwà dídára rẹ̀ ẹ nù. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ bíi olùtọ́pa ọ̀nà ni bákàn. Lápàapọ̀, Nollywood ò kìí ṣe àwọn ipa oní agbára ìbílẹ̀ dáradára. My Village People ṣe é yàtọ̀ ní ọ̀nà tó dára, ó sì yẹ fún ìgbóríyìn. positive Kìí se pé ìtàn yí jẹ́ èyí tí ojú kò rírí ṣùgbọ́n ọ̀nà ìṣọwọ́ ronú tí Nàìjíríà ni wọ́n fi kọ ọ́. Ó pani lẹ́rìn-ín, kò múná d’óko tó àti pé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ inú rẹ̀ dára jù àwọn èyí tí a tún lè rí rà ní ọjà Nàìjíríà. Mo gbádùn fíìmù yẹn gan-an ni, máà rí I pé mo sọ fún àwọn tèmi ní Nàìjíríà kí wọ́n wò ó. positive Àwọn ọdún 1980,àwọn tí wọ́n ń lọ oògùn olóró, àwọn obìnrin dúdú tí wọ́n rẹwà… ìgbádùn ọ̀run ni mò ń jẹ yìí o. positive Eré- aládùn tó ní ìrírí tó sì ń lo létòlétò. Eré tó dára, tó sì dá lóríi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ káàkàkiri, ìtàn náà sì jágere, àmọ́ wọ́n o ṣe kíá kíá , ṣe ló fáà , àti pé irúfé orin tí wọ́n lò àti bí wọn ti gbàkókò ènìyàn kò yẹ fún irú eré àgbéléwò báyìí . Àmọ́ ó dára ní wíwò fún ẹni tó bá ní àkòkò púpò lọ́wọ́. positive Àtúnṣe. Esé fún èyí. Orí mìi wú. Sùgbọ́n kí Nelso Orah ṣe apá ìwà Umar. Inú mi á dùn tí àtúnse bá wà ní ipa yìí. positive O kọja bẹẹ, ẹ ó fẹ́ wọ fíìmù yìí, fíìmù náà jẹ́ oun tí e ma gbádùn yàtọ̀, Nollywood to dùn gaara positive Inú mi dùn lẹ́yìn tí mo wo fíìmù náà, ohun gbogbo lọ bó se yẹ kó lọ. àwọn Olùdarí àti atùkọ̀eré yí mú inú mí dùn gan. Olùdarí, Kémi Adétiba ṣe gudugudu méje yàyà mẹfà, inú mi dùn sí i. Mo ti gba àwọn èèyàn láti wo sinima yìí. Mo n'ireti láti wo àwọn sinima tí Kémi adétiba máa tún darí. positive Genevieve Nnaji kan ẹsẹ mọlẹ ninu awọn.oludari olóyè. Kò já kulẹ nínú iṣẹ àkọkọ rẹ. Eré lion heart je agbọdọ wo, bi o se polongo ibi Nollywood káàkiri àgbáyé. positive Nollywood ńṣe bẹbẹ!!! Eré yii sọ̀rọ̀ nípa àsà, ìbásepọ̀ ati ìdílé. Orísirísi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ ninu eré yii tí nkò lè sọ́ tán. positive Sinimá tó dára ni. Ó fihàn ẹwù tó wà nínu ẹlẹ́yà mẹ̀yà ní orílé èdè Nàìjíríà àti bí ó ṣẹ nípa tí o da lórí àwọn ọmọ positive Eré yìí dára positive "Mo fẹ́ràn eré yi Ó se mí ní kàyéfì láti ka ìròyìn burúkú lóri àjábọ̀ eré yìí. ṣé ati ẹ mọn eré ti ódára bí? Eré yii dára ósì lárinrin púpọ̀ pẹ̀lú. Àwon òsèré to pójú òsùwòn, ìtàn to dabi ìsẹ̀lẹ̀ tootọ. ati kúọ́lítì rẹ̀ kamama. Ekú isẹ́ takuntakun. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gan ju ""Wedding party"" apá kinní ati apá kejì lọ. kò já mi kulẹ̀ rárá" positive Mo wo àkọ́kọ́ ìgbéjáde rẹ̀ ní Houston Texas Ó yẹkí fíìmù yìí gba Oscar Award. Ìtàn eré náà dára púpọ̀. Gbogbo àwọn òṣèré rẹ ló fakọyọ. positive Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn àwòrán, tí ó wo apá kíní yóò ní òye ìtan tí wọ́n lò àti ti wọ́n tẹ́lẹ̀ nínú àgbéjáde eré náà. positive Gbígbéjáde tó dára. positive Eré tó n ṣí ní lójú Eré yi dára gan o sì tún dáa yàtọ.̀ Àwọn èlòmíràn léè má feran eré náà bóyá torí wọn ti má feran eré èfè àti eré ẹrù tàbí ayé pẹlú ọkọ kotii mọ́ wọn lára. Eré na fihàn bi ayé atún ọkọ̀ se, ọmọ ikọse àti àwọn oníbara. Ósì tún kọ́ àwọn òbí àti àwọn ọmọ ní èkó. O jẹ́ eré tí o máa ṣí ní lójú. positive Ìfi ojú tẹ́nbẹ́lú, ère nípa ọ̀ràn tí ó lágbára pẹ̀lú adùn ìtàn Èyí jẹ́ fíìmù ọlọrọ púpọ̀ nípa ìwà . Kò sí ààyè kan tí ó pàdánù. positive Ìtèsíwájú eré nlá ní. Olùkòtàn àti Olùdarí eré yìí ní ọpọlọ. Ẹsé gan fún eré nlá yìí. positive Mo gbàdún pé mo rí àwọn mélaǹdì àti áilàndì tí wọ́n lò, èyí yàtọ̀ sí àwọn eré mìíràn. Èkó jẹ́ ibi tí ó rẹwà láti ya fíìmù, pàápàá tí ó bá jẹ́ wípé àwọn èyàn aláràmbàrà ni wón lé lò gẹ́gẹ́ bi aṣe rí i nínú eré yìí. Àwọn apá ìjàm̀bá máa ń jẹ́ ìdàmù fún Nollywood láti ṣe, sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé wọ́n rí i ṣe níbí positive Eré Itokasi Fíìmù to pe. Mo feran gbogbo iseju aaya Fíìmù na, Mi ko fe ko pari mo. positive Íṣe Olùdarí àkọkọ Akinnuoye - Agbaje je itan tí o bá ní nínú jẹ́ to dá lórí ìrírí Olùdarí náà èyí tí o jẹ ọmọ ti wọ́n 'gbìn jáde' ni Nàìjíríà lọ sí ìlú ọba ni asiko ìgbà kan . Wí wo ìgbà àkọ́kọ́ fíìmù yìí fi ibi ati òṣèré tí o ṣé gbàgbọ́ nípa wípé a ti ni ìrírí rẹ̀,ìgbà míràn yíò gbà ọnà ti o ni ìtúmọ̀ yíò fi ipá eni tó n rántí ìrírí ayé rẹ̀ ti o fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki hàn. Sí wájú sí, fíìmù nà kò tọ́ka sí ibi tí o ti ṣẹlẹ, ṣùgbọ́n ìjàkadì tí òṣèré pàtàkì n jà nínú rẹ. Pẹlú gbagbo èyí, òṣèré pàtàkì fíìmù na ni ìwà ti o fé kí àwọn olùwò yíò fe mo bí o ṣe dàgbà sókè nínú fíìmù náà. Lápapọ̀, ìgbìn jẹ iṣẹ Olùdarí àkọ́kọ́ tí o kọjú sí ọ̀rọ̀ ìdánimọ̀ méjì àti ìkórìrá ẹni ní ọnà tí o fi òun púpọ lẹ̀laisọ sùgbọ́n o pèsè ìbànújẹ́ ati ìkòrò fun ènìyàn tó n tiraka fún ìtumò ati ìdánimọ̀. Òun tí a lè nifẹ sí pọ ninu fíìmù yìí, èyí tí o mú ìgbà kan ninu ìtàn àwọn aláwọ̀ funfun wá sáyé, pàtàkì kókó ọ̀rọ̀ ara eni ye ju ìṣẹ́jú éjeléniọgọ́run ti won fi ṣe. positive Eré to yanilenu tí a gbọ́dọ̀ wo. positive Ipele eré tó dára Mo gbádùn eré yìí. Gbogbo òṣèré ṣe dára dára mo ṣì gbádùn wíwò ẹ. Ó wù mí kó sésìn tó pọ̀. Mo ń dúró de sésìn tó kù. positive Iṣẹ́ ṣíṣe láti inú àkọsílẹ àtowọ́ olùkọ̀tàn Darci Picoult, Dòsùnmú ṣe ìtàn lẹ́ṣọ̀ọ́ lónà tí ó bòjúmu, eré orí ìtàgé tí ó ṣe wẹ́kí pẹ̀lú ohùn orin, ó sọ ojú abe àṣà níkǒ (a lo ọ̀pọ̀ ìgbà láti tẹjú mọ́ àwọn tí àwọ̀ ara wọn ṣe rẹ́gí, bí a ṣe lo ọ̀pọ̀ ìgbà náà láti yófẹ̀ẹ́ ojú Gurira tí ó ń sọ orísirísi ọ̀rọ̀ láì lanu), tí ó sì ń farajọni. positive Eré tí o lágbara positive Kò sí ọ̀rọ̀ kánkán tí ó le júwe irú agbára tí ère yìí ni ati wípé ó ṣe ìrántí oriire tí ó jé láti là ìjà abéle kọjá. Ìtàn àgbàyanu tí ó sọ nípa ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ ni burúkú tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti nípa àwọn ènìyàn inú rẹ. positive Ó dára positive oniduro àwon ígbò Lionheart se aṣojú ohun tí ó tú mọ̀ si láti jẹ́ ọmọ ígbò- ṣíṣe iṣẹ́ taratara àti ètò ìgbé ayé positive Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣọwọ́ ṣeré tó mẹ́hẹ àti àwọn ǹkan kan tí kò mú ọpọlọ dání sí èmí ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo gbádùn rẹ̀ b’óșe rí. Mo lè má tún un wò mọ́ láyé, àmọ́ ó dára ní ẹ̀ẹ̀kan tí mo wò ó yẹn. positive Nígbà tí àwọn àkòrí rẹ̀ jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ òtítọ́ tí ó dùn moní, àwọn olùpilèsè eré náà ó kàn ṣe àwítúnwí asán àwọn fíìmù tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Ohùn wọn jẹ́ tiwọn. Irinṣẹ́ ìyafọ́tò (camera) náà kò dúró ṣin nígbà tí ó yẹ kí ó máa káà kiri, ṣùgbọ́n ó dúró lópòlopò ìgbà láti fi àyè sílẹ̀ fún àwọn òṣèré kí wọ́n lè fi àwọn àbùdá wọn hàn kedere gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fíìmù náà ń dán ìrọ́jú wọn wò. positive Ó pa ni lẹ́rìín ó pa ni lẹ́rìín Ó ga, fíìmù yí pa ni lẹ́rìín gan-an ni. tí ó bá ń wá fíìmù kan láti gbé ìṣe sí rẹ sókè lẹhinna èyí ni fíìmù tí ó tọ́ fún ọ. positive Fíìmù tó ga jù !! Èyí ní láti jẹ́ fíìmù tí ó dára jù lọ tí a ṣe jáde ní Nàìjíríà, kí a tó mẹ́nuba abala àrín tàkìtì?! positive ÀWỌN OBÌNRIN ILẸ̀ ADÚLÁWỌ̀ TÍ Ó RẸWÀ. positive Mi ò mọ ìdí tí àwọn èèyàn fi ń fún fíìmù yìí ní òṣùwọ̀n tó kéré. Ṣùgbọ́n tí e ó bàá gbàmígbọ́, ó ti pé tí mo ti wo eré tó dára tó báyìí, tí ó sí tún dára ju eré Bollywood lọ. positive Àwòrán eré yìí dára púpọ̀. Olùdarí náa ṣe iṣẹ́ tó dára. positive Iṣẹ́ tí ó tayọ Ìṣe Temi Otedola jẹ́ ìyàlẹ́nu gan-an ní tòótọ́ . Mo gbádùn àwọn ìpele tí ìtàn náà ní ní kíkún àti ọ̀nà tí wọ́n fi ṣàfihàn àlàyé pàtàkì. positive Igbese tó lakaaki láti ṣe ipepada ìṣe àti ìtàn wá. Sinima àgbéléwò yìí safihan kirakita àwọn ènìyàn tí a máa ń yìn nù. Ó rọrùn láti gbé sí orí ìwọ̀n àmọ́, nígbà tí irú ìtàn yìí bá jẹyọ ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a fi máa wo oníkálukú. Looto, ní ìgbẹ̀yìn, aisedeede fi o hàn gẹ́gẹ́ bí alaimokan, yóò si gbé ọ gesin aáyán lórí ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣojú rẹ positive Ó wà ní bẹ̀!!! 🔥🔥🔥 Dájúdájú ère Áfríkà tó gbayì nínú ọdún yìí, mo gbádùn gbogbo ìṣẹ́jú tó wà nínú wákàtí méjì àti ọgbọ̀n ìṣẹ́jú 😀👏👏👏🔥🔥🔥🔥🔥🔥✔️✌️ positive Ìtàn to sọwọn nipa àṣà ìdílé lati ọna ti o yàtọ ti won sì gbejade pẹlu òṣèré ti o koju osunwon. positive Níparí eré orílèdè Nigeria tó lágbára, fún òpọ̀lopọ̀ mò ún nírètí pé orílèdè Ngeria ma pèsè eré tó lágbára, àti ibè ni àwon arákùnrin Esiri tí má wolé positive Ka má parọ́ ṣiṣé eré orí ìtàgé yìí dára gan nii. Àgbà ní o sí jẹ́ láàárín àwọn eré orí ìtàgé. positive Tipátipá ni a fi lè rí ojú ìṣẹ́jú márùn-ún tí kò pa ènìyàn lẹ́rìn-ín. N kò rò pé ere àgbéléwò kankan wà ní Nàìjíríà tó lè borí fíìmù yìí. Iṣẹ́ eré yìí kúnjú òṣùwọ̀n. positive Eré Nollywood tí ọ̀rọ̀ ìfé ti ó n panilérìn-ín. Eré yìí Dára tó láti Fi Ẹ̀rín síni lẹ́nu lẹ́yìn ọjó tí ó burú. positive Eré àgbéléwò dìdára lórí jákèjádò- orílè-èdè Oun kan pàtó tí mi ò féràn nípa fíìmù yìí ni pé ko si ibásepò pẹlu ágbègbè orílè-èdè Nàìjíríà ati india bó ti wu ó kéré mọ. Eré àgbéléwò ìfé tó lárindin lè yìí positive Ìtàn yí kò já fáfá láti ìbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n má jẹ́ kí ó sú ọ. Ìtàn gidi gbáà ni. positive King of Boys Eré yìí dára gidi, láti ìtàn dé àwọn òṣèré, aṣo ati ìmọ̀lára tí akoni eré náà. Inú mi dùn láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà. Kú iṣé takuntakun Kémi Àdetìbà, Kú iṣé takuntakun Solá Sóbòwálé. positive Àgbọ̣dọ̣ rì fún gbogbo ènìyàn Namaste wahala jẹ̣́ ọ̀gá nínú àwọn eré, ó sì kó orísìí àṣà papọ̀. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Nollywood àti Bollywood yìí ni gbgogbo oun tí eré ìfẹ́ tó bá dára máa ní. Àwọn òṣèré tí ó jẹ́ ọmọ India fakọyọ, wọ́n sì kọ́ ipa wọn dáradára positive Ojúlówó, ìdánilárayá àti ìmọ̀lára dídára. Mo le fi gbogbo ọjọ́ wò ó. Ó wù mí kí wọ́n gbé e jáde síi ju ẹ̀kan lọ́sè lọ. Yàtọ̀ sí èyíinì, ó kàn sáa dára púpò ni. Òpò nínú àwọn eré olótìtọ́ọ́ jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń kó kí wọ́n tó ṣe é, ṣùgbọ́n, èyí kọ́. positive Màá fún ere yìí ni ẹẹ́sàn an lórí òṣùwọ̀n Nollywood nítorí ìtàn ere náà jẹ àrà ọ̀tọ, bẹ́ẹni àgbéjáde rẹ̀ tó jẹ́ kó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn eré àgbéléwò yòókù ni ilẹ̀ Nàìjíríà positive Ìtàn gidi. Ó jẹ́ eré àti ìtàn gidi. Mo fẹ́ràn rè. positive Ó gbenután Eré yìí wọ akínyẹmí ara mìi lọ. Mo bá eré náà lọ tọkàntọkàn. Lóòtọ́ọ́, ó fi ọlọ́run hàn lónà tó yẹ. Olórun yóò bùkún olùkọ̀tàn náà, àwọn olùgbéjáde, àti gbogbo àwọn tó kópa pátápátá. Àwọn òsèré náà kò gbéyìn, gbogbo ènìyàn ló ṣe iṣé tó dára. positive Mo gbádùn ìbáṣepọ̀ tó wà láàrín-in Mr. Tayo (Bimbo Manuel) àti Ejiro (RMD) positive Nǹkan kan tí ó mo fẹ́ràn nínú eré yìí ni bí a ṣe sọ ìtàn rẹ̀ àti bí àwọn òṣèré ṣe túmọ̀ rẹ̀. Ó yẹ kí a gbé oríyìn fún àwọn òǹkọ̀tàn, olùdarí, àti àwọn a yàwòrán fún làálàá wọn lórí iṣẹ́ yìí. positive Fíìmù krììstẹ́nì tí ó dára jùlọ̣ !!! Mo fẹ́ràn eré yìí! Wọ́n ṣe é dáradára. Eré ṣíṣe náà kọjá àfẹnusọ, ìtàn náà sì dára. Ìgbóríyìn fún àwọn òsèré àti àwọn ẹgbẹ́ tó kópa nínú ṣíṣe eré náà. Dájúdájú àgbọdọ̀ wò ni. Ṣùgbọ́n, wàá nílò ǹkan ìnujú. positive Fẹ́ràn rẹ̀! Mo fẹ́ràn eré sinimá nàá, àwọn òṣèré, olùdarí, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. Gbogbo ènìyàn lo jé kí ó dára púpọ̀ pẹ̀lú eré ṣíṣé wọn. Dájúdájú, ẹnikẹ́ni tí ó bá so wípé kò dára ò mọ fíìmù gidi, tàbí kí àṣà àwọn elòmíràn má nítumò síi. positive Erè naa dára pẹ̀lù àwọ̀n òsèré tó rẹwà. Mo fẹ́ràn lati maa rí Bísọ́lá nínú eré, ó dára positive Eré ṣíṣe tó fakọyọ, ìdarí tó fi òye hàn ṣùgbọ́n ìtàn yìí kò fi bẹ́ẹ̀ wúni lórí. Mo ní láti sí a sì àkáǹtì kí n lè ṣe àgbéyẹ̀wô eré yìí. Iṣẹ́ yìí rẹwà púpọ̀. positive Ó dùn móni Mo gbádun eré náà. Eré náà àti ìtàn náà Dára púpọ. Mó rí gẹ́gẹ́bí oun tí ó múmi ronú Lórí ọ̀rọ̀ ìgbèsí ayé– èyí dájúdájú yíò je ìlanilójú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wón ń to ṣe ìgbéyàwó. positive Gabriel Afolayan tún jẹ́ òṣèré tó yàtọ̀ láàyè tirè. Òye iṣẹ́ máa ń yé e ni sáá. positive Kò burú fún àgbéyẹ̀wò positive Fíìmù gidi àti ìsesí àwọn òșèré tí ó máyàn lórí. Ojúlówó ìtàn gidi, ìṣọwọ́ ṣeré gidi àti ì dá ẹ̀rín pá òșónú rere ni wọ́n pò pọ̀ sí ojú kan. Fíìmù tí ó mú ara gbá yágíyágí àti àwọn òșèré tí ó lé kenkà. positive Ere tí àgbékalẹ̀ rẹ dára ṣùgbọ́n tí ó tiraka láti sàfihàn àmúyẹ ere apanilẹ́rìín àti dírámà pẹ̀lú èrò láti ni ipa mọ́nigbàgbé. positive Ó LÉ KENKÀ Nígbà tí mo kọ́kọ́ wo sinimá yìí, ó yà mí lẹ́nu gan-an ni o. N kò fẹ́ dàbí ẹni tí ó ń ronú ju bó ṣe yẹ lọ o, ṣùgbọ́n mo máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ohun ayé yìí. Mò ń fi ojú sọ́nà fún apá kejì pẹ̀lú àwọn òșèré kan náà àti ìtàn tí yóò tún rújú ju èyí lọ. positive Ìyàlẹ́nu Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mi ò kí n kàsíí, ṣùgbọ́n nítòótó, eré yìí yanilẹ́nu. Níṣe ni èèyàn máa mọ wípé, wón kò náwó púpọ̀ lórí eré náà sùgbọ́n ìfojúsùn wọn àti ìṣe eré náà yanilẹ́nu. Bótilẹ̀jẹ́pé, ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjà náà kò dára tó, síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ fún wíwo. positive Ìtàn idile àti ogun. Mo fi taratara fi ọwọ́ sí eré náà. positive Ó gajù Fíìmù yìí ti jẹ́ kí n yí ọkàn mi padà nípa nǹkan tó dára. Ere tó fakọyọ ni. Ere yìí fà nílẹ̀ díẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ó wuyì láti wò. Ìrántí àwọn abala tó ti kọjá jẹ́ kí ìparí ere náà túnbọ̀ dùn nítorí pé gbogbo nǹkan kàn ń ṣẹlẹ̀ papọ̀ ni. positive Awon eniyan ko ni kekoo ti won ko ba gbiyanju nkan. Eré yìí fi oríṣii ìṣòro hàn, pàápàá jùlọ, èyí tó ṣe pabambàrì èyí tí ó jẹ mọ̣́ ìpòrúru ipò àwọn aláwọ̀ dúdú ní àwùjọ positive Nípasẹ̀ ọrọ̀ -ajé ti ìṣà fihàn, Èyímofẹ́, (tí a túmọ̀ sí “Èyí ni Ìfẹ́ Mi”) ṣe àfihàn àílákókò, àwòrán àgbáyé ti ìfarabalẹ̀ ènìyàn lákòókò tí ó ṣe ìdásílẹ̀ Arie ati Chuko gẹ́gẹ́bí ọìtẹ́wẹ́gbà tuntun sí ṣíṣe fíìmù. positive Eré ńlá ni eré náà fún ẹni tí a mọ̀ sí olùsọ̀tàn àgbà. Gold Statue lè má jèé ọ̀kan lára àwọn eré Tádé Ògìdán tó dára jù o, ṣùgbọ́n iṣé ńlá ni iṣé náà. positive Ere gidi. Eré tí Ìtàn rẹ lágbára nìyí. Ó yẹ láti wò. Mo rọ yín láti wò ó. positive Èyí dùn ń wò Ọmọ a báni gbẹ́ ẹrú jíșẹ́ yẹn mú ìbàlẹ̀ bá ọkàn ẹni púpọ̀. Ìtàn gidi ti wọ́n sọ lọ́nà tó mú ọgbọ́n dání. Ó yẹ kí o wò ó. positive Ó ye kí eré yìí ni sísìn karùn-ún Eré yii dára yà àti pé ó dùn gan. Ti àwọn cálífátì kò bá ní ìfé si. Èyí orúkọ náà padà tàbí ke yọ kúrò lára rẹ̀. Òṣèré ńlá, eré kíko ńlá!! Àwòrán ńlá. positive Eré ńlá Mi ò ní òye ìdí tí eré ńla yìí fi ní àgbéyèwò tí ó kéré tó bayi.Eré náà dùn tí mo fi gbogbo ọkàn mi síi gẹ́gẹ́ bí ọmọ akẹ́kọ̀ ilé ìwòsàn. Ise takuntakun and òsùbà fún àwọn adarí àti olùgbéjáde Eré náà. positive Iṣẹ́ lọ́pọ̀ rẹ tí yọrí ju awọn akẹgbẹ rẹ̀ lọ ní orílẹ́-èdè Afirika. Fíìmù náà jẹ́ ìgbésẹ̀ àrà ní ọ̀nà tí o tọ fún ṣinimá Afirika. positive Orin atunilára tí ó sín pẹ́pẹ́ pẹ̀lẹ́ orin jáàsì àti pọ́ọ̀pù tí ó peregedé àti ẹgbẹ́ akọrin eléré ìtàgé tí ó kún ojú òṣùwọ̀n. positive Ìpadàbọ̀ ọba náà dáa positive Iṣé ńlá. positive Àgbékalẹ̀ rẹ̀ gún régérégé, ìtàn tí ó kani lára gbọ̀ngbọ̀n tí a sọ pẹ̀lú ìṣèrè tí ọ dára gidigidi. positive Ọ̀kan lára fíìmù tí a ṣe tó dára jù ni ọdún 2017 ni “Isoken”. Ere yìí sàfihàn àṣà tó wà ní agbègbè orílè-èdè tí a ti se é jáde. Àlàkalẹ̀ eré naa ati, ìgbàwòran jáde, àti àwọ̀ àti aṣọ ló se àfihàn àṣà ìbílẹ̀ ni. Ère yìí tún ní ọ̀kan ò jọ̀kan abala ti tó lè pa ènìyàn lẹrin ín. positive Ó duǹ-ún wò. Eré gidi! Mo gbádùn pé wọ́n mú ìdàgbàsókè bá èdè igbo positive Àwọn àbí tí wọ́n fi kámẹ́rà àmúlọ́wọ́, àwọn abala tí ó tọ́ ni lọ́kàn, àpilẹ̀kọ tó gbọkàn kan àti ìkọ̀tàn tí ó fún ìtàn tí a ti mọ ní àwọn àmúyẹ ilẹ̀ Adúláwò ló jẹ́ kí ‘Oloture’ jẹ́ sinimá tó lágbára tí o ò kàn ní rọ́jú wò ṣùgbọ́n tí yóò yà ọ́ lẹ́nu tí o ó sì fẹ́ràn. positive O nilo lati wo eyi!!!!! Agbọdọ wo !!! Mo feran ipa ti awon osere ko, itan naa, koda gbogbo re lapapo positive Eré tí o dára . positive Mo fẹ́ràn-an rẹ̀ - Mo ní ọmọ kan… positive Íṣe àrà làti ọwọ́ Kẹ́mi Adétiba, ìtàn náà ni akọsilẹ dáadáa, ìwà àkọọlẹ tí o yege. Gbogbo àwọn òṣeré ṣiṣe takuntakun. Fíìmù yìí jé ti àgbáyé,mo kàn sárá sí gbogbo ẹgbẹ awọn atuko positive Eré alágbára tí agbọn ìtàn tí a ti gbàgbé . Èyí kìí ṣe fún àwọn tí kò ní àyà. positive Eré tó dára gan ni o sì kọ́ ní lọ́gbọ́n positive Eré tí o lé ti ó sí ní àsìkò ẹ̀rín. Ìyẹn ní irú àwọn eré tí mo fẹ́ràn. positive Itan tooto yii! O le kenka Ìtàn ńlá ni ìtàn yìí. Ìtan ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ adúláwò tí ó wá ní òkè òkun láti ìgbà ìwáṣẹ̀. Inú mi dùn pé arákùnrin wa sọ ìtan tirè, tí ó sì kọ ọ, darí, tí ò tún kópa nínú síṣe rẹ̀. Isé eré Damson dára púpọ̀. positive Ó mó rí wu , ósì pa ni lẹ̀rín bi wón ti ṣàpèjúwe àṣà méjèjì. Mo ni idálaráyá jálè ! Erè àgbéléwò to jágeree ní è yìí. positive Àgbéjáde tó tayọ. Fíìmù yí jẹ́ èyí tó sọ nípa ìkọlù ìbálòpọ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà lóri àwọn ọmọ obìnrin láti ọwọ́ àwọn olùkó. Ó ṣe ìfiránsé tó rọrùn ní ònà tí a kò lérò. Ònà tí a kò fọkàn sí, Ìpàdánù díẹ̀díẹ̀ wà níbẹ̀. positive Iyanu! Mo fẹ́ràn ìfihàn àṣà àní ninu orin. Ó dára láti rí àwon ènìyàn tí ó mú mi wo eré Nollywood lẹ́ẹ̀kan si. Ósì mù ni rẹrin. positive Eré oní pele sí ipele tí Naijiria tó dára Mo féràn eré yìí. Ó dùn wò. Eré ṣíṣe tó dára. Gbogbo ènìyàn fakọ yoo. Àwàdà inú eré na jojú. Ó ṣì kó èèyàn lọ́gbón. positive Eré náà sọ ojú abẹ́ niko Èdè tí wọn ló jẹ èdè oríta, àwọn òṣèré náà ṣe bẹbẹ, ìgbé eré jáde àti ìsàtúntò naa dara lọ́pọ̀. Ó sì tún ní ìtàn tó dára. Pabambarì rẹ̀ ni wípé ó gbé Ajegunle sórí àwòrán ayé. positive Àjàkálè àrùn tó ṣì tún le ṣẹlẹ̀ Ó jẹ́ eré tó tayọ, tó ṣì jẹ́ yọ pẹ̀lú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni àyíká wa. Ó dára ju gbogbo àwọn eré tí mo ní lọ́kàn lọ. Eré na ṣàfihàn ohun tó pọ̀. Ó jẹ́ àjàkálè àrùn tó lágbára àkókó ni ìwàláàyè mi. Má nì fẹ́ láti ra kásẹ̀tì rẹ̀ ṣọ́wọ́, mo tí wá káàkiri US ṣùgbọ́n mí ó tí ríi. Ṣé amo bí tí mo tí lé e ri rà. positive Bo ni o ṣe jẹ wípé eré tó ní irú akole yii se di wipe o lọrá ti o sí danilagara. Nibo ni ìkánjú wa? Nibi ni ifẹni sokunkun ati aibalẹ ọkan wa pẹlu? Isatunkọ ati iwọn rẹ bi mi nínú ti o sí ònà ti o fi je kí eré náà tó wakati meji at'abo. Nkan to dojutì ni ni wípé eré náà ṣàfihàn ìṣòro tó ṣe kókó, emi kan ro wipe won le eré náà lai mu kí àwọn oluworan ma sun. positive Lionheart jé eré tó lẹ́wà. Eré yìí jẹ́ eré ilé adúláwọ̀ tí ó dára jùlọ tí mo ti wò. Gbogbo abala eré náà dára, ó tún ní àwàdà díẹ̀ àti ọ̀rọ̀ akọ́nilọ́gbọ́n. Mo fẹ́ran wípé ó ṣojú Nàíjíríà dáadáa positive Ìpín kejì Mo fẹ́ràn ìpín àkọ́kọ́ àti wípé mò ń fojú sọ́nà fún ìpín kejì. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn òṣèré náà. Mò ń sì ní ìrètí wípé àwon ìpín tuntun mìíràn yóò jáde. positive Eré náà jẹ́ eré oní wákàtí méjíì tí mi ò ní pè ní ìgbádùn ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkókò ìrónilágbára. Tí mo bá ń ṣiyèméjì, ìgbàgbó mi tún ti lékan si… Eré náà yé mi dáadáa nítoripé ó dájú pé olórun ti fọwọ́ tó mi rí. Mo tún jẹ́ ìpè ọlọ́run léékàn si. positive Ó fẹ́ẹ̀ rí bí wọ́n ti ń ṣe àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin ni Nàìjíríà àti ìwọ oòrùn Áfíríkà báşubàşu. positive Ó ní àwọ̀ àti àlàyé ṣùgbọ́n ìwúnilórí kìí ṣe ọ̀rọ̀ náà Ní gbogbogbò, Àádọ́ta jẹ́ bó ṣe wà , ó ní ẹwà àti iwunlere, ìrètí ni láti jẹ́ìwúnilórí ní ìparí ṣùgbọ́n kò wọ̀ mí ní akíyẹmí ara ṣùgbọ́n inú mi dùn tí mo bá ń rántí diẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti síìnì wọn ní òpin. positive Ise to lami laaka ti Kunle Afo se yi si eyin Eré yi mu enu ba oro to se koko si abala eko orile ede Naijiria. Itan to dara, ibEré to dun,sise Eré to mu ako yo. Fíìmù yi je Eré to dara ju lati wo lori koko oro lako labo ni ile eko agba ti ile adulawo. E gbadun re ki e si di atunyewo yin mu. Fíìmù to dara ni. positive Eré tó tayọ Mo ṣẹ̀ wo Lara ati Beat lóri Netflix . Eré yii ya ni lẹ́nu. Ìtanná eré tí ó rẹwà, eré síse tí ó wà n bẹ́, ìtàn tí ó lágbára, orin tí ó dára ati ìdárayá tí ó pé tí gbogbo ẹbí máa gbádùn. positive Onítura Mo fẹ́ràn gbogbo nkan ní bẹ̀. Àsà, èdè àti orin naa rẹwà positive Eré náà láìsí àníàní fún wa níbí ǹkan ti rí ní ìgbà àwọn bàbáa wa, títí dé ibi ayẹyẹ ṣíṣẹ, ọ̀rọ̀lóríi bíbóra, àwọn aṣọ̀, àti bí wọ́n ti lo àwọn aṣọ àdìrẹ àti damask positive Eré tí ó ní ètò ní ó jẹ́, ó sì kún fún àwọn òṣeré tí wọ́n mọ iṣẹ wọn ṣe. Wọ́n gbé eré yí jáde pẹ̀lú ìmọ tó dánkiá nínú ètò ati ìdarí eré sinimá. Ìtàn inú eré, bó tí lẹ jẹ́ wípé kín ṣe pé ó dáa gán nà, sùgbón wọ́n gbìyànjú láti lè mú kí àwọn èèyàn jókòó tí eré náà. positive Sísìn ẹlẹ́kejì ejò ó! Mo wo “Fifty Series “ mo tún wo Castle & Castle torí ojú Tola faramí. Mo féràn eré oní pele sí ipele yìí, ma sí ní ìfé pé kí sísìn kejì jáde. Mí ò féràn pé ẹ́písòdù tó kù ló kù mí kù. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fúnmi ni sísìn ẹlẹ́kejì oo!! positive Sinimá yìí le o. Eré mọ̀lẹ́bí tó káni lára, pani lẹ́kún tí wọ́n rí ìtàn rẹ̀ kọ́ tí àwọn òșèré inú rẹ̀ sì rí ṣe. positive O fúyẹ́ o sí pa'ni l'ẹrin Ìdíyelé góòlù àwàdà pelu ìtàn tó dára. Lati ọ̀dọ̀ awọn arábìnrin dé orí awọn alátakò,o gbọdọ̀ wò. Ka na so ìdá pìlẹ̀ àlà aìròtẹ́lẹ̀ ati ipá pàtàkì! Mo gba yi. Níye kí ẹ wòó. positive Wọ́n farawọn wéwu ṣùgbọn ìgbéjáde eré náà dára. positive Àlàyé lè má jẹ́ ọ̀nà tó dára láti sàgbékalẹ̀ ìtàn, àmọ́ sá Desmond Idris sàgbékalẹ̀ ere yìí dáadáa bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ ìtàn àsọtúnsọ. positive Ó TU NI LÁRA! Gbogbo ǹkan tó wà nípa eré yìí ló dára! Ìtàn-àn eré náà, àwọn òṣèré, àti dídarí, títí dé àwọn ǹkan ìmúra. Mo gbádùn èyìí lọ́pọ̀! Gúgúrú mi tán-án ní ìséjú péréte! Mo fẹ́ràn rẹ̀ gaan! Ẹ jòwó, ẹ ṣe fíìmù síi. positive Eré àgbéléwò dìdára lórí jákèjádò- orílè-èdè Oun kan pàtó tí mi ò féràn nípa fíìmù yìí ni pé ko si ibásepò pẹlu ágbègbè orílè-èdè Nàìjíríà ati india bó ti wu ó kéré mọ. Eré àgbéléwò ìfé tó lárindin lè yìí positive Eré tó jọjú Mo fẹ́ràn láti máa wo ere yìí nítorí àkójọpọ̀ ìtàn rẹ̀, ìdárí àwòrán eré, dakore àti bí àwọn tó kó pa nínu eré náà se fakọyọ ninu ere síse. Wọ́n gbé àṣà ati ìṣẹ̀ṣe wa lárugẹ nínú eré náà. Ó yẹ́ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ ọ́síkà tí ó bá jẹ́ pé ti wa n ti wa ni. Láì sí àní àní, eré náà gba ẹ́ẹ̀wá lori ẹ́ẹ̀wá láti ọ̀dọ̀ mi. positive Eré orí ìtàgé dára jù. Nollywood tíì gòkè àgbà. positive Fíìmù tó wuyì Ìtàn tó dára tó bẹ̀rẹ̀ fún àkíyèsí púpò. Ní gbogbo rẹ̀ jùlo, Fíìmù náà kú iṣé takuntakun. positive Eré nlá làti ọwọ́ọ Nollywood Wọn ò kọ̀ kọ erée Lion Heart lásán. ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí on ṣẹlẹ̀ ní Nàíjírìa hán ni gbàgede ti o ma gba eni tí ó bá farabalẹ́ tí ósì ní ojú inú láti rii ninu eré naa. positive Eré yii jẹ́ eré tí ètò rẹ̀ dára jù lọ lára eré Nollywood. Ṣe ló jọ eré Afíríkà àti Amẹ́ríkà. Eré ṣíṣe inu rẹ̀ nẹgba, ótún wá yani lẹ́ nu torí pé eré àkọ́kọ́ tí òsèré asíwájú kọ́kọ́ kó pa ninu rẹ̀ ni. Mo júbà. positive Ǹkan bí eré apanilérìn-ín ti Shakespeare, ó kún fún àwọn òṣèré adérìínpani tó o dámúsé, o sì fúnnú ní ìwòye tí ó dájú sí bi gbígbé nínú ìlú tó fi fúni nídánimò àti Ìja àda àwọn àrè. positive Àwọn ọmọ orílẹ́-èdè Nàìjíríà ní Brooklyn Èyí jẹ́ fíìmù ìyàlẹ́nu , ìfura, ìronú jinlẹ̀, àti àwọ̀. positive Ise takuntakun ni Temi Otedola se positive Ẹ ṣeun fún àpẹrẹ́ tí ẹ ṣe nípa bí Ó ti ṣe ń ṣiṣé nínú ayé e wa. Eré yìí ṣí ni lórí, ó rán wa létí bí ó ti máa ń ṣiṣé nípasè ẹ àwọn tí kò jẹ́ pípé tí wọ́n sì ní ìrònúpìwàdà tí wọ́n jẹ́ àwọn tí a pè láti gbọ́rọ̀ síi lẹ́nu. Òun ló ń ṣèyókù. Yóò parí iṣé tí ó ti bèrè. Eré tí ó bu ọlá fún ọlórun, tí ó sì ń fi oore, ògo, àti agbára métalọ́kan hàn. Ẹ ṣé púpọ̀. positive Ìtàn náà rẹwà. Ìgbèrò eré náà dára púpọ̀. Ìrètí kíkún, àti ìfanimọ́ra. Ó fọwọ́ kan púpọ̀ lórí pàtàkì ìbánisọ̀rọ̀ nínú ìbásepọ̀. Màá tún Fíìmù náà wò ní orísirísi ìgbà. positive Mo nífẹ̀ẹ́ eré yìí mo sì ti wòó fún àìmọ̣ye ìgbà. Mo sì retí òmíràn n bọ láìpẹ́. positive Ọmọ Nigeria ìgbàlódé aláìlẹ́gbẹ́ Aájò oni sinima àgbéléwò ti Nollywood ni tòótọ́ ìwà òṣèlú, ẹṣin àti ẹ̀yà nigbonni yìí, fún àwọn tó bá fẹ́ fikún òye wọn nípa ìdí tí a fi ni àwọn òkè ńláńlá lagbaye. Nípa báyìí, àwọn ìletò kereje ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí farahàn lónìí. Ẹ̀mí ọkàn fara hàn nínú ojutaye nítorí orisirisi ìrírí, ìpín kan lára nǹkan wọ̀nyí ni sinima àgbéléwò yìí gbé síta. positive Ó dun láti wò pàá pàá tí ó bá ní òye èdè Igbo ṣùgbọ́n ní gbogbogbò,o jẹ fíìmù tí o dára positive Eré yìí dàbíi wípé ó jẹ àgbápọ̀ àwọn àbọ̀ odidi eré tí wọ́n tún fi eré ìfẹ́ sí. Kò jọ pé eré ẹ̀fẹ̀ lásán tàbí eré ẹ̀fẹ̀ àti sẹ ǹkan nínú ayé. positive Genevieve Nnaji tún fihàn lẹẹkan si wípé óun sì ni óṣèré Nollywood tí ó jáfáfá jùlọ pẹ̀lù ìtọ́sọ́nà eré alákọkọ. Ohun tí a ni la ti sọ nipé kí agbára naa kí ó ma pọ̀ si positive Fiimu tó ṣàfihàn ìrètí orílè-èdè kan fun àyípadà sinemá tó dára Ìrètí ni pé àwọn alágbè jáde eré tí ń ṣe tii Naijiria náà le fọwọ́ ṣò wọ́pọ̀ torí ọjọ́ ọ̀la tó dára fún ilé-isé ìgbé fiimu jáde ti ìlú Nàìjíríà. positive If̀ọ̀kànbalẹ̀! O fún mi ní igbéraga okan. Yàtọ̀ sí ìtàn, Isé òṣèré láti ọwọ́ àwọn òsèré jẹ́ ǹkan tó dára ó tún fa ọkàn mi mọ́ra. positive Mo ń wá ohùn orin àti àgbéyẹ̀wò Ohùn orin kan wà ní ìparí Fíìmù náà. Ní abẹ́lẹ̀, kò ní ọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohùn aládùn ni ó jẹ́. Mo ń gbìyànjú láti wá orúkọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, Fíìmù ńlá ni, ó fi àpẹ̀lẹ́ púpò tẹ̀síwájú. Ìṣọwọ́ṣeré rẹ̀ bòjúmu. Kò sí ìmọ̀sílára tàbí ohunkóhun bíirẹ̀ tí kò bòjúmu. Àwọn ìbánisọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí wọ́n yàn láti sọ, àwọn ìbádọ́gba, ìfanimọ́ra ní ọ̀tún àti òsì. Gbogbo wọn ló bá ìwà ẹ̀dá mu bí ẹni ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsìkò ìdákẹ́rọ́rọ́ àti ohun bíirẹ̀ wà. Nítorínâ, o ní láti fẹ́ràn irú Fíìmù yìí àbí kí o mâ fẹràn rẹ̀; kò sí wíwà ní àárín méjì. positive Àkókó nípò àwọn eré Nàìjíríà ti mo féràn jù. Mo ni ìfé eré náà, ó bọ́ si ọ́kan lára eré tó má ń tèmi lọ́rùn. Igbiyanju mi ni pé kí àwọn ará ìlú Nàìjíríà gbárúkùtì eré náà láti ri pé gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ re jáde láti wòó. positive Kémi àdetibà King Of Boys kọjá àdému ròyìn. Lat'ori yíyan àwọn òṣeré títí tó fí dé ṣíṣe ìtàn inú eré orí ìtàgé yìí. Eré orí ìtàgé yìí dára gan ní gbogbo ètò bí wọn ṣe ṣẹ o múná dóko. positive Pípé Kí enìkan jọ̀wọ́ bámi wá àbàwọ́n nínú ré yí nítorípé mo ti wò ó nígbà mérìn-in ati wipe emi ko ri abawon kankan ninu re. Gbogbo nkan nipa Eré na ni o pe. Ojulowo ni Eré na positive Ere yìí jé ìtàn tòótọ́ tí ó sì jẹ ìṣe ọpọlọ positive Eré Naijiria oní pele sí ipele to ní ìtura Eré ti Nàìjíríà tó fún ni itura tó ṣì dùn wò, tí kò sì sí àwọn orin buburu tí a kọ níbè. Mí ò féràn pé sísìn kan péré ní netiflesi gbé níbè. Kò dùn mo mi pé mí ò lè rí sísìn kejì. positive Tí ó bá jẹ́ oúnjẹ ni máa ní ó bu omi rẹ ẹnu Àgbọdọ̀ wò ni fíìmù 'citation' jẹ́, mi ò ri bí ohun tó le kù tà. Wọ́n fi ara balẹ̀ yan àwọn Òṣèré náà wón sì fi àmì ògbóǹtagì hàn, àwọn ibi tí wón lò dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mi ò sì mọ̀ pé àwọn ilé ìwé gíga tí ó dára wà ní Senegal, àwọn ọnà àwọn adarí wa ní Áfríkà gbé àmì ìdáni mọ̀ Áfríkà yọ. Ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú eré yìí, bí wón ṣe sọ ìtàn naa jẹ́ ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì, tí ó ní òye àti iṣẹ́ ọnà tí ó peléke. Ìdádúró náà wà ní ìpele mìíràn, ìdàpọ̀ ti àwọn ìkùnsínú tí ó dá sí àwa oluùwò jẹ́ ǹkan mìíràn. Citation jẹ́ ohun tí o gbọ̀dọ̀ wò lọ wòó lórí NETFLIX positive Fíìmù tó peregedé Fíìmù dára púpọ̀. Ìtàn tí kò rújú rárá tó sọ nípa àwọn ọmọ ọkùnrin méjì pẹ̀lú ìgbésí ayé tí wọ́n ti gbé sẹ́yìn tí àwọn ènìyàn kò mọ̀. Lẹ́yìn èyí ni àwọn kòtò àti gegele tó yí bí wọ́n ṣe padà ríra wọn nígbà tí wọ́n ti dàgbà. Ẹ kú ișẹ́. Èyí yàtọ̀ sí àwọn èyí tí mo ti ń wò tẹ́lẹ̀. positive Mó fẹ́ràn rẹ̀ erè ti o rẹwà... Mo fẹ́ràn àwọn ọmọ Naijiria mi. ìtàn erè naa dara. Ekú iṣẹ́. positive Ó lẹ́wa, ó lẹ́wa, ìbànújẹ́ àti ìṣe kókó. positive My Village People ni àwọn isé sinimá tó dára kan tí wọn kò sì ní àṣejù. Ara àwọn isé yìí ni òjò náà. Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ náà yẹ fún ìgbóríyìn fún iṣé takuntakun tí wọ́n ṣe. positive Ó dá lórí ìtàn, ó ń wúnilórí, ó ń kọ́ni lógbón, ó sì dára jọjọ. positive Eré Naijiria ti mo yàn fẹ́ niyi. Ó dára nípasẹ̀ àwọn ẹ̀yà tí ó ní. positive Mo máa ń gbóríyìn fún fíìmù tó fi okùn ìfẹ́ tó gbópọn sáàárín àwọn ọmọbìnrin méjì tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan so papọ̀ ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àti òṣèlú ló yà wọ́n sọ́tọ̀. Àwọn òṣèré tó kópa nínú eré yìí fakọyọ. Oníkálukú wọn ló kó ipa tirẹ̀ dáadáa. positive "Ere akọ́nilọ́gbọ́n, ṣùgbọ́n tí ó ń wọ inú akínyemí ara ènìyàn pẹlú ìrora. Àgbékalẹ̀ pẹlú ìmòye tí ó lágbára. Fíìmù ńlá tí wọ́n ṣe tí wọ́n sì darí pẹ̀lú ìmòye. Àgbékalẹ̀ rẹ̀ ń kọ́nilọ́gbọ́n sí ipele kan, ṣùgbọ́n ó kún fún ìrírí tí ó ń ki ni sínú ìrora.. Ó ń ṣàwarí ẹ̀yà àti ìṣesí àwọn ọmọ jàgídíjàgan, ní orílẹ-èdè England, ó ṣòro láti gba àwọn oun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀ gbọ́, ìmọ̀ wí pé Fíìmù náà dálórí oun tí ó ṣẹlẹ̀ lójú ayé tún bọ̀ sọ́ di òtítọ kíkorò. Bóyá awọn abala kan wà níbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ fún ìṣèré lásán, ṣùgbọ́n ó sì wà láti ohun tí ó dìídì ṣẹlẹ̀. Àwọn ibi kan wà nínú sinemá àgbéléwò tí màá kàn bèèrè pé: “Kílódé""? Báwo ló ṣe máa ṣe bẹ́yen? Rárááá!. Kò wà fún àwọn ọlọ́kàn yẹpẹrẹ, ó sì ń sẹni lọ́kàn básubàsu. Ó jẹ́ eré Fíìmù tí yóò fi ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú òpòlopò ìbéèrè. Ó ń dánilárayá ṣùgbọ́n áá fa àròjinlè àti ìdáhùn sí yọ. Iṣẹ́ ọnà. Ọkàn nínú àwọn ògidì ere tí mo ti wò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àfojúsùn tuntun tí ó tọ́nà láti wò." positive O jẹ fíìmù tí ì dára tí o sí ní anfààní nípa òrò ìfẹ, ìgbàgbọ, mọlẹbi ati ìdánwò ayé,ko pẹ ojú òṣùwọ̀n ṣugbọn mo gbádùn rẹ, mo nifẹ Mawuli Gavor má tún wo lati rí ní ẹ̀kàn si. positive Eré aladidun ti o ni awon isele itan Benin Kingdom ninu. Ére yìí kọ́nilékọ̀ọ́ púpọ̀, ó sì dùn-ùn ní wíwò. Ó sì yàmílẹ́nu wípé ọdún 2014 ni wọ́n ṣe é. Ìṣe eré náà àti dídarí rẹ̀ dára gaan gidi. Ìgbóríyìn fún àwọn tó kópa nínú síse eré náà. positive Àgbékalẹ̀ ńlá. Ìtàn tó mọ́pọlọ wá lárà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré tí wọ́n mọ iṣẹ́ wọn níṣẹ́. Ìmọ́lẹ̀ títán sí àtẹ̀yìnwá ọ̀rọ̀ pọ̀ lápọ̀jù dìẹ̀ ṣùgbọ́n ó wuni láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. positive Ojúlówó!!! Eré yii ní ìrírí ayé nínú ní àwọn apá kan! Àwọn èèyàn máa ń yá aṣọ ati ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ láti bù ga, wón a pa irọ̀ lójú méjèèjì láti le sọ wípé wọn jẹ́ nkan. Àwọn ènìyàn máa ń fi àṣìṣe wọn kẹ́kọ̀ọ́, wọn yóò sì ràn wọ́n lówó. Eré á panilérìn pẹ̀lú àwọn àwọn ẹ̀kọ́ tó dára bi pe gbogbo oun tó ń dán kó ni wúrà.! positive Ó yẹ kí á lu àwọn ènìyàn yìí lọ́gọ ẹnu fún ere yìí. Bí ṣíṣe ere náà tilẹ̀ lágbára síbẹ̀ síbẹ̀ wọ́n ṣe é. Ó yẹ kí a gbóríyìn fún èyí. Bákan náà, kì í ṣe eré àgbéléwò Nàìjíríà nìyí. Ere olólùfẹ́ apanilẹ́rìn-ín tó ní ogún òyìnbó aláwọ̀ funfun ni fíìmù yìí. positive DOMITÍLÀ! Sinimá tí ó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ni DOMITÍLÀ jẹ́ nínú ilé ișẹ́ sinimá àgbéléwò ní orílè èdè Nàìjíríà. positive Iyalenu! Oludari ati Olugbejade se ise takuntakun lori Eré yi. positive Eré ọlọ́gbọ́n Eré yìí jẹ́ irú eré tó ṣàfihàn ìbàjẹ́ tó wà nínú àwọn oun èmí tí ilẹ̀ áfríkà nípasẹ ìdọ̀tí àyíká àti agbègbè. Ó sì tún ṣàfihàn bí oun tí ara ṣe ṣe àkóbá fún oun témi ati bi oun témi náà ṣe ṣe àkóbá fún ohùn rara. Nítòótó, eré yii yẹ fún wíwo. positive Ó múnú ẹni dùn, eré tí ó dára. Mo gbóríyìn fún ẹ̀kọ́ nípa bí ìfé ṣe jé ǹkan gbogboogbò àti bí eré náà ṣe gbé iṣẹ́ olú òsèré náà yọ pèlú ìwà àti ẹwà rẹ ẹ̀. positive Nírọ̀rùn,o jẹ́ òun tó dára. kò jẹ òun ìyàlẹ́nu wípé Kẹ́mi Adétiba ló ṣe iṣẹ́ yìí. Gbogbo nkán nípa fíìmù na ni o pẹ ojú òṣùwọ̀n lára akẹgbẹ́ re ni Nollywood. Síbe sí,ayé wà fún ìtẹ̀síwájú. Ìwà àkọọlẹ jẹ́ oun ìpele gíga. Ṣùgbọ́n òun tí o tani lẹ́nu jùlọ ní bí wọ́n ṣe tunmọ ìtàn náà. positive Eré ńlá Nípa ṣíṣe eré, Eré yìí jẹ́ òkan lára eré tó dára jùlọ tí mo ti wò. Ó mú mi rántí àwọn eré ayé àtijọ́ tí ó dùn tí ó jẹ́ tòótó. Ìtàn eré náà dùn àti wípé ó jinlẹ̀. Eré ńlá. positive Isé n'lá lẹ sẹ. Isokan pàdé òun tuntun positive Ohun tí mo gbádùn nínú fíìmù yìí ni wípé ó rí ìtàn inú ìwé yẹn gé kúrú síbẹ̀ wọ́n rí gbogbo rẹ̀ ṣe. positive Mo gbádùn fíìmù yìí àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ni tí wón ń tẹpẹlẹ mọ́ ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n gidi ló kọ́ni. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bí títò ìtàn yẹn ṣe lọ àti gbogbo ǹkan ló bójúmu. positive Ìtàn tí a gbélẹ̀ ni ọ̀nà tó yàtọ̀ Eléyìí jẹ́ eré àgbéléwò to múná-dóko . Wo eré yìí pẹ̀lú inú kan. positive Ìyanu! ètò Netflix padá mú nkan tó dára positive Iṣẹ́ ìtàn tí ó ṣọ̀wọ́n tí ó ní ẹ̀kọ́, ó pani lẹ́ẹ̀rín, ó tọ́ ni lọ́kàn, ó nííṣe pẹ̀lú ìmọ̀lára. positive Eré náà lọ dáradára, ó sì ní àwọn ìpín kúkurú tí wọn gbé ẹ̀kọ́ náà jáde dáradára. positive Eré tí ó dára gan-an ni positive Sún sókè! Àwọn eré Nọ́líwuùdù náà tí ń wà ní ipò gíga tí ó yẹ kí wọ́n wà. Mo fẹ́ràn bí àwọn òșèré yẹn ṣe ṣe, bí ìtàn yẹn ṣe lọ, àwọn òșèré tí wón lò. Eré onífẹ̀ẹ́ apani lẹ́rìn-ín tiwantiwa tó dára ni. Ẹ kú ișẹ́ gbogbo yín. positive O labawọn sugbon mo gbádùn rẹ o sí tun se kókó. Eré yii farapẹ ọkan ninu awọn ìtàn tó bẹrẹ litireso Hausa nigba ikonileru nipasẹ adari orile-ede tẹlẹ rí Abubakar Tafawa Balewa. Wọn gbìyànjú ninu eré náà. Hausa je ede tó tóbi jù lọ ní gúúsù áfríkà. Ti o ba fẹ lati wo ere ni ede Hausa, ma ro ọ lati wo eleyii. Nigbati mo wo ere yii ni òkè òkun pẹlu ọrẹ mi, a wo itakuroso to Gun ni ibẹrẹ ti o sí ní akọle kékeré. Ọrẹ mi bere pe kini won sọ, mo sì saleyi fún. Eré yii jẹ eré tó dáa ti o sí yẹ fún wíwo. positive Fíìmù tó wuyì àti ìfẹ́ Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ikọ̀ àti bí wọ́n ṣe ṣii. Gan dun ati ki o farabale movie. Ronu Love Jones. positive òṣèré náà ní ìgboyà o sì fihàn pé o dáa lójú bóṣeyẹ. Ṣùgbón omidan adétiba mọ bóṣeyẹ kó darí eré náà. Mo gbóríyìn fún-un. Mo sì fi ọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà fún gbogbo àwọn tí mo mọ̀ positive Iṣẹ́ ìyàlẹ́nu. Nítòótó, mo bẹ̀rẹ̀ síí wo fíìmù náà láì nírètí púpọ̀ nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnu yà mí sádùn. Àwọn abala eré náà kan wà tí mi ò tíì bọ́ nínú rẹ̀. Àgbékalẹ̀ iṣẹ́ tí ó rẹwà, ọ̀kan lára àwọn eré tó fakọyọ. Mo máa tún wòó dájúdájú. positive Ìtàn tí kò le ṣùgbọ́n tí wọ́n gbe kalẹ̀ dáadáa. Máà gba àwọn ènìyàn nímọ̀ràn láti wòó. Ó dára gidigidi, ó sì yẹ láti wò. positive Eré àgbéléwò dìdára lórí jákèjádò- orílè-èdè Oun kan pàtó tí mi ò féràn nípa fíìmù yìí ni pé ko si ibásepò pẹlu ágbègbè orílè-èdè Nàìjíríà ati india bó ti wu ó kéré mọ. Eré àgbéléwò ìfé tó lárindin lè yìí positive Ìyàlẹ́nu oun ìrusókè láì fi ìgbà kan bòkan nínú, Nnaji nítòtó ní ọjọ́ iwájú tó dára nídi isé adaŕi eré. positive Àgbọ̣dọ̀ wò Eré tó dára. Seye ní àwọn iwa tí ó jẹ́ pẹ́ gbogbo obìnrin ni yóò fẹ́ ẹ…Tí ó bà sí fé wo ǹkan pẹ̀lú ti obìnrin, màá gbà ọ́ níyànjú kí o wo èleyí. Eré tó bójúmu fún èèyàn láti wò pẹ̀lú ẹbí ni. positive Gbogbo oun tí mó lè sọ ní wípé Eré yìí ni mo dìbò fún ní ọdún yìí positive Fíìmù yìí ni àdó olóró náà. positive Fíìmù tó dára yàtọ̀ Sinimá yí ṣe àfihàn gbogbo àwọn ìṣòro tí àwọn ọmọ ayé òde òní ni ilẹ̀ Nàìjíríà ń kojú kò kàn fi ọwọ́ ba ohun kankan lérèfé. Yóò mú inú bí ọ làwọn ibì kọ̀ọ̀kan. Yóò ru ọ nínú sókè ní èyí tí mo rò pé ìdí tí wọ́n fi ṣe é náà nìyẹn. Láti jẹ́ kí àwọn tí ó wò ó gbé ìgbésí ayé àwọn òșèré tó kópa nínú rẹ̀. Inú mi dùn pé ìtàn yìí di sísọ. positive Eré yìí pani lẹ́rìn-ín gidi lọ́nà kọnà ni o. Fíìmù tí ó tíì pani lẹ́rìn-ín jù nínú ọdún yìí tí mo ti ṣe alábàápàdé lèyí. Bí àwọn òșèré tí ṣe, bí wọ́n ti ya sinimá yẹn àti bí wọ́n ṣe dárí rẹ̀ ló ṣe rẹ́gí Ó yà mí lẹ́nu gan-an. positive Ise Òṣeré tí ó pè dé gé tí ó sì ní ìmọ̀lára gidigidi. Ìtàn na lágbára. positive Fíìmù Arie ati Chuko Esiri yénii nípa àfojúsí àtúnṣe sí àwọn ìdíwó tó wà láti ṣe àṣeyọrí. positive ọkàn lára sinima àgbéléwò Nollywood tí ó dára jù. Mo gbádùn sinima àgbéléwò náà púpọ̀, mo ti wá mọ ìdí tí a fi tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí sinima àgbéléwò Nollywood tó lamilaaka jùlọ. positive Eré yìí jẹ́ eré òṣèlú tó dára jùlọ ní ilé adúláwọ̀ Ẹ jẹ́ kín bẹrẹ́ láti ṣe òṣùbà fún àwọn òṣèré tuntun ti won fi owo si aseyori Eré oselu yi positive Ó dàbíi fíìmù gidi. Ó nílò aáyan ògbufọ̀ láti lè jẹ́ kí ohun tí ìtàn yí ń sọ yé’ni yékéyéké ṣùgbọ́n àwọn òșèré yẹn ṣe dáadáa ní. Oríyìn fún ìhà Nàìjíríà tí wọn kò fi hàn rí. positive Èyí dùn wò. Mo gbádùn fíìmù yìí. Mo fẹ́ràn ọ̀nà ìrònú olùkọ̀tàn àti àwọn àwòrán tí ó dára tí wọ́n lò. Mo mọ rírì pé kì í ṣe fíìmù Nọ́líwuùdù kan lásán. positive Fíìmù tó dára fún ìgbà ìsínmí O pa ni l'ẹrin pẹ̀lú àwàdà ti o ṣe gbádùn. Òṣèré ti o dára positive Fíìmù tó fi ìmọ̀sílára hàn lákoláko, àwọ̀ tí wọ́n dúró déédé àti àwọn ohun tí wọ́n sojúringindin, tí wọ́n ń gbé ipò ìmọ̀sílára àwọn òṣèré nígbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò ìsọkùnrin-ṣobìnrin ènìyàn nípasẹ̀ ìrírí Adéniìkẹ́. positive Eré yìí jẹ́ ìyàlẹ́nu tí ó dùn gidigidi. Àwọn eré tó dálẹ́ ìtàn ìgbésí ayé ènìyàn má n dún gidigidi positive Fíìmù tó dára gidigidi! Láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni ẹ̀rín àti ẹkún wà.Ó ṣe àfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run àti agbára nínú nígbà ìkorò àti ìgbà ìkẹhìn. Òsùbà fún àwon òṣèré àti Olùgbéjáde fún Fíìmù tó le yí,ìróra,ìyà, ìfé àti ìṣégun níno Fíìmù náà. positive O ye awon adulawo to wa ni oke okun daradara. O so nipa iririi mi gege bi adulawo ti ko gbe nile adulawo ti o si n gbiyanju lati wa ibugbe miiran. positive Sinimá tí ó dára ní. Ó pe ni sí ìrònú. Kò yẹ kí ó sí ìdẹ́yẹ sí ọmọ ènìyàn nítorí àwọ̀ wọn. positive Mo féràn rẹ̀!!! Gbogbo Eré tí ó bá ti ọwọ́o Kúnlé Afoláyan jáde máa ńjẹ́ Eré tí a le fi ọkàn bálo. Ìtàn náà,ṣiṣẹ́ Eré to dara, awon òṣèré gidi je awon nkan ti a ri. Eré Itokasi ni itan gidi pelu idite daadaa ati nkan ti o n soro nkan ti o n sele ninu aye wa. Mo le so wipe, Fíìmù to yani lenu lati wo. positive Òkan lára àwọn Eré ilẹ̀ adúláwọ̀. Mo gbadun Eré na. O ye mi idi ti won won fi n pe ni Eré ile adulawo to laamilaaka. positive Ódara lóòótọ́ Ó ní gbogbo nkan. Binge ti wo gbogbo sísìn eré na. Ó kún fún àwọn òshèré tó mọ ìṣe, ó sì tùn fi ìmò òfin han àwọn olùwòran. Ó kún fún ẹ̀kọ́ pípé, ìfura, ẹ̀rín àti àwọn gbajúgbajà òsèré. Kí ni mò tú ń wá, eléyi tayọ. positive Irú eré tí ó wuni wò ni èyí? Gẹ́gẹ́ bíi fífi ìfẹ hàn àti ìtàn, ní ìdàkejì, ó panilẹ́rìn-ínó sì wà pẹ̀lú àjálù, ó kún fún ìfojúsọ́nà àti ayẹyẹ ṣíṣe, kò sì ṣàìdánilárayá lákọ lákọ. positive Mo rò wípé eré náà dára. Àmó ìkòrí eré náà lágbára. Mo gbé òsùbà fún àwọn olùfokànsín lọ́kùnrin and lóbìnrin ilé èkó. positive Ọ̀gbìn jẹ́ fíìmù tí ó tayọ ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi ò ó gba wíwò líle Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn fíìmù tí ó dára jù lọ tí mo ti rí ní ọdún yìí. Èmi kò mọ ìdí tí ìwọ̀n rẹ̀ fi burú jáì. Fíìmù yìí dára púpọ̀ ju díẹ̀ nínú àwọn fíìmù tí ó ti gba Oscars pẹ̀lú Moonlight. Ọ̀gbìn jẹ́ fíìmù tí ó le púpọ̀ láti wò. Gbogbo ìpele ló tọ́ ni lọ́kàn... Líle tó láti bóyá mú ẹ sunkún ní ìrora, ìbínú tàbí ọ̀kan tí ó dára àtijọ́ itele ìbànújẹ́. Ńkọ́ lè dá ègún gégé dúró! positive Torí Ọlọ́run báwo ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ń wo eré yii. Gbogbo ara mí wà nínú eré yìí. Mo féràn gbogbo ẹ̀fẹ̀ ẹ. Stella ará bìnrin nìyẹn… òṣèré obìnrin tó jágeree. positive sinemá àgbéléwò tí ó dára, tí àgbéyẹ̀wò rẹ̀ kò sí bàjẹ́ rárá. positive Eléyìí lágbára. Màá fẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn àkọlé yìí wo ere yìí, tàbí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn fíìmù gidi. positive Eré tí o jáfáfá Mo gbádùn ẹ ni gbogbo ìgbà tí mo fi n woo! ìtàn ti o dára. positive Ọlọ́run ti pè mí ....... Bí òun ti jẹ́ ẹlẹ́rìí mi, mo ní ìdarí láti wo sinimá ńlá yìí lánàá. Pàápàá bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń wá fíìmù kan tí yóò sí ọkàn mi sí ibòmíràn, a fi agbára mú mi láti wo fíìmù aláìlégbẹ́ tí wọ́n fi ọ̀nà àrà ṣe ní àná. O bọ́ sí ilà ní pípé pẹ̀lú wíwá ti ara ẹni ti ẹ̀mí tí mo ti wà láìpẹ́. Ní àkókò tí mo wòó , ìdáhùn lẹ́hìn ìdáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbéèrè wá sí mi. Mo sì wádìí nínú ìyàlẹ́nu . Wo èyí, jọ̀wọ́ , pẹ̀lú ọkàn tí ó ṣí. positive Fíìmù tí a pilẹ̀ ṣe ni Áfíríkà lórí àwọn ará Áfíríkà ni. Ìyàtọ̀ tí ó dára. Ó tú ni lára láti wo fíìmù tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Áfíríkà tí ó sì dá lórí àwọn ènìyàn Áfíríkà ti òde òní yàtọ̀ fún ògbójú ọdẹ òyìnbó àti ìgbà ìmúnisìn positive Eré sise àti ètò tó yanilẹ́nu Ohun ti o dára jù tí ó ti Nollywood jáde wá. Mo fẹ́ràn eré ṣíṣe àti ìtàn naa. positive Eré tó dára jù positive Eré onípele tó tayo Eré yìí mú mi mólè fún ogún ìṣẹ́jú àkókó! Gbogbo ń kan ní mo fi ní ìfé eré yii láti ìbèrè dé dópin. Pàápàá àwọn atọ́ka lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tí àwọn ènìyàn fí nílò àwọn adájó. Àti pé ẹ̀rín ò dúró láti ìbèrè títí dópin eré yìí. Mí ò tí lè féràn pé sísìn 1 parí. positive Ìran keèje ṣàfihàn ìtàn àwọn ènìyàn Áfríkà ti o sí tuń sọ nìpa àwọn akọni tí ó ti kọjá tí wón sì kópa nínú gbígba òmìnira fún Nàìjíríà. positive Oríì mí wú pẹ̀lú ìtàn inú eré yi ati ìgbéjáde rẹ̀ positive Mo wo eré Lionheart ní ọjọ́ kẹẹrìn-in lé ní ogún,oṣù kejìlá, mo tún padà lọ wò ó ní ọjọ́ kòkan lé ní ọgbọ̀n oṣù kejìlá, Bẹ́ẹ̀ni,o dáára tó bèe! Gbogbo ènìyàn pàtéwọ́ fún eré náà. positive Ìyanu ayọ̀ rere. Ìșọwọ́ ṣeré tó yáyì ! positive À gbọdọ̀ wò ni. Fíìmù ère ìfẹ́ tó fani mọ́ra ni. positive Ko sí ipele kan nínu eré orí ìtàgé tíì àwọn olùwo eré yìí kò b'áwọn lọ. Fún ẹni ti kò bá mọ ju èdè gẹ̀ẹ́sì lọ, e wo eré yìí, eré orí ìtàgé tí ẹ máa wò lẹ́ẹ̀kansi ni. positive Ó ju oun tí a lérò lọ. positive Eréym yìí jẹ́ àwòrán dídára tí ó sá fihàn iwọntún-wọnsì láàrin ayo àti ìbànújẹ́ nígbà ìjà ogún abẹlẹ ni Nàìjíríà. Mo feran rẹ mọ sì tún ro awon eniyan lati wo. positive olè ròpé ẹ̀yí lè jẹ́ ibi gíga eré nollywood ní ọ̀nà púpọ́ sùgbón gégé bí alákóbẹ̀rẹ̀ olùwòran síbẹ̀ asì gbádùn ẹ̀. ófi hàn nínú rè gbobo rògbòdìhàn àti bí eré nollywood se gùn sí pẹ̀lú ìtàn tuntun tí wọ́n tẹ̀lé àti ìwà orílèdé àsà òsèlù Nigeria positive igbó dídí, tólójúpọ̀ pèlú okùn iná tí ò lópin- amú èkó wá sí ayé positive Living in Bondage jé ìb̀ẹ̣̀rẹ̀ eré ilẹ̀ adúláwọ̀. Mo jáde pèlu ìgbàgbọ́ tí o le pèlú ìgbàgbọ́ nínú orílè èdè nàìjíríà. positive Fíìmù tí ó dára ni. Gbogbo ọ̀nà ni ó fi dáni lára yá. Ișẹ́ lẹ ṣe. positive O mu ní mólè Zainab ṣe dára dára gẹ́gẹ́ be Sylvia. O je kí ń ma pe òùngbẹ eré yìí si. Nínú gbogbo ká lọ ká bọ̀ ṣe ni mo le jù mọ ẹ̀rọ àgbéléwò yii. Níse ni mo ranjú mọ́ ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán mi mo sì ríi pé ọkàn mí fà sí Sylvia. Ìfanimọ́ra rẹ̀ pọ́ọ̀ jù, ṣùgbọ́n eré síse rè tayo jù béè lọ. positive Iṣẹ́ tó kún fún ìgbádùn nípa ìmọ̀lára Tí ó bá jẹ́ ẹni tí ó ṣí ọkàn payá, àìní ìrètí ìfẹ́, ó dájú pé wàá gbádùn wíwò fíìmù yìí. Mo rò pé àwọn òṣèré aṣáájú ní kemistri ńlá àwon òṣèré tó kù ṣe àwọn ipa wọn dáradára. Ó jẹ́ ohun tí ó dun ni nínú láti rí ìkọlù àwọn àṣà àti bí wọ́n ṣe yanjú rẹ̀ ní àlàáfíà nikẹhin. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrín tàkìtì, eré àti àwọn àkókò a ìfọkànbalẹ̀ wà láti pé ọkàn rẹ. Dájúdájú ó wà nínú àwọn eré tí mo yàn fẹ́. positive "“ Narradores de jave"" Jẹ́ eré tó ń pánilérìn pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ pérétè tí a tì léyìn pelu àwòrán gidi , ìpele sí ìpele tó dára tó sì kún fún àwọn òṣèré lókùrin ati lóbìnrin." positive Mo maa sọpé: Ó tó bẹ, ó ju be lo! Eré àgbéléwò náà dára ,ó kún fún àwọn òshèré tó mọ isé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó n fáà lẹ́kọ̀ọ̀kan (bíi wákàtí méjì lápapò) . Lọ́kàn mi eeré náà tó bẹ́ẹ̀ . Eré àgbéléwò yìí kò sí lára àwọn fíìmù tó dára jù, tí ó yẹ kí ènìyàn wò ni àsìkò kòrónà yìí…… Àmọ́ mo fẹ́ràn rẹẹ̀. positive Mo mọ rírì ère yìí kódà jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo mọ rírì dókítà àti nọ́ọ́sì àgbáyé fún iṣẹ́ ribiribi wọn àti fífi ẹ̀mí wọn wé wu láti gba ti wa là. positive Lara ati beat ni ojúlówó eré tí n tọ́jú adùn ẹ̀rín àti ìfẹ́. Mo nírètí wípé ó ma di eré tí a maa ma wò ní inu gbogbo amóhùnmáwòrán káàkiri, tí yòó si gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwúrí tí ó yẹ. Àwò tún wó ni. positive Eré tó tayo láti orílẹ̀ ède nàíjíríà Inú mi dùn gidi láti bá a pàdé. Mo gbádùn eré yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mò ń retí apá kejì. positive """Chief Daddy "" jẹ́ ọ̀kan lára àwon eré tí o le wò kí o tún wò. Àwon òsèré inú rẹ fakọyọ àti wípé eré na je akójopọ̀ ìtàn ti kò gbomínínú pẹ̀lú awon àkókò ẹkọ ti o ni ìtumọ̀. bótilẹ̀jẹ́ àkójọpọ̀ eré naa ní àwon àbùkùn ti o yẹ ki wọ̀n gbìyànjù lati tun se,sùgbón ju gbogbo ẹ lọ mo ma sọ nípa rẹ̀." positive Ojúlówó ere tí kò dára rárá nìyí. Ìtàn yìí ní àbùdá tó dára. Lóòótọ́ mo fẹ́ràn ere yìí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ó olólùfẹ́ sinimá ilẹ̀ òkèèrè, ère yìí dàbí èyí tí a dàkọ. positive Ó dára gan-an ni, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo abala ere náà ló gbádùn. positive Wọ́n daríirẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́ ó rẹwà. Nollywood ń dàgbà sókè🔥 dáadáa. Ìtumọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tòótọ́, pẹ̀lú ìlọsókè-sódò tí ó ń pè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrònú. positive Ó jẹ́ déédéé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ó dààmú ọkàn ṣùgbọ́n ó ní ìkópa tó yani lẹ́nu. Mo dàgbà ní àsìkò yìí àti ní ìbànújẹ́ pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn tí a gbé jáde nínú fíìmù yìí. Mo ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí ó ní ìrírí “ọ̀gbìn” àti pé àwọn àbájáde rẹ̀ wà nínú ìgbésí ayé rẹ̀ àti ẹbí rẹ̀ lónìí. Fíìmù náà jẹ́ ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n ó ṣe déédéé díẹ̀ nínú àwọn ìfihàn ti àkókò ní UK. Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi ní ìfihàn ìkẹhìn nípa ẹni tí Enitan jẹ́ ni lójú ayé, èyí tí ó dájú bí a ti ṣàlàyé tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ olùyẹ́wò mìíràn tí mú ìlọsíwájú ẹ̀dùn pọ̀ si. Ó tayọ, ṣùgbọ́n ó ba ni nínú jẹ́, ṣùgbọ́n ó tọ́ láti wò bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ fún ti ìtàn tó ní. positive Ìtàn gidi lórí ifeniyan ṣòwò. Bí ó ṣe rí gan-an ni a ṣe sọ ọ. A dúpẹ́. Kí nìdí tí sinima àgbéléwò yìí ṣe gba ipò karùn-ún lórí osunwon? Mẹ́wàá lórí mẹ́wàá ló jẹ́. Èyí dára púpọ̀. Regi ni Oluture sáà ṣe. Ó lágbára! Ó níyì. positive Àwọn ìtàn rẹ̀ tó fọ́nká padà ní ipa tó jinlẹ̀. positive Fíìmù ńlá. Mo Gbádùn gbogbo àkókò tí mo fi wo eré náà. ìtàn tí ọ ládùn ní àti pé mo gbóríyìn fún gbogbo àwọn òṣèré àti àwọn àtùkọ̀ tí ọ lọwọ sí King of boys, ẹ ṣe fún eré orí ìtàgé yìí. positive Ó ní pé, ó ní pé positive Ó ga jù Fíìmù ‘Citation’ jẹ́ àlọ̀pọ̀ ișẹ́ ọpọlọ àti àwọn òșèré tí ó ní ẹ̀bùn púpọ̀. positive Gbogbo àwọn òṣèré inú eré yìí ni wọ́n ṣe isẹ́ takuntakun. positive Ó pé Fímù yìí ń sọ̀rọ̀ nípa Nàìjíríà àti àwọn olóṣèlú tàbí àwọn olè ń ṣèlú bí mo ṣe ń pè wọ́n. Tí gbogbo wọ́n jẹ́ aláwàdà àti apanilẹ́rìín ní agbègbè ìgbésí ayé tí ó yàtọ̀ tí wọ́n pinnu láti lọ sínú ìṣèlú láti fi ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ṣeré bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe eré fún yín lórí ìpolongo tí Wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n yàn wọ́n fún . Mo gbọ́wọ́ sókè sí àwọn olùṣe, àwọn òṣèré lọ́'kùnrin àti ló' bìnrin , olùdarí àti àwọn iyokù òṣìṣẹ́, fíìmù tó dára ní ìsúná pàápàá nígbà tí a bá fi wé nollywood. Ohun gbogbo dára ṣùgbọ́n a ò bá nífẹ̀ẹ́ tí fíìmù náà bá parí ní ọ̀naà tí ó yẹ kí ó jẹ́ kìí ṣe ní ìfura tàbí apá kan mìíràn tàbí a àtẹ̀lé láti gbé jáde nígbà míì. Fíìmù rere pàápàá tí o bá jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹgbẹ́ tàbí ojú ṣàájú láti ọ̀dọ̀ àwọn aládarí. Ó kàn fihàn ọ́ pé àwọn ènìyàn tí a yàn gẹ́gẹ́bí aṣáájú ní orílẹ̀-èdè yí jẹ́ àwọn aláwàdà tí kò ní ìmọ̀ lórí bí a ṣe le ṣe ìjọba orílẹ̀-èdè. Ní ẹ̀kan si mo gbọ́wọ́ sókè sí gbogbo yín. positive Mọ gbádùn wíwọ fíìmù náà. Ìgbà àkọkọ tí mo rí kí Nollywood ṣe nkán tí o le díje ní àgbáyé positive Eré tó tayọ Eré yii je eré tí ó tayọ lati ọwọ́o nollywood. Ìyà lénu ló jẹ́ fún mi bí ìpele dídára eré yii ṣe jẹ́. Sinimá Naijiria n ga si nítootọ́. Isẹ́ tó dára, a ní lò àtẹ̀lé rẹ. positive Atayán yán eléyìí ṣò wọ́n , ṣùgbọ́n bí ati ríi nínú eré àgbéléwò aládùn tí a ṣètò dáradára tí ó si fani móra yìí, àṣà ati ìṣe àwọn ènìyàn ti a korira yii sèfárahàn ti o ye . positive Ìtàn kò le dára jù báyìí lọ! Ó dàbíi tòọ́tọ́ púpọ̀. Ó fi ìtàn àti ìgbésí ayé àwọn òdókùnrin Nàìjíríà tí ó ń gbé ní Èkó. positive Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe irú fíìmù tí mo fẹ́ràn, àwọn òṣèré tí mo fẹ́ràn ló ṣe é. positive Ìtura, ọ̀tun, eré ìtàn ìfẹ́. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwon eré ìfẹ́ tó dára. Ó pani lẹrin, eré tí won ṣe dáradára tí mo ti mọ̀ rí fún ọjọ́ pípẹ́ re. Mo fẹ́ran àwon òṣèré arewà dúdú ati wípé ó jọ eré ìfẹ́ Indianí. positive Eré náà je atinuda pẹlu ìyàwòrán ti ko ni idiwọ ti o sí n sọ èdè eré olominira, mo ri bi tètè ni òye àwọn apá ìtàn ti mi o mọ tẹlẹ. positive Eré gidi tí màá fẹ́ láti rí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ ni eré yìí jẹ́. positive Ìṣeré tó péye Ẹ kú ișẹ́! Àwọn òșèré yẹn gbìyànjú gidi gan-an ni o pàápàá, eni tí ó kópa bíi ìyá àti ọkùnrin tòun tobìrìn tó léwájú. Dájúdájú, máà wo àwọn ìtàn eré tó bá fara pẹ́ irú èyí. positive Mo gbádùn láti wò fíìmù náà, ìgbà àkọ́kọ́ tí màá rí kí Nollywood ṣe ǹkan tí ó le díje ní àgbáyé. positive Jumbled' jẹ fíìmù tí o dùn tó sì pa'ni l'ẹrin. O ò kórìra àwọn òṣeré fún ìgbà díẹ̀ o sí tún fẹràn wọn díẹ̀ si. 'Jumbled'jẹ fíìmù pàtàkì tí awọn ọmọ Nigeria má n fẹràn. Fíìmù tí o dára gidigan, kò pẹ́ ṣùgbọ́n o dára bákanáà positive Mo gbádùn eré náà. Eré tí ó dára tí ó sì ní ìparí tí ó dára yàtọ̀. positive Nollywood náà ti ń gbòrò síi ṣùgbọ́n ó lè ní rògbòdìyàn díẹ̀ àmọ́ ọmọbìnrin náà gbà ìjọba taló ṣe ìjọba pẹ̀lú fífi ojú fani mọ́ra. Agbára pọ̀. positive Eré yii a fún ẹ ló yẹ Gégé bi ọmọ bibi ilé ea Naijiria, mo mòn pe ẹ̀yà mẹ́ta gbòógì lani: Haúsá, igbo àti Yorùbá. Sí bẹ̀ o le gbó nípa Haúsá ní bi Amẹ́ríkà, wón ri àwọn Haúsá gẹ́gẹ́ bi àwọn tálákà tí ò kàwé lórílẹ̀ – èdè. Ṣà dédé ni wa fi ri won nínú eré to rí nà gbogbo àgbáyé kò mò wón. Mo lé rò pé won yóò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ fiimu bí èyí. Awọn ènìyàn ni láti mo nípa àwọn Haúsá dáradára. positive Mo fẹràn fíìmù yìí, iṣẹ́ eso aṣọ, aṣọ kagba ati orin wà ní ìbámu. Èkó dára loju,iṣẹ náà ṣé gba gbàgbọ́. Mo sì gbádùn àwàdà aìròtẹ́lẹ̀ bíi,lọ wò fún rà rẹ̀ positive Apá kejì dà!!! Mo wo apá Kínní jù. Ó dára gan-an. positive Wọ́n kọ dáradára, ìdarí rẹ̀ dáradára, wíwò rẹ̀ dára, àwọn òṣèrè tó gbámúsé àti ìtàn aládùn. positive Wọn kò buyì kun tó. Àwọn òṣèré dáradára. Ipa ìtàn dáradára. Ó rí gẹ́gẹ́ bí àwọn nkan ṣe rí ní Ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. positive Àwòrán Ìyàlẹ́nu Ní àpapọ̀ mo nífẹ̀ẹ́ fíìmù náà ní kíkún àti nírètí pé àwọn olùdarí àti àwọn olùpilẹ̀ṣẹ̀ sii tí wọ́n le pèsè kíká àwọn fíìmù nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn. positive Gbogbo ọ̀nà ni mo gbà fẹ́ràn rẹ̀. Fíìmù ìgbafẹ́, tó gbé oge jáde tó sì tún kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni!!! Àwọn tí ó kọ ọ́ àti àwọn tí wọ́n darí rẹ̀ mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Ṣe ló ń ṣe mí bíi kí ó má tán mọ́. Mo ti wàá gba ti àwọn òșèré yìí lọ kùnrin àti lóbìnrin o. Ẹ jọ̀wọ́, ṣé mo rí ìkan síi? positive Eré tí wọ́n kọ dáradára tí wọ́n ṣè dáradára pẹ̀lú Eré yìí ṣiṣẹ́ gidi lóri àìjẹ́ olótìtọ́ nínú ìgbéyàwó. Ìtàn eré náà dára púpọ ti o pe àkíyèsí mi láti ìbẹ̀rẹ̀ eré náà. Eré náà ju bí mo ti rò lọ nípa iṣ̣ẹ́ takuntakun pẹ̀lu ọ̀nà ọlọ́gbọ́n tí wọ́n gbà ṣeré náà tí ó sí jẹ́kí o yẹ fún wíwò. Ìparí eré náà dára púpọ o sí kọ́ni lẹ́kọ̀ó. Ní ọ̀nà mííràn, àwọn eré Nollywood ní lásìkò yìí dùn mó mi gidi. Àwọn ìtàn àti akọle eré náà jẹ́ ìlọsíwájú fún eré àwọn èèyàn dúdú nítorípé wọ́n ṣe bẹbẹ ju ti tẹ́lẹ lọ nípa fí fojú sí ìgbéayé ojojúmọ́ ju kí wọ́n má polówó ǹkan tí kò kún ojú òsùnwọ̀n. Ó dára gidigidi. positive ... òní àwọn ìran mọ́nıgbàgbé, ṣùgbọ́n ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ kùdìẹ̀ kùdìẹ̀ tí kò fi ìdarí tó bá òde òní mú hàn. positive Fíìmù tó peregedé Láti àwọn òșèré inú rẹ̀ dórí ìtàn eré yìí, ó dára gan-an ni. Gbogbo rẹ̀ ló bára wọn mu ní șíșẹ̀ n tẹ̀lé. Kò sí bíi ọkàn yín kò ṣe ní gbé sókè sódò. Eré yìí dára gan-an ni o. Kò sí iye tí ènìyàn ná sí orí rẹ̀ tí kò tó bẹ́ẹ̀. positive Àwọn eré ìfẹ́ tí ó wà láàrín-ín Éfà Ìwàrà àti Bísọ́lá Ayéọlá wuni púpọ̀, àtipé nígbàtí Éfà gbé àwọ̀ ti ẹ̀fẹ̀ wọ̀ ó pani lẹ́ẹ̀rín ní tòótọ́. positive Eré tó dára ní, ẹ wòó positive Eré Naijiria to dára jùlọ Lionheart ṣiṣẹ̀ bi eré oniṣe àti àwàdà láì gbìyànjú. Àwàdà n ṣàn ó sì fi àsà àti ìṣe Naijiria hàn ni ọ̀nà tí ó lẹ́wà. Àwòrán naa si dara Kú iṣẹ́ Genevieve Nnaji, o sé ti oò dójú ti wa. positive Iṣé àtinúdá tí ó gba ìgbóríyìn tó kéré jù nínú ìtàn ẹ̀dá positive Eré náà sọ nípa ìgbésẹ̀ ìsọtẹ́ ológun ni ọdún 1976 ni ílẹ̀ Naijiria. Eré tó dára. Kò sì ayé fún yinyín ìbọn sugbon eré tó dára ní. positive Ìtèsíwájú ńlá ni fún Nollywood Mo gbádùn eré yìí gán láì sí ìjiyàn rárá bí wọ́n ṣe to eré yìí mú kí ó dáa yàtọ̀ l'áàrín-in àwọn eré ìyókù!. positive Eré tó dára sùgbón ko ní ìparí tó dára. Ere yìí dùn títí tí ó fi dé ìṣẹ́jú ogún tí yóò fi parí. Eré náà dára títí di ìgbà tí wọ́n fi fi àṣejù síi, èyí ni kòsì jẹ kí eré náà parí dáradára positive À gbọ́dọ̀ wò Ère náà yani lẹ́nu, ó jẹ́ a gbọ́dọ̀ wò. Tí o bá fẹ́ lo àkókò rẹ kíákíá wo èyí. Mo nífẹ̀ẹ́ abala òní takisí, òun ló wù mí jù. positive Ibi tí wọ́n ti ya eré yìí jẹ mọ́ ibi tí ó bá eré náà mu, èyí tí ó fún wa ní ìwòrán tó dára jù, ó gbé wá lọ kúrò ní ibi tí ǹkan ti rọrùn dé ibi tí àwọn èyàn ti ń ṣiṣẹ́ gbowó kí wọ́n tó lè jẹ. positive Ìgbà ọ̀tun ní ilé ișẹ́ fíìmù Nàìjíríà. Eléyìí yàtọ̀ sí àwọn sinimá gbàrọgbùdù Nọ́líwuùdù. Ó dání lára yá gidi gan-an ni tí o kò sì ní fẹ́ dìde lórí ìjókòó rẹ fún gbogbo ìgbà tí sinimá yìí bá ń lọ lọ́wọ́. positive Èsì isé na je ki àsà ati ìṣe parapò lati gbé àsà ati ìṣe won jade lọ́nà to dara. positive Mo bẹ̀rẹ̀ fíìmù náà ní ìrètí pé yóò jẹ́ èyí tí kò gbéwọ̀n bí ó ti jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn fíìmù tí mo ti rí láti apá kan yẹn ní àgbáyé. Ṣùgbọ́n bí fíìmù náà tí ń lọ síwájú, mo rii pé kò jìyà nínú àwọn iye ìgbé sini á jáde rárá; ní pàtó, ó peléke ní àwọn ọ̀nà sí ohunkóhun tí mo ti rí tó jáde láti apá ìwọ̀-oòrùn láìpẹ́. positive Mo fẹ́ran rẹ̀ Ó pani lẹrin, ó sì jẹ́ eré tó dára. Ó jọjú ó sì jẹ́ eré ìfẹ́. Inu mi dun láti rí àwon òṣèré ati erée Naijiria. positive Eré nla. Iṣẹ atinuda ti o yanilenu. Nítorípé mi o le ṣọtẹlẹ nkan ti yóò ṣẹlẹ nipari yamilenu gidigidi. Ifẹnisokunkun náà lagbara. Kò sí asẹsẹ ti ma fi àkókò ẹni ṣofo, niiṣe ni eré náà lọ tààrà síbi kókó eré náà. Eléyìí sì yii ìtàn sísọ àwọn Nollywood pada, koriya fún olukowẹ ati oludari. Mo ro awon eniyan lati wo. positive Ìpele tó parí yóò pa ó lẹ̀rín débi pé wàá rẹ̀rín jáde nínú ilé sinimá. Wà á sì tún máa rérìn-ín músẹ́ ní gbogbo ìgbà tí o bá rántí àwọn àwòrán kọ̀ọ̀kán nínú eré náà. positive Fíìmù tó wuyì Mo gbádun ìgbà tí mo fi wò ó Fíìmù naa, àwọn òsèré àti ẹgbẹ́ tó kù. Fíìmù yìí gbayì. Ìtàn tó dára. Ìgbóríyìn fún àwọn òṣèré, àwọn olùdarí àti olùgbéjáde. Ó yẹ ní wíwò positive Fíìmù ńlá nípa ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Mo gbádùn wíwò fíìmù yìí pátápátá, ó ru ohun kan sókè nínú ẹ̀mí mi láti dúró pẹ̀lú ìrìn mi pẹ̀lú Ọlọ́run àti pé ó jẹ́ ìrántí pé Òun ni bàbá mi tí mo lè bá sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo nígbàkúùgbà . Àyè wà fún ìlọsíwájú fún iṣẹ́ tó dára jù lọ . positive Nínú gbogbo àwọn fíìmù tí ń ru ẹni sókè tí mo ti wò, eléyìí ló gbé igbá orókè. Ọ̀nà tí ó jọni lójú ni wọ́n fi darí rẹ̀ àwọn tí ó kópa níbẹ̀ sì ṣe iṣẹ́ takuntakun. positive Ó dára láti rí bí Kọ́ládé ti ṣe wa mótò. Daddy Showkey ni ọ̀daràn àti alátàḱo, ó sì kó ipa náà dáadáa. Eré ṣíṣe rẹ̀ kúù díẹ̀ káàtó, ṣùgbọ́n kò jánikulẹ̀ positive Eré yìí dùn, o nsọ́ nípa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kan ní Chicago ọ̀kan sìì ti fìgbà kan jẹ́ olórí àwọn ológun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. positive Apanilẹ́rìn-ín. Ó kún fún ẹ̀rín àti ere ṣíṣe gidi. Mo fẹ́ràn bí olú ẹ̀dá-ìtàn ṣe fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ àti bí àwọn obìnrin ṣe kojú àwọn ọkùnrin. positive Ìtàn alailọwaya, a lè gbà iṣẹ́ ọpọlọ àwọn òṣeré gbọ́, dídára àwòrán náà jẹ́ iyalẹnu. positive Eré tí ó yára, tí o panilerin ti o sí dun. Ile igbafe Royal Hibiscus ti fihàn pé àwọn irú eré yìí kò yẹ kí o ́yorísí eré tí ó kún ojú òṣùwọ̀n. positive Tí o bá ń fẹ́ ìtàn tí ó dára, ìseré ti ó gbáyì, àwọn eré tí ò kọ́mọn, pẹ̀lú eré ìfẹ́ tilé fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, eré yìí ni fún ọ. positive "Ìtàn nípa ògùn pín sí oríṣi mẹ́ta nínú eré àgbéléwò tó pàdé sí wákàtí kan lé ogún ìṣéjú. Ìtàn àkókó “love portion"" lódùn ju . Elékejì “yam"" burú jáì àti elékeèta ‘suffer the witch' dùn díẹ̀. Eré méjì nínu méta dára, wọ́n gbìyànjú." positive Fíìmù nla Fíìmù náà máa mú kí o ní ẹ̀dùn ara púpọ̀ tí o sì jẹ́ àmì fún eré àgbéléwò tó dára. Ó mú mi rérìn-ín, sunkún, ó sì fi ọkàn mi sónà lóríi oun tí yóò ṣẹlẹ̀. Gbígbéjáde eré náà dára púpọ̀, àwọn òṣèré náa sì se iṣé takuntakun nípa kíkó ipa a wọn. Mo gbádùn gbogbo àkókò tí mo fìi wò ó. positive Ìtàn yìí kìí kàn án ṣe ìtàn àròsọ́ lásán o. Dókítà obìnrin tí ó gbà orílè-èdè rẹ̀ (àti bóyá gbogbo ayé gan-an) lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn așekú pani Ebola fúnra rẹ̀ ti kú nípasẹ̀ àìsàn náà. Fíìmù tó fọwọ́ tọ́ ni lọ́kàn yìí sọ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni ìlú Èkó ni oṣù keje ọdún 2014 ní ọ̀nà gidi tí kò lè rárá. Àwọn òșèré yẹn ṣe é bí ó ti yẹ. Ní òótọ́, ó bani lọ́kàn jẹ ṣùgbọ́n ó mú ìrètí púpọ̀ dání. positive Ifojutembelu Òṣèré tó dára ati ìtàn tó dára. O fi awọn nkan ti n sele ni Afrika hàn. O jẹ eré tó yẹ fún wíwo. positive Agbọdọ wo Mo nifẹ fíìmù yii o jẹ ẹrin pupọ & romantic Nìkan o wuyi positive Eré orí ìtàgé yìí pani leerín gán Ọmọ!! eré yí jẹ́ eré tó pani l'ẹ́rìn-ín gidi gán. Tí ó bá nwá eré aláwàdà keríkerì eré yí gangan ní kí o mú. positive Àwọn agbègbè tí wọ́n ló jẹ́ kí eré e The Movie Called Life tún yé ni síi. Wọ́n ṣe é dáradára, ò sì múyàn gbádùn rẹ̀ è. positive Eré orí ìtàgé tí a ṣe lórí lè èdè Nàìjíríà kò tíì wú mi lórí tó báyìí rí àti pé mò ńri fún ìgbà ìkejì nii. Eré orí ìtàgé yìí dára púpọ̀ ìtàn nípa orílè-èdè nìí láì parọ́ rárá tó síi nsọ nípa orílè-èdè yìí. positive O dára láti rí eré Nollywood ti sọ ẹyà papọ ti o polongo dọgbadọgba laarin ọkunrin ati obinrin ni ona ti yanilenu. positive Àbùdá tó yàtọ̀ ni ọkàn kìnìún (Lion heart) o gbé àmì ìdáyàtọ̀ lórí. Iṣẹ́ lọ́pọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọrun gbogbo nkán, o jẹ alára dan mère mère. positive Ìtàn tó dára, ohùn ati fídíò tó dára púpọ̀, iṣelọpọ jẹ ohun ìpele gíga, àpapọ àwọn òṣeré dáa púpọ. positive Eré ńlá Pèlú kókó lórí ìdílé, ìsòótó, ìtẹpámọ́sé àti oríire obìnrin positive Fíìmù tí o dára Mo ṣìyèméjì bóyá kí n wò fíìmù náà kí n to ka iwe rẹ̀, ṣugbọn lẹ́hìn ìgbà tí mo wò fíìmù náà,ara mi ya gágá nípa ìwé àti ìtàn rẹ. Fíìmù tí o dára ni,má ṣìyèméjì nípa rẹẹ positive Àtòpọ̀ tó dára, isẹ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ Níwòn ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ mi ò lè dúró mó, mo ti ẹ̀ tun wò lèra tí nkò se bẹ́ẹ̀ rí!. Ìtàn tó fakọyọ, àwon òsèré ati isẹ́ tí ó lágbára. A lè sọ nípa ojúlówó àpèjuwe tí ó kún inú eré yii. Ó wú mi lórí, òmíràn ẹjo. positive Eré tó dára ní, ṣùgbọ́n mo rò wípé ó ti gùn jù. Sùgbọ́n nítòótó, ó yẹ fún wíwo. positive Àfihàn orí amóhùnmáwòrán ńlá! Mo fi ara balẹ̀ gbádùn apá Kínní, ìtàn àti ọ̀nà àgbé gbé ìtàn kalẹ̀ fani mọ́ra mo dẹ̀ fẹ́ràn pé ó ní eẹ̀fẹ̀ nínú. Mí ò le dúró láti wo apá kejì! Mo kí àwọn òṣèré kú oríire. positive Fíìmù tí wọ́n rí dárí dáadáa ni tí wón sì rí tò pọ̀. Ohun tó dálè lórí wọra dé lẹ̀. Wọ́n rí ìtàn yẹn sọ tí wọ́n sì rí ṣe pẹ̀lú àwọn òșèré tó yáyì positive Kòṣemawo ni fún àwọn ọdọ Nàìjíríà àti àwọn olólùfẹ́ sinima gidi Maa fojú sọ́nà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ isẹ mìíràn láti owó Kunle Afolayan. Ẹ kú iṣẹ́. positive Eré náà dára, pípín rẹ̀ náà sì dara. Àwàdà náà jẹ́ tòótọ́, tí àwọn ònwòran síì ní òye rẹ̀. positive Imi ti afẹfẹ titun! Níkẹyìn – eré tí a yà ní Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn ìlànà àgbáyé. ó pa ni lẹ́ẹ̀rín pẹ̀lú àrékérekè, ìtọ́sọ́nà ti o ga jùlọ ati sinimá. ó dánilárayá ó sì mú àkíyèsí ènìyàn dání. ìdarapọ̀ pípé ti ọgbọ́n ati akitiyan tí a fihàn nípasẹ̀ àwórán tí kò le. Ó fi mí sílẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ìdùnnú. positive "Mo fẹràn eré orí ìtàgé ti àkọlé rẹ ńjẹ́ "" king of boys"" Kémi adétiba jẹ́ olùpilẹ̀sẹ̀ tó wuyì. King of Boys jẹ́ eré tí o gbọdọ̀ wo. Mo fẹràn ṣíṣe àti ìfojúsọ́nà náà." positive Fíìmù tó gba èye ìràwọ̀ márùn-ún! Fíìmù Citation jẹ́ Fíìmù tí a gbodò wò. Ó kó abala òrò àsa ilẹ̀ adúláwọ̀. Eré to yanilénu, ní gbogbo Fíìmù náà dùn gidigidi. positive Àgbéjáde ere yìí dára ṣùgbọ́n ìtàn rẹ̀ kò dára tó. Wọ́n ṣeré yìí dáadáa. Àyànfẹ́ ni Charley Boy láti wò lórí ẹ̀rọ ayàwòrán. Isẹ ńlá tí Kemi Atiba ṣe nìyí. Inú mi dùn pé mo ní ààyè láti wo ere yìí positive Ó dára gidigidi. Ó dàbí wípé wón se eré náà ju bí óti yẹ lọ àmó mo gbádùn eré náà. positive Eré yìí dára púpọ̀ Dókítà lánre ámú kí o má lè dìde nígbàtí o bá bẹ̀rẹ̀ síí wò ó. Ìtàn inú rẹ dára gán ni, gbogbo oun tí wọ́n ṣ̣e nínú sinimá ní o dára àti òṣèré gbogbo nínu eré sakitiyan púpọ̀. Ọnà tí wọ́n fí ṣe àgbékalẹ̀ eré yìí dára púpọ̀ positive Títayo Àwọn òṣèré tí wọ́n ṣe ipa wọn dáadáa Àwòrán fídíò tó dára. eré tó dára tí a le fi se àpèjúwè é àye àdúgbò ọ̀pọ̀lọpọ̀. Pípé. positive Ó jẹ́ irú ìyàsọ́tọ̀ti àṣà -ìṣèré ti àṣà láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣèré fíìmù ti o dide ti Mo fẹ pe a rii diẹ sii. positive Eré tó ya ni lénu Eré ya ni lénu gidigidi, ó ní ẹ́písòdù mẹ́tàlá, mo sì wò gbogbo ẹ́písòdù náà tán lọ́jọ́ méjì. Mí ò le dúró kí sésìn kejì jáde Gbogbo ènìyàn ló ṣe dáradára, mí ò lè sọ pé ẹni tí mo féràn jù lèyí. positive Mo ri ere yii ni FIFF (festival de films international dé Fribourg ìn Swiss). Ìtàn na rẹwa ati wipe Adéwálé Akinnuoye Agbájé se bẹbẹ. Bi o ba le wo eré náà, o ni láti lọ, kì yóò bá ọ ninu jẹ. positive Mo gbádùn eré yii gidigidi. Won ya dáradára, o sí panilerin positive Ó fi ọwọ́ tọ́’ni lọ́kàn gidigidi. A dára gan. Mo sọ pé, ẹ lọ wò ó. positive "Tí o bá gbádùn ""Godfather"", a jẹ́ pé wà á gbádùn èyí. Ìtàn eré náà rẹwà bẹẹni ẹ̀hun rẹ̀ pàápàá lọ́wọ́ ẹ̀yìn wúni lórí jọjọ ṣùgbọ́n àwọn abala kan wà tí kò lè ṣẹlẹ̀ lójú ayé. Èyí sì ni àléébù tí eré yìí ni. Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ àhunpọ̀ itan yìí fakíki. " positive Eré tí ó dára. Ní tootọ́, eré tí a ti n retí láti ọwọ́ọ Nollywood 2019 tí wọ́n òsì já wa kulẹ̀. Genevieve Nnaji àti àwon ẹgbẹ́ rẹ kú iṣẹ́. positive Yíyípadà ìtàn náà jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Ẹ kúuṣẹ́ Mi ò kíí wo àwọn fíìmù Nàìjíríà. Èyí yàtò. Bí ìtàn náà ti ń yípadà yàtọ̀ tó jẹ́ pẹ́ mi ò le sọ ǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ níwájú. Olùkọ̀tàn náà, Ifeanyi Opara kúuṣẹ́. Àwọn òṣèré náa ṣe bẹbẹ. Wọ́n rí àwọn ipa tí wọ́n kó nínú eré náà ṣe e positive Eré tó dùn Yíyàn àwọn òṣèré pé, áṣo ṣe régí àti wípe wọ́n mú alátakò gidi positive "“ Narradores de jave"" Jẹ́ eré tó ń pánilérìn pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ to dára àti eré ṣíṣe to kún ojú òsùnwọ̀n, ìdarí náà dára púpọ̀, eré náà sì kún fún àwọn òṣèré lókùrin ati lóbìnrin tí wón ṣe iṣé wọn dájú." positive Ìtàn ayé Adéwálé Akínnùóyè Agbájé Kàn mí ní ọkàn Fíìmù tí a fojú di ni Wọ́n darí è dáadáa àti wípé ó ní ìtaara èrò ọkàn Mo fowó sòyà Fíìmù yí fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn ìtàn ayé ènìyàn. positive Ayé yìí rẹwà lápọ̀jù, ṣùgbọ́n nǹkan ìrẹ́jẹ wà nípa títóbi rẹ̀. Àwọ̀ rẹ̀ kò pọ̀ káàkiri rẹ̀, sùgbón ó jẹ́ kí ó ki. positive Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àfojúsùn sí rògbòdìyàn tí ó bùáyà yìí ṣe àfikún ìròyìn ọ̀kan ò jọ̀kan àti ìlànà-àgbékalẹ̀-ìlú láti jẹ́ kí àwọn nkan hàn sí ọ̀gbẹ̀rì. sinemá àgbéléwò tí ó tẹ́ni lọ́rùn ní ipele tí ó pọ̀ ni, ó sì jẹ́àṣeyọrí pàtàkì fún ilẹ iṣẹ sinemá àgbéléwò nigeria tí ó ṣì wà ní ìkókó. positive Obìnrin tí à ń pè ní èémí ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti eré ìfẹ́ papọ̀ mọ́ àwọn wàhálà tó jẹ mọ́ àìní ìtọ́jú òbí àti èpè àtìdílé wá. positive Lẹ́wà-lẹ́wà, lówe-lówe, bẹ́ẹ̀ ni ń luni wọnú eegun láìloagbára lápọ̀jù, tí ó sì kún fún oríṣiríṣi ipele nígbà tí ó ń gbé ìjọ̀gbọ̀n ìrírí obìnrin wá lágbègbè. positive Bí a ṣe nílò rẹ̀ gan-an rèé Eléyìí kìí kàn ṣe ìkan lára àwọn fíìmù arìndìn Nàìjíríà. Síbẹ̀, fíìmù Nàìjíríà náà sì ni kò sì mú ọgbọ́n dání tó ṣùgbọ́n lọ́nà kúkúrú tó lóye tó sì pè fún ìrònú jinlẹ̀. Ọ̀rọ̀ kànkàkà ni tí ó fi ojú sùnnùkùn wo ìședọ́gba láàrin ipa tẹ̀mí àti ipa tara, tí gbogbo ènìyàn ń lépa lónìí. Fààbú tí wọ́n ríṣe láì pariwo ni. positive Eré tó dára fún wíwò Eré Nollywood Nàìjíríà ti gun òkè àjà. Ìtàn tó dára. positive Nollywood lọ sóke sa.nkan titun lẹ̀yí elegbẹ́ àtipé mofẹ́rán pé wọ́n kọ́ kalè àtipẹ́ obìrin ló kọ́ positive Fíìmù tó lẹ́wà lọ sí inú ìtàn ọdún séyìn tí ìnira láti ọwọ àwọn olùkọ́. Ẹjó á nílò ǹkan tí ó ju ọgbọ́n wa. Kìíse àwọn Fíìmù tó sọrọ nípa Lékkí tàbí owó epo sí ìgbésí ayé. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ǹkan mìrán-àn le dáa sùgbọ́n eléyìí gba mẹ́wàá láti òdò mi nítorí wípé irú ǹkan tí mo fẹ́ràn láti rí kọ́ jáde nínú Eré adúláwò. Ìgb́oríyìn ńlá fún ọ Kúnlé positive Eré ṣíṣe nlá, isatunkọ to dara ti o se pelu ìtàn tó dára, eré kíkọ náà dára pẹlú, ni àkótán, iṣẹ nla láti ọwọ Genevieve Nnaji. positive Ọlọ́tọ ní t’òun ọ̀tọ̀ Èyí kìí se àwọn sinimá gbẹ̀ẹ́gbẹ̀ẹ́ ojojúmọ́ o. Àwọn gbajúmọ̀ òșèré inú rẹ̀ tọ́ sí àmì ẹ̀yẹ fún ipa tí wọ́n kó. Gbogbo Ìșẹ́jú inú rẹ̀ ni mo fẹ́ràn. Jọ̀wọ́, wò ó! positive Gbogbo ohun tí ó wà nínú fíìmù yí ni mo fẹ́ràn. Mo ti wo fíìmù ni ìgbà márùn-ún báyìí. Mo fẹ́ràn fíìmù yí gidi gan-an ni. positive Iṣẹ́ tín yani lẹ́nu. Ò ti ṣe díẹ̀ tí mo wo eré tí ó ní ìgbékalẹ̀ gidi. Genevieve Nnaji àti àwon ẹgbẹ́ rẹ kú iṣẹ́. Mo n retí àwon èsì tí n bọ̀ positive Isoken lẹ́wà púpọ̀ Mo feran àwọn aṣọ eré náà. Ibi ìparí náà rẹwà pupọ̀, mo sì gbádùn ìparí eré náà pẹ̀lú Inú mi kò dùn ṣùgbọ́n Eré náà gbé ọkàn mi dìde. positive Ere apanilẹ́rìn-ín lórí Kérésìmesì. Ere yìí kún fún ẹ̀rín àríntàkìtì. positive Eré oní pele sí ipele tá ṣètò dáradára nípa ètò òfin orílè-èdè Naijiria. Àpèjúwe tó kún lórí ètò òfin. Ó tún ṣàpèjúwe àwọn ẹwu tó wà nínú òwò ìdílé àti ìfihàn tó tẹ́lẹ. positive Ó ní ìmọ̀ àfojúsí, tí ó yàtọ̀ gedegbe, tí ó ń fa àronúsí láàrín àwọn olùwòran. positive Mo yàn fíìmù yìí fún ẹnikẹ́ni tó bá nifẹ sí ìtàn àti orísun Nàìjíríà positive "Ìtàn nípa ògùn pín sí oríṣi mẹ́ta nínú eré àgbéléwò tó pàdé sí wákàtí kan lé ogún ìṣéjú. Ìtàn àkọ́kọ́ “love portion"" lódùn ju . Elékejì “yam"" burú jáì àti elékeèta ‘suffer the witch' dùn díẹ̀. Eré méjì nínu méta dára, wọ́n gbìyànjú." positive Ọ̀sẹ̀ kan nínú ayé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria. Iṣẹ́ gidi. positive Ìbùkún ni wíwo sinimá ‘Coming From Insanity’ pẹ̀lú àwọn olùwòran tó dáńtọ́ bíi ọgbọ̀n. Níșe là ń ríi bíi pé gbogbo iṣan wọn ló ń dìde torí wípé inú wọn dùn yàtọ̀ bí a ṣe ń sún mọ́ àgbàlá tí ó dùn jù nínú sinimá yìí. positive Àwò gbádùn Fíìmù yìí jẹ́ àwò gbádùn. Kàn sí ọkàn rẹ payá, ó dára láti ríi bí àwọn òṣèré tí ń bọ àti àwọn akọrin ṣe le di tiwọn mú. Mo wòó pa. positive Fíìmù tó jọjú tí ó ń sọ nípa àwọn ohun tí ó làmì laaka nínú ìtàn ilẹ̀ Bìíní ni. Sàdánkátà fún àwọn òșèré àti gbogbo àwọn tí ó ṣe iṣẹ́ nínú rẹ̀. positive Eré tó tayọ. Àwọn òṣèré náà kú ojú òsùnwọ̀n. Ìwòyè àti ètò eré náà dára púpọ. Orin eré náà tayọ. Ìtàn eré náà sì dára gidigidi. positive "Láìsí àníàní, àwọn òǹwòran yóò gbádùn ere ""The Wedding Party"" tí Kemi Adetiba ṣe. Ere lọ́kọláya apanilẹ́rìn tó ní èròjà ilẹ̀ òkèèrè nínú." positive Ere yìí panilerin positive Ere yi he eyi ti o gba okan mi to o si tun mu rewesi sugbon o tun gba okan mi pada. positive Ìgbéga, ìwúnilórí, fíìmù tó dára. Ọ̣kọ mìi ló yan eré sinimá yìí, mi ò sì fẹ́ wò ó. Ṣùgbọ́n ó mú mi mọ́lè tó jẹ́ wípé mi ò le kúrò nínú yàrá. Ìtàn Ṣadé banínínújé, ṣùgbọ́n gbogbo oun tí ó là kọjá mú ìtùnú bá a tí ó sì yí ayé rẹ̀ padà sí èyí tó nítumọ̀ ní ònà tó dáa. Èmi àti ọkọ mi fẹ́ràn eré yìí positive Òládùn àmọ́…. Àsọdùn pọ̀ nínú eré náà. Ṣùgbọ́n mo gbádùn rẹ̀. Lọ́nà míràn ẹ̀wẹ̀, eléyìí wá láti gbóríyìn fà wọn dókítà àti elétò ara tí wọn kọjú àwọn àarùn káàkiri àgbáyé. positive Ìkíni. Eré náà ran mi leti ẹkọ kan lati inu iwe geesi kan ti mo ka nígbàtí mo wa níleewe, ti a akọle re je The bottle Imp. Ìtàn eré yii jọmọ ìtàn The bottle imp. Ẹ jo kó sì àríyànjiyàn o, ẹrọ témi nìyẹn. Ẹsẹ. positive Eré iyalẹnu gidigidi. Ìkópa òṣèré didara nipasẹ òṣèré pakiti obìnrin. positive Kunle Afolayan àgbà ni positive Mímú àwọn òsèré KOB 2 fi àwọn ipá tó tọ́ mo àwọn òṣèré tí yóò ṣe é dáradára. Wọ́n sì ṣe bẹbẹ nínú síse eré náà, papọ̀ mó àwọn tí kò sọ̀rọ̀ àti àwọn tó kàn farahàn lásán. Eré síse náà dára púpọ̀ kódà fífi ojú sọ̀rọ̀ wọn gaan sọ tóó positive Àgbà nínú àwọn eré orí ìtàgé Gbogbo oun tí mo fẹ sọ ni pé eré yìí jé àgbà laarin àwọn eré orí ìtàgé. Kẹ́mi Adétiba ọgá lọ jẹ́. positive ÈyÍ tó dárajù ninu Nollywood Eré yii jẹ́ ìyàtọ̀ nítòótọ́. àwọn òsèré naa gbìnyànjú wón dẹ̀ ku iṣẹ́ takuntakun. Mo gbóríyìn fún àwon ẹgbẹ́ tí ó wà lẹ́hìn eré naa ati Bíọ́lá Àlàbí. Ìràwọ̀ ni Seyi Shay ẹ jọ̀wọ́ . Ẹ̀rọ ayàwòrán naa pé. Òkè òkè bayi ni Nollywood nlọ positive Citation : iṣẹ́ Kunle Afolayan fi ẹ̀tàn rọrùn bẹ́ẹ̀ ó lè ní ọ̀nà alágbàyídá positive Ìtàn tí ó tayọ pẹ̀lú àwọn òṣèré ńlá Mi ò le duro fún apá kejì!!! Wọn kọ ère àfihàn náà dáadáa, àwọn òṣèré náà kún fún ìdàgbàsókè ní kíkún pẹ̀lú ìtàn tó le. positive Eré tó wuyì Eré yìí kò le d̀un ju báyìí lọ. Mi ò le rò ǹkan tí ó ma ṣẹlẹ̀ léyìn eré yìí ṣùgbọ́n ǹkan tí wọ́n kó sí ìgbéjáde eré yìí pọ̀ gidi gan. positive Iṣé ńlá. Èyí dára, bótilẹ̀jẹ́pé èkan ni mo wòó. positive akọ̀ lerí ẹ̀bì nínú àkosílẹ̀ ojúlówó ìtan nàà.ó fi hàn pé ìwádi àkosílẹ̀ eré kò lábáwọ́n. ó ma jé ìyalénu fún e wá dè ma ró pé kí o ti ségun èsè náá,léyin ná lowá mòpé àkosílè ìtàn jù bose rò le. wákàtí méjì àbò ní eré ná sùgbón wón fi falẹ̀ rárá positive Fíìmù nla Mo ṣiṣ̣ẹ́ lóri fíìmù yìí. Mi ò kìí sába wo àwọn eré tí mo bá ti ṣiṣẹ́ lórí won-on rí, ṣùgbón èyí yanílẹ́nu. Ade John kúusé. positive Máṣe tẹ́tísí èsì òdì yìí Mo ti wòye àwọn kan kò le mú òótọ́ mú kí wọ́n parọ́ irọ́ ni fíìmù ńlá kìí ṣe òótọ́ oun gbogbo nínú fíìmù ṣùgbọ́n Adéwálé ti sọ béè sùgbọ́n awo Tilbury àtijó jowú lásán.... Mú fíìmù fún oun tí ó jẹ́ kí ó sì yé ayé jẹ́ búburú ní ayé e ‘70 ati ‘80 fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn gbádùn àwọn fíìmù àti kí ó kọ́ fetí sí yìí búburú lódì. positive Ó mu mí mólè !!! Mo gbádùn rẹ. Èyí jẹ́ eré àgbéléwò tó dára púpò to jáde wá lá́ti inú àwọn fíìmù Hollywood . Mi ò fi àkókò mi ṣòfò rara. positive O dára tí ó bá gbádùn kókó- òrò eré àgbéléwò náà Tí ó bá jẹ́ pé ķókó òrò náà ló gbádùn dájúdájú eré àgbéléwò tí ó dára ni. Àmọ́ bí fíìmù náà ti ń lọ ti fàà jù. Níṣe ló dà bíi eni wípé wọ́n fẹ́ tẹlè múyé. positive Eré to tayọ, báni nínú jẹ́, tí ó dunni tí ó sì kún fayo pẹlu positive Eré to ye fún Wiwo. Ó wú mi lórí. positive N kò n ṣe olólùfẹ́ fíìmù Nàìjíríà, ṣugbọn eleyii tẹ́nilọ́rùn. Olùdarí Yan kasiti pẹlú ọgbọ́n, awọn òṣèré jí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀yìn òtítọ́ gbogbo. O jẹ́ asetanse ṣinimá èyí tí ì já sí kí Netflix ma kpin positive Mo maa sọpé: Ó tó bẹ, ó ju be lo! Eré àgbéléwò náà dára ,ó kún fún àwọn òshèré tó mọ isé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó n fáà lẹ́kọ̀ọ̀kan ( bíi wákàtí méjì lápapò) . Lọ́kàn mi eeré náà tó bẹ́ẹ̀ . Eré àgbéléwò yìí kò sí lára àwọn fíìmù tó dára jù, tí ó yẹ kí ènìyàn wò ni àsìkò kòrónà yìí…… Àmọ́ mo fẹ́ràn rẹẹ̀. positive Mo gbádùn gbogbo ìpele ère “Lionheart”. Ó tu ọ̀kan mi lára láti wo àwọn àgbààgbà òṣèré ṣ̣e ipá wọn. Mo gbádùn eré ṣíṣe Genevieve . positive Fíìmù alágbára tí ó ń bini léèrè, tí ó sì ń tú àṣírí ètò àjọ elétò-ìlera àgbáyé gẹ́gẹ́ bí oníwà bíi Sàtánì positive Nitooto, àwòrán tó dùn wo tí ó sì yanilenu. Ina náà àti, ìṣeré àti àwọn ohun èlò ìṣeré náà lewa púpò. A lè fi eré yìí sí ẹka àwọn eré ayé òde òní. positive Ní òye tèmi o Ìtàn bí èrè yìí ṣe lọ dùn gan-an ni mo sì fẹ́ràn ohun gbogbo nípa sinimá yìí positive Ìyàlẹ́nu Bí ìtàn na ti lo lárindin, àwọn òṣèré náà ṣe dára dára àti pé ìparí eré na ò ṣé mo láti ìbèrè. Àwòrán na jágeree. Ìdàgbàsókè tí bá eré noliwudu o positive Àgbọdọ̀ wò! Láti ìbẹrẹ dé òpin, àwọn irun tí o wà ní ẹhìn ọrùn mi kò le sai má dúró. ìtàn náà rọrùn sibẹsibẹ ó jẹ́ iyanilẹnu fún mi, gbígbé eré náà kalẹ jẹ́ ailabawọn. positive Fíìmù náà dára mó sì gbádùn rẹ,mo rí òun tí mo gb'ọ̀kán le nigba tí Chief Daddy fí ma parí. Awọn òṣeré ṣé iṣẹ́ takuntakun àti wípé fíìmù náà pa ni l'ẹrin. positive Eré yii aṣoju tó dára ní ayé òde òni nipa awọn idile to dari ilé-iṣẹ́ to n dojukọ wàhálà ni Naijiria. Iṣẹ ìyàwòrán, ipa awọn òṣèré àti gbogbo àyíká eré náà mú kí eré na pedege. Mo fẹràn rẹ. positive Eré ojoojúmó aláwòdúdú tó dára. Ẹ kúusẹ́ positive Mo rò wípé eré náà kò ní dùn ni, ṣùgbọ́n ó ju bí mo ti rò lọ. Eré náà ni àwọn osere daradara ti wọn ṣiṣẹ́ takuntakun, mo fẹ́ràn àwọn eré Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n ǹkan tí kò dára tí mo rí nínú eré náà ni bí ìyàwó ilé ṣe fi ara rẹ̀ sẹlẹ́yà tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lórí eékún, bótilẹ̀jẹ́pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà panilérìn-ín síbẹ̀síbẹ̀, kò kún tó. positive Kíko náà dára púpọ̀! Òtítọ̀ bí o ṣe yẹ! Èyí kóni lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀kọ́, o sì sàfihàn òwò ìtànìyàn! Àtiwípé Sharon Ooja jẹ́ òṣèré tó tún yàtọ̀ positive Eré Sinimá tó dára jù lọ Things Fall Apart jẹ́ eré tó dára jù. Kódà, ó dáa ju The Force Awakens lọ. Ó yẹ kí ó ti gba Oscar márùn-ún, ó kéré tán. Òkónkwo jẹ́ okùnrin tí ó wuni jù tí mo ti ríí, béè sì nìyí, gbogbo àwọn tí mo ti pàdé tí wón ti ríi rí nífèé rè. positive Iṣẹ ́ìtàn ńlá Lọ gbogbo àkókò náà ní wíwò àwọ̀ara rẹ̀ tí ó lẹ́wà( bev naya) àti gbígbọ́ orin ìtùnú náà. positive Eré ti wọn kọ dára tí wọn sì dárí dáadáa pelu. Nàìjíríà je orílẹ̀-èdè tí ó yàtọ̀ pelu ilẹ̀, iye ènìyàn àti onírúurú tí ó wà nínú rẹ. Eré Doctor Lanre fọwọ́ bà gbògbò èka ìgbé ayé ènìyàn lójoojúmọ́. Eré dókítà Lanre je dandan láti wò. positive Ìkan lára àwọn eré alábala ilé Adúláwò tí ó dára jù. Ẹ̀bùn yẹn lé téńté. Ìșọwọ́ ṣeré àwọn ọmọbìnrin yẹn kún ojú òṣùwọ̀n. Bí wọ́n ṣe kọ eré náà kọ́ni lọ́gbọ́n wọ́n sì ríi ṣe. Nọ́líwuùdù, ẹ rí èyí ṣe, ẹ máa tẹ̀ síwájú. positive Mo ní ọrọ ìgbìyànjú méjì tí mò fẹ́ gbà yín!! Mo nífẹ̀ẹ́ sinimá púpọ̀ Sinimá yìí dùn láti ìbẹ̀rẹ̀ títí tó fí dé òpin rẹ, mo ṣe sàndákátà fún Olùdarí àti àwọn òṣeré tó ṣe sinima yìí. Njẹ sinima yìí lè tẹsiwaju àti ìponlogo eré orí ìtàgí yìí ju tẹlẹ lọ? positive Mo féràn Eré náà O bẹ̀rẹ̀ pèlú àíyára ṣùgbọ́n ó dìde kíákíá! Àìgbọdọ̀ máwò ó ni positive Ó lágbára, ìjìnlẹ̀ fíìmù nípa ẹ̀dá Èyí jẹ́ eré tí ó dára tí ó sì ń múni ronú tí mo máa gbàníyànjú kí gbogbo ènìyàn wó ò. positive Eré ńlá Òsùbà fún ẹgbé tó gbé eré náà jáde.Eré tó tayọ. Àwòrán dídára ni wọ́n gbé jáde. O gbe asa, iwa ati ede to gbe jade je nkan gidi. positive "“Narradores de jave"" eré àgbéléwò ti àwọn ènìyàn ò ti mò nípa púpò kódà ni ìlú Brazil ti wón tí ń ṣe é , jẹ́ eré àgbéléwò Brazil tó dára tó sì jẹ́ pàtóo." positive Eré ahesọ àti àwàdà tí ó yàn fẹ́ 'You bitches can never', mo ń fi ọwọ́ sọ̀ya fún ọkùnrin òyìnbó.... Kini nípa rẹ? Mo le korira kí n sì tún féràn wọn lekan ṣoṣo, ipa méjì ọkùnrin náà, ẹsẹ. positive Fíìmù tí ó ru ẹni sókè gidi ni. Fíìmù mọ̀lẹ́bí tí ó yẹ kí a wò pẹ̀lú àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ni. positive Mo féràn èyí positive Eré nla, mo fi ìfẹ ranṣẹ láti naija. positive Ikọwẹ ti o yanilenu Dokita Lanre jẹ eré tó yanilenu. Mo gbádùn arami nigbati mo wo. O ṣàfihàn igbe-aye ojojumọ awon eniyan, iye-eniyan ati ẹkùn, o yàtọ o sí dun fún wíwò. positive Eré ọpọlọ, ti o dára fún wíwò. positive Ìyanilẹ́nu Àìgbodò máwo fíìmù rè. Ó mà fanimọ́ra,nínú ìtàn tó dá lórí ìsẹ̀lẹ̀ òótọ́ yìí, Ẹjọ̀wọ́, ẹjọ̀wọ́,ẹ wo Fíìmù yìí, ẹ kò ní rí ìjáníkulẹ̀. positive Ìparí tí ó dára. Ère yìí mú kí nifẹ si títí dé ìparí tí ó sì ní ra láti rí nínú àwọn ère láyé òde yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lè sọ nkan ti o ṣẹlẹ̀ nínú eré náà sibesibe ó ti fi èèyàn sínú òkùnkùn. positive Eré tí wọ́n ṣe dáradára. Pẹlú gbogbo àwọn ayédèrú eré Nollywood tí kò ní ǹkankan sọ nípa ìgbéayé àwọn ọmọ Nàìjíríà. Àmó Mokálìk tàbí ìrònúpìwàdà kúrò nínú ǹkan tí a mọ eré Nollywood fún. Ìtàn eré náà kún fún ẹ̀kọ́ iyebíye. Ìfẹ́ ọkan mi ni wípé eré náà yóò jẹ́ àṣà titun. positive Mo fẹ́ tún wò. èyí jẹ́ ìkan lára fíìmù orílè-èdè Nàìjíríà tí mo fé tún wò. Iṣẹ́ àrà ní o jẹ́ títí dé òpin. positive Lákòótán, ó jẹ́ ìtàn ayé òde-òní tó fanimọ́ra ṣùgbọ́n tó sàjèjì sí àwọn mìíràn. Ere yìí fún wa ní ìmọ̀ nípa Nàìjíríà òde òní. positive Ojúlówó Ó mú orí mi wú. Àwọn fíìmù Nàìjíríà kìí sábà mú orí mi wú. Aago kan òru ni mo wà tí mò ń wo fíìmù yìí lọ́wọ́. Gbogbo rẹ̀ ló bára wọn mu. Wọ́n kú ișẹ́ takuntakun. Sàdánkátà yín o. positive Kìí ṣe pé ìtàn náà kùnà láti di àkíyèsí olúwo náà nìkan, ṣùgbọ́n ṣíṣe rẹ̀ ló jùlọ, tí kò ní ìdánilójú láíláí. negative Eré yìí gùn s̩ùgbón kò dùn. Kódà, orin ti wó̩n ń ko̩ ní abé̩lè̩ gan-an kò wúlò. Kò tilè̩ si ́nǹkankan tí a lè s̩e láti s̩àtúns̩e eré yìí. negative Ọ̀nà tó dára lati ba ọjọ́ èyàn jẹ́ tán yányán. negative Kò farabalẹ̀. negative Àwọn kókó-ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Swallow yóò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kígbe - òṣì, ìfipábánilòpọ̀ ìbálópọ̀, ìṣòwo ogun olóró, ìbàjẹ́ ẹ̀tọ́ - ṣùgbọ́n fíìmu náà àti gbogbo àwọn ohun kíkọ jẹ́ aláìlérò àti àìbìkítà. negative Bótilẹ̀jẹ́pé iṣẹ́ àárín jẹ́ ìwúnilórí àìse àìbalẹ̀ àìbìkítà tí àgbẹ̀ bigbé e rì ìtàn tí ó fanimọ́ra náà, tí ó jẹ́ kí ó jẹ́ wíwú tí ó nira púpọ̀ ju tí ó nílò láti jẹ negative Àwọn ìdákú dájí inú ìtàn yìí àti àwọn ohun bíi òògùn àti awo tí kò mú ọgbọ́n kankan dání tí pọ̀ ju kí ènìyàn tọ́jú sinimá yìí lọ. negative Kò sí ènìyàn kan tí kò gàn èyí bí a ṣe ń ja ogun jáde. Pàápàá àwọn òṣìṣẹ́ sinimá tí kò sanwó, tí ń rẹ́ẹ̀rín. Ìríra! negative Bákánnà ni agbára àti àìbalẹ̀, Ọ̀gbìn jẹ́ olùránnilétí tí ó wuyì tí àwọn gígùn tí ó léwu ti ìkóríra ara ẹni lè já sí. negative Ọnà tó burú láti bẹ̀rẹ̀ ọdún, 'Apke' ò já mọ ǹkankan negative Ọ lè máa kórira ará pé ọ pàdé ṣùgbón ọ kúrò bi ẹni pe ọ ọpọlọ rẹ kú. negative Ìyà jẹ ní fún àwọn tí ó kópa nínú eré tí mo bà yọ èyí kúrò. Kò dáa rárá. negative Bíi àwọn eré tó kùnà ókù, 'Knock Out Blessing' ń polongo àwọn tó gbé e jáde kìí se fún àwọn tó ń wòó ni Nigeria. negative Eré Akínnùóyè-Agbájé fẹ́rẹ̀ kú kò gbà láti díi mu ẹnití Ẹ̀ní jẹ́. negative Àádọ́ta ìṣẹ́jú ni a fi wọ ìpolówó ilé ìgbafẹ́ ní èkó, ère parí. Owó wọ'gbó. Kò ṣeé ròyìn. negative Ojútì gbáà, 'The Island' fi àkókò àti tálẹ́ńtì ṣòfò negative tí mo bá sọ fun ọ pé fíìmù ìyàlẹ́nu ni èyí, irọ́ ni èmi yóò sọ. negative Yàtò sí pípe rè, ìṣòro 'Funke' ni pey kò dùn. negative Ẹ má wò o. Ó ṣá, kò dáni lára yá. Eré tẹ́ńbẹ́lú ni. negative Níkẹhìn, èyí jẹ́ ẹ̀bùn ìnira tí kò yẹ kí ó mú wá sí sinimá. negative Ní ti ìgbékalè̩ is̩é̩, ó dára. Àwòrán rè̩ jáde dáadáa. Kíkópa àwo̩n òs̩èré náà kò fi bé̩è̩ burújáì. Ibi tí wàhálà wà ni àìsí àpe̩re̩ ìmúlò o̩gbó̩n inú nínú ìtàn àti ìtàn síso. negative Ìwà ìkà tí ọmọ ọdún mẹ́fà yí ti ṣe lórí pàápàá ti yí fíìmù di púpọ̀ láti kà negative Ó dára fún àwọn ọmọ ọdún mẹrinla. Ìṣe eré nà dàbi ìtàn Disney tó mọ. negative Díẹ̀ nínú àwọn fọwọ́kàn alárinrin àti àwọn àkókò tí agbára ọ̀fẹ́, ṣùgbọ́n ó gbòòrò púpọ̀, pẹ̀lú iṣé àti àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó jẹ́ díẹ̀ bíi tẹlifísọ̀n ọ̀sán. negative Àpapọ̀ àpéjọ eré jẹ́ kúkurú púpọ̀ àti àsọtẹ́lẹ̀. negative ṣùgbọ́n, àkókò dídán yí kéré ósì jìnà fún won láti san owó tójọju láti fi wo yí negative Àti pé dirama tí ó wà láàrín Jósẹ́fù àti aya rẹ̀ àṣẹ bí àdáyébá ṣùgbọ́n idà í ìgbà wípé àṣẹ bí dọkumẹ́tìrì negative Nítoríbẹ́ẹ̀, àwọn rídìmù ti gígùn àti kúkúrú wọ́ òsé ṣe ń fọhùn láìpẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olùgbọ́ negative Kò sí ẹnì kankan tí ó yẹ kí o wo eré rádaràda yìí. negative Dídùn hàn, Ìtàn tí kò pọ̀, ohun agbohùn burúkú negative Ìlò ohùn àwọn òșèré mìíràn lórí tí àwọn tí à ń wò ní ọ̀nà tí kò dára rárá ní èyí àti ìṣọwọ́ ṣeré tí kò kún ojú òṣùwọ̀n dé orí pé kò dára rárá. Àlákálàá ni èyí yóò fún ọ negative Kí í ṣe è̩è̩kan náà ni gbogbo rẹ̩̀ dojúrú. Kí í ṣe dandan ni kí àwo̩n tó ń gbé fíìmù jáde jẹ́ kí Nollywood gún bí í tí Bollywood láìsí ìtàn, ọgbọ́n àti nǹkan tó yẹ láti jẹ kí a gbádùn rẹ. negative Ǹkan tódáa àti ìhà-bóṣewà. Aláìdùn àti ìsàlè òmùgọ! negative Fíìmù ẹ̀ya àkọ́kọ́ tí ó ní àbàwọ́n, ṣùgb́ọn ó fihàn àdéhùn ńlá kan. negative Nípa eré to gbajúmọ̀ yí #KOB nko lè sọ pé ó dára tàbí burú ju àwọn ìyókù nollyhood lọ negative "Ere àwọn òpònú tí kò mú ọpọlọ lọ́wọ́ rárá ní eré ""Made in Heaven"" jẹ́. Ẹni tó bá wo ère yìí kò ni í mọ ìgbà tí òun yóò máa ré̩rìn in látàrí ìbínú tí ere náà lè fà. Ère tó lè fà ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ni. Réderède tó kún inú ère náà tó láti pá ènìyàn lẹrin-in. Òsì pátápátá gbáà ni ère yìí." negative Gbígbé lọ́ra, ìṣeré ńlá àti pé ó ní àwọn bíba díẹ̀ nínú, ṣùgbọ́n ìparí kò ní ìdáríjì. negative Ní àìsí ohun tí òní láárí kan tí a lè rí dì mú, má wulẹ̀ fi owó rẹ ṣòfò pé ò ń ra sinimá Dagger. N kò gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn láti wò ó rárá. negative Tí mo bá sọ wípé kìràkìtà pé a fẹ́ ṣe eré apani lẹ́rìn-ín ti wá ń sọ kókó inú àwọn fíìmù di rádaràda, èyí gan-an ni àpẹrẹ àkọ́kọ́. negative Tí o bá ti wo sinimá Chief Daddy :Mò ń lọ wo Broke ní ọjọ́ ọdún tuntun tí wọ́n gbé e jáde, léṣẹ̀kẹsẹ̀ ni mo gbà á lérò pé ó yẹ kí ó díje fún sinimá tó burú jù nínú ọdún yìí. Mọ̀ pé ìwọ kọ́ ni o ni ẹ́bi. negative Ọ̀lẹ àti ìrẹ̀wẹ̀sì! negative Sún kẹẹrẹ, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ǹkankan nínú eré yìí, àwọn orin tí wọ́n lò kò dára rárá. negative fíìmù kó jẹ́ ńlá, díẹ̀ nínú àwọn òsère ń seré ju bóti yẹ lọ (bóyá lórí-ìdarí?) Ṣùgbọ́n ibi tí wọ́n ti yà á dára negative Iṣé̩ ye̩pe̩re̩ tó kéré sí adúrú owó tí a ná lé e lórí. negative Ìpìlẹ̀ ère díída lẹ́yin ìgbèjàde rẹ̀ tó buru negative Kò ṣeé dá l'ábàá negative Ìtàn ńlá, ṣíṣe tí kò dára. negative Eré tí ó kún fún àwọn gbajúmọ̀n tí ó wà dàbí wípé wọn ń ṣe eré ọmọdé. negative àìfọwósí negative Ìbànújẹ́! ìtìjú! Ìtìjú didan. negative Àkójọpọ̀ eré yi ló jẹ́ kín fẹ ní gbogbo ọ̀nà, ó sòro láti m'ójúkúrò nítorí isé ribiribi ti Genevieve Nnaji ṣe síbẹ̀. negative ní dídájú, ọ̀kan lára eré tí ó bani lérù tí wón ṣe negative Tí a bá ń sọ̀rọ̀ ní́pa eré síse, ìko̩sílé̩ ìtàn, nǹkan ìyàlẹ́nu tó jó̩ni lójú ni. negative Bó tilè je pe wón kà á sí eré tó ń ba ni lẹ́rù, 'Bridal Shower' kìí se eré bẹ́ẹ̀. Ereé rádaràda ni, kò ní ìtumò rárá. negative ó jẹ́ ọ̀nà tó dára àmọ́ kò ní tumọ̀ - wíwá owó kíá kíá negative ìjákunlẹ̀ ní pàtó negative Ìdáni lágara ni negative Ó n dùn ṣùgbọn kò kún ojú òṣùwọ̀n tó. negative ló bàájẹ, 'àwòrán ti dára jùlọ' fi dáni lójú pé eléyìí jìnà púpọ̀ sí ohun tó dára. negative Ó lọ́ra gbígbé àsọtẹ́lẹ̀ Eléèyí fíìmù pàtó jẹ́ ti ní àwọn high junior Circuit. negative Ṣùgbọ́n ohun àti orin rẹ̀ burúkú tí ó tilẹ̀ ń bá ohunkóhun tí o dáa jẹ́ negative Nkò wo gbogbo ìranù yíí. Kò yẹ fún ìgbóríyìn rárá, Ìranù láti ilè aláwò dúdú tí kò ní àkójopò àwọn òṣèré. negative Ọ̀nàìkọ̀tàn tó dára , Ìṣe tí kò dára negative Ṣíṣe ere náà kódà a, orin rẹ̀ jẹ́ àkọtúnkọ..... Ọ̀nàìkọ̀tàn náà jẹ́ . . (bí ó bá jẹ́ pé mo le fi ùn kan tọ́ka sí i níbí ) negative Ìpì̀lẹ̀ ère náà daada, ṣùgbọ́n ẹ̀ka tẹ́kíníkà kò dára rárá. negative Abojútó, mímú mímú ìwé kan pẹ̀lú (níbi tí a kò tẹ̀) ìjìnlẹ̀ negative Kò sí òun kán tó dára nípa 'What Binds Us'. negative Ṣíṣejáde fíìmù yìí ti ṣòro, ṣùgbọ́n ọkàn ti ń sọnù. negative Kọ́kọ́ wà lórí ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrín Jósẹ̀fù àti súsì, Eré tí ó rán ìmọ́lẹ̀ sí Fẹ́búárì 13,1976,Ìpànìyàn, tí ó mú Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ wá sí ìjọba. negative Ìsekúse gbàá! Àwọn ẹni yìí kò ní nkán ṣe. Dákun, má fí náírà rẹ fún wọn lérè. negative Eré yìí ní láti jẹ́eré ìfẹ́ apanilẹ̀rin tí kò dùn tí a ti wò rí. negative Eléyìí ni yóò fẹ́ jẹ́ iṣẹ́ eré sinimá tí ó burú jù bó tilẹ̀ jé wípé owó tí ó tó ni wón fi sé é. negative Ó ti falẹ̀ jù. Ìf'àkókó ṣòfò ni negative Ojú gbà mí tì pé mo fi wákàtí méjì mọ eré yìí negative N kò fi bẹ́ẹ̀ gba ti sinimá yìí jàre. negative Eré nàa fẹ́ẹ̀jẹ́ kòròfo negative Ọ̀rọ̀ sísọ wọn kò kún ojú òsùwọ́n, àwọn ogun tí wọ́n jà dà bíi ti àwọn tí ó sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ isẹ́ tíátà ní kíkọ. negative Láti ìdarí tí kò da, dé ìtàn ti kò dùn, ó kún fún àìlọ́pọlọ àti àìláròjinlẹ̀ negative Eré náà burẹ́wà negative Yàtọ̀ sí pé èniyàn lè sọ oun tó ṣẹlẹ̀ ni ú eré náà àti àwọn Òṣeré tí kò kún ojú òṣùwọ̀n, òkun fún àwọn àwí_túńwí asán. negative Mo kórira bí wọ́n ṣe fún eré yí ní àkọlé. negative Òfúútù fẹ́ẹ́tẹ̀, áásà tí kò ní kánún. Ẹ̀FÚNSETÁN ANÍWÚRÀ jẹ́ àfihàn ìṣe ìmẹ́lẹ́ àti ọ̀nà ìgbà sọ ìtàn tí ó dun’ni jọjọ negative Inú ń bí mi gidigidi. negative Àìsí àwọn ìwé àlẹ̀ mọ́ ògiri oní ìdábùú lẹ́lẹ́gbẹ̀ẹ́ fún àwọn fíìmù Nọ́líwuùdù. negative Ósi parakutu negative Eré yìí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrètí dání ṣùgbọ́n ó padà di oun tí ó ń múnú bíni púpọ̀. negative Nítorí wọ́n lọ bro orí ọ̀rọ̀ láti fi ṣe ìfihàn àwọn ẹ̀dá... negative Fíìmù náà dàbí ẹnipé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti wà ní fífà dé ìparí negative Ó ṣe ìlérí ẹ̀rín, ṣùgbọ́n àwàdà jẹ́ ìwọ̀nba àti àwọn ẹ̀rin músẹ́ dípò ẹ̀rin ahun tí ó nírètí nígbàtí ó lọ sí sinimá fún àwàdà kan. negative Ábígẹ́lì kò dára tó bẹ́ẹ̀ náà, ẹni búburú ibẹ̀ jẹ́ asorun iwájú pọ̀ mọ́ tí ìpàkọ́. Wọ́n tún wá padà ríi wípé kò dára fún àwọn Adúláwò láti máa ka ọwọ́ aago padà sẹ́yìn. negative Ipò asíwájú obìnrin tó ga jù jẹ́ ìjákulẹ̀ negative ìparí rẹ nìkan ni ó padà du fún mi. Ó da fún ọ. negative Ìdójútì gbáà ni ètí jẹ́ Kódà, ó ta àbùkù bá CNA. negative Ọ̀nà ṣe ère náà. Ìsẹ́jú àádọ̀rún tí ìjánikulẹ̀ ohun àgbéyèwo àti ṣíṣe ere negative Ó ti dàrú mọ́ mi lójú o. Ṣé oun tí wọ́n pè ní sinimá gidi nílẹ̀ Adúláwọ lọ́dún 2012 rèé? Tí ó bá jẹ́ bẹ̀ẹ̀, ó dára! Mo wá ń rò ó wò pé ṣé ó ti dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ní ọdún un 2021 bí? negative Knock Out Blessing' jẹ́ eré tí kò ní ìwúlò rárá, kódà kò yẹ kí wọn gbe jáde. Òṣì. negative Gígùnjù tí kò wúlò negative Fún àwọn òsèré tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ tí ó tún ní kò sí ìtọ́sọ́nà láti Akinrópò. Ohùn náà burú, bóyá láti àìní àwọn ariwo gbohùngbohùn. negative Súgà Súgà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwòye yíyí ojú tí ó parí ní ìparí ní ìpinnu apanirun tí rògbòdìyàn aláìlágbara. negative ìbànújẹ ọkàn, ìyípadà Ẹniìtàn láti ẹ̀mí tí ó sọnù sí ọ̀mọ̀wé kan àti ní báyì òṣèré kan ti lọ sínú àwọn ìṣẹ́jú ìkẹhìn tí ó kù lẹ́hìn gbogbo àìbalẹ̀ náà. negative Ere ilẹ̀ Nàìjíríà àgbéléwò mi àkọ́kọ́ Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo ti ṣe alábàápàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èsì àti ìròyìn tó ń sọ nípa pé Nàìjíríà tí ni ile ìṣe tó n sàgbéjádé èré àgbéléwò. Bí ó tilè je pé èyí wúmi lórí, n kò rí eré ilé̩ Nàìjíríà kankan wo àfi ìgbà tí mo kàn sàdéédé rí èyí lórí Netflix. Lóòótọ́, nǹkan ti mò ń retí ni mo rí. Mo rí àwọn ibi tí w̩o̩n kó ṣe dáadáa látàrí àìsí irinsé̩ tó múnádóko. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ibi kọ̀ọ̀kan wà tí wọ́n ṣe dáadáa ati ìdarí tó tókasí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan ni àwọn osere ṣe, ère yìí ni àwọn kùdìè̩kudie̩ tó pò̩. Abala àwòrán yíya kò dára tó bẹ́ẹ̀ sì ni ère sise àwọn òs̩èré kò fi wọ́n hàn bí akó̩s̩é̩mo̩s̩é̩. Lóòótọ́, ǹ bá tilè̩ ní kí n fojú fò gbogbo àwọn kùdìè̩kudie̩ yìí ká sọ pé wàhálà ńlá tí ere yìí ni kò sí nibẹ. Ère yìí tí gùn ju (ìsé̩jú mó̩kànléló̩gó̩fà) bẹẹ si ni o ti fà nílè ju. Ó yẹ kí wọ́n gé ìtàn yìí kúrú yálà nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ ní tàbí nígbà tí wọ́n ń ṣe àgbéyè wo rẹ. Ibikan wá ní ibi ìparí rẹ tó wú ni lórí bí ó tilè̩ jé̩ pe mo wòye rẹ̩̀ kì ó tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò pẹ́ rárá àti pé ìgbéjáde abala yìí ti pé̩ jù láti yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà nipa ere tó gùn tó sì tún fà nílè̩. Síbẹ̀ síbẹ̀ tí ó bá ti gbó̩ nípa Sinima ilé Nàìjíríà tí ó sì tún ń wù ọ láti ni ìrírí rẹ̀, a jẹ́ pé mò ti fi ìkan hàn ọ́. negative Láìlóríre, a ò lá fara dàa ìbọn Cowboy, ìbọn àlàfo, asoí wón ranrí wọ́n fi dábírà, eré tíwónse tí ó bí yàn nínù rí kòlébùn ríkòsí se pàtàkì, ayẹyẹ rí wón fi rántí eré tí wọ́n tí fi hàn tẹ́lẹ̀ tí wọ́n kójo pọ̀ tí kòsì nítumọ̀ láti bèrè negative Ó n ṣe ní àánú, fíìmù náà nígbàgbogbo jẹ́ dáradàra àti onílọ́ra pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn àkókò ọ̀ṣẹ̀ ọ̀sán púpọ̀ ti ìfihàn ẹ̀dùn. negative Eré náà ò dára, àṣejù díẹ̀ lát'ọ̀dọ̀ àwọn òṣèré (bóyá ìdarí tí pọ̀jù) sùgbón lílò rẹ̀ dára. negative once upon a night' jẹ ọun tíkò níyì negative bó sewà, kò láyè tàbí ìwà torí aní làti se oun púpọ̀ kóbalè wọlé tán negative Fíìmù yìí jẹ́ aláìdùn púpọ̀ fún sinimá. negative Kò dára negative apeè ní ajínigbé nínú àhámọ́ fun odidi àádọ́ta ìséjú, wọ́n fi tipátipá jẹ́ kalọ sí ìrìn àjò asegbyinti, àìfọwọsí negative Kìnnìún yìí kò lè bú ramúramù tó. Ṣé ẹnìkan fi ìtàn eré Netflix wọn tó ti fìdí rẹmı ṣòwò sì Nàìjíríà ni? Àfi bíi aṣọ àwọ̀díje ẹgbẹ́ t’ó fìdí rẹmı nínú àșekágbá Super Bowl ni. negative Ì fagídí sọ ìtàn àti ìṣọwọ́ ṣeré tó ti ni l’ójú ni àwọn ǹkan tí ó jẹ́ àdámọ̀ ère rádaràda tí ń pe ara rẹ̀ ní ohun tí kò jẹ́ yìí. Ó lè má rọrùn fún yín láti gbà ṣùgbọ́n eré yìí dàbí ayédèrú Isoken. negative eré tíkò ní ìtumọ̀ àwàdà leré yí negative Ẹ̀bu burúkú ! Èyí ni Eré oníṣe burúkú tí mo ti rírí ní Ilé ayé mi! negative Àkójọpe Ere náà ki ṣe èyí tó burú. Ọkàn rẹ sì wá ní ibi tó dáa gangan, ṣùgbón óṣeni láànú láti wo ni ọ̀nà oríṣiríṣi negative Bíotìlẹ̀jẹ́pé ere náà dá bí ti akọ́ṣẹ́mọsẹ́, má jẹ́ kí ó mú ọ́ bíi òmùgọ̀. Ibi ni negative Kò s'órí kò s'írù, ìtàn burúkú àti ìranù tó wọ́n. Ó tilẹ̀ le láti wò. Nkò lè ròyin rẹ̀ fun elòmíràn negative dídára ìràwọ̀ wọn kò ní nínú fíìmù yìí negative Ẹ̀rín pa mí. negative nkan àìtọ́. rẹwà. kò rẹwà negative Ojú gbà mí tì. Àwọn òsèré tó kópa nínú eré yìí rí àwọn ibi kọ̀ọ̀kan se dáadáa nibe paapaa, Kabiyesi ati Amina, sugbon awon osere to sugba won(Maladi),ko tile yeni boya won kan ni ki o maa pa wa lerin ni nitori o ye ki o fi ara si ju bi o ti se lo. negative Oshi! Nkò lè sọ fún ẹnikẹ́ni nípa rẹ̀. Kò dá b'ó jẹ́ ọmọdé. Ère náà rínílára. negative Láì sí àní-àní, eléyìí wà lára àwọn sinimá tó burú jù tí mo ti wó. negative Sinimá àtúngbékalẹ̀ tí kò dára rárá. Ní ìbẹ̀rẹ̀ eré yìí, ní ibití Áhánásì ti ń rántí ẹni tí wọ́n da iná sun, bí wọn ṣe darí ibẹ̀yẹn kò dára tó. negative Rádaràda ohun òṣì kan sìì láti ọwọ́ NETFLIX ní àkókò yìí. negative Gbogbo ọ̀nà ni ó fi mẹ́hẹ̀e negative Mo fo èyí. Kò sí ọna ti mo lè fi wọ gbogbo kiní yìí negative Ó má kàbámọ́wípé o wo eré yìí. negative Tí Kò dára negative Ìpìlẹ̀ tí ó pọ̀jù. negative Àwọn Mílíọ̀nù' jẹ́ pàtàkì jíjá òsùnwọ̀n tí kò ní ìtìjú tí àwọn ìwé àfọwọ́kọ 'Ocean's film series'; ṣùgbọ́n kò wú wa lórí rárá. negative Gbàràdá jé ìjìnlẹ̀ eré yorùbá ìdúmọ̀tà pẹ̀lú gbogbo ìwà wèrè tó bá abala nollywood yẹn wá. negative Ẹni mímọ́ Isrélì! Kínni Genevieve rò pé òún ṣe? Eré? Ìwà ìbàjẹ́ tó gajù ni èyí. Olùkọ'tàn naa kò dáa tó. negative Àsopò eré tí ó tíi burú jù. negative Òṣì lásán negative """Special Jollof"" tún jé̩ eré mìíràn tí àwọn òs̩èré Nollywood tó wà ní Turkey ṣe ṣùgbọ́n tí kò gbádùn rárá. Eré yeye ni a fi ṣe bẹ̩́ẹ̩̀ ni ó kún fún onírúurú àwọn iṣé tí kò kún ojú òṣùwọ̀n. Kò sí ń kankan nínú eré yìí. Ìfàkókò àtowó ṣòfò lásán ni." negative Gbogbo ẹnu ni mo lè fi sọ wípé, bi Lúnà ṣe gba ìgbàkugà gan-an, ìtàn tó wọ̀ ni lára ju Chief Daddy apá kejì lọ. negative Mí o mọ iye ìjàmbá ọkọ̀ Òfurufú ti o waye ni orilẹ èdè Nàíjíríà ,bẹ́ẹ̀ni Ere to jade ni ọjọ́ márùn-ún . negative Fíìmù náà kò bá ti dára tí ó bá jẹ wípé wọ́n ná owó síi dáadáa negative Láìsí ìtọ́sọ́nà àti ìtumọ̀, eléèyí jẹ́ kan tó gùn , tó le tí yóò ti ò fi le dára níwájú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí tí àwọn tí olùdarí àti àwọn òṣèré. negative Kò yẹ̩ láti gba àkókò rẹ negative Réderède gbáà! Kò wọ́ pọ̀ kí n pa sinimá tì, ṣùgbọ́n, n kò le wo èyí tán. Lẹ́yìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni mo dáa dúró. Má fi àkókò rẹ sòfò. negative Fún ohun tí kò bá jẹ́ sinimá tó lágbára, tí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ inú rẹ̀ kàn ń ṣubú lé ara wọn, ó ṣeni láàánú pé wọ́n kàn bú omi rín ni. negative Ó tini lójú pé àìle ṣe iṣẹ́ à ṣe parí lórí ohun gbogbo kò tán sì àwọn àpẹrẹ tí a ti mú ẹnu bà tẹ́lẹ̀. negative Ìdúró náà kún fún àwọn ìràwọ̀, ṣúgbọ̀n kò tan ìmọ́lẹ̀. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń tọ́jú wáìnì kan tí kò tíì dàgbà, bóyá tí wọ́n fi èso àjàrà tí kò tíì pọ́n ṣe. negative Eré yí kò kún tó. negative Fíìmù yìí ó dáa rárá bẹ́ẹ̀ sì ni kò dùn. negative òsì ni ènìyàn tó jẹ̀bi negative Mo nílò o láti wo fun ìwúlò ẹ̀ka ẹ̀kó negative Ó ti falè̩ jù. Ifàkókò ṣòfò lásán ni negative Kò dùn. negative Eré oníṣe náà jẹ́ òbu ẹyin fún Nollywood negative Nígbà tí mò ń wo sinimá Paramọ́lẹ̀, ohun tí Nọ́líwuùdù jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ yé mi ni. negative Pẹ̀lú gbogbo kàrámọ̀ ìpani ni ẹ̀ẹ̀rín àti ìṣọwọ́ ṣeré tí ó ń fò sókè sódò láàrín ín pé wọ́n ti tẹșan mọ́ ọ jù àbí pé wọn kò tilẹ̀ ríi ṣe rárá. negative Ìsejáde ti wà ní gbogbo ibí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kíkọ́ kò ní ìdàgbàsókè ní kíkún. negative Ìfàkókò àti àwọn oun èlò ṣòfò ni sinimá yìí negative Wà á kórira rẹ̀ negative Eré naa dára ṣùgbọ́n ófi wákàtí méjì ṣ'òfò negative Sa gbogbo ipá tí o le sà; 'Ọlọlá jùlọ fi hàn pé òun ò k'ójú òṣùwọ̀n, nípa àìlè mú gbogbo ìlérí tó ṣe nigba tí ìbò m bọ̀ ṣẹ. negative òṣì rándanràndan kò tó láti jẹ́ àwòrán Àwọn Òṣeré lẹ, Akọ ìwé náà láti ọwọ́ ẹni ọdún méjìlá. Ohùn wọn kò ká ojú òṣ̣ùwọ̀n negative Gbígbé ojú ìwòye, ọ̀nà eré nípasẹ̀ ogun ábẹle Nàìjíríà tí àwọn ọdún 1960 yípadà láti jẹ́ àṣìṣe lílọ kiri nínú èyítí ìṣelọ́pọ̀ tí a yàn láwùjọ yíì kò le gbà padà pátápátá. negative Ìlọsíwájú kò ṣe dáradára fún díẹ̀ nínú àwọn ìwòyè náà. negative The Final List jẹ́ kìkìdá òsì. negative Ní òótọ́ ló pani lẹ́rìn-ín, ṣùgbọ́n òșì pátá gbáà ni. Ère yìí dáni lára yá o. Kí la tún fẹ́ẹ́ sọ? negative Mi ó kaun ọkùnrin tó dárí nínú eré náà bẹ rí. Ní tótó Team sylvia. Ọkùnrin na ṣeré ayo negative Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí ó le ra fíìmù tí ó burújù jẹ́ iye owó. negative ó mú ni rẹ̀wẹ̀sì kò sì ní kókó. Ní ìparí , àwòrán náà já ni kulè ni gbogbo ọ̀nà . negative """Ojúlówó ìyàwó ilé tí èkó ní àgbègbè tó ga""kò dára" negative Ẹ̀gbin . Òun òmùgọ̀ àti afọ́kungbému ni ìtàn ní ẹ̀ka akọ àwòrán ní orílẹ̀dè Nàìlíríà negative Yàgò fún èyí abala ti ìnira nípa gbogbo àwọn ọ̀nà pàtàkì. negative Ó sẹ́ kù sí ibì kan. Ẹ̀rọ. Àìlọ́gbọ́n. Ní òtítọ́ sísọ. negative Lionheart kò ṣe tàbí sọ ohunkóhun titun. negative """Mofe ni mofe"" jé̩ àkànṣe ère àgbéléwò tí a ṣe fún African Magic Yoruba tàbí fun YouTube. Kò ní nǹkan ṣe pe̩lu sinimá." negative Fíìmù náà gbìyànjú láti lo ìfura láti ṣe àfihàn díẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn náà, ṣùgbọ́n wọn kò ṣiṣẹ́ dáradára. negative Ó kọmi lóminú. Eré ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Nọ́líwuùdù tó tún ń polongo àtúnbí ọmọ lẹ́yìn Jésù ni. negative Orí awọ àtijọ́ ni ìlú. Ìtàn tí kò dára ṣùgbọ́n ó fara sìn láti dàbí òtítọ́ negative Bí èròǹgbà rẹ̩̀ àti ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ṣe dára tó, Black November tí fà nílè jù láti ni ipa tó yẹ. negative bí òwe náà selọ 'gbogbo tóún dán kọ́ni wúra' ' àwọn tóún gbé lékò tóún dán kọ́ni wúra' negative Ìmẹ́lẹ́, Àìlérò. Àṣìṣe. Oun tí kò ṣẹlẹ̀ rí negative Bridal Shower' sha gbogbo àwọn òsèré tí kò dára jọ láti gbé eré jáde. negative Olúwa ò! Kíni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wò fún bíi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú yìí? Mo tiraka títí ṣùgbọ́n kò bójú mu náà ni! Báwo ni ẹnìkankan ṣe gbà á lérò pé ó yẹ kí wọ́n ṣe sinimá yìí jáde? negative Wòó! Ó burú jù negative Eré rádaràda pátá́ gbáà ni. Kò tilẹ̀ ṣe é máa sọ,réderède, ráunràun, òṣì rata má rayọ̀. Kí ni wọ́n tilẹ̀ ṣe sinimá yìí gan fún ná?! negative Háà ẹ gbàmí! Radáràda. Ṣùgbọ́n a ti rí àwọn sinimá tí ó ń sọ nípa ìjàmbá burúkú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà àti wípé eléyìí kò jẹ́ tuntun. negative Ìtàn náà kò le tó.' Mai'Muna' jẹ́ eré ìrìnsẹ̀ tí kò yẹ fún àkókò ẹnikẹ́ni. negative Ohun tó bàjẹ́ àti irú ibi tí Ọwá ni gbogbo ibi ni ti ìpílẹ̀ negative fíìmù tí ó dára jù. Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ tún nílò ìyàrá. negative Kò bójúmu rárá negative Ááwù. Ó janikulẹ. Igi búburú pẹ̀lú èyí tí ìlú ọba ní èyí negative Sísọ ìtan ìyà tí àwọn akoni jẹ àti ojútùú sí ìmúnisìn, '1921' le. negative àìní oníìwé- ti agbára fíìmù yẹn. negative Kò ṣeé ròyìn. Ìranù ni èyí. negative Mo kórira rẹ̀ negative Pẹ̀lú àwọn kùdíẹ̀káàtóo Nollywood, Jẹ́ kí á ya ìtàn náà negative Mo rò ó wípé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ìtara fún sinimá ṣíṣe. Èyí dára. Ẹ máa tẹ̀síwájú negative Ẹ má bínú, n kò kàn féràn rẹ ni. Fíìmù yìí jẹ àpẹrẹ ńlá ìṣe tó wuni lórí fún ìrántí ṣùgbọ́n tí ó tètè sú ènìyàn nípasẹ̀ àwọn òsèré tí kò kún ojú òṣùwọ̀n àti àwọn tán tí kò farapé̩ra. Bẹ́ẹ̀ni, mo ti ka ìwé náà. Ń kó reti láti ri ìtúpalẹ̀ o̩lórò̩só̩rò̩ bíkòse kókó inú re̩ nítorí ìwé yìí menuba ọ̀pọ̀lọpọ̀ akópa. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Fíìmù yìí sọ nípa ìtàn ìgbésí ayé àwọn ìbejì kan, Olanna (Thandie Newton) àti Kainene (Akina Noni Rose) lé̩yìn ti Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn Òyìnbó amúnisìn àti pé nípasẹ̀ ogún abé̩lé Biafra, nígbà tí àwọn ẹ̀yà Igbo fé gba òmìnira. Fíìmù yìí (tó farapera pẹ̀lú ìwé) gbìyànjú láti sàfihàn àwọn gbajúmò̩ obìnrin méjèèjì, ìbásepò̩ wọn pẹ̩̀lú ọkùnrin àti ìbás̩epò̩ wọn láàárín ara wọn gẹ́gẹ́ bí a ṣe sàfihàn rẹ̀ ní ìfè̩gbé̩kè̩gbé̩ pẹ̀lú orílè̩-èdè Nàìjíríà. Mo lọ wo fíìmù yìí láti sàtìle̩yìn fún sinimá ilé̩ aláwò̩ dúdú Áfíríkà àti láti fi ìdùnnú hàn fún Olùdarí láti Nàìjíríà tó ń darí ère ńlá yìí. Ṣùgbọ́n èdùn ọkàn ni àbájáde rẹ̀ tó kún fún iṣé tí kò dára. negative Dájúdájú n kò f'ọwọ́rẹ̀ sọ̀yà. 'Detour' jẹ́ òmùgò gidi. negative Eré tí ò dára negative Àkọ́kọ́ ìṣòro nínú eré yìí ní lati jẹ́ àgbà òṣèré. Ǹǹkan míì ni ṣíṣe eré gan-an. negative Sista Sista jẹ́ ìfowósòfò míraǹ tí Enyimma Nwigwe hàn nínúu rẹ̀, ló á di eré rádaràda méjì. negative Eré tí kò ní ìdí negative Ní èrò tèmi eléyi kò yẹ fún Netflix negative Ko ṣe iṣeduro fun awọn ọkan ti o ni oye. negative Àwọn ìyípadà nínú fíìmù náà jẹ́ rògbòdìyàn àti ká fi orin sí àárín eré. negative Fíìmù tí ó ní ìtara tí ó yẹ àkíyẹ̀sí, láànú kò ṣe àpéjọpọ̀ ní agbára bí ò ṣe nírètí. negative The Final List' jẹ́ ìsẹ́po tí kò wúlò aláìlópin. negative Ìtàn náà kò ní àtìlẹ́yìn àti pé kò ṣáfikún ǹkankan sí oríṣi àwòran tí ó gbìyànjú láti ṣojúṣe. negative Eré yìí ní ìpinu tó dáa àtipé ó sì tọ́ ka si kókó , ṣùgbọ́n ó bá ni nínú jẹ pe àwọn tó ṣe eré náà wón ò ká ojú́ òṣùwọ̀n tí ó tọ́kasí oun tó wọ ni lára negative kò rí bẹ́ẹ́ níbí. 'Ajíbádé' jẹ́ aṣoju eré orí ìtágé tí kò ní ojúlówó ẹ̀bùn kankan lẹ́yín rẹ̀ negative Àtúnṣe rẹ dára, wọn kò ṣeé dáadáa negative Mo ní ìrètí fún ní ibẹ̀rẹ̀ ṣùgbọn ó tètè kú negative Èyí jẹ́ ohun tó burú ní gbogbo ọ̀nà . negative Ní tòótọ, wọ́n rẹ́wa jẹ ni. negative Eré oníṣe náà fún wa ní ohun tí wọn ró Ohun fún wa. negative Owo titun negative Àsọdùn pọ̀ nípa eré náà, kìí se oun tí mo retí rárá. negative Fíìmú yìí jẹ́ ìwọ̀sí gbáà negative Big fat lie', kò panilẹ́rìn, kòsì tó ojú òsùwọ̀n negative Rants Queens' jẹ́ ìkàa nkan sí pẹ̀lú òmùgọ̀ negative Ó dàbí wípé wọ́n mànánmàn ṣe fíìmù yìí láti kàn dá àyà já àwọn olùwòran ni. O jẹ sinimá tí o dun ni láti wò. negative Àìdáa tó. Òsì. Àbùkù. negative Sinimá tí kò dùn rárá tí àwọn òṣèré inú rẹ̀ kò tún wá ṣe daádaá. negative Ó pániláyà! Olúwa mi! Kò yẹ fún ìgbóríyìn, nkò lè gbàgbọ́ pé wọ́n gbé ìranù yíí jáde. negative Irú ̀ifàsìkòsòfò ńlá wo lèyí! Àwo̩n gbajúmò̩ òs̩èré kò ní ìtàn Kankan láti so̩. Kò sí ìdarí Kankan tàbí àkòrí tó fogbó̩nyo̩…onírúurú ìs̩è̩lè̩ àyàbá látorí àkòrí apá kìnínní…. negative Kò ṣeé ròyìn fún ẹlòmíràn torí, pẹ̀lú bí àgbékalè rè ṣe dáa tó, àwọn òsèré inú rẹ̀ kò ń ṣe ìranù ni. negative Ó yọrí sí àìlọ́pọlọ àti àìkún ojú òṣùwọ̀n. negative Àwọn àyíká tó dùn, ìwé búburú negative Sinimá àgbéléwò yìí lé̩tò̩ó̩ sí àmì è̩ye̩ sinimá àgbéléwò àkó̩kó ló̩dún 2022 tó ní àjálù. Fún àwo̩n tí kò mo̩ ilé-is̩é̩ Nollywood dáadáa, sinimá àgbéléwò yìí kò jé̩ ìté̩wó̩gbà s̩ùgbó̩n fún àwo̩n tí òye Nollywood yé, èyí burújáì. negative Òkú àti ọmọ ta' ni a jẹ́ ki ó lọ sílẹ̀ nípasẹ̀ sísọ ìtàn àìṣàn, ṣíṣe púpọ̀jù àti gbogbo àwọn iṣẹ́ ṣíṣe àìníìdí yíká. negative Nọ́líwuùdù tún gbé ìṣe wọn dé. negative Ìṣekúṣe àti àgbéjáde gbá à negative Ìwúnilórí ṣùgbọ́n kìí ṣe ǹkankan tí ó fanimọ́ra tàbí ìyanilẹ́nu. negative Bí ìgbàtí ènìyàn kàn ń jẹ ẹ̀wà tí ó tí bàjẹ́ ni wíwò sinimá yìí jẹ́. negative Ìtàn sísọ burúkú negative àìṣedéédé àìdọ́gba ti melodrámà àti àwọn ẹ̀rù ti ogun abẹ́lé negative Kò ṣe é wo. negative Àìní i ìgboyà tọ́ka ojú òṣùwọ̀n ni ipa ètò ìṣẹ̀dá iran ti oluro Ìtàn gbọdọ̀ jẹ́ ti àròjinlẹ̀ ní ti ọpọlọ negative Kí ènìyàn fi owó wo eré yí dàbi kó ra oun tó ma suu. negative "Ní ìdàkejì sí àkọ́lé rẹ̀, ""Ṣúgà Ṣúgà"" fi díẹ síi ẹ̀kan àti ìdádúró ní ẹnu ju adùn lọ." negative Kòbámi lára mu negative N kò ní fẹ́ sọ wípé wọ́n ṣe àwọ́n àṣìṣe ni. Bí ìgbà tí àwọn aròbó ilé ẹ̀kọ́ ọmọwẹ́wẹ́ bá kan tó eré papọ̀ ni. negative Ṣe gbogbo yín sí jẹ aláìlóye nínu ìṣe yìí. negative eré Nàìjíríà tí ń lọ lọ́ra nípa ìfipá bánilòpọ̀, ìkọlù negative Nǹkan díè nínú fíìmù yìí ló mú ọpọlọ dání negative Àwọn sinimá nínú fíìmù náà jẹ́ ìpìlẹ̀ àti pé kò ní ìgbádùn púpọ̀. negative kò dára tó. negative bóyá ìyì tódára jù nípé ó dùn gan osììní kábàmò tí obá wò negative wón fà ìtàn nàà gùn làí nítumọ̀ negative Ó já ni kulẹ̀ gan ohun tí a yọ láti Ìwé ìtàn ńlá a Half of a Yellow Sun negative Fíìmù náà jẹ́ ẹ̀rù láti sọ pé ó kéré jù, láìbìkítà àwọn òṣèré tí ó ga jù lọ. negative Guynman ṣe pàtàkì. ósepàtàkì tí ó jé òmùgọ̀ negative ìtàn tó lárágba... ìse òṣì negative Gbogbo àgbéjáde jẹ́, tí ohùn jẹ́ ohùn tí ò ṣe ní negative Àtúnwí àti ṣígọ́gọ́, 'Kasala' jẹ́ ìsọnu tí ó ga jùlọ tí owó, agbára àti àkókò. negative Àsọdùn, kò sí ìdarí negative níyanjú jẹ́jẹ́. Bíbẹ̀rẹ̀ dáradára ṣùgbọ́n ó bàjẹ́ bí ó tí ń ṣiṣẹ́ gùn jù fún àwọn oníìwé-dára. negative Fíìmù ẹ̀gbin àti ti ẹrú ohun ni fíìmù tí ó burú jù tí mo ti rí, Ṣíṣe rẹ̀ ń gbé ní. negative àwon awòran tí wón sùn tí wón sín harun negative Iyì díẹ̀ lówà níbẹ̀ kòsì yẹ kọsan owó púpọ̀ fun negative Ìranù!Rírí fíìmù jẹ́ irú kan ìrora. negative Òun tí mo wó kò wù mí negative Àgbéyè̩wò RHH negative Ohun tí a ní ní ìparí kò níyì pẹ̀lú ìjíròrò tí kò dájú. negative orin àti à̀wọn ipa ohun kò nígbàgbogbo báramu bí ó ṣe pàtàkì díẹ̀ nínú àwọn ìwòye fíìmu náà. negative Ogbin jẹ itan nla kan nikẹhin ti ṣẹgun nipasẹ irẹwẹsi aibikita tirẹ. negative ìtàn kò lábara, bẹ́ẹ̀ni àwàdà kò burú jù. negative Sinimá yìí ,sí èmi ò, kì í ṣe ara rẹ̀ rárá. negative Eré burúkú, ìfọ̀rọ̀wérọ tí olè, àti aloju àgbéjáde ohunofin ìṣeré negative Ìtúpalẹ̀ tí kò dára. Èdè Igbo ni wọ́n sọ ṣùgbọ́n wọn fi àkọlé Hausa sí i. negative Nítòótọ́, àwọn ọ̀nà ìtọ́wò díẹ̀ sìi àti iṣẹ́ ọ̀nà láti gbe àwọn ọjà sínú fíìmù kan, láìsí nítòótọ́ bórí àwọn alábara. negative WTF Ó sú ènìyàn! Ó ti ré̩ mi gidigidi bí mo ṣe ń wo eré yìí. Eré yìí tí wà ṣáájú negative Eré oníṣe burúkú ... Eré oníṣe Nàìjíríà tí mo ti rírí . negative Kò dùn rárá negative Ayọ̀ ọtí mímu tuntun rèé o. Ní gbogbo ìgbà tí o bá ti rí àwọn òșèré tí wón wọ wíìgì ọ̀ràn tuntune, kí o sẹ́ gẹ̀ẹ́ kan mú. negative Kí lelé yìí negative Líĺò owo nílòkulò. Ó jẹ́ kí eré yìí jẹ́ asán pátápátá . Kó tún wa bárámu, ṣígọ́gọ́ àti kó móríyá. negative Fíìmù náà ti ṣe dáradára ṣùgbọ́n mi ò le mọ irú fíìmù tí ó fẹ́ láti jẹ́ àti kíni ìtàn náà títí di ìgbà tí mo dúró wíwó ibìkan ní àárín. negative Pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ṣíṣe tí ó lágbára àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, òǹkọ̀wé àti olùdarí Bíyì Bándélé kùnà láti fi ìdí ìtàn-àkọọ́lẹ̀ náà múlẹ̀ tí orílẹ̀-èdè àti ti ìṣèlú, àti pe fíìmù náà kò ṣe pàtàkì bí àbájáde. negative aláìdùn àti àìnípa àwòrán negative Wọn yàá dáadáa ṣùgbọ́n wọn kò ṣeé dáadáa. Kò wú mi lórí nítorí bí wọn tí ṣeé ni ọ̀nà ṣíṣe àti kíkọ negative ìkan lára eré òṣì tí mi ò rírú ẹ̀ rí negative Ẹ̀yà ẹ̀fẹ̀ wọn ti di ohùn tí o dùn mọ, ó ti di ohun ti wọn tún ṣe ní gbogbo ìgbà àti ohun tí a lè sọ òpin rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. Ìtìjú ni láti f'ọwọ́irú eré yìí sọ̀yá negative Ó bíni nínú òsì rínilára. negative Irú fíìmù u Nollywood yin ni,ìrẹ́jẹ ,Ìtàn atijo ,Ere burúkú negative Èyí tó wá burú jù ninu gbogbo rè̩ ni ìtàn; bí ìtàn eré Yorùbá ti ro̩rùn tó, eré yìí kò ní àyínìke Kankan tabi ìfìtànpamó̩, tabi àpe̩re̩ Kankan ó fi o̩gbó̩n àtinúdá hàn. negative Ìtàn tí ó ní adùn tí ó ní ìbànújẹ́ tí ó dínkù sí fíìmù aládùn kan. negative Ó ṣeni láàánú pé ìtàn ìgbésí ayé ènìyàn kan fúnra rẹ̀ ló wàá di ohun tí wọ́n ń làkàkà ṣe tí kò tilẹ̀ máyàn lórí rárá. negative A lè ṣe ju irú fíìmù jakujaku yí lọ negative Fún fíìmù alárinrin ẹlẹ́rìí kan, Nneka the Pretty Serpent gba àkókò púpọ̀ láti jẹ́ kí ó jẹ́ ààyè. negative kíni ohùn n tòun ṣẹlẹ̀ ní bí? Eré yìí burú gan ni, lójú kan ó ma rò wípé ṣé òún wo kọ́mẹ́dì ni tàbí Eré oníṣe negative Àwọn fíìmù ni ó ní àwọn jùlọ yẹ̀yẹ́ jíja sì ń mú láílái ́nínú àwọn fíìmù àgbáyé, àti àwọn tí ó jẹ́ ọ̀nà gùn jù. negative Àwòrán tí kò dára negative Ìpin tí ó burú jù ni pé; fún díẹ̀ nínú àwọn àìbìkítà ìdí, àwọn tí ó ń se yàn láti má tun ọ̀rọ̀ kan náà sọ, tálákà wọn jẹ́pè pẹ̀lú àtúnkọ tí ó lágbára tí ó ń farasin gan ní kíákíá. negative Lẹ́ẹ̀kan si, ẹni tó gbé eré yi jáde sìnà Eré náà kò dá lé oun kan pàto, ó kan jálu ara wọn negative Ọ̀nà sí àná kìí se àwòràn tó burújù tí a wò, kò dun, kò sì yéni tó. negative Sùúrù l' èrè' jẹ́ rádaràda negative Àpẹẹrẹ tí òṣèré tí kò ní ìbámu sí ipa nínú fíìmù yìí ni Tọ́pẹ́ Tedela. Nínú ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mai-suya ọlọ́kọ̀ọ́kọ̀ọ́-ọ̀wọ́-ọ̀wọ́, ó ti sàn jù ó sì sọ̀rọ̀ dáradára. negative Kò fọwọ́sí negative Rádaràda páta gbáà ni sinimá yìí. negative Bí àwọn àwàdà tí ó bẹ̀rẹ̀ jáde dáradára tó ṣùgbọ́n negative Inú ń bími wípé mo wo eré yìí. negative Èyí jẹ́ ǹkan àìmọ́gbọ́nwá ẹ̀rẹ̀kẹ́ tí kò ní ẹ̀mí tí ó ṣe àìṣedédé ńlá sí ìwé ńlá kan. negative Bí àkọlé eré yí ti dojú tíni tó, díè ni 'Makate Must Sell' fi yàtò sí 'Knock Out' tí Pápá Ajasco negative Oc Ukeje ló ni ìràwò kan yìí negative Ìtàn dára ṣùgbón iye rẹ̀ kòdáa negative Àwọn ohun kíkọ rẹ̀ (pàápàá Sadé) j́ẹ ìdòtí àti pé ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀dùn tí kò dára àti àwọn ipele tí ìbìnújẹ́ tàbí ìdùnnú. negative Wọ́n ṣe é fún èrè ìtàgé tí ó dun. Kò dára ní àwọn apá kan tí ó sì nira fún mi láti tesiwaju nínú wíwò rẹ̀ Ń ó lè gbà enikeni nímọ̀ràn láti wo ó negative Kò yẹ kí o wo eré tí kò sì pé ojú òṣùwọ̀n yìí negative Fíìmù dídọ̀tí Kòsí ẹ̀kọ́ kíkó kankan. Ẹjọ̀ọ́ afẹ́ apá kejì negative Eré yìí kò tilẹ̀ mú orí ẹni wú rárá. Mo kàn fi wákàtí méjì àti ogún ìṣẹ́jú nínú ayé wo eré tí kò ní ọpọlọ àti láárí kankan ni. Kò dára rárá. negative Ṣíṣe burúkú àti kíkó radarada. Riiki Hallmark ṣanẹli lè yìí negative A kò lè sọ pé ó dára, a kò sì lè sọ pé ó burú, ṣùgbọ́n kò ṣe é máa rántí. negative Ó lọ́ra gbígbé àsọtẹ́lẹ̀ negative Ní agbára, ṣùgbọ́n ó kùnà láti fà ọ́ wọlé negative Ó lè ti jẹ́ ǹkan tí ó dára jùlọ. negative já ra rẹ gbà lọ́wọ́ ọ àwòrán tóún rí ni lára yìí negative Ojútì ni 'Fantastic Numbers' jẹ́ tí a bá wo bí àwòrán rẹ̀ tí dáa tó negative Kò kún ojú òṣùwọ̀n negative Ó lọ́ra Ìseré yẹn dára, ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ jẹ́ ohun tí kò dára. negative Ní òpin kò ṣé iṣẹ́dúró. Ṣíṣẹ takuntakun láti yàgò fún ìdọ̀tí yìi láíláí; àti lórí Amóhùnmáwòrán . negative Nígbà tí a bá rò pé ó ti pari, ìṣẹ̀lẹ̀ ìparí tí ó tún mú ìdàmú díẹ̀ síi. negative Iṣẹ́ àwọn tí ó ṣẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ iṣẹ́ ni wọ́n ṣe sínú sinimá yìí. Ó dà bíi wípé iṣẹ́ àkànṣe kékeré ẹnìkan láti ilé ẹ̀kọ́ ni, kò jọ ojúlọ́wọ̀ rárá. Bí àwọn òṣèré ṣe ń ṣe nínú eré yìí kò báamu rárá àti wípé, ìsopọ̀ gbogbo eré yìí kò ní láárí. negative Àwọn ìṣe náà fọ́jú pọ̀ negative Sinimá yìí ni ó yẹ kí a máa pè ní mẹ́rin nínú ọ̀kan ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe polówó Kóòkì nínú rẹ̀ kò jẹ́ kí àsopọ̀ rẹ̀ dára. negative """My London Slave"" kò tilè̩ yẹ̩ fún wíwò rárá. Ìfowójóná ni. Kò sí ẹnì tí yóò wọ ere yìí tí inú rẹ kò ní bàjé̩ pé òun fowó jóná torí pé wọn ṣe àgbékalè̩ gbogbo nǹkan tó wà nínú eré náà ni lati bà ọ́ nínú jẹ. Lóòótọ́ ni. Nítorí náà, mo bẹ ọ kí ó má sún owó rẹ níná." negative Igbesi aye gidi lórí ère buruku, paapaa lati ọdọ awọn onijagidijagan ni fiimu yii negative Ìtàn ìyanjú jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀jù lórí èdè-àìyedè, ìró àti ètò àrékérekè. negative Titun Alákadá jẹ́ irọ́ lásán ni negative MÁ WO SINIMÁ YÌÍ negative Eré yìí kò mú ọgbọ́n wá rárá negative Mi ò mọ Ọkùnrin, Eré òní ṣe yí Ka mi kò ese mi dùn mi. negative Kò s̩e é fo̩wó̩s̩ò̩yà rárá pé ó dára láti wò. negative Àṣìṣe àkókò nínú fíìmù náà ni gigun rẹ negative Nígbà tí òun kan ṣoṣo tí àwọn ènìyàn ń sọ dára dára nípa ère jẹ́ àwò, ó yẹ kí ènìyàn mọ̀ pé òun kò ní gbádùn ère náà. negative Níkẹhìn, kò ní ìtàn gidi èyíkèyí àti níwọ̀n bí ìṣelọ́pọ̀ bá kan. negative À ti ó dára ìtàn dabarú nípa búburú screenplay negative Ìwé tí ó lágbára ti ṣe láìsí agbára.. negative Mi ò bá ní ìfẹ́ rẹ̀ tí ó ba jẹ́ ti Ọmọbabìrin Vitarah negative Irú ìtìjú! negative Awada Nollywood gbòòrò nìkan ni ipò ṣe o ni ì́dánilójú nítòótọ́. negative Ẹ̀dà àti fíìmù tí kò dùn negative èmí tóburú, kòrẹ́rín, ológe negative fíìmù yìí jẹ́ aláìdùn púpọ̀. Ìrẹ̀wẹ̀sì púpọ̀. Púpọ̀ púpọ̀. negative Ó ṣe pàtàkì láti yọ Eré oníṣe náà kúrò láti leerì nínú àwọn Media tí o fi hàn ati ojú ríran ọ̀hùn tóún ṣẹlẹ̀ ní agbègbè wa ní òde òní tó fi arapẹ́ negative Òkú náà àti ọmọ ta' jẹ́ aláìṣedéédé aláìbìkítà nínú ohun gbogbo. negative Eré lásán-làsàn tí kò yẹ kí wọ́n ṣe rárá ni. negative Kín ni rádaràda tí mo wò yí! negative Àwọn tí kò kọ́ iṣẹ́ yanjú ló ṣe àsopò eré yìí. Mo bẹ̀rẹ̀ síní wò ó, ṣùgbọ́n kò bára wọ́n mu, wọ́n kàn ń so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́ ni. Èyí ló jẹ́ kí n pa á tì lẹ́yìn ogún ìṣẹ́jú. negative Ìjákulè̩ tó dùn ni dọkàn ni. negative O diti tán yanyan gàn si ohùn toun lo lọ́wọ́ negative Àṣìṣe lásán. 1985 ère India pè, wọ́n fẹ́ ìwé ère wọn padà. negative Ó fì, kò dáa tó, kò wu ni bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú ọgbọn dání. negative Bóyá ó súnmọ́ kókó-ọ̀rọ̀ náà láti sọ pẹ̀lú mímọ́ tí ó ń béèrè. negative Àwọn òsèré jẹ́ ńlá, ṣùgbọ́n àwọn àpéjọ eré kò lágbára. negative Wíwò eré mú mi lọ́ra negative Ó bani nínú jẹ́. Ó yà mí lẹ́nu gan-an ni pé Netflix lè jẹ́ kí àwọn tí ó ń wọn eré àgbéléwò wọn fi ojú wọn rí réderède tí wọn ò rí owó gidi fi ṣe yìí. negative Ní ìwò àti rílára ti eré kan láti ọdún un 1985 àyàfi pẹ̀lú àwọn ìyípo díẹ̀, ìpágọ́ díẹ̀, kò sí ìyànílẹnu, ìfura dìẹ́ àti àpéjo eré tí ó gùn púpọ̀. negative "Àhunpò̩ ìṣé̩ ìmé̩lé̩ tí kí í ṣe ojúlówó ni ""Social Media 101"". Isẹ́ ọwọ́ àwọn tó ń ṣ̩e àgbélè̩ro̩ sinima ni èyí. Àwọn ló ń sọ isẹ́ onísé̩ di tiwọn. Àpẹrẹ sísọ ìṣe onísé̩ di tẹni ni ""Social Media 101"" jé̩. Kò sí àfihàn ọgbọ́n àtinúdá kankan ní́bè̩." negative Ìpílẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn jẹ́ ìyanilẹ́nu díẹ̀ síì ju àwọn pàtó tí ìtàn ìtànjẹ àti akíkanjú yìí, èyítí kò ní ìjìnlẹ̀ ìwà tó pé àti sojúrigindin alayé. negative ìfàkókò ṣòfò ohun tí mo níìfẹ́ẹ́ sí tàbí tí ò ká mi kò. . Kò sí ǹkankan Ó ń su ni!! negative ÀSOPÒ ERÉ YÌÍ Ń MÚ ORUN KUN ÈNÌYÀN. Ó wà lára àwọn eré ilẹ̀ Nàìjíríà tó rí rádaràda jù tí mo ti wò rí. negative Korọrun lati wo negative fẹ́rẹ̀ dàbi sinimá méjì tí ó yàtọ̀. Ìtàn náà nílò ìtúmọ̀ tó súnmọ́ sí ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí n ṣẹlẹ̀. negative Ànfàní sọnù negative Èyí kìí ṣe sinimá rárá. negative nkantóbani lẹ́rù lọ́pọlọ,Nollywood dárà!!! ọjọ́ kẹrìnlá osù kẹwá negative Sinimá yìí gùn ṣùgbọ́n kò wu’ni lórí rárá. negative Pé Nọ́líwuùdù yóò lè ṣe sinimá gidi kò dájú rárá. negative Ọ̀nà àgbà wo ère Nollywood ó burú bẹ́ẹ̀ni ò tèrè bàní bẹ́ẹ̀ni óún mú nú bíni negative Mi ó lè sọ wípé eréoníṣe yí ni ọpọlọ. negative gan àìrọrùn. negative Ó bajẹ́ gan negative Gbogbo ohun tí ó yí fíìmù yí ka ni ìfi tipátipá pani lẹ́rìn-ín lọ́nà tí kò rajaja. negative Bótilẹ̀jẹ́pé ẹ̀dọ̀fú kò pọ̀ jù, Ìyàlẹ́nu kìí ṣe ǹkan. ìdíwọ́ yẹn le ti gba oògùn àti ẹbọ ṣùgbọ́n, Síbẹ̀síbẹ̀, ọkàn kìnìún dára gaan. negative Ìfàkókòṣ'òfò míràn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìranù ní Netflix, inú mí dùn pé ọ̀fẹ́ ni, nkò san owó fún àkójọpọ̀ burúkú yii. negative Níkẹhìn, ìpànìyàn nípasẹ̀ àwọn ọ̀ràn tí ó nira tí ìṣè-ṣe àti iró, 'Hire a Woman' jẹ́ fíìmù tí kò ní idán gidi èyíkèyí. negative Eré àtìgbàdégbà Eré eléyì kàn ń fi ara rẹ̀ pe eré bàálù ojú òfurufú tí ó ní ìjàmbá ni jàre. negative Clustered Colours' dà bí ìpanu tí kò wón tí kò sì ní ń kankan nínú. negative Kí lóde tí wọn kò ṣe ohun gbogbo parí. Kí ló ṣẹlẹ̀? negative Fíìmù yìí dá lórí àrùn ẹ̀bólà ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ ìbànújẹ́ púpọ̀ àti pé kò ṣe ńlá bí Mo ti rò pe yóò jẹ́. Ní òtítọ́, kìí ṣe ohun tí mò ń retí, pẹ̀lú. negative Kò yẹ kí o wo sinimá yìí negative Ìsejáde àti ohùn orin bá ìtàn tí ó dára jẹ́ negative Ó dun’ni pé sinimá ayọ́mẹ́yẹ ni àti pé, sinimá yẹpẹrẹ ìgbà dé ìgbà tó báni lẹ́rú. Ohun kan ni pé, ẹ ó mọ̀ pé ilẹ̀ Nàìjíríà ni ó ti wá. negative Àti síbẹ̀ míran ìpa àwàdà. Àwọn òṣèré orí ìtàgé gan kò gbà. negative àwò tó dìpò ódàbí oun tíkò wọ́n tó ní nkan tó pọ̀ tó jẹ́ asán láyìká oun tó kéré negative Èmi kò wo gbogbo rádaráda tí wọ́n pè ní sinimá yí tán jàre. N kó tilè le gbé e lé òsùwọ̀n ìpele kejì . Dájúdájú, eré yìí kàn tẹ́mbẹ́lụ́ ìran àwọn ènìyàn kan ni. Ìdójútì ni pé ilè Adúláwọ̀ lèyí ti wá. negative Kò sí òun to dára nipa àwòrán yìí negative Ìtàn ìtàn jẹ́ aṣiwèrè ó sì ní àwọn àwàdà tí kò tọ́ àti àwàdà. negative Eré sísé kò jé bàbàrà, ósì tún se ìgbélárugẹ ìdáríjì fún ọkùnrin tó n lu ìyàwó rẹ̀, eni tó n fi'pá báni lòpò, tó tún bá ọmọ ìyawó rẹ̀ sùn. negative Ère yìí dà bí oun tó ṣekú láti ayé àtijó. Ìf'owósòfò pátápátá. negative Báyìí, kíkún àwọn ògbóǹtarìgì olólùfẹ́ sinimá ni oorun lórí owó gegele tí wọ́n san kìí ṣe ìwà ọ̀daràn ní gbogbo ìgbà. negative Ìkún omi tí kò ní ìwọ̀n tí àwọn àbùdá àìṣedéédé orísirísi ara fíìmù 'Ó dára' yìí. negative Ẹ́kọ́ tí ó dára, ṣíṣe rẹ kò dára negative Àwọn apá kan nínú eré yìí dá bíi àgbélẹ̀rọ lórí kí àwọn òșèré méjì lè rí ǹkan jà sí. Àwọn òșèré kọ̀ọ̀kan gbìyànjú bẹ́ẹ̀ àwọn kọ̀ọ̀kan kàn ń mú inú bíìyàn ni. negative Ẹ̀tàn Hollywood kan negative ìtàn tó daa tí àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ bà jẹ́ negative Bàbá olóyè kejì jẹ́ àìmọ́gbọ́nwá, èyítí yóò jẹ́ ìfàradà tí ó bá jẹ́ kí a rẹ́rìn nígbà gbogbo. negative OMG kíkégbe Kí ní Kókó. Ìbánisọ̀rọ̀ ,ṣíṣe rẹ̀,ohùn orin rẹ̀ negative "Ní ìrora lọ́ra àti ẹlẹ́sẹ̀ ẹ̀rù eré tí àràtuntun nìkan ni ""Ó wà láti Nàìjíríà!""" negative Ìjákulè tó dun ni. Ó dun ni láti jókòó wòó tán. N sọkún. negative Ọ̀ràn tí òkánjúwà wíwuyì Bàjẹ sínú ní ipele àpótí-kíká negative